Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  April 2013

 TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”

Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”

NÓÀ dáwọ́ dúró díẹ̀ láti na ẹ̀yìn torí pé ara ti ń ro ó. Fi ọkàn yàwòrán bó ṣe jókòó lé ìtì igi ńlá kan, tó ń sinmi, tó sì ń wo bí iṣẹ́ ọkọ̀ áàkì ràgàjì náà ṣe ń lọ sí. Bí òórùn ọ̀dà bítúmẹ́nì gbígbóná ṣe gbalẹ̀ kan, bẹ́ẹ̀ náà ni ìró irinṣẹ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ń dún kíkankíkan. Níbi tí Nóà jókòó sí, ó ń rí bí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ ní pẹrẹu, tí kálukú wọn ń kan àwọn igi pọ̀ mọ́ ara wọn. Òun àti aya rẹ̀ ọ̀wọ́n, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìyàwó wọn ti ń bá iṣẹ́ áàkì yìí bọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Wọ́n ti rìn jìnnà nínú iṣẹ́ yìí, àmọ́ iṣẹ́ tó kù ṣì pọ̀ gan-an!

Àwọn èèyàn àgbègbè ibẹ̀ rò pé òpònú ni Nóà àti ìdílé. Bí iṣẹ́ náà ṣe ń lọ, tí àwọn èèyàn ń rí bí áàkì náà ṣe rí lóòótọ́, ni wọ́n túbọ̀ ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé, kí ni wọ́n tiẹ̀ rò débi pé ìkún-omi ń bọ̀ wá bo gbogbo ayé? Lójú wọn, ìparun tí Nóà ń kìlọ̀ fún wọn nípa rẹ̀ dà bí àlá tí kò lè ṣẹ, wọ́n wò ó pé èrò yẹn kò tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu rárá! Kódà, ṣe ló ń yà wọ́n lẹ́nu pé, báwo ni ọkùnrin kan á ṣe fi ayé rẹ̀, àti ti ìdílé rẹ̀ pátá ṣòfò láìnídìí, lórí iṣẹ́ òmùgọ̀ bẹ́ẹ̀? Ṣùgbọ́n Jèhófà, Ọlọ́run tí Nóà ń sìn, kò ka Nóà sí òmùgọ̀.

Ohun tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ni pé: “Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Kì í ṣe pé Ọlọ́run fìgbà kan rìn lórí ilẹ̀ ayé rí, tàbí pé Nóà gòkè lọ sí ọ̀run lọ́nà kan ṣá. Ṣe ni Nóà ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn, ó wá dà bíi pé òun àti Jèhófà jọ ń rìn bí ọ̀rẹ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, Bíbélì sọ pé: “Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ [Nóà], ó dá ayé lẹ́bi.” (Hébérù 11:7) Báwo ló ṣe dá ayé lẹ́bi nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo ni bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó kọ́ wa lónìí?

Ó JẸ́ ONÍWÀ MÍMỌ́ NÍNÚ AYÉ ONÍWÀ BURÚKÚ

Inú ayé kan tó ń burú sí i ni Nóà dàgbà sí. Láti ìgbà ayé Énọ́kù baba ńlá Nóà ni ayé ti bà jẹ́. Olódodo ni Énọ́kù, ó sì bá Ọlọ́run rìn. Nígbà yẹn, Énọ́kù tiẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé ọjọ́ ìdájọ́ ń bọ̀ wá sórí àwọn èèyàn burúkú. Ṣùgbọ́n nígbà tó máa fi di ìgbà ayé Nóà, ìwà ibi ti wá pọ̀ lápọ̀jù. Àní lójú Jèhófà, ilẹ̀ ayé ti bà jẹ́ pátápátá, torí pé ṣe ni ìwà ipá kún inú rẹ̀ bámúbámú. (Jẹ́nẹ́sísì 5:22; 6:11; Júúdà 14, 15) Kí ló fà á tí nǹkan fi wá burú tó bẹ́ẹ̀?

