Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Ó dáa, wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí:

Nígbà tí òpin bá dé, kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó máa dópin?

Díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa dópin ni ìjọba èèyàn, ogun àti ìwà ìrẹ́jẹ, ìsìn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run tó sì ń mú àwọn èèyàn ṣìnà àti àwọn èèyàn tó ń dá ayé rú.5/1, ojú ìwé 3 sí 5.

Ta ni Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù tí ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

Àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tó máa gbìyànjú láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́ ráúráú lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀ ni Bíbélì pè ní Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù kì í ṣe Sátánì.5/15, ojú ìwé 29 sí 30.

Àwọn nǹkan mẹ́fà wo ló lè mú kéèyàn dàgbà lọ́nà tó ń yẹni?

Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká (1) mọ̀wọ̀n ara wa, (2) wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, (3) ní èrò tó dáa, (4) jẹ́ ọ̀làwọ́, (5) jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, ká sì (6) máa dúpẹ́ oore. Béèyàn bá ń fi àwọn ànímọ́ yìí kọ́ra, á jẹ́ kéèyàn lè dàgbà lọ́nà tó ń yẹni.6/1, ojú ìwé 8 sí 10.

Báwo làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ṣe jẹ́ ká rí bó ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́ tó?

Níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan tó wáyé nílùú Kánà, Jésù sọ omi tó tó ọgọ́rùn-ún gálọ̀nù di wáìnì. Nígbà kan, ó tún bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] èèyàn lọ́nà ìyanu. (Mát. 14:14-21; Jòh. 2:6-11) Àpẹẹrẹ ìwà ọ̀làwọ́ Bàbá rẹ̀ ló ń tẹ̀ lé níbi tó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu méjèèjì yìí.6/15, ojú ìwé 4 sí 5.

Bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, kí ló mú kó dá wa lójú pé a lè múnú Ọlọ́run dùn?

Àwọn ọkùnrin bíi Jóòbù, Lọ́ọ̀tì, àti Dáfídì ṣe àṣìṣe. Síbẹ̀, wọn ò fi Ọlọ́run sílẹ̀, wọ́n kábàámọ̀ ohun tí wọ́n ṣe, wọ́n sì ṣàtúnṣe. Wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run. Àwa náà lè rójú rere rẹ̀.7/1, ojú ìwé 12 sí 13.

Ṣé gbogbo àwọn tó ń ṣe ìsìn èké ló máa pa run nígbà ìparun Bábílónì Ńlá?

Bóyá ni. Ìwé Sekaráyà 13:4-6 sọ pé kódà àwọn