Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  January 2013

 TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

“Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”

“Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”

ÉBẸ́LÌ ń wo àwọn àgùntàn rẹ̀ bí wọ́n ṣe rọra ń jẹko lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè tó wà. Ó wá gbójú sókè wo ọ̀ọ́kán, bóyá láti wo ibì kan tó dà bíi pé àwọn nǹkan kan ti ń tàn yanran. Ó mọ̀ pé apá ibẹ̀ ni ọgbà Édẹ́nì wà, àti pé abẹ idà oníná kan tó ń yí nígbà gbogbo láìdáwọ́ dúró, dí ojú ọ̀nà tó wọ ọgbà náà. Inú ọgbà yẹn ni àwọn òbí rẹ̀ ń gbé tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí àwọn àti àwọn ọmọ wọn kò tó ẹni tó ń wọ ibẹ̀ mọ́. Fojú inú wo bí afẹ́fẹ́ ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ tó ń fẹ́ yẹ́ẹ́ á ṣe máa fẹ́ irun orí Ébẹ́lì bó ṣe gbójú sókè tó ń ronú nípa Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Tó ń rò ó pé, ǹjẹ́ àárín Ọlọ́run àti èèyàn máa tún lè pa dà gún régé? Ohun tó wu Ébẹ́lì kó ṣẹlẹ̀ nìyẹn.

Ébẹ́lì yìí ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì lónìí. Ǹjẹ́ o ń gbọ́ ohun tó sọ? O lè máa rò ó pé ìyẹn kò lè ṣeé ṣe. Ó ṣe tán Ébẹ́lì tó jẹ́ ọmọ kejì tí Ádámù bí ti kú tipẹ́tipẹ́, òkú rẹ̀ sì ti jẹrà mọ́ inú ilẹ̀ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà sẹ́yìn báyìí. Ohun tí Bíbélì sì sọ nípa àwọn òkú ni pé: “Wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5, 10) Yàtọ̀ síyẹn, kò síbì kankan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ tí Ébẹ́lì sọ sí nínú Bíbélì. Báwo la ṣe wá lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?

Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ̀rọ̀ nípa Ébẹ́lì pé: “Nípasẹ̀ èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kú, ó ń sọ̀rọ̀ síbẹ̀.” (Hébérù 11:4) Ipasẹ̀ kí ni Ébẹ́lì fi ń sọ̀rọ̀? Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ni. Òun ni ẹni tó kọ́kọ́ ní irú ìgbàgbọ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ tó ní lágbára débi pé àpẹẹrẹ rẹ̀ ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì jẹ́ àwòkọ́ṣe fún wa lóde òní. Tí a bá ń ka àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé Ébẹ́lì ṣe, tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìgbàgbọ́ rẹ̀, tí a sì ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ṣe ló máa dà bíi pé òun fúnra rẹ̀ ló ń bá wa sọ̀rọ̀.

Ẹ̀kọ́ wo la wá lè rí kọ́ lára Ébẹ́lì àti ìgbàgbọ́ tó ní nígbà tó jẹ́ pé ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀? Jẹ́ ká wò ó ná.

ÈÈYÀN KÒ TÍÌ PỌ̀ NÍ AYÉ NÍGBÀ TÓ Ń DÀGBÀ

Ìgbà díẹ̀ lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá àwọn èèyàn àkọ́kọ́ ni wọ́n bí Ébẹ́lì. Nígbà tó yá, Jésù fi hàn pé “ìgbà pípilẹ̀ ayé” ni Ébẹ́lì gbé láyé. (Lúùkù 11:50, 51) Ó hàn gbangba pé ayé tí Jésù ń tọ́ka sí ni àwọn èèyàn tí ó ní ìrètí pé àwọn lè rí ìràpadà ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Lóòótọ́, Ébẹ́lì ni ẹni kẹrin lára àwọn tó kọ́kọ́ gbé inú ayé, àmọ́ ó jọ pé òun lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run rí pé ó ṣeé rà pa dà nínú aráyé. * Ó ṣe kedere nígbà náà pé kì í ṣe àárín àwọn tó fi gbogbo ọkàn ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni Ébẹ́lì gbé dàgbà.

