Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  May 2013

Ṣé Wàá Fọkàn Tán Ọlọ́run?

Ṣé Wàá Fọkàn Tán Ọlọ́run?

KÁ SỌ pé o ní ọ̀rẹ́ kan tó o fẹ́ràn gan-an, àmọ́ ó ṣe nǹkan kan tó rú ẹ lójú. Àwọn kan sọ pé ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ ṣe kò dáa, wọ́n sì dá a lẹ́bi pé ìkà ni. Ṣé wàá yára gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ láì tíì gbọ́ tẹnu rẹ̀, àbí ńṣe ni wàá kọ́kọ́ gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ? Tí ọ̀rẹ́ rẹ yìí kò bá sí níbẹ̀, ṣé wàá mú sùúrù kó fi dé, tó ò kàn ní dá a lẹ́jọ́ láìdúró gbọ́ tẹnu rẹ̀?

Kí o tó fèsì, o lè fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yẹn. O lè béèrè pé, ‘Báwo ni mo ṣe mọ ọ̀rẹ́ mi yìí tó, àti pé kí ló mú kí n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?’ Ó dára tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ rò ó wò ná: Ṣé kò yẹ́ ká rò ó sọ́tùn-ún rò ó sósì kí àwa náà tó parí èrò lórí ìbéèrè nípa bóyá ìkà ni Ọlọ́run?

Ó lè ṣòro fún ẹ láti lóye àwọn nǹkan kan tí Ọlọ́run ṣe. O sì lè máa ṣe kàyéfì nípa àwọn nǹkan míì tí Ọlọ́run jẹ́ kó ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ fún ẹ pé ìkà ni Ọlọ́run, wọ́n á sì máa dá a lẹ́bi fún àwọn nǹkan tó ṣe. Ohun tí wọ́n á sì fẹ́ kí ìwọ náà ṣe nìyẹn. Ṣé o máa fi ojú tó tọ́ wo ọ̀rọ̀ yìí títí tí wàá fi mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an? Ohun tí o máa ṣe sinmi lórí bí o ṣe mọ Ọlọ́run tó. Torí náà, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Irú ọ̀rẹ́ wo ni Ọlọ́run jẹ́ sí mi?’

Tó bá jẹ́ pé ṣe ni ìgbésí ayé nira fún ẹ, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé, Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀rẹ́ tó dáa rárá. Àmọ́, ronú nípa rẹ̀ ná. Ṣé Ọlọ́run ló ń fa ìṣòro tí o ń ní àbí òun ló mú kí àwọn nǹkan dáadáa tó o ti gbé ṣe láyé bọ́ sí i? A ti rí i pé, Sátánì ni “olùṣàkóso ayé yìí,” kì í ṣe Jèhófà. (Jòhánù 12:31) Torí náà, Sátánì ló ń fa èyí tó pọ̀ jù nínú ìnira àti ìwà ìrẹ́jẹ tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. Láfikún sí i, ìwọ pẹ̀lú á gbà pé ẹran ara ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a ní àti àwọn nǹkan míì tí a kò rò tẹ́lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ ló ń fa ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìṣòro wa.

Ṣé Ọlọ́run ló ń fa ìṣòro tí o ń ní àbí òun ló mú kí àwọn nǹkan dáadáa tó o ti gbé ṣe láyé bọ́ sí i?

Kí wá ni a gbà pé Ọlọ́run ṣe? Bíbélì sọ pé: Ọlọ́run ni “Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Àti pé lára iṣẹ́ tí Ọlọ́run ṣe ni pé ó ṣẹ̀dá ara wa “lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù.” Ó tún sọ pé Jèhófà ni “ẹni tí èémí [wa] wà lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 124:8; 139:14; Dáníẹ́lì 5:23) Kí ni gbogbo èyí túmọ̀ sí?

Ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ló ni ẹ̀mí wa, òun ni Ẹlẹ́dàá wa. (Ìṣe 17:28) Ìyẹn ni pé ẹ̀bùn Ọlọ́run ló jẹ́ bá a ṣe ń mí, tá a wà nínú ayé tó rẹwà, tá a ní àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ wa, tá à ń láyọ̀ bí a ti ń gbọ́ ìró, tá à ń fọwọ́ ba nǹkan, tá à ń gbóòórùn tá a sì lè tọ́ nǹkan wò. (Jákọ́bù 1:17) Ṣé ìwọ náà ti wá rí i pé gbogbo ìbùkún yìí mú ká gbà pé Ọlọ́run jẹ́ Ọ̀rẹ́ tó yẹ ká máa gbé ga, ká sì fọkàn tán?

Lóòótọ́, ó lè má rọrùn fún ẹ láti fọkàn tán Ọlọ́run. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò tíì mọ̀ ọ́n dáadáa débi tí wàá fi lè fọkàn tán an. O ò jayò pa tó o bá ronú bẹ́ẹ̀. A kò lè ṣe àlàyé lórí gbogbo ìdí tí àwọn kan fi rò pé ìkà ni Ọlọ́run sínú àwọn àpilẹ̀kọ tí a kọ ní ṣókí yìí. Àmọ́ tí o bá sapá láti mọ Ọlọ́run sí i, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. * A ní ìgbàgbọ́ pé tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ gan-an nípa Ọlọ́run. Ṣé a wá lè sọ pé ìkà ni Ọlọ́run? Rárá o! Òdìkejì pátápátá ni: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:8.

^ ìpínrọ̀ 8 Bí àpẹẹrẹ, o lè rí àlàyé síwájú sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi, tí o bá ka orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.