Nǹkan burúkú kan ló bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ yọ láàárín àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì. Ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀kan lára wọn ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó wá di Sátánì Èṣù torí pé ó sọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìdáa, ó sì tan Ádámù àti Éfà sínú ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà ayé Nóà, àwọn áńgẹ́lì míì bá Sátánì lẹ̀dí àpò pọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà tó ń ṣàkóso lọ́nà tí ó tọ́. Wọ́n pa iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn ní ọ̀run tì, wọ́n wá sí ayé, wọ́n sì gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n wá ń fẹ́ àwọn arẹwà obìnrin ṣe aya. Àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀, tí wọ́n gbéra ga, tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀ yìí, wá kó ìwà ibi ran aráyé.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; 6:1, 2; Júúdà 6, 7.

Yàtọ̀ sí èyí, àwọn áńgẹ́lì tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ yìí ń fún àwọn obìnrin lóyún, èyí sì lòdì sí ẹ̀dá tiwọn, wọ́n wá ń bí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tó jẹ́ òmìrán, tí agbára wọn bùáyà. Bíbélì pe àwọn òmìrán yìí ní Néfílímù, èyí tó túmọ̀ sí “Abiniṣubú.” Ìkà paraku ni wọ́n, ṣe ni wọ́n wá túbọ̀ jẹ́ kí ìwà tó burú jáì pàpọ̀jù láyé. Abájọ tí Ẹlẹ́dàá fi wò ó pé “ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.” Jèhófà wá pinnu  pé òun yóò pa àwọn èèyàn burúkú yẹn rẹ́ láàárín ọgọ́fà [120] ọdún.—Jẹ́nẹ́sísì 6:3-5.

Nóà àti aya rẹ̀ ní láti tọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà tí ìwà ibi kò fi ní ràn wọ́n

Ẹ wo bó ṣe máa nira tó fún òbí láti tọ́ ọmọ yanjú nínú irú ayé bẹ́ẹ̀! Síbẹ̀, Nóà tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ yanjú. Ó kọ́kọ́ wá aya rere fẹ́. Lẹ́yìn tó sì di ẹni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún, aya rẹ̀ bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un. * Orúkọ wọn ni Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì. Nóà àti aya rẹ̀ jọ tọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà tí ìwà ibi tó gbòde kan kò fi ní ràn wọ́n. Bí ẹ ṣe mọ̀, tí àwọn ọmọdékùnrin bá rí àwọn ẹni tó jẹ́ “alágbára ńlá” àti “àwọn ọkùnrin olókìkí,” ó máa ń jọ wọ́n lójú gan-an, ó sì máa ń wù wọ́n. Nígbà tó sì jẹ́ pé irú èèyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn Néfílímù, àwọn ọmọdékùnrin á fẹ́ máa fi wọ́n ṣèranwò. Lóòótọ́, kò sí bí Nóà àti aya rẹ̀ ṣe lè gbìyànjú tó tí àwọn ọmọ wọn kò ní máa gbọ́ ìròyìn nípa itú tí àwọn òmìrán wọ̀nyẹn ń pa. Àmọ́, wọ́n lè kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó fani mọ́ra nípa Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó kórìíra gbogbo ìwà ibi pátá. Wọ́n ní láti jẹ́ kí ó yé àwọn ọmọdékùnrin wọn pé ìwà ipá àti ọ̀tẹ̀ tí àwọn èèyàn ń hù nígbà yẹn dun Jèhófà gan-an.—Jẹ́nẹ́sísì 6:6.

Àwọn òbí lóde òní mọ̀ dájú pé iṣẹ́ gidi ni Nóà àti aya rẹ̀ ṣe, kí wọ́n tó lè kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìwà rere láyé ìgbà yẹn. Torí pé bí ìwà ipá àti ọ̀tẹ̀ ṣe gbòde kan lónìí náà nìyẹn. Kódà àwọn nǹkan eré ìnàjú tí wọ́n ń ṣe fún àwọn ọmọdé máa ń gbé ìwà ipá àti ọ̀tẹ̀ lárugẹ. Ṣe ni àwọn ọlọ́gbọ́n òbí máa ń sa gbogbo ipá wọn kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ má bàa kó èèràn ran àwọn ọmọ wọn. Ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé wọ́n á máa kọ́ wọn nípa Jèhófà, Ọlọ́run àlàáfíà, tó máa mú kí gbogbo ìwà ipá dópin lọ́jọ́ kan. (Sáàmù 11:5; 37:10, 11) Ó dájú ṣáká pé àwọn òbí lè ṣàṣeyọrí. Ìdí ni pé Nóà àti aya rẹ̀ ṣàṣeyege. Àwọn ọmọ wọn dàgbà di èèyàn rere, wọ́n sì fẹ́ aya tí wọ́n jọ nífẹ̀ẹ́ sí fífi ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn.

