KÍ NI ÌFẸ́?

Ìfẹ́ wé mọ́ kí ọkàn èèyàn fà mọ́ àwọn míì lọ́nà tó jinlẹ̀. Ẹni tó ní ìfẹ́ máa ń fi ìfẹ́ yìí hàn nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀ sí àwọn tó fẹ́ràn, kódà tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá tiẹ̀ gba pé kó fi àwọn nǹkan kan du ara rẹ̀.

BÁWO NI MÓSÈ ṢE FI HÀN PÉ ÒUN NÍ ÌFẸ́?

Mósè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Rántí ohun tí Bíbélì sọ ní 1 Jòhánù 5:3 pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” Nítorí pé Mósè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ó ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀. Gbogbo ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe ló ṣe, látorí àwọn iṣẹ́ ńlá, irú bó ṣe lọ kojú Fáráò alágbára, dórí àwọn iṣẹ́ tó dà bíi pé kò tó nǹkan, irú bó ṣe na ọ̀pá rẹ̀ sórí Òkun Pupa. Yálà ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ rọrùn fún Mósè láti ṣe tàbí kò rọrùn, ó máa ń ṣègbọràn. Bíbélì sọ pé: “Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.”—Ẹ́kísódù 40:16.

Mósè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn náà sì mọ̀ pé òun ni Jèhófà ń lò láti darí àwọn. Torí náà tí wọ́n bá ní ìṣòro, wọ́n máa ń wá bá Mósè. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ènìyàn náà sì ń dúró níwájú Mósè láti òwúrọ̀ títí di alẹ́.” (Ẹ́kísódù 18:13-16) Fojú inú wo bí á ṣe máa rẹ Mósè tó lẹ́yìn tó bá ti fi gbogbo ọjọ́ tẹ́tí gbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bí ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn ṣe ń sọ ìṣòro rẹ̀ fún un! Síbẹ̀, torí pé Mósè nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn náà, inú rẹ̀ máa ń dùn láti fetí sí wọn.

Yàtọ̀ sí pé Mósè máa ń tẹ́tí sí àwọn èèyàn rẹ̀, ó tún máa ń gbàdúrà fún wọn. Kódà, ó tiẹ̀ gbàdúrà fún àwọn tó ṣẹ̀ ẹ́! Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Míríámù ẹ̀gbọ́n Mósè ń kùn sí Mósè, Jèhófà mú kí àrùn ẹ̀tẹ̀ bo Míríámù. Dípò kí inú Mósè wá máa dùn pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni ó ń jẹ, ṣe ni Mósè bá a bẹ Ọlọ́run. Ó gbàdúrà pé: “Ọlọ́run, jọ̀wọ́! Mú un lára dá, jọ̀wọ́!” (Númérì 12:13) Kí ló mú kí Mósè ṣe ohun tó ṣe yìí? Ìfẹ́ ni!

Ẹ̀KỌ́ WO LA RÍ KỌ́?

Àwa náà lè ṣe bí ti Mósè, tí a bá ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run. Ṣe ni irú ìfẹ́ yìí máa ń mú ká ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run “láti inú ọkàn-àyà.” (Róòmù 6:17) Tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà láti inú ọkàn wa, a ó mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) Fún àǹfààní wa sì tún ni. Ó ṣe tán, tó bá jẹ́ pé ojúlówó ìfẹ́ ló ń mú ká sin Ọlọ́run, yàtọ̀ sí pé a ó máa ṣe ohun tó tọ́, inú wa yóò tún máa dùn pé à ń ṣe bẹ́ẹ̀!—Sáàmù 100:2.

Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Mósè ni pé ká jẹ́ kí ìfẹ́ mú ká máa fi ara wa jìn fún àwọn ẹlòmíì. Tí àwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn tó wà nínú ìdílé wa bá wá sọ ìṣòro wọn fún wa, ìfẹ́ ló máa mú ká (1) fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ; (2) ká fi ọ̀rọ̀ wọn ro ara wa wò; (3) ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún.

Àwa náà lè ṣe bí ti Mósè, ká máa gbàdúrà fún àwọn èèyàn wa. Nígbà míì, tí wọ́n bá sọ àwọn ìṣòro wọn fún wa, ó lè dùn wá gan-an tí a kò bá rí nǹkan ṣe sí i. A tiẹ̀ lè máa dárò pé, “Ó dùn mí pé kò sí ohun tí mo lè ṣe, àmọ́ màá máa fi ọ̀rọ̀ yín sí àdúrà.” Àmọ́, ká má gbàgbé pé: “Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo n ṣe ní agbára púpọ̀.” (Jákọ́bù 5:16, Bíbélì Mímọ́) Àdúrà wa lè jẹ́ kí Jèhófà ṣe ohun tí ì bá má ṣe fún ẹni náà ká ní a kò gbàdúrà pé kó ṣe é. Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ ò rí i pé ó dára gan-an ká máa gbàdúrà fún àwọn èèyàn wa. *

Ṣé ìwọ náà gbà báyìí pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ lára Mósè? Lóòótọ́ èèyàn bí tiwa ni, àmọ́ ni tí kéèyàn jẹ́ ẹni tó nígbàgbọ́, tó ní ìrẹ̀lẹ̀ tó sì tún ní ìfẹ́, àpẹẹrẹ tó ta yọ ló fi lélẹ̀. Tí a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Mósè dáadáa, a ó ṣe ara wa àti àwọn míì láǹfààní.—Róòmù 15:4.

^ ìpínrọ̀ 8 Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti máa fi òótọ́ inú ṣe ohun tó fẹ́. Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 17 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.