Ìran èèyàn dáyé tàì-dáyé ni wọ́n ti wọ ìjàngbọ̀n. Ó sì jọ pé arẹwà, abarapá àti akíkanjú èèyàn ni Ádámù àti Éfà tó jẹ́ òbí Ébẹ́lì. Ṣùgbọ́n, wọ́n ti balẹ̀ jẹ́ jìnnà, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn ti tẹ́. Ẹni pípé ni wọ́n tẹ́lẹ̀, wọn ì bá sì máa gbé ayé títí láé ni. Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run, ni Ọlọ́run bá lé wọn kúrò nínú Párádísè tó jẹ́ ilé wọn nínú ọgbà Édẹ́nì. Bó ṣe jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn tiwọn ni wọ́n fẹ́ tẹ́ lọ́rùn, láì tiẹ̀ ro ti ẹnì kankan mọ́ tiwọn, títí kan àtọmọdọ́mọ wọn pàápàá, wọ́n pàdánù ipò pípé tí wọ́n wà àti bí wọn ì bá ṣe wà láàyè títí láé.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15–3:24.

 Nígbà tí Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà jáde kúrò nínú ọgbà yẹn, ìyà bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ wọ́n. Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n bí àkọ́bí wọn, wọ́n sọ ọ́ ní Kéènì, ìyẹn “Ohun Tí A Mú Jáde.” Éfà sì sọ pé: “Mo ti mú ọkùnrin kan jáde nípasẹ̀ àrànṣe Jèhófà.” Ọ̀rọ̀ Éfà yìí fi hàn pé ó ní láti jẹ́ ìlérí tí Jèhófà ṣe nínú ọgbà Édẹ́nì, tó fi sọ tẹ́lẹ̀ pé obìnrin kan máa bí “irú ọmọ” kan tí yóò pa ẹni burúkú tó kó Ádámù àti Éfà ṣìnà, ni Éfà ní lọ́kàn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 4:1) Bóyá ṣe ni Éfà kàn tiẹ̀ ń rò pé òun ni obìnrin tí Jèhófà sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn àti pé Kéènì ni “irú ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí náà.

Tó bá rò bẹ́ẹ̀, àṣìṣe ńlá ló ṣe o. Àgàgà tó bá jẹ́ pé irú èrò yìí ni wọ́n gbìn sí Kéènì lọ́kàn bó ṣe ń dàgbà, kò sí bí ìyẹn kò ṣe ní sọ ọ́ di ẹni tó jọ ara rẹ̀ lójú. Nígbà tí Éfà bí ọmọkùnrin kejì, wọn kò sọ irú ọ̀rọ̀ ìwúrí bẹ́ẹ̀ nípa ìyẹn. Wọ́n sọ ọ́ ní Ébẹ́lì, tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Èémí Àmíjáde,” tàbí “Asán.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:2) Àbí wọ́n ti rò pé Ébẹ́lì kò ní fi bẹ́ẹ̀ rọ́wọ́ mú ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní orúkọ yẹn, bíi pé wọ́n kò gbójú lé e tó Kéènì? A ò kúkú lè sọ.

Bó ti wù kó rí, àwọn òbí òde òní lè kọ́gbọ́n lára àwọn òbí wa àkọ́kọ́ yẹn. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ, irú ẹ̀mí wo lo ń gbìn sí ọmọ rẹ lọ́kàn? Ṣé kì í ṣe ìgbéraga, lílépa ipò ọlá àti ìmọtara-ẹni-nìkan? Àbí ṣe lo ń kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run kí wọ́n sì jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀? Ó dunni pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kò ṣe ojúṣe wọn. Àmọ́ ṣá o, ìrètí wà fún àwọn irú ọmọ wọn.

ÉBẸ́LÌ DẸNI TÓ NÍ ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ ỌLỌ́RUN

Ó dájú pé bí àwọn ọmọkùnrin méjèèjì ṣe ń dàgbà, Ádámù kọ́ wọn ní iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n á fi máa ṣètìlẹyìn fún ìdílé náà. Kéènì di àgbẹ̀, Ébẹ́lì sì ń da àgùntàn.

