Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 KÓKÓ Ọ̀RỌ̀: KÍ LA LÈ RÍ KỌ́ LÁRA MÓSÈ?

Ta Ni Mósè?

Ta Ni Mósè?

Èwo nínú nǹkan wọ̀nyí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ orúkọ Mósè? Ṣé ohun tó o máa ń rántí ni . . .

  • ọmọ ìkókó kan tí ìyá rẹ̀ gbé sínú apẹ̀rẹ̀ létí Odò Náílì?

  • ọmọdékùnrin tí ọmọbìnrin Fáráò tọ́ dàgbà nílé ọlá ní Íjíbítì àmọ́ tí kò gbàgbé pé ọmọ Ísírẹ́lì ni òun?

  • ọkùnrin kan tó ṣe olùṣọ́ àgùntàn ní ilẹ̀ Mídíánì fún ogójì ọdún?

  • ọkùnrin tó bá Jèhófà * sọ̀rọ̀ níwájú igi kékeré kan tó ń jó?

  • ọkùnrin tó fìgboyà sọ fún ọba Íjíbítì pé kó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko ẹrú?

  • ọkùnrin tí Ọlọ́run sọ pé kó kéde Ìyọnu Mẹ́wàá sórí ilẹ̀ Íjíbítì nígbà tí ọba ilẹ̀ náà ṣàfojúdi sí Ọlọ́run tòótọ́?

  • ọkùnrin tó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì?

  • ọkùnrin tí Ọlọ́run ní kó pín Òkun Pupa níyà?

  • ọkùnrin tí Ọlọ́run tipasẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin Mẹ́wàá?

GBOGBO nǹkan wọ̀nyí ló jẹ́ òótọ́ nípa Mósè. Kódà ó tún ṣe àwọn nǹkan ńlá míì. Abájọ tó fi jẹ́ pé ẹni ọ̀wọ̀ ni àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni, àwọn Júù àti àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ka Mósè ọkùnrin olóòótọ́ yìí sí!

Ní tòdodo, wòlíì tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Mósè. (Diutarónómì 34:10-12) Ó jẹ́ kí Ọlọ́run lo òun lọ́nà àrà. Síbẹ̀, èèyàn ẹlẹ́ran ara ni Mósè. Bí wòlíì Èlíjà tó fara hàn lẹ́gbẹ̀ẹ́ Mósè nínú ìran kan nígbà tí Jésù wà lórí ìlẹ ayé ṣe jẹ́ “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa” náà ni Mósè ṣe jẹ́ èèyàn bí tiwa. (Jákọ́bù 5:17; Mátíù 17:1-9) Ọ̀pọ̀ ìṣòro tí à ń ní lónìí ni Mósè ní nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sì borí wọn.

Ṣé wàá fẹ́ mọ ohun tó jẹ́ kí Mósè borí àwọn ìṣòro yẹn? Wo mẹ́ta lára ìwà dáadáa tí Mósè ní àti ẹ̀kọ́ tí a lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 7 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.