“ṢE ÁÀKÌ KAN FÚN ARA RẸ”

Lọ́jọ́ kan, ìgbé ayé Nóà yí pa dà, àyípadà títí láé sì ni. Jèhófà sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ tó fẹ́ràn yìí pé òun ti pinnu láti pa ayé ìgbà yẹn run. Ọlọ́run sì pàṣẹ fún Nóà pé: “Fi igi ṣe áàkì kan fún ara rẹ láti ara igi olóje.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:14.

Áàkì yìí kì í ṣe ọkọ̀ ojú omi o, bí àwọn kan ṣe rò. Torí kò níbi tó jẹ́ iwájú tàbí ẹ̀yìn, kò ní àkànṣe igi tàbí irin tó máa ń wà lábẹ́ ọkọ̀ ojú omi láti iwájú dé ẹ̀yìn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìtọ́kọ̀ àti àwọn igun tàbí ẹ̀gbẹ́ tó ṣe kọdọrọ bíi ti ọkọ̀ ojú omi. Àpótí tó tóbi fàkìàfakia kan ni. Jèhófà fún Nóà ní gbogbo ìwọ̀n áàkì náà àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí ọkọ̀ náà ṣe máa rí, ó tún sọ pé kí ó fi ọ̀dà bò ó nínú àti lóde. Ó sì sọ ìdí rẹ̀ fún Nóà pé: “Kíyè sí i, èmi yóò mú àkúnya omi wá sórí ilẹ̀ ayé . . . Ohun gbogbo tí ó wà ní ilẹ̀ ayé yóò gbẹ́mìí mì.” Ṣùgbọ́n Jèhófà fún un ní ìtọ́ni pé: “Ìwọ yóò sì wọnú áàkì náà, ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti aya rẹ àti aya àwọn ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú rẹ.” Ó ní kí Nóà mú lára gbogbo onírúurú ẹranko sínú áàkì náà. Torí pé kìkì àwọn tó bá wà nínú áàkì ni yóò la Àkúnya Omi tó ń bọ̀ náà já!—Jẹ́nẹ́sísì 6:17-20.

Bí Nóà ṣe gba iṣẹ́ bàǹtàbanta nìyẹn o. Fàkìàfakia ni áàkì yẹn máa tóbi. Gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ mítà mẹ́tàléláàádóje [133], fífẹ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ mítà méjìlélógún, gíga rẹ̀ yóò sì jẹ́ mítà mẹ́tàlá. Kò tíì sí ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi igi ṣe tó tóbi tó o títí di òní pàápàá. Ṣé Nóà wá yẹ iṣẹ́ náà sílẹ̀, tàbí kó ṣàròyé nípa àwọn ìṣòro tó máa ní, tàbí  kó tiẹ̀ yí àwọn nǹkan kan pa dà nínú bí wọ́n ṣe ní kó ṣe é, kó bàa lè rọ̀ ọ́ lọ́rùn? Rárá o. Ohun tí Bíbélì sọ ní pé: “Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:22.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni iṣẹ́ náà gbà, ó ṣeé ṣe kó tó ogójì sí àádọ́ta ọdún kó tó parí. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ igi ńlá ni wọ́n máa ní láti gé lulẹ̀, wọ́n á wọ́ wọn lọ sí ibi tí wọ́n ti máa lò ó, wọ́n á là wọ́n, wọ́n á gé wọn sí ìwọ̀n tó yẹ, wọ́n á wá kàn wọ́n pa pọ̀. Áàkì náà yóò ní àjà mẹ́ta àti àwọn yàrá bíi mélòó kan, yóò sì ní ilẹ̀kùn kan ní ẹ̀gbẹ́. Ẹ̀rí fi hàn pé apá òkè ni àwọn fèrèsé áàkì náà máa wà, ó sì jọ pé orí rẹ̀ lókè máa dagun síhà méjèèjì láti àárín kó lè dami nù.—Jẹ́nẹ́sísì 6:14-16.

Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, bí áàkì yẹn ṣe máa rí bẹ̀rẹ̀ sí í hàn dáadáa. Ó dájú pé Nóà á máa dúpẹ́ pé ìdílé rẹ̀ kọ́wọ́ tì í lẹ́nu iṣẹ́ náà! Ṣùgbọ́n iṣẹ́ kan ṣì wà lára iṣẹ́ tí Nóà máa ṣe, tó ṣeé ṣe kó tiẹ̀ tún gba ìgboyà ju áàkì tí wọ́n ń kàn lọ. Bíbélì sọ pé Nóà jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (2 Pétérù 2:5) Bí ó ṣe mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ kíkìlọ̀ fún àwọn èèyàn oníwà ibi àti àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run pé ìparun ń bọ̀ wá sórí wọn, fi hàn pé ó jẹ́ onígboyà. Ǹjẹ́ wọ́n kọbi ara sí ìkìlọ̀ rẹ̀? Nígbà tí Jésù Kristi ń sọ̀rọ̀ nípa ayé ìgbà náà, ó sọ pé àwọn èèyàn yẹn “kò sì fiyè sí i.” Ó ní ìgbòkègbodò ojoojúmọ́, irú bíi jíjẹ, mímu àti gbígbé ìyàwó ló gbà wọ́n lọ́kàn tí wọn kò fi fetí sí ọ̀rọ̀ Nóà. (Mátíù 24:37-39) Ó dájú pé ṣe ni ọ̀pọ̀ nínú wọn á máa fi Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn míì tiẹ̀ lè lérí léka sí i, kí wọ́n sì fìbínú ta kò ó.

Pẹ̀lú gbogbo bí àwọn èèyàn ṣe rí i pé Ọlọ́run ń bù kún Nóà, ṣe ni wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀

Síbẹ̀, Nóà àti ìdílé rẹ̀ kò pa ohun tí wọ́n ń ṣe tì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí àwọn èèyàn yẹn ń lépa ní ìgbésí ayé ni wọ́n kà sí pàtàkì jù, tí wọ́n sì ka áàkì tí ìdílé Nóà ń kàn sí àìríkan-ṣèkan, iṣẹ́ àṣedànù tàbí ìwà òmùgọ̀, síbẹ̀, Nóà àti ìdílé rẹ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni àwọn ìdílé tó jẹ́ Kristẹni lè kọ́ lára ìgbàgbọ́ tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ní. Ó ṣe tán, àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé burúkú yìí ni àwa náà wà báyìí. (2 Tímótì 3:1) Jésù sọ pé ìgbà tiwa yìí máa dà bí ayé ìgbà tí Nóà kan áàkì. Nítorí náà, tí àwọn èèyàn bá dágunlá sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tí à ń sọ fún wọn, àbí tí wọ́n fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, tàbí tí wọ́n tiẹ̀ ṣe inúnibíni sí wa, ṣe ni ká máa rántí pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ sí Nóà. Àti pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìṣáájú náà.

“LỌ . . . SÍNÚ ÁÀKÌ NÁÀ”

Ogún ọdún kọjá, ọgbọ́n kọjá, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ áàkì náà dúró rekete. Nígbà tí Nóà fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ẹgbẹ̀ta [600] ọdún, àwọn èèyàn rẹ̀ kan kú. Bí àpẹẹrẹ, Lámékì bàbá rẹ̀ kú. * Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, Mètúsélà bàbá Lámékì, ìyẹn baba ńlá Nóà, kú lẹ́ni ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n [969]. Òun ló pẹ́ jù láyé nínú gbogbo èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 5:27) Mètúsélà àti Lámékì ṣì bá Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, láyé kó tó kú.

