Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 OHUN TÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ LÁYỌ̀

Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Tí Ọmọ Yín Bá Jẹ́ Abirùn

Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Tí Ọmọ Yín Bá Jẹ́ Abirùn

CARLO: * “Angelo ọmọ wa ọkùnrin ní àrùn kan tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ ọmọ jí pépé, tí wọ́n ń pè ní Down syndrome. Ìtọ́jú rẹ̀ máa ń tán wa lókun, ó sì máa ń jẹ́ kó rẹ̀ wá tẹnutẹnu. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni èèyàn máa ń ṣe láti tọ́jú ọmọ tí ara rẹ̀ le dáadáa, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti èyí tó bá jẹ́ abirùn. Ṣe ló máa ń gba gbogbo agbára tí èèyàn ní pátápátá. Nígbà míì, kì í jẹ́ ká ráyè gbọ́ tara wa bíi tọkọtaya.”

MIA: “Ó máa ń gba sùúrù gidi ká tó lè kọ́ Angelo ní bó ṣe lè ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, torí kì í tètè mọ nǹkan. Nígbà míì, tó bá ti rẹ̀ mí, ara máa ń kan mí, màá sì máa kanra mọ́ Carlo ọkọ mi. Ìgbà míì sì wà tí a kì í gbọ́ ara wa yé lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan, àá wà bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wa jiyàn.”

Ǹjẹ́ o rántí ọjọ́ tí o bí ọmọ rẹ? Ó dájú pé ó ń wù ẹ́ pé kí o gbé ọmọ náà. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn òbí bíi Carlo àti Mia, ṣe ni àníyàn bá wọn bí wọ́n ṣe ń yọ ayọ̀ ọmọ, nítorí wọ́n sọ fún wọn pé abirùn ni ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí.

Tí o bá jẹ́ òbí tí ọmọ rẹ̀ jẹ́ abirùn, o lè máa ro bí o ṣe máa tọ́jú rẹ̀. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, má mikàn. Àwọn òbí míì bíi tìẹ ti ṣàṣeyọrí. Jẹ́ ká wo àwọn ìṣòro mẹ́ta tó sábà máa ń jẹ yọ àti bí ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ṣe lè mú kó o borí wọn.

ÌṢÒRO KÌÍNÍ: O KÒ GBÀ PÉ ÒÓTỌ́ NI DÓKÍTÀ SỌ.

Inú ọ̀pọ̀ òbí máa ń bà jẹ́ gan-an tí wọ́n bá gbọ́ pé ara ọmọ wọn kò yá. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Juliana ní ilẹ̀ Mẹ́síkò, sọ pé: “Nígbà tí àwọn dókítà sọ fún mi pé Santiago ọmọ wa ọkùnrin ní àrùn inú ọpọlọ tí kì í jẹ́ kí èèyàn lè gbé apá àti ẹsẹ̀ bó ṣe fẹ́, tí kì í sì í jẹ́ kí èèyàn lè sọ̀rọ̀ dáadáa, mi ò gbà gbọ́. Ohun tí wọ́n sọ yìí sì dà mí lọ́kàn rú gidigidi.” Bákan náà, ó lè ṣe àwọn míì bíi Villana, obìnrin kan nílẹ̀ Ítálì. Ó ní: “Èmi ni mo pinnu láti bímọ bó  tilẹ̀ jẹ́ pé ó léwu fún obìnrin tó wà ní irú ọjọ́ orí mi. Àmọ́ ní báyìí tí ọmọ tí mo bí wá ní àrùn tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ ọmọ jí pépé, ṣe ni mo ń dá ara mi lẹ́bi.”

Tí ọkàn rẹ bá ń dà rú tàbí tí o ń dá ara rẹ lẹ́bi pé ìwọ lo fa ohun tó ṣẹlẹ̀, mọ̀ pé ìwọ nìkan kọ́ ló ń nírú èrò yẹn, ó máa ń ṣèèyàn bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé Ọlọ́run kò pète pé kí a máa ṣàìsàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Kò sì dá àwọn òbí lọ́nà tí wọ́n á kàn fi máa gba gbogbo ohun tí kò bára dé mọ́ra láìjanpata. Torí náà, kò burú bí o bá kẹ́dùn nítorí pé ara ọmọ rẹ kò dá. Ó sì lè pẹ́ díẹ̀ kí o tó gba kámú, kí o sì máa bá ipò náà yí.

