NÍ OṢÙ April ọdún 2006, àwọn ìwé ìròyìn kárí ayé gbé ìtàn kan tó ṣeni ní kàyéfì jáde. Wọ́n ní àwùjọ ọ̀mọ̀wé kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ọ̀rọ̀ inú ìwé àtijọ́ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí jáde, èyí tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì. Àwọn ìwé ìròyìn náà sọ pé àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé ọ̀rọ̀ inú ìwé àtijọ́ yẹn máa yí èrò wa pa dà nípa Júdásì, ọmọ ẹ̀yìn tó da Jésù. Wọ́n ní àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé akọni ni Júdásì, pé òun ni àpọ́sítélì tó mọ ìwà Jésù dáadáa jù àti pé iṣẹ́ tí Jésù rán an ló jẹ́ bó ṣe fà á lé àwọn tó pa á lọ́wọ́.

Ṣé òótọ́ ni pé ìwé ìṣẹ̀ǹbáyé ni ìwé yìí àbí ayédèrú ìwé ni? Tó bá jẹ́ ojúlówó ìwé, ṣé ńṣe ni ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ tú àṣírí àwọn nǹkan pàtàkì kan tí àwọn èèyàn ti bò mọ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́ nípa irú ẹni tí Júdásì Ísíkáríótù jẹ́ àti Jésù Kristi àti àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀? Ǹjẹ́ ó yẹ kí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ nípa lórí ojú tí a fi ń wo Kristi àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ wa?

BÍ WỌ́N ṢE RÍ ÌWÉ TÍ WỌ́N PÈ NÍ ÌHÌN RERE JÚDÁSÌ

Ọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe rí ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì kò tíì ṣe kedere. Dípò kó jẹ́ pé àwọn awalẹ̀pìtàn ló rí i kí wọ́n sì ṣàkọsílẹ̀ tó yẹ nípa rẹ̀, ṣe ni àwọn kan ṣàdédé gbé ìwé yẹn wá sójú táyé níbi tí wọ́n ti ń ta àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé nígbà kan lẹ́yìn ọdún 1978. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọdún 1978 ni wọ́n rí i níbi sàréè kan, bóyá tó wà nínú ihò àpáta, ní ilẹ̀ Íjíbítì. Ọ̀kan lára ìwé ìṣẹ̀ǹbáyé mẹ́rin kan tí wọ́n fọwọ́ kọ ni. Èdè Coptic, ìyẹn èdè kan tí wọ́n ń sọ ní ilẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì, ni wọ́n fi kọ ọ́.

Ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n fi awọ bò lẹ́yìn yìí ti wà ní ìpamọ́ láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, ojú ọjọ́ ilẹ̀ Íjíbítì tó máa ń gbẹ fúrúfúrú ni kò jẹ́ kó ti bà jẹ́. Bí wọ́n ṣe wá mú ìwé tó ti gbó gan-an tó sì wà nípò ẹlẹgẹ́ yìí kúrò níbẹ̀, kíákíá ló bẹ̀rẹ̀ sí í bà jẹ́. Wọ́n fi ìwé náà han àwọn ọ̀mọ̀wé mélòó kan fìrí ní ọdún 1983, àmọ́ iye tí wọ́n fẹ́ tà á ti wọ́n jù, torí náà kò sí ẹni tó rà á. Ni wọ́n bá tún pa ìwé náà tì fún ọ̀pọ̀ ọdún láìtọ́jú rẹ̀ síbi tó yẹ, ìyẹn sì jẹ́ kó tún tètè bà jẹ́ sí i. Ní ọdún 2000, ọmọ ilẹ̀ Switzerland kan tó ń ṣe òwò àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wá rà á. Nígbà tó yá, ó kó ìwé àfọwọ́kọ náà fún àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé kan láti onírúurú orílẹ̀-èdè. Ó ní kí wọ́n ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀ lábẹ́ àbójútó àjọ méjì kan tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé, ìyẹn àjọ Maecenas Foundation for Ancient Art àti àjọ National Geographic Society. Iṣẹ́ tó díjú tó ní kí wọ́n ṣe lórí rẹ̀ ni pé kí wọ́n tún ìwé yẹn àti ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ tò pa pọ̀ sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ àwọn apá kan lára rẹ̀ ti gbó débi pé wọ́n ti ń já.  Àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé yìí yóò tún wádìí ìgbà tí wọ́n kọ ìwé náà, wọ́n á túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ wọ́n á sì ṣàlàyé rẹ̀.

Àyẹ̀wò èròjà kan lára ìwé náà, ìyẹn carbon-14 tí wọ́n fi ń mọ ìgbà tí ohun kan dé ayé, fi hàn pé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1700] sí ẹgbẹ̀sán [1800] ọdún sẹ́yìn ló jọ pé wọ́n kọ ìwé náà. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀mọ̀wé yẹn gbà pé inú ẹ̀dà kan tó ti wà tipẹ́tipẹ́ ní èdè Gíríìkì ni wọ́n ti túmọ̀ ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì tó wà ní èdè Coptic yìí. Ìgbà wo gan-an ni wọ́n kọ́kọ́ kọ ìwé náà, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n kọ ọ́?

ÌWÉ Ẹ̀YA ÌSÌN ÀWỌN ONÍMỌ̀ AWO NI “ÌHÌN RERE JÚDÁSÌ”

Inú àwọn ìwé ọ̀gbẹ́ni Irenaeus, òǹkọ̀wé kan tó ń ṣe ẹ̀sìn Kristẹni, ni wọ́n ti kọ́kọ́ rí Ìhìn Rere Júdásì. Ọ̀gbẹ́ni yẹn gbé láyé ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1900] ọdún sẹ́yìn. Kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ẹgbẹ́ kan tó jẹ́ aládàámọ̀, ó wá kọ̀wé láti fi ta ko ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ náà. Ó ní: “Wọ́n sọ pé Júdásì ọ̀dàlẹ̀ . . . tó mọ òtítọ́ ju àwọn yòókù lọ, ló rí iṣẹ́ afinihàn tó jẹ́ àdììtú ṣe yanjú. Pé ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí gbogbo nǹkan dojú rú ní ayé àti ọ̀run. Wọ́n wá hùmọ̀ ìtàn irọ́ kan láti fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn, èyí tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì.”—Against Heresies.

“Kì í ṣe ìgbà ayé Júdásì ni wọ́n kọ ìwé Ìhìn Rere yìí, kì í sì í ṣe ẹni tó tiẹ̀ mọ̀ ọ́n ló kọ ọ́”

Ṣe ni Irenaeus dìídì fẹ́ fi hàn pé ẹ̀kọ́ èké ni onírúurú ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀ya ìsìn Kristẹni tí wọ́n ń pè ní Onímọ̀ Awo [Gnosticism], torí wọ́n sọ pé àwọn ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Oríṣiríṣi ẹ̀ya ìsìn Kristẹni ni wọ́n fi orúkọ náà Onímọ̀ Awo kó pọ̀. Olúkúlùkù wọn ló ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà túmọ̀ ohun tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ nínú ìsìn Kristẹni. Àwọn Onímọ̀ Awo yìí máa ń lo ìwé tí àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn bá kọ láti fi ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ òtítọ́, irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ sì gbilẹ̀ gan-an láàárín nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1900] ọdún sẹ́yìn.

Àwọn Onímọ̀ Awo sábà máa ń sọ nínú àwọn ìwé ìhìn rere tí wọ́n kọ pé àwọn àpọ́sítélì Jésù tí àwọn èèyàn mọ̀ jù ṣi Jésù lóye àti pé ẹ̀kọ́ kan wà tí Jésù sọ láṣìírí àmọ́ tó jẹ́ pé ìwọ̀nba àwọn mélòó kan tó jẹ́ àṣàyàn láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn ló yé. * Àwọn míì nínú àwọn Onímọ̀ Awo yìí gbà pé bí ẹní wà ní ẹ̀wọ̀n ni ìgbé ayé wa nínú ayé àìpé yìí rí, pé tí a bá kú la tó lè bọ́ nínú rẹ̀. Wọ́n ní ìyẹn sì fi hàn pé ẹlẹ́dàá tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ pé ó dá ayé yìí rẹlẹ̀ sí oríṣiríṣi ọlọ́run míì táwọn gbà pé ó jẹ́ ọlọ́run pípé. Wọ́n máa ń sọ pé ẹni tó bá ní ìmọ̀ àrà ọ̀tọ̀ ló máa ń lóye àṣírí yìí, tí yóò sì máa wá bó ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ àgọ́ ara wa yìí.

Irú ohun tí wọ́n gbé yọ nínú ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì nìyẹn. Bí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí: “Ọ̀rọ̀ àṣírí tí Jésù sọ fún Júdásì Ísíkáríótù láàárín ọjọ́ mẹ́jọ, èyí tó parí nígbà tó ku ọjọ́ mẹ́ta kí wọ́n ṣe àjọ̀dún ìrékọjá.”

Àbí ìwé àfọwọ́kọ yìí ni ìwé tí Irenaeus kọ̀wé nípa rẹ̀, tí àwọn èèyàn gbà pé ó ti sọ nù láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn? Ọ̀gbẹ́ni Marvin Meyer, tó wà lára àwùjọ tó kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ìwé àfọwọ́kọ yìí sọ pé, ìwé tí Irenaeus “ṣàpèjúwe bá ìwé àfọwọ́kọ tí a ní lọ́wọ́ báyìí lédè Coptic mu gan-an ni, èyí tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì.”

ÀWỌN Ọ̀MỌ̀WÉ Ń JIYÀN LÓRÍ IRÚ ẸNI TÍ JÚDÁSÌ TÍ ÌWÉ YẸN SỌ JẸ́

Ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì sọ pé Jésù máa ń fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, nígbà tí wọ́n bá ṣe ohun tó fi hàn pé ohun tó ń sọ kò fi bẹ́ẹ̀ yé wọn. Ó ní Júdásì nìkan ló mọ Jésù dénúdénú láàárín àwọn àpọ́sítélì méjìlá. Pé ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ òun nìkan ni Jésù máa ń sọ “àwọn ohun tó jẹ́ àṣírí nípa ìjọba náà” fún.

Ohun tí Irenaeus sọ nípa ìwé àfọwọ́kọ yìí ní ipa púpọ̀ lórí àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé tó kọ́kọ́ tún ọ̀rọ̀ inú ìwé yẹn tò pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Nínú ìtumọ̀ tí wọ́n wá ṣe, wọ́n sọ pé Jésù gbà pé Júdásì ni ọmọ ẹ̀yìn tó máa lóye àwọn ohun tó jẹ́ àṣírí, tí yóò sì “wọ” inú “ìjọba náà.” Àti pé àwọn àpọ́sítélì tó ṣìnà máa yan ẹlòmíì rọ́pò Júdásì, àmọ́ Júdásì á tipa bẹ́ẹ̀ di “ẹ̀mí kẹtàlá” tó máa “ta gbogbo [àwọn àpọ́sítélì yòókù] yọ,” torí Jésù ti gbà pé òun ló máa ṣe òun lóore, tí yóò jẹ́ kí òun kú láti lè bọ́ lọ́wọ́ àgọ́ ara yìí.

Àwọn òǹkọ̀wé tí ìwé wọn tà jù, irú bí ọ̀gbẹ́ni Bart Ehrman àti ìyáàfin Elaine Pagels, tí wọ́n jẹ́ gbajúgbajà ọ̀mọ̀wé tó ṣèwádìí nípa ẹ̀sìn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ àti  àwọn Onímọ̀ Awo, sáré gbé àkíyèsí àti àlàyé tiwọn lórí ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì yìí jáde. Orí ohun tí àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé tó kọ́kọ́ ṣàtúnṣe ọ̀rọ̀ inú ìwé yẹn sọ ni wọ́n sì gbé àkíyèsí àti àlàyé wọn kà jù. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí àwọn ọ̀mọ̀wé míì bí ìyáàfin April DeConick àti ọ̀gbẹ́ni Birger Pearson kéde pé àwọn kọminú sí ohun tí wọ́n gbé jáde nípa ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì yìí. Wọ́n ní ìwà ọ̀kánjúwà ló mú kí àjọ National Geographic Society fi ìkánjú gbé ọ̀rọ̀ nípa ìwé àtijọ́ yẹn jáde, kí wọ́n bàa lè lórúkọ láwùjọ. Bákan náà, wọ́n tún fo gbogbo ìgbésẹ̀ àkíyèsí fínnífínní àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àyẹ̀wò tí àwọn ọ̀mọ̀wé máa ń ṣe lórí iṣẹ́ tí ọ̀kan lára wọn bá ṣe kí wọ́n tó gbé e jáde. Torí wọ́n ti sọ pé kí àwọn ọ̀mọ̀wé tó ṣe ìwádìí náà fọwọ́ sí ìwé pé àwọn kò ní ṣe ẹnu fóró nípa àbájáde ìwádìí àwọn.

Nínú gbogbo àwọn ọ̀mọ̀wé tó ṣàyẹ̀wò ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì, kò sí ìkankan tó sọ pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ jẹ́ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́

Ìyáàfin DeConick àti ọ̀gbẹ́ni Pearson wá lọ ṣe ìwádìí tiwọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìwé náà. Àbájáde ìwádìí àwọn méjèèjì sì ni pé àwọn ọ̀mọ̀wé tó kọ́kọ́ túmọ̀ ìwé àtijọ́ tó ti já náà ṣi àwọn apá tó ṣe kókó nínú ìwé náà túmọ̀. Nígbà tí DeConick tún ọ̀rọ̀ inú ìwé náà kọ jáde fúnra rẹ̀, àtúnkọ tirẹ̀ sọ pé “Ẹ̀mí Èṣù Kẹtàlá” ni Jésù pe Júdásì, kì í ṣe “ẹ̀mí kẹtàlá.” * Bákan náà, ṣe ni Jésù là á mọ́lẹ̀ fún Júdásì pé kò ní wọ “ìjọba” ọrun. Dípò kó sì jẹ́ pé Júdásì máa ‘ta yọ’ láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù, ṣe ni Jésù sọ fún Júdásì nínú ìwé yẹn pé: “Tìrẹ ló máa burú jù nínú gbogbo wọn. Ìwọ yòó rí ìyọnu torí pé o ṣekú pa mí.” Lójú DeConick, ṣe ni àwọn Onímọ̀ Awo tó kọ ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì kọ ọ́ láti fi gbogbo àwọn àpọ́sítélì ṣẹ̀sín. Nígbà tí DeConick àti Pearson wo ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì látòkèdélẹ̀, wọ́n ní ìwé náà kò fi hàn lọ́nàkọnà pé akọni ni Júdásì.

KÍ LA LÈ RÍ FÀ YỌ NÍNÚ Ọ̀RỌ̀ INÚ “ÌHÌN RERE JÚDÁSÌ”?

Nínú gbogbo àwọn ọ̀mọ̀wé tó ṣàyẹ̀wò ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì, yálà àwọn tó ka Júdásì tí wọ́n sọ níbẹ̀ sí akọni tàbí àwọn tó kà á sí ẹ̀mí èṣù, kò sí ìkankan tó sọ pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ jẹ́ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Ohun tí ọ̀gbẹ́ni Bart Ehrman sọ ni pé: “Kì í ṣe Júdásì ló kọ ìwé Ìhìn Rere náà, kò sì sí nínú ìwé náà pàápàá pé òun ló kọ ọ́. . . . Kì í ṣe ìgbà ayé Júdásì ni wọ́n kọ ìwé Ìhìn Rere yìí, kì í sì í ṣe ẹni tó tiẹ̀ mọ̀ ọ́n ló kọ ọ́ . . . Torí náà, kì í ṣe ìwé tí a ti lè rí àfikún ìsọfúnni nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nígbà tí Jésù wà ní ayé.”

Àwọn Onímọ̀ Awo ló kọ ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1900] ọdún sẹ́yìn, èdè Gíríìkì ni wọ́n sì kọ́kọ́ fi kọ ọ́. Títí di báyìí, àwọn ọ̀mọ̀wé ṣì ń bá ara wọn jiyàn lórí bóyá ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí, bá èyí tí Irenaeus sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mu àbí kò bá a mu. Ṣùgbọ́n ṣe ni ìwé tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Júdásì tún jẹ́ kó hàn kedere pé àsìkò kan wà tí àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni yapa síra, tí wọ́n pín sí onírúurú ẹ̀ya ìsìn tí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì ń ta ko ara wọn. Ìwé yìí kò fi hàn lọ́nàkọnà pé Bíbélì parọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló jẹ́ kó hàn pé òótọ́ ni ohun tí àwọn àpọ́sítélì kìlọ̀ nípa rẹ̀, irú bí èyí tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Ìṣe 20:29, 30 pé: “Mo mọ̀ pé lẹ́yìn lílọ mi . . . láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.”

^ ìpínrọ̀ 11 Wọ́n sábà máa ń fi orúkọ àwọn tí wọ́n gbà pé ó lóye ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ tí Jésù kọ́ni dunjú pe àwọn ìwé ìhìn rere yẹn. Irú bí èyí tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Tọ́másì, àti Ìhìn Rere Màríà Magidalénì. Nǹkan bí ọgbọ̀n irú ìwé àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó ń ṣe ìwádìí ti rí.

^ ìpínrọ̀ 18 Àwọn ọ̀mọ̀wé tó sọ pé ẹ̀mí èṣù ni wọ́n pe Júdásì níbi tí ìwé yìí ti sọ pé òun ló mọ Jésù dénúdénú jù láàárín àwọn àpọ́sítélì, ṣàkíyèsí pé gbólóhùn tí wọ́n lò níbẹ̀ jọ ọ̀nà tí ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì gbà sọ pé àwọn ẹ̀mí èṣù sọ ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an.—Máàkù 3:11; 5:7.