Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  May 2013

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ǹjẹ́ Ọlọ́run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá?

Kò ṣòro láti rí ojú rere Ọlọ́run

Bíbélì fi hàn pé, gbogbo èèyàn ni ẹlẹ́ṣẹ̀. Látọ̀dọ̀ Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́, ni a ti jogún èròkérò tó máa ń mú ká dẹ́ṣẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, nígbà míì a lè ṣe ohun tó burú, tí à á wá máa kábàámọ̀ rẹ̀ tó bá yá. Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, kú nítorí tiwa, kó lè san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti jogún. Ẹbọ ìràpadà rẹ̀ ló mú ká lè máa rí ìdáríjì gbà. Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa ni.—Ka Róòmù 3:23, 24.

Àwọn kan tó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì máa ń wò ó pé bóyá ni Ọlọ́run lè dárí jì wọ́n. Àmọ́, ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ sì ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.” (1 Jòhánù 1:7) Kódà, tí ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá bá tiẹ̀ burú jáì, Jèhófà máa dárí jì wá pátápátá, tí a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.—Ka Aísáyà 1:18.

Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó lè dárí jì wá?

Tí a bá fẹ́ kí Jèhófà Ọlọ́run dárí jì wá, a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, ìyẹn ni pé ká lóye bó ṣe máa ń ṣe nǹkan, àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ àti àwọn ohun tó ń fẹ́ ká ṣe. (Jòhánù 17:3) Tayọ̀tayọ̀ ni Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó ronú pìwà dà, tí wọ́n kọ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì sapá láti yí ìwà wọn pa dà.—Ka Ìṣe 3:19.

Kò ṣòro láti rí ojú rere Ọlọ́run, torí pé Jèhófà mọ ibi tí a kù sí. Aláàánú àti onínúure ni. Ǹjẹ́ bí Jèhófà ṣe ń ṣàánú wa tìfẹ́tìfẹ́ mú kó wù ọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wàá ṣe máa ṣe ohun tó fẹ́?—Ka Sáàmù 103:13, 14.