Tó bá wá ń ṣe ẹ́ bíi pé ìwọ gan-an lo fa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ yìí ńkọ́? Ó máa dára kí o rántí pé kò sí èèyàn tó mọ gbogbo bí àwọn nǹkan tó pilẹ̀ àbùdá wa, àyíká ibi tí a ń gbé àti àwọn nǹkan míì ṣe máa ń ṣàkóbá fún ìlera àwọn ọmọ. Yàtọ̀ sí èyí, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kí o máa dẹ́bi fún ọkọ tàbí aya rẹ. Má ṣe fàyè gba irú èrò yìí. Nǹkan á túbọ̀ rọrùn tí o bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ bí ẹ ṣe ń sapá láti tọ́jú ọmọ yín.—Oníwàásù 4:9, 10.

ÀBÁ: Gbìyànjú láti mọ̀ nípa ohun tó ń ṣe ọmọ rẹ. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n ni a ó fi gbé agbo ilé ró, nípa ìfòyemọ̀ sì ni yóò fi fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”—Òwe 24:3.

O lè lọ gbọ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa irú àìsàn tó ń ṣe ọmọ rẹ lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn, o sì tún lè ka àwọn ìwé tó ṣe ojúlówó àlàyé nípa rẹ̀. O lè fi ọ̀rọ̀ mímọ̀ nípa ohun tó ń ṣe ọmọ rẹ wé bí ìgbà tí o bá ń kọ́ èdè tuntun kan. Lóòótọ́, ó máa ń le ní ìbẹ̀rẹ̀, àmọ́ ohun tí o lè kọ́ kí o sì mọ̀ ni.

Carlo àti Mia tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ lọ ṣèwádìí nípa àìsàn tó ń ṣe ọmọ wọn lọ́dọ̀ dókítà wọn àti àwọn tó ń ṣètọ́jú irú àìsàn bẹ́ẹ̀. Carlo àti Mia wá sọ pé: “Èyí mú ká lè lóye ọ̀pọ̀ nǹkan. Yàtọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ ká mọ àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó yọjú, wọ́n tún kọ́ wa ní àwọn nǹkan tí ẹni tó bá ní irú àìsàn yìí ṣì lè máa ṣe. A wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ọmọ wa yóò lè máa ṣe fúnra rẹ̀. Gbogbo èyí sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an.”

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Fọkàn rẹ sí àwọn nǹkan tí ọmọ rẹ lè ṣe. Máa ṣètò àwọn nǹkan tí ìdílé lè jọ ṣe pa pọ̀. Tí ọmọ rẹ bá ṣe nǹkan kan láṣeyọrí, rí i pé ò ń yìn ín, kó o sì bá a yọ̀.

ÌṢÒRO KEJÌ: Ó MÁA Ń RẸ̀ Ọ́, Ó SÌ Ń ṢE Ọ́ BÍI PÉ O KÒ NÍ ALÁBÀÁRÒ.

Ó lè máa ṣe ọ́ bíi pé ìtọ́jú àìlera ọmọ rẹ máa ń tán ọ lókun. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Jenney ní orílẹ̀-èdè New Zealand sọ pé: “Fún ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí àwọn dókítà sọ pé ihò wà nínú eegun ọ̀pá ẹ̀yìn ọmọ mi, tí mo bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ ilé tó ju èyí tí mo máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó máa ń rẹ̀ mí wá, omijé á sì máa bọ́ lójú mi.”

Ìṣòro míì ni pé ó lè máa ṣe ọ́ bíi pé o kò tiẹ̀ ní alábàárò kankan. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ben ní ọmọ kan tó ní àrùn kan tó ń ba ìṣù ẹran ara jẹ́, títí ẹni náà yóò fi rù hangogo. Ọmọ náà sì tún ní àrùn ọpọlọ kan tó máa ń mú kó ṣòro fún un láti sọ ohun tó ń rò tàbí kí ara rẹ̀ má máa yá mọ́ni, [Asperger’s syndrome]. Ben sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn kò lè mọ irú ìṣòro tí a ń bá yí.” Ó lè máa wù ẹ́ pé kí o rí ọ̀rẹ́ kan fọ̀rọ̀ lọ̀. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ni ara ọmọ wọn dá ṣáṣá, ó lè má yá ẹ lára láti sọ ìṣòro rẹ fún wọn.

