Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  March 2013

 Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ṣé Ọ̀run Ni Jésù Sọ Pé Aṣebi Tó Wà Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òun Yóò Lọ?

Ṣé Ọ̀run Ni Jésù Sọ Pé Aṣebi Tó Wà Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òun Yóò Lọ?

Ohun tó fa ìbéèrè yìí ni pé Jésù ṣèlérí fún ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé yóò wà lára àwọn tó máa gbé ní Párádísè. Jésù sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Kíyè sí i pé Jésù kò sọ ibi tí Párádísè náà máa wà. Ṣé ohun tí Jésù wá ń sọ ni pé aṣebi náà máa wà lọ́dọ̀ òun ní ọ̀run?

Jẹ́ ká kọ́kọ́ wò ó bóyá aṣebi yìí tiẹ̀ kúnjú òṣùwọ̀n láti wà lára àwọn tó ń lọ sí ọ̀run. Àwọn tó bá máa lọ sí ọ̀run gbọ́dọ̀ ti ṣèrìbọmi, kí wọ́n sì ti fi ẹ̀mí mímọ́ batisí wọn. Wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ di ọmọlẹ́yìn Jésù tí Ọlọ́run ti sọ dọmọ. (Jòhánù 3:3, 5) Wọ́n tún gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Wọ́n sì ní láti jẹ́ olóòótọ́ èèyàn, oníwà títọ́ àti olójú àánú. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Yàtọ̀ síyẹn wọ́n á tún jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run àti Kristi jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. (Lúùkù 22:28-30; 2 Tímótì 2:12) Ìgbà tí wọ́n bá dójú ìlà àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe yìí nìkan ni wọ́n tó lè yẹ lẹ́ni tó máa jíǹde sí ọ̀run. Ìgbà yẹn sì ni wọ́n tó lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ojúṣe ńlá tí wọ́n máa ṣe ní ọ̀run, ìyẹn ni pé wọn yóò ṣàkóso pẹ̀lú Kristi gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àti ọba lé ilẹ̀ ayé lórí fún ẹgbẹ̀rún ọdún.—Ìṣípayá 20:6.

Ní ti aṣebi tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù, ìgbé ayé ọ̀daràn ló gbé, inú ìwà burúkú yìí ló sì kú sí. (Lúùkù 23:32, 39-41) Lóòótọ́ o, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ló bá Jésù sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ fún un pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” (Lúùkù 23:42) Síbẹ̀, aṣebi yìí ò tíì ṣèrìbọmi, kò sì tíì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù àti ẹni tí Ọlọ́run sọ dọmọ. Ìgbé ayé rẹ̀ ò sì fi hàn pé ó jẹ́ oníwà rere àti olóòótọ́ èèyàn. Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu pé Jésù máa wá ṣèlérí fún ẹni tó jẹ́ aṣebi yìí pé yóò jẹ́ ọba pa pọ̀ pẹ̀lú òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn òun olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin títí dojú ikú?—Róòmù 2:6, 7.

Àpèjúwe kan rèé: Tí ẹnì kan bá jí owó rẹ, àmọ́ tó wá tọrọ ìdáríjì, o lè pinnu pé o kò ní bá a ṣe ẹjọ́ lórí ohun tó ṣe. Àmọ́ ṣé o lè fọkàn tán irú ẹni yẹn débi pé wàá ní kó máa bá ẹ bójú tó òwò rẹ tàbí ìdílé rẹ? Ó dájú pé àwọn tí o fọkàn tán dáadáa nìkan ni wàá fa irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lé lọ́wọ́. Bákan náà, àwọn tí Ọlọ́run yàn pé wọ́n máa lọ sọ́run gbọ́dọ̀ ti fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán, àti pé àwọn yóò máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá ń ṣàkóso aráyé. (Ìṣípayá 2:10) Ní ti aṣebi yìí, òótọ́ ni pé, ní gẹ́rẹ́ kí ó tó kú, ó bẹ Jésù tọkàntọkàn pé kó rántí òun, àmọ́ ìgbé ayé rẹ̀ àtẹ̀yìnwá kò fi hàn pé ó jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán.

Àmọ́, ṣé ohun tí Jésù sọ fún aṣebi yẹn kọ́ ni pé ọjọ́ yẹn gangan ló máa wà pẹ̀lú òun ní ọ̀run ni? Rárá o, kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, torí Jésù pàápàá kò lọ sí ọ̀run lọ́jọ́ yẹn. Dípò bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé Jésù “wà ninu ilẹ̀,” ìyẹn inú sàréè, fún ọjọ́ mẹ́ta. (Mátíù 12:40, Ìròhìn Ayọ̀; Máàkù 10:34) Kódà lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ogójì ọjọ́ ni ó lò lórí ilẹ̀ ayé, kó tó gòkè lọ sí ọ̀run. (Ìṣe 1:3, 9) Torí náà, kò ṣeé ṣe kí aṣebi yẹn wà lọ́run pẹ̀lú Jésù lọ́jọ́ yẹn.

Párádísè wo wá ni Jésù sọ pé aṣebi yẹn máa wà? Lẹ́yìn àjíǹde, aṣebi yẹn yóò wà nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí Jésù máa ṣàkóso lé lórí. (Ìṣe 24:15; Ìṣípayá 21:3, 4) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Párádísè àti àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká máa ṣe, béèrè lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá rí.