Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  February 2013

 SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

Ọlọ́run Àwọn Alààyè Ni

Ọlọ́run Àwọn Alààyè Ni

Ǹjẹ́ ikú lè lágbára ju Ọlọ́run lọ? Rárá ó! Báwo tiẹ̀ ni ikú tàbí “ọ̀tá” èyíkéyìí míì, ṣe lè lágbára ju “Ọlọ́run Olódùmarè” lọ? (1 Kọ́ríńtì 15:26; Ẹ́kísódù 6:3) Ọlọ́run ní agbára láti jí àwọn tó ti kú dìde kó sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ikú dòfo. Ohun tó sì ṣèlérí pé òun máa ṣe nìyẹn nínú ayé tuntun rẹ̀ tó ń bọ̀. * Kí ló jẹ́ kí ìlérí yìí dá wa lójú? Jésù Ọmọ Ọlọ́run sọ ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ ká lè fọkàn sí ìlérí yẹn.—Ka Mátíù 22:31, 32.

Nígbà tí Jésù ń bá àwọn Sadusí tí kò gba àjíǹde gbọ́ sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Ní ti àjíǹde àwọn òkú, ṣé ẹ kò ka ohun tí Ọlọ́run sọ fún yín ni, pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’? Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè.” Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún Mósè níbi tí iná ti ń jó igi kékeré kan, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún [3,500] sẹ́yìn, ni Jésù ń tọ́ka sí níbí. (Ẹ́kísódù 3:1-6) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, ṣe ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Mósè pé “Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù,” ń fi hàn dájú pé Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde bó ṣe ṣèlérí. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn ná. Nígbà tí Jèhófà ń bá Mósè sọ̀rọ̀ yìí, àwọn baba ńlá náà Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù ti kú tipẹ́tipẹ́. Kódà ó ti tó ọ̀ọ́dúnrún ọdún ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [329] tí Ábúráhámù ti kú nígbà yẹn, ikú Ísákì ti tó igba ó lé mẹ́rìnlélógún [224] ọdún sẹ́yìn, ti Jékọ́bù sì tó igba ó dín mẹ́ta ọdún [197]. Síbẹ̀, ó hàn nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì pé nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ wọn fún Mósè kò sọ ọ́ bíi pé ìgbà kan sẹ́yìn, tí wọ́n ṣì wà láàyè lòun jẹ́ Ọlọ́run wọn. Ṣe ló sọ ọ́ bíi pé àwọn baba ńlá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ṣì wà láàyè. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

Jésù ṣàlàyé pé: “[Jèhófà] kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè.” Ronú díẹ̀ nípa ohun tí Jésù fẹ́ fi ọ̀rọ̀ yìí fà yọ nípa àjíǹde. Kókó yẹn ni pé, tí kò bá sí àjíǹde, a jẹ́ pé Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù ti kú gbé nìyẹn títí ayé. Tó bá sì wá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Ọlọ́run àwọn òkú lásánlàsàn ni Jèhófà jẹ́. Ohun tí ìyẹn sì máa túmọ̀ sí ni pé agbára ikú ju ti Jèhófà lọ, bíi pé Jèhófà ò lágbára tó láti dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú.

Nígbà náà, kí ni ká wá sọ nípa ọ̀rọ̀ Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù àti gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà olóòótọ́ tí wọ́n ti kú? Ohun pàtàkì tí Jésù sọ nípa wọn ni pé: “Gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀.” (Lúùkù 20:38) Àní, ó dá Jèhófà lójú pé òun máa jí àwọn ìránṣẹ́ òun olóòótọ́ tó ti kú dìde débi pé ṣe ló máa ń wò ó bíi pé wọ́n wà láàyè. (Róòmù 4:16, 17) Gbogbo wọn pátá ni Jèhófà tí kì í gbàgbé nǹkan fi sọ́kàn pé òun máa jí dìde pa dà nígbà tó bá yá.

Wẹ́rẹ́ ni Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde, torí agbára ikú kò jẹ́ nǹkan kan lọ́dọ̀ rẹ̀

Ǹjẹ́ kò dùn mọ́ ọ láti mọ̀ pé o tún lè pa dà rí àwọn èèyàn rẹ̀ tó ti kú? Torí náà, máa rántí pé wẹ́rẹ́ ni Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde, torí agbára ikú kò jẹ́ nǹkan kan lọ́dọ̀ rẹ̀. Kò sí ohun tó lè dá a dúró kó máà jí àwọn òkú dìde bó ṣe ṣèlérí. O ò ṣe túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlérí àjíǹde àti Ọlọ́run tó máa mú ìlérí náà ṣẹ? Èyí máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, “Ọlọ́run . . . àwọn alààyè.”

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún February

Mátíù 22-28Máàkù 1-8

^ ìpínrọ̀ 3 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa jí àwọn èèyàn dìde kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó nínú ayé tuntun, ka orí 7 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.