Ṣùgbọ́n Ébẹ́lì tún ṣe ohun kan tó ṣe pàtàkì ju gbogbo ìyẹn lọ. Kí ló ṣe? Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, ó dẹni tó ní ìgbàgbọ́. Ìgbàgbọ́ tó ṣe pàtàkì yìí ni Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa rẹ̀ nígbà tó yá. Ìwọ rò ó wò ná. Nígbà yẹn, kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tí Ébẹ́lì lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere rẹ̀. Báwo ló ṣe wá dẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run? Wo ìdí mẹ́ta tó fi lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára.

Àwọn ohun tí Jèhófà dá.

Lóòótọ́ Jèhófà ti fi ilẹ̀ gégùn-ún, ó sì ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú èyí tí kò jẹ́ kí iṣẹ́ àgbẹ̀ rọrùn. Síbẹ̀, ilẹ̀ ṣì ń mú oúnjẹ jáde dáadáa fún ìdílé àwọn Ébẹ́lì, èyí tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n fi wà láàyè. Bákan náà, àwọn nǹkan yòókù tí Ọlọ́run dá ṣì wà tí kò fi gégùn-ún, irú bí àwọn òkè, adágún omi, odò àti òkun. Ojú ọ̀run, àwọsánmà, oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ náà sì wà níbẹ̀. Gbogbo ibi tí Ébẹ́lì bá wò ló ti ń rí ẹ̀rí ìfẹ́ jíjinlẹ̀, ọgbọ́n ńlá àti inú rere Jèhófà Ọlọ́run tó dá gbogbo nǹkan wọ̀nyí. (Róòmù 1:20) Bó ṣe ń ṣàṣàrò lórí nǹkan wọ̀nyí ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ á túbọ̀ máa lágbára sí i.

Ó dájú pé Ébẹ́lì máa ń fara balẹ̀ ronú nípa àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Fojú inú yàwòrán rẹ̀ bí ó ṣe ń tọ́jú agbo ẹran rẹ̀. Àwọn darandaran sábà máa ń rìn káàkiri gan-an. Torí náà, yóò máa da àwọn ẹran  ọ̀sìn náà lọ sí orí àwọn òkè àti àfonífojì, yóò kó wọn sọdá odò, yóò dà wọ́n lọ sí ibikíbi tí wọ́n bá ti lè rí koríko tútù yọ̀yọ̀ jẹ, ibi tí wọ́n bá ti lè rí omi mu àti ibi ààbò tí wọ́n ti lè sinmi. Nínú ìṣẹ̀dá Ọlọ́run tí kò mọ bí wọ́n ṣe ń dáàbò bo ara wọn rárá, ti àwọn àgùntàn yọyẹ́. Àfi bíi pé ṣe ni Ọlọ́run dìídì dá wọn lọ́nà tó fi jẹ́ pé èèyàn ní láti máa tọ́ wọn sọ́nà, kó sì máa dáàbò bò wọ́n. Ó ṣeé ṣe kí Ébẹ́lì wá rí i pé òun náà nílò ìtọ́sọ́nà àti ààbò àti ìtọ́jú Ọlọ́run tó ní ọgbọ́n àti agbára ju ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ irú èrò bẹ́ẹ̀ ni yóò máa bá Ọlọ́run sọ nígbà tó bá ń gbàdúrà, ìyẹn á sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ máa pọ̀ sí i.

Àwọn iṣẹ́ àrà inú ìṣẹ̀dá tí Ébẹ́lì ń rí mú kó gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá jẹ́ onífẹ̀ẹ́

Àwọn ìlérí Jèhófà.

Ádámù àti Éfà á ti sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì tí Ọlọ́run fi lé àwọn jáde kúrò níbẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. Torí náà, Ébẹ́lì máa rí ọ̀pọ̀ nǹkan ṣàṣàrò lé lórí.

