Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mósè Jẹ́ Ẹni Tó Ní Ìgbàgbọ́

Mósè Jẹ́ Ẹni Tó Ní Ìgbàgbọ́

KÍ NI ÌGBÀGBỌ́?

Bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ìgbàgbọ́,” ó túmọ̀ sí kéèyàn gba ohun kan gbọ́ dájú nítorí pé ó rí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ nípa ohun náà. Ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run máa ń ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

KÍ LÓ FI HÀN PÉ MÓSÈ NÍ ÌGBÀGBỌ́?

Àwọn ìpinnu tí Mósè ṣe ní ìgbésí ayé rẹ̀ fi hàn pé ó gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 22: 15-18) Dípò kí Mósè máa gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, kó sì máa jayé orí ẹ̀ lọ ní Íjíbítì, ṣe ni “ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” (Hébérù 11:25) Ṣé kì í ṣe pé kò ronú jinlẹ̀ kó tó ṣe ìpinnu yìí, èyí tó lè kábàámọ̀ rẹ̀ tó bá yá? Rárá o, nítorí Bíbélì sọ pé Mósè “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:27) Kò kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tó ṣe nítorí ìgbàgbọ́ tó ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run.

Mósè wá ọ̀nà láti mú kí ìgbàgbọ́ tí àwọn míì ní nínú Ọlọ́run fẹsẹ̀ múlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní àárín àwọn ọmọ ogun Fáráò àti Òkun Pupa. Iwájú kò ṣeé lọ ẹ̀yìn kò ṣeé pa dà sí. Ìbẹ̀rùbojo bá wọn, wọ́n rò pé ọwọ́ ti tẹ àwọn. Làwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ké jáde sí Jèhófà àti sí Mósè fún ìrànlọ́wọ́. Kí ni Mósè wá ṣe?

Ó ṣeé ṣe kí Mósè fúnra rẹ̀ má mọ̀ pé ṣe ni Ọlọ́run fẹ́ lànà sáàárín Òkun Pupa, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè rí ọ̀nà kọjá. Àmọ́ ṣá, ó dá Mósè lójú pé Ọlọ́run máa ṣe nǹkan kan láti dáàbò bo àwọn èèyàn Rẹ̀. Ó sì fẹ́ kó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà lójú. Bíbélì sọ pé: “Mósè wí fún àwọn ènìyàn náà pé: ‘Ẹ má fòyà. Ẹ dúró gbọn-in-gbọn-in, kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà, èyí tí yóò ṣe fún yín lónìí.’” (Ẹ́kísódù 14:13) Ǹjẹ́ Mósè sì mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹsẹ̀ múlẹ̀ lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Ohun tí Bíbélì sọ nípa Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni wọ́n la Òkun Pupa kọjá bí pé lórí ilẹ̀ gbígbẹ.” (Hébérù 11:29) Mósè nìkan kọ́ ló jàǹfààní ìgbàgbọ́ tó ní yìí o. Ó tún ṣe gbogbo àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ lára ìgbàgbọ́ rẹ̀ láǹfààní.

Ẹ̀KỌ́ WO LA RÍ KỌ́?

A lè ṣe bí ti Mósè tá a bá ń ṣe ìpinnu tó fi hàn pé a gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run ṣèlérí pé tá a bá fi ìjọsìn òun ṣáájú ní ìgbésí ayé wa, òun máa pèsè àwọn ohun tí a nílò. (Mátíù 6:33) Lóòótọ́ o, ó lè má rọrùn pé ká má ṣe jẹ́ kí àtijẹ àtimu tàbí gbígbọ́ bùkátà gbà wá lọ́kàn, torí ohun tí ọ̀pọ̀ gbájú mọ́ nìyẹn nínú ayé yìí. Ṣùgbọ́n, tí a bá jẹ́ kí ìwọ̀nba àwọn nǹkan kòṣeémánìí tẹ́ wa lọ́rùn, tí a sì pa ọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn Ọlọ́run, gbogbo nǹkan tá a nílò ni Jèhófà máa pèsè fún wa. Kódà Ọlọ́run fi dá wa lójú pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Hébérù 13:5.

Ó yẹ kí àpẹẹrẹ tiwa náà mú kí àwọn míì ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n máa ń rí i pé àǹfààní ńlá ni àwọn ní láti mú kí àwọn ọmọ wọn nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Láti kékeré ló ti yẹ kí àwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn pé Ọlọ́run wà àti pé ó fún wa ní ìlànà nípa ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ kí àwọn òbí mú kí ó dá àwọn ọmọ wọn lójú pé, téèyàn bá ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run nìkan lèèyàn tó lè gbé ìgbé ayé tó dára. (Aísáyà 48:17, 18) Ẹ̀bùn iyebíye ni àwọn òbí ń fún àwọn ọmọ wọn tí wọ́n bá kọ́ wọn débi tí wọ́n á fi gbà gbọ́ pé Ọlọ́run “ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.