ÀBÁ: Máa sọ pé kí àwọn èèyàn ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má sì kọ̀ tí wọ́n bá sọ pé àwọn fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Obìnrin tó ń jẹ́ Juliana tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà míì, ojú máa ń ti èmi àti ọkọ mi láti ní kí àwọn míì ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ ní báyìí, a ti rí i pé kò sí bí àwa nìkan ṣe lè máa dá ṣe gbogbo nǹkan. Tí àwọn míì bá wá ràn wá lọ́wọ́, ṣe ló máa ń jẹ́ ká rí i pé wọn kò dá wa dá wàhálà náà.” Tí ẹ bá wà níbi àpèjẹ kan tàbí nínú ìpàdé ìjọ, tí ọ̀rẹ́ rẹ kan tàbí ará ilé rẹ kan sì fẹ́ bá ẹ jókòó ti ọmọ rẹ, gbà wọ́n láyè, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.

Rí i pé o ń tọ́jú ara rẹ. A lè fi ọ̀rọ̀ yìí wé ọkọ̀ tí wọ́n máa fi ń gbé àwọn aláìsàn lọ sílé ìwòsàn. Kí ọkọ̀ náà tó lè máa ṣiṣẹ́ déédéé, wọ́n gbọ́dọ̀ máa rọ epo sínú rẹ̀ lóòrèkóòrè. Bákan náà, o gbọ́dọ̀ máa jẹun dáadáa, kí o máa ṣe eré ìmárale, kí o sì máa sinmi dáadáa, kí o lè ní okun àti agbára tí wàá lè máa fi tọ́jú ọmọ rẹ bó ṣe yẹ. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Javier, tí ẹsẹ ọmọ rẹ̀ rọ sọ pé: “Níwọ̀n bí ọmọ mi kò ti lè rìn, mo máa ń rí i pé mo jẹun dáadáa torí pé èmi ni mo máa ń tì í káàkiri. Ẹsẹ̀ mi ló ṣáà fi ń ṣe ẹsẹ̀ rìn!”

Báwo lo ṣe lè máa ráyè tọ́jú ara rẹ? Àwọn òbí kan máa ń gba iṣẹ́ títọ́jú ọmọ wọn ṣe láàárín ara wọn. Nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n á lè máa ráyè sinmi lọ́kọ̀ọ̀kan, wọ́n á sì tún lè ṣe àwọn nǹkan tara wọn míì tó yẹ kí wọ́n fún láfiyèsí. Ohun tó dáa ni pé kí o wá àyè látinú àkókò tí o máa fi ń ṣe àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, kí o lè máa ráyè gbọ́ ti ara rẹ. Lóòótọ́, ó lè máà kọ́kọ́ rọrùn. Àmọ́, ohun tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Mayuri ní ilẹ̀ Íńdíà sọ ni pé: “Tó bá yá, wàá mọ ọgbọ́n tí wàá máa dá sí i.”

 Bá ọ̀rẹ́ kan tí o lè fọkàn tán sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro rẹ. Kódà àwọn ọ̀rẹ́ tí ara àwọn ọmọ wọn dá ṣáṣá pàápàá lè jẹ́ orísun ìtùnú fún ọ. O tún lè máa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run. Ǹjẹ́ àdúrà sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Yazmin ní ọmọ méjì tó ní àìsàn kan tí kò gbóògùn, tí kì í jẹ́ kéèyàn lè mí dáadáa, tí kì í sì í jẹ́ kí oúnjẹ dà nínú èèyàn. Obìnrin yìí sọ pé: “Àwọn ìgbà kan wà tí wàhálà pọ̀ fún mi débi pé mo fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.” Ṣùgbọ́n ó ní: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó gbà mí, kó sì fún mi lókun. Ó sì gbọ́ àdúrà mi, torí ó jẹ́ kí n lè forí tì í.”—Sáàmù 145:18.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Máa gbé irú oúnjẹ tí o ń jẹ yẹ̀ wò, ìgbà tí o máa ń ṣe eré ìmárale àti bí o ṣe ń ráyè sùn tó. Wá bí o ṣe lè máa rí àyè látinú àkókò tí o fi ń ṣe àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì láti fi tọ́jú ara rẹ. Máa ṣe ìyípadà tó bá yẹ nínú àwọn nǹkan tí o ń ṣe.

ÌṢÒRO KẸTA: ỌMỌ RẸ TÍ ARA RẸ̀ KÒ YÁ LO GBÁJÚ MỌ́, O KÌ Í FI BẸ́Ẹ̀ RÁYÈ GBỌ́ TI ÀWỌN TÓ KÙ NÍNÚ ÌDÍLÉ.

Tí ọmọ kan bá ń ṣàìsàn, èyí lè nípa lórí irú oúnjẹ tí ìdílé á máa jẹ, ibi tí wọ́n lè lọ àti bí àwọn òbí ṣe máa ráyè gbọ́ ti àwọn ọmọ yòókù tó. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ tó kù lè máa rò pé àwọn òbí ò tiẹ̀ ráyè gbọ́ ti àwọn. Síwájú sí i, ọwọ́ àwọn òbí lè dí gan-an bí wọ́n ṣe ń tọ́jú ọmọ tí ara rẹ̀ kó yá débi pé wọn kò tiẹ̀ ní ráyè gbọ́ ti ẹnì kejì wọn. Ní ilẹ̀ Làìbéríà, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Lionel sọ pé: “Nígbà míì, ìyàwó mi máa ń sọ pé òun nìkan ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ ìtọ́jú ọmọ wa tí ara rẹ̀ kò yá, pé mi kì í dá sí i. Mo máa ń wò ó pé ọ̀rọ̀ àrífín ló sọ, èyí sì máa ń jẹ́ kí n fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí i.”

ÀBÁ: Máa ṣètò láti ṣe àwọn nǹkan tí gbogbo ọmọ rẹ fẹ́ràn, èyí á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ gbogbo wọn jẹ ọ́ lógún. Jenney tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń ṣe nǹkan àrà ọ̀tọ̀ fún ọmọ wa ọkùnrin àgbà, kódà bí kò tiẹ̀ ju pé ká lọ jẹun ní ilé oúnjẹ tó fẹ́ràn jù.”

Máa wáyè gbọ́ ti gbogbo àwọn ọmọ rẹ

Rí i dájú pé ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ jọ ń sọ̀rọ̀, ẹ sì jọ ń gbàdúrà pa pọ̀ kí àárín yín lè gún régé. Ọkùnrin kan tó ń jẹ Aseem ní ilẹ̀ Íńdíà, tí ọmọ rẹ̀ ní àrùn wárápá, sọ pé: “Lóòótọ́ nígbà míì, ó máa ń rẹ èmi àti ìyàwó mi, ó sì máa ń tojú sú wa, síbẹ̀ a máa ń rí i dájú pé a jọ jókòó sọ̀rọ̀, a sì jọ gbàdúrà pọ̀. Láràárọ̀, a jọ máa ń jíròrò ẹsẹ kan nínú Bíbélì pa pọ̀ kí àwọn ọmọ wa tó jí.” Àwọn tọkọtaya míì máa ń wáyè láti jọ sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó lọ sùn. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ máa ń bá ara yín sọ àti àdúrà àtọkànwá yín máa jẹ́ kí àárín yín ṣe tímọ́tímọ́ ní àsìkò ìṣòro. (Òwe 15:22) Tọkọtaya kan sọ pé: “Ara àwọn nǹkan tó máa ń múnú wa dùn tí a bá rántí ni àwọn ìgbà tí a ṣe ara wa lọ́kàn ní ìgbà ìṣòro.”

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Máa yin àwọn ọmọ rẹ yòókù fún gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá ṣe nítorí ọmọ rẹ tí ara rẹ̀ kò yá. Jẹ́ kó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ lóòrèkóòrè pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ àti ìyàwó tàbí ọkọ rẹ, o sì mọyì ìsapá wọn.

FI SỌ́KÀN PÉ Ọ̀LA Ń BỌ̀ WÁ DÁRA

Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run máa tó mú gbogbo àìsàn àti àìlera tó ń yọ tọmọdé tàgbà lẹ́nu kúrò. (Ìṣípayá 21:3, 4) Nígbà náà, ‘Kò ní sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.”’ *Aísáyà 33:24.

Kódà ní àsìkò tí a wà yìí, o lè ṣe ojúṣe rẹ yanjú gẹ́gẹ́ bí òbí, bí o ṣe ń tọ́jú ọmọ rẹ tí ara rẹ̀ kò dá ṣáṣá. Tọkọtaya tó ń jẹ́ Carlo àti Mia tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Má rẹ̀wẹ̀sì tó bá tiẹ̀ fẹ́ dà bíi pé gbogbo nǹkan ń dojú rú. Àwọn nǹkan tí ọmọ rẹ lè ṣe ni kí o máa fọkàn sí, wàá sì rí i pé wọ́n pọ̀ lóòótọ́.”

^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

^ ìpínrọ̀ 29 O lè kà sí i nípa àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe pé aráyé yóò ní ìlera pípé nínú orí 3 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

BI ARA RẸ PÉ . . .

  • Kí ni mo máa ń ṣe láti rí i pé ara mi le koko, àti pé mo ń fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run?

  • Ìgbà wo ni mo yin àwọn ọmọ mi kẹ́yìn nítorí ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń ṣe?