Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  January 2013

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí ni orúkọ Ọlọ́run?

Gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé wa ló ní orúkọ. Àwọn ẹran tí à ń sìn nínú ilé pàápàá ní orúkọ tí à ń pè wọ́n! Ǹjẹ́ kò wá yẹ kí Ọlọ́run náà ní orúkọ? Ọ̀pọ̀ orúkọ oyè bí Ọlọ́run Olódùmarè, Olúwa Ọba Aláṣẹ àti Ẹlẹ́dàá ni wọ́n pe Ọlọ́run nínú Bíbélì, àmọ́ ó ní orúkọ tí ó ń jẹ́ gan-an.—Ka Aísáyà 42:8.

Nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an fara hàn ní Sáàmù 83:18. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ẹsẹ yẹn sọ pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo orúkọ Ọlọ́run?

Ọlọ́run fẹ́ ká máa lo orúkọ òun. Tí a bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ojúlùmọ̀ wa tí a fẹ́ràn sọ̀rọ̀, a máa ń lo orúkọ wọn. Ọlọ́run náà ńkọ́? Ó fẹ́ ká máa lo orúkọ òun tí a bá ń bá òun sọ̀rọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù Kristi pàápàá rọ̀ wá pé ká máa lo orúkọ Ọlọ́run.—Ka Mátíù 6:9; Jòhánù 17:26.

Àmọ́ ṣá o, tí a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kì í ṣe orúkọ rẹ̀ nìkan ni a máa mọ̀, a tún gbọ́dọ̀ mọ àwọn nǹkan míì nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, irú ẹni wo gan-an ni Ọlọ́run jẹ́? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí wà nínú Bíbélì.