Jèhófà ti fi ilẹ̀ gégùn-ún. Ébẹ́lì alára yóò sì ti máa rí bí ilẹ̀ ṣe ń mú ẹ̀gún àti òṣùṣú jáde lóòótọ́. Jèhófà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé inú ìrora ni Éfà yóò máa lóyún, inú ìrora ni yóò sì ti máa bímọ. Ébẹ́lì á tún ti máa rí i pé ìyẹn náà ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ bí ìyá rẹ̀ ṣe ń bí àwọn àbúrò rẹ̀. Jèhófà ti rí i ṣáájú pé ọkàn Éfà yóò máa fà sí Ádámù ọkọ rẹ̀ lọ́nà tó pàpọ̀jù, yóò sì fẹ́ máa fa ojú rẹ̀ mọ́ra ṣáá. Àmọ́ ṣe ni Ádámù yóò máa jọba lé e lórí. Gbogbo ìwọ̀nyẹn ni Ébẹ́lì á máa rí pé ó ń ṣẹlẹ̀ láàárín bàbá àti ìyá rẹ̀. Ébẹ́lì rí i pé nínú gbogbo nǹkan, ọ̀rọ̀ Jèhófà máa ń ṣẹ bó ṣe sọ gẹ́lẹ́. Gbogbo èyí sì mú kí Ébẹ́lì lè ní ìgbàgbọ́ tó dájú nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé “irú-ọmọ” kan ń bọ̀ wá ṣàtúnṣe gbogbo àìtọ́ tó bẹ̀rẹ̀ látinú ọgbà Édẹ́nì.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15-19.

Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà.

Lóòótọ́, kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tí Ébẹ́lì lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere rẹ̀ nígbà yẹn, àmọ́ àwọn èèyàn nìkan kọ́ ni ẹ̀dá olóye tó wà nínú ayé lásìkò náà. Nígbà tí Jèhófà lé Ádámù àti Éfà jáde nínú ọgbà Édẹ́nì, ó rí i dájú pé kò sí èyíkéyìí nínú wọn tàbí àtọmọdọ́mọ wọn tó máa lè wọnú Párádísè orí ilẹ̀ ayé yẹn pa dà. Ohun tí Jèhófà ṣe ni pé ó fi àwọn kérúbù, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì tó lágbára gan-an ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ọgbà náà, ó sì fi abẹ idà tí ń jó lala, tí ń yí ara rẹ̀ láìdáwọ́ dúró sí ibi àbáwọlé rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 3:24.

Wá fojú inú wò ó pé Ébẹ́lì ń rí àwọn kérúbù yẹn nígbà tó wà lọ́mọdé. Bí Ébẹ́lì ṣe ń rí wọn nínú ara ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n gbé wọ̀, yóò rí i pé agbára wọn bùáyà. “Idà” tó sì wà níbẹ̀, tó ń jó lala nígbà gbogbo, tó sì ń yí láìdáwọ́ dúró náà tún jẹ́ ohun àgbàyanu. Bí Ébẹ́lì ṣe ń dàgbà, ṣé ó fìgbà kankan rí i pé ìdúró sú àwọn áńgẹ́lì náà, tí wọ́n sì fi ibi tí wọ́n ń ṣọ́ sílẹ̀? Ó tì o. Ojú ń mọ́, ilẹ̀ ń ṣú, ọdún ń gorí ọdún, títí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún fi ré kọjá, síbẹ̀ àwọn ẹ̀dá tó ní làákàyè wọ̀nyẹn kò kúrò ní ojú ibi tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣọ́. Ìyẹn jẹ́ kí Ébẹ́lì lè mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ní àwọn ìránṣẹ́ tó jẹ́ olódodo àti adúróṣinṣin. Ó wá rí àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ àti ìgbọràn sí Jèhófà kọ́ lára àwọn kérúbù yẹn, èyí tí kò lè rí kọ́ nínú ìdílé rẹ̀. Ó dájú pé àpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì yẹn máa mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára.

Ní gbogbo ọjọ́ ayé Ébẹ́lì, ó rí i pé àwọn kérúbù jẹ́ ìránṣẹ́ olóòótọ́ àti onígbọràn sí Jèhófà

Bí Ébẹ́lì ṣe ń ṣàṣàrò lórí gbogbo ohun tí Jèhófà fi hàn nípa ara rẹ̀ nínú àwọn nǹkan tó dá, àwọn ìlérí rẹ̀ àti àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣe ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ ń lágbára sí i. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rẹ̀ ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ lóòótọ́. Èyí sì tún ń jẹ́ kó dá àwọn ọ̀dọ́ lójú pé wọ́n lè ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run, yálà àwọn ará ilé wọn sin Jèhófà àbí wọn kò sìn ín. Lónìí, a ń rí àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run lára ìṣẹ̀dá tó yí wa ká, a ní Bíbélì lódindi, a sì tún ń rí àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Dájúdájú, nǹkan wọ̀nyí lè mú kí àwa náà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára.

