Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ May 2013 | Ṣé Ìkà Ni Ọlọ́run?

Àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí àti àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì mú kí àwọn kan kọminú sí ìdí tí Ọlọ́run fi ṣe ohun tó ṣe. Ǹjẹ́ wọ́n fi hàn lóòótọ́ pé ìkà ni Ọlọ́run?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Kí Nìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Ń Sọ Pé Ìkà Ni Ọlọ́run?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé ìkà ni Ọlọ́run tàbí pé kò tiẹ̀ bìkítà. Kí ni Bíbélì sọ?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Fi Hàn Pé Ìkà Ni Ọlọ́run?

Níwọ̀n bí Ọlọ́run tòótọ́ ti kórìíra ìwà ìkà, kì nìdí tó fi jẹ́ kí àjálù máa pa àwọn èèyàn?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé Àwọn Ìdájọ́ Ọlọ́run Fi Hàn Pé Ìkà Ni?

Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì nínú àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì. A máa wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún-omi ọjọ́ Nóà àti nígbà ìparun àwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé Wàá Fọkàn Tán Ọlọ́run?

Ọkàn ẹ máa balẹ̀ gan-an tó o bá ka Ọlọ́run sí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan.

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Ó Wù Mí Kí N Di Àlùfáà”

Láti ìgbà tí Roberto Pacheco ti jẹ́ ọ̀dọ́ ló ti ń wù ú pé kó di àlùfáà nínú ìjọ Kátólíìkì. Wo ohun tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.

OHUN TÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ LÁYỌ̀

Bí Àárín Àwọn Tó Tún Ìgbéyàwó Ṣe Àti Àwọn Ẹlòmíì Ṣe Lè Tòrò

Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè mú kí ọkùnrin tàbí obìnrin tó lọ fẹ́ ẹlòmíì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àti ẹni tí wọ́n ń fẹ́ tẹ́lẹ̀?

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ Jẹ Jèhófà Lógún Lóòótọ́?

Ǹjẹ́ ó ṣòro fún ẹ láti gbà pé ọ̀rọ̀ rẹ jẹ Ọlọ́run lógún? Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní Jòhánù 6:44 fi ẹ̀rí tó lágbára hàn pé ọ̀rọ̀ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ Ọlọ́run lógún.

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì jini? Tí a bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọrun, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì