Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  February 2013

Mósè Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

Mósè Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

KÍ NI Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀?

Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni pé kéèyàn jẹ́ ẹni tí kì í gbéra ga tàbí ẹni tí kì í jọ ara rẹ̀ lójú. Ẹni tó bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kì í fojú kéré àwọn ẹlòmíì. Ó tún yẹ kí ẹ̀dá aláìpé tó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ mọ ìwọ̀n ara rẹ̀, kó sì gbà pé ó níbi tí agbára òun mọ.

BÁWO NI MÓSÈ ṢE LO Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀?

Mósè kò jẹ́ kí agbára gun òun. Lọ́pọ̀ ìgbà, tí àṣẹ bá dé ọwọ́ ẹnì kan, ó máa ń hàn kíákíá bóyá onítọ̀hún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tàbí agbéraga. Ní nǹkan bí igba ọdún sẹ́yìn, òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Robert G. Ingersoll sọ pé: “Lóòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tí kò lè fara da ìpọ́njú. Àmọ́ tó o bá fẹ́ mọ̀ bóyá ẹnì kan ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àbí kò ní, yàn án sípò agbára.” Àpẹẹrẹ tó ta yọ ni Mósè fi lélẹ̀ ní ti kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Lọ́nà wo?

Bí Jèhófà ṣe yan Mósè pé kó darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, agbára ńlá ló gbé lé e lọ́wọ́. Síbẹ̀, Mósè kò jẹ́ kí agbára gun òun. Bí àpẹẹrẹ, wo bó ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ bójú tó ìbéèrè ẹlẹgẹ́ tó jẹ yọ nípa ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ogún. (Númérì 27:1-11) Ìbéèrè ńlá ni ìbéèrè yìí, torí pé ìpinnu tí wọ́n bá ṣe ló máa di òfin tí ìrandíran wọn yóò máa tẹ̀ lé lọ́jọ́ iwájú.

Kí ni Mósè máa wá ṣe? Ǹjẹ́ ó wò ó pé òun kúkú ni aṣáájú Ísírẹ́lì, torí náà òun mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe? Ṣé ó gbára lé òye ara rẹ̀, kó ronú pé kì í ṣe òní kì í ṣe àná ni òun ti ń darí Ísírẹ́lì àti pé òun ti mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan?

Ó lè jẹ́ pé ohun tẹ́ni tó jẹ́ agbéraga máa ṣe nìyẹn. Àmọ́ Mósè kò ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Mósè mú ọ̀ràn [náà] wá síwájú Jèhófà.” (Númérì 27:5) Tiẹ̀ rò ó wò ná! Ó ti lé ní ogójì ọdún tí Mósè ti ń darí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, síbẹ̀ kò gbára lé òye ara rẹ̀, Jèhófà ló gbára lé. Èyí mú kó ṣe kedere pé Mósè ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lóòótọ́.

Mósè kò ronú pé ọwọ́ òun nìkan ló yẹ kí àṣẹ wà. Ṣe ni inú rẹ̀ dùn nígbà tí Jèhófà yan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì míì ṣe wòlíì, kí wọ́n jọ máa ṣiṣẹ́. (Númérì 11:24-29) Nígbà tí àna rẹ̀ fún un ní ìmọ̀ràn pé kó yan àwọn ọkùnrin tó lè máa bá a ṣe àwọn iṣẹ́ míì tó máa ń ṣe fúnra rẹ̀, Mósè fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ìmọ̀ràn yìí. (Ẹ́kísódù 18:13-24) Bákan náà, ní apá ìgbẹ̀yìn ayé rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara rẹ̀ ṣì le, ó bẹ Jèhófà pé kí ó yan ẹni tí yóò máa darí Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí òun bá kú. Jèhófà wá yan Jóṣúà. Tọkàntọkàn sì ni Mósè fi ti Jóṣúà tó kéré sí i lọ́jọ́ orí lẹ́yìn. Ó sì rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gbọ́rọ̀ sí Jóṣúà lẹ́nu bí yóò ṣe máa darí wọn lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Númérì 27:15-18; Diutarónómì 31:3-6; 34:7) Òótọ́ ni pé Mósè mọyì àǹfààní ńlá tó ní láti máa darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú ìjọsìn. Àmọ́ kò jẹ́ kí àṣẹ tó ní yìí jẹ ẹ́ lógún ju ire àwọn míì lọ.

Ẹ̀KỌ́ WO LA RÍ KỌ́?

A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí agbára, ipò àṣẹ tàbí ẹ̀bùn àbínibí tá a ní máa gùn wá gàràgàrà. Ká rántí pé: Tí a bá fẹ́ wúlò fún Jèhófà, ó yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ torí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe pàtàkì ju ẹ̀bùn àbínibí èyíkéyìí tí a bá ní lọ. (1 Sámúẹ́lì 15:17) Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a ó máa ṣe ìgbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.”—Òwe 3:5, 6.

A kẹ́kọ̀ọ́ lára Mósè pé a kò gbọ́dọ̀ sọ ipò tàbí agbára tí a ní di nǹkan bàbàrà.

Dájúdájú, tí a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Mósè èrè wà níbẹ̀. Tá a bá ní ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ a kò ní máa fayé ni àwọn míì lára, a ó sì jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé Jèhófà Ọlọ́run máa fẹ́ràn wa, torí pé òun fúnra rẹ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. (Sáàmù 18:35) “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pétérù 5:5) Ẹ ò rí i báyìí pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bí ti Mósè!