ÌDÍ TÍ ẸBỌ ÉBẸ́LÌ FI TA YỌ

Bí ìgbàgbọ́ tí Ébẹ́lì ní nínú Jèhófà ṣe ń lágbára sí i, ó fẹ́ ṣe ohun tó máa fi ìgbàgbọ́ tó ní yìí hàn. Ṣùgbọ́n, kí ni ọmọ aráyé lásán-làsàn lè fún Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé? Ó dájú pé Ọlọ́run kò nílò ẹ̀bùn kankan tàbí ìrànlọ́wọ́ kankan lọ́dọ̀ èèyàn. Nígbà tó yá, òye òtítọ́ kan yé Ébẹ́lì. Ó yé e pé, tí òun bá lè fi ohun tó dára jù nínú nǹkan tí òun ní rúbọ sí Jèhófà tó sì jẹ́ pé ọkàn tó dáa lòun fi ṣe é, inú Jèhófà tó jẹ́ Baba òun ọ̀run onífẹ̀ẹ́ yóò dùn sí i.

Ni ó bá ṣètò láti fi àwọn kan lára àwọn àgùntàn rẹ̀ rúbọ. Ó yan àwọn àkọ́bí tó dára jù, ó sì fi ibi tó gbà pé ó dára jù lára wọn rúbọ. Kéènì náà fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run kó sì gba ìbùkún, torí náà, ó ṣètò àwọn  èso oko rẹ̀ láti fi rúbọ. Ṣùgbọ́n ìdí tó fi fẹ́ rúbọ yàtọ̀ sí ti Ébẹ́lì. Ìyàtọ̀ yìí wá hàn kedere nígbà tí tẹ̀gbọ́n tàbúrò yìí rú ẹbọ wọn.

Ìgbàgbọ́ ni Ébẹ́lì ní tó fi rú ẹbọ, ní ti Kéènì, kò nígbàgbọ́

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni àwọn ọmọ Ádámù méjèèjì yìí fi iná sun ẹbọ wọn lórí pẹpẹ, níbi tí àwọn kérúbù yóò ti lè rí wọn, torí àwọn nìkan ni aṣojú Jèhófà tí wọ́n lè rí sójú láyé ìgbà náà. Jèhófà sì dá wọn lóhùn! Bíbélì sọ pé: “Jèhófà fi ojú rere wo Ébẹ́lì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:4) Bíbélì kò sọ bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ èyí. Àmọ́ kí nìdí tí ó fi fojú rere wo Ébẹ́lì?

Àbí torí ohun tó fi rúbọ ni? Ẹ̀dá abẹ̀mí ni Ébẹ́lì pa, tó ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ iyebíye sílẹ̀, tó wá fi rúbọ. Àbí Ébẹ́lì tiẹ̀ fòye mọ bí ẹbọ náà ṣe máa níye lórí tó ni? Ìdí ni pé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, Ọlọ́run fi ẹbọ ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lábùkù ṣàpẹẹrẹ ẹbọ tí ó fi Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ẹni pípé rú, ìyẹn “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run,” tí wọ́n máa ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ láìṣẹ̀. (Jòhánù 1:29; Ẹ́kísódù 12:5-7) Àmọ́ ṣá, ó dájú pé Ébẹ́lì ò lè mọ gbogbo ìyẹn nígbà náà.

Ohun kan tá a mọ̀ ni pé: Ébẹ́lì fi ohun tó dára jù lára ohun tó ní rúbọ. Jèhófà sì fi ojú rere wo ẹbọ yẹn àti Ébẹ́lì alára tó rú ẹbọ náà. Ìfẹ́ Jèhófà àti ojúlówó ìgbàgbọ́ tó ní ló mú kó rú ẹbọ náà.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ ti Kéènì yàtọ̀. Jèhófà “kò fi ojú rere kankan wo Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:5) Kì í kúkú ṣe pé ohun tí Kéènì fi rúbọ kò dáa, torí Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè lẹ́yìn náà sọ pé wọ́n lè fi irè oko rúbọ. (Léfítíkù 6:14, 15) Ohun tí Bíbélì sọ nípa Kéènì ni pé “àwọn iṣẹ́ tirẹ̀ burú.” (1 Jòhánù 3:12) Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe títí dòní ni Kéènì ṣe. Ó rò pé téèyàn bá ṣáà ti ń ṣe ohun tí àwọn èèyàn á fi lè gbà pé ó ní ìfọkànsìn Ọlọ́run, ìyẹn náà ti tó. Ṣùgbọ́n kíá ni ìṣe rẹ̀ fi hàn pé kò ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, kò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn.

Nígbà tí Kéènì wá rí i pé Jèhófà kò fi ojú rere wo òun, ṣé ó gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ébẹ́lì? Rárá o. Ṣe ló kanrí àbúrò rẹ̀ sínú. Jèhófà rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ọkàn Kéènì, ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gbà á nímọ̀ràn. Ó kìlọ̀ fún Kéènì pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ohun tó ń pète máa yọrí sí, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé ara rẹ̀ ṣì lè “yá gágá” tó bá lè yíwà pa dà.—Jẹ́nẹ́sísì 4:6, 7.

Kéènì kọ etí ikún sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run. Ó wá ní kí àbúrò rẹ̀ tó fọkàn tán an yìí bá òun lọ sí pápá. Ibẹ̀ ni Kéènì ti lu Ébẹ́lì pa. (Jẹ́nẹ́sísì 4:8) Nípa báyìí, a lè sọ pé Ébẹ́lì wá di ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe inúnibíni ẹ̀sìn sí, òun sì ni ẹni àkọ́kọ́ tó jẹ́ ajẹ́rìíkú. Ó kú lóòótọ́, àmọ́ ìtàn rẹ̀ kò kàn parí síbẹ̀.

Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì wá ń ké jáde sí Jèhófà Ọlọ́run kó lè gbẹ̀san tàbí kó ṣèdájọ́ lórí ẹni tó tá a sílẹ̀. Ọlọ́run sì rí i dájú pé òun ṣèdájọ́, torí ó fìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ Kéènì oníwà ìkà. (Jẹ́nẹ́sísì 4:9-12) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, a ń rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ìgbàgbọ́ Ébẹ́lì tó wà lákọsílẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ayé rẹ̀ kò ju nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún, tó fi hàn pé ẹ̀mí rẹ̀ kò gùn tá a bá fi wé bí ọjọ́ ayé wọn ṣe máa ń gùn nígbà yẹn, síbẹ̀ ó fi ìwọ̀nba tó lò láyé ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kó tó kú, ó mọ̀ pé òun ti rí ojú rere Jèhófà Baba òun ọ̀run, ó sì fẹ́ràn òun. (Hébérù 11:4) Ìyẹn fi hàn dájú pé Jèhófà tí kì í gbàgbé nǹkan á ṣì máa rántí rẹ̀, yóò sì jí i dìde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. (Jòhánù 5:28, 29) Ṣé ìwọ náà á wà níbẹ̀ láti lè fojú kàn án nígbà yẹn? Wàá lè wà níbẹ̀ tó o bá kọbi ara sí ẹ̀kọ́ tó o rí kọ́ lára Ébẹ́lì, tó o sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó ta yọ.

^ ìpínrọ̀ 8 Ní èdè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “pípilẹ̀ ayé” níhìn-ín jẹ mọ́ fífúnrúgbìn, èyí tó máa túmọ̀ sí mímú irú ọmọ jáde. Ó fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí àkọ́kọ́ nínú irú ọmọ ẹ̀dá èèyàn. Kí nìdí tó fi wá jẹ́ pé Ébẹ́lì ni Jésù fi “ìgbà pípilẹ̀ ayé” tọ́ka sí dípò Kéènì tó jẹ́ ọmọ àkọ́kọ́ tí wọ́n bí ní ayé? Ìdí ni pé, ìwà Kéènì àti ìpinnu rẹ̀ fi hàn pé ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Kéènì wá dà bí ti àwọn òbí rẹ̀, torí kò jọ pé ó wà lára àwọn tó máa ní àjíǹde àti àwọn tó lè rí ìràpadà ẹ̀ṣẹ̀ gbà.