Ọdún tí Mètúsélà kú yìí ni Jèhófà Ọlọ́run bá Nóà sọ̀rọ̀ pé: “Lọ, ìwọ àti gbogbo agbo ilé rẹ, sínú áàkì náà.” Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún sọ fún Nóà pé kí ó kó gbogbo onírúurú ẹran sínú áàkì. Ó ní kí ó kó méjeméje lára àwọn tí ó mọ́, tí wọ́n lè fi rúbọ, kí ó sì kó àwọn yòókù ní méjìméjì.—Jẹ́nẹ́sísì 7:1-3.

Ó dájú pé bí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹranko wọ̀nyẹn ṣe ń rọ́ wọlé tìrítìrí lọ́tùn-ún lósì máa jẹ́ nǹkan tí kò ṣeé gbàgbé. Ọ̀tọ̀ ni àwọn tó ń rìn bọ̀, àwọn tó ń tọ, àwọn tó ń fò àti àwọn tó ń wọ́ nílẹ̀. Àti ńlá àti kékeré wọn, èyí tó ga àti èyí tó kúrú, gbogbo wọn ń bọ̀ lónírúurú ọ̀nà, kálukú pẹ̀lú ìṣe tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Nóà kò máa sá sókè sódò kó lè ká àwọn ẹranko wọ̀nyẹn mọ́ ibì kan, bẹ́ẹ̀ ni kò máa pariwo tàbí kó máa fọgbọ́n tàn wọ́n láti lè dà wọ́n lọ sí àyè wọn nínú áàkì náà. Bíbélì sọ pé ṣe ni “wọ́n wọlé . . . lọ bá Nóà nínú áàkì náà.”—Jẹ́nẹ́sísì 7:9.

Àmọ́ àwọn oníyèmejì lé sọ pé: ‘Báwo ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣẹlẹ̀ láyé yìí? Báwo ni onírúurú ẹranko wọ̀nyẹn  ṣe máa lè wà pa pọ̀ ní àlàáfíà nínú áàkì tó kó gbogbo wọn sí yẹn?’ Ṣùgbọ́n rò ó wò ná: Ṣé Ẹlẹ́dàá tó dá ọ̀run òun ayé kò ní lágbára tó fi lè darí àwọn ẹranko tó dá, bóyá kó rọ̀ wọ́n lójú kí wọ́n sì rọrùn láti darí, tó bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀? Rántí pé Jèhófà ni Ọlọ́run tó pín Òkun Pupa níyà tó sì mú kí oòrùn dúró sójú kan lójú ọ̀run. Ǹjẹ́ kò wá ní lè ṣe gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn Nóà yìí? Dájúdájú ó lè ṣe wọ́n, ó sì ṣe é lóòótọ́!

Ní ti gidi, Ọlọ́run lè gba àwọn ẹranko wọ̀nyẹn là lọ́nà míì. Ṣùgbọ́n, ṣe ni ó lo ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu yẹn ká lè máa rántí iṣẹ́ tó fà lé àwa èèyàn lọ́wọ́ níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ìyẹn ni pé ká máa tọ́jú gbogbo ẹ̀dá abẹ̀mí orí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ òbí lónìí máa ń fi ìtàn Nóà kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà fọwọ́ pàtàkì mú àwa èèyàn àti àwọn ẹranko tó dá.

Jèhófà sọ fún Nóà pé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, Àkúnya Omi máa dé. Ó dájú pé ọwọ́ ìdílé náà máa dí gidigidi láàárín àkókò yìí. Fojú inú wo iṣẹ́ ńlá tí wọ́n á máa ṣe láti to àwọn ẹranko àti oúnjẹ wọn sí àyè tó yẹ àti bí wọ́n á tún ṣe máa kó ẹrù ìdílé náà sínú áàkì. Iṣẹ́ aya Nóà àti àwọn ìyàwó Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì tún máa légbá kan, torí wọ́n á fẹ́ rí i dájú pé àwọn nǹkan tí wọ́n máa nílò àti ibi tí wọ́n máa wà nínú áàkì náà wà ní sẹpẹ́.

Àwọn èèyàn tó yí wọn ká ńkọ́, kí ni wọ́n ń ṣe? Pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe ń rí ọwọ́ ìbùkún Jèhófà kedere lára Nóà àti gbogbo ohun tó ń gbé ṣe, Bíbélì sọ pé wọn “kò sì fiyè sí i.” Wọ́n á ṣáà rí bí onírúurú ẹranko ṣe ń rọ́ wọnú áàkì náà, àbí? Àmọ́ ṣá, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé wọ́n dágunlá sí i. Àwọn èèyàn òde òní náà ò ṣáà fiyè sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀rí tó fi hàn pé àkókò òpin ayé burúkú la wà yìí. Bí àpọ́sítélì Pétérù sì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn olùyọṣùtì ti wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọ́n sì ń fi àwọn tó ń tẹ̀ lé ìkìlọ̀ Ọlọ́run ṣe yẹ̀yẹ́. (2 Pétérù 3:3-6) Bí àwọn èèyàn ìgbàanì ṣe fi Nóà ṣe ẹlẹ́yà náà nìyẹn.

Ìgbà wo ni gbogbo yẹ̀yẹ́ tí wọ́n ń ṣe dópin? Bíbélì sọ pé gbàrà tí Nóà kó ìdílé rẹ̀ àti àwọn ẹranko sínú áàkì tán “Jèhófà ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn.” Ṣe ni ẹnu èyíkéyìí tó bá wà nítòsí lára àwọn tó ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà máa wọ̀ ṣin-in bí wọ́n ṣe rí i pé Jèhófà ti ilẹ̀kùn. Bí ìyẹn kò bá sì tó, ó dájú pé òjò ńlá tó bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn náà máa jẹ́ kí ara wọn rọ̀ wọ̀ọ̀! Òjò náà ń ya mùúmùú, ó ń dà wìì-wìì-wìì láì dáwọ́ dúró, títí tó fi di ìkún-omi tó bo gbogbo ayé bí Jèhófà ṣe wí.—Jẹ́nẹ́sísì 7:16-21.

Ṣé inú Jèhófà wá dùn pé àwọn èèyàn burúkú yẹn kú dà nù? Ó tì o! (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti fún wọn láyè tó pọ̀ tó kí wọ́n lè ronú pìwà dà kí wọ́n sì ṣe ohun tí ó tọ́. Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ lè yí pa dà? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ìwà àti ìṣe Nóà fi hàn pé wọ́n lè ṣe ohun tó tọ́ tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Bí Nóà ṣe bá Jèhófà rìn, ní ti pé ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, jẹ́ kó hàn kedere pé àwọn èèyàn yòókù náà ṣì lè yí pa dà, kí wọ́n ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì la ìkún-omi náà. Ṣe ni Nóà tipa bẹ́ẹ̀ fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ dá ayé ìgbà náà lẹ́bi; ó jẹ́ kó hàn kedere pé àwọn oníwà ibi inú ayé ìgbà yẹn ló jẹ̀bi. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì gba òun àti ìdílé rẹ̀ là. Bí ìwọ náà bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nóà, tó o ní irú ìgbàgbọ́ tó ní, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn èèyàn rẹ là. Ìwọ náà lè bá Jèhófà Ọlọ́run rìn, kí o sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀ bíi ti Nóà. Ìwọ àti Ọlọ́run sì lè jẹ́ ọ̀rẹ́ títí láé!

^ ìpínrọ̀ 10 Àwọn èèyàn ayé ìgbà náà lọ́hùn-ún máa ń pẹ́ láyé gan-an ju àwa ti òde òní lọ. Ìdí sì ni pé ìran wọn kò jìnnà púpọ̀ sí ti Ádámù àti Éfà tó ní ara pípé àti ìlera pípé kí wọ́n tó pàdánù rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 20 Lámékì sọ orúkọ ọmọ rẹ̀ ní Nóà, tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ìsinmi tàbí Ìtùnú.” Ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé orúkọ yìí máa ro Nóà lóòótọ́ nítorí ó máa kó àwọn èèyàn yọ nínú làálàá tí wọ́n ń ṣe lórí ilẹ̀ tí Ọlọ́run fi gégùn-ún. (Jẹ́nẹ́sísì 5:28, 29) Ṣùgbọ́n Lámékì ti kú kí àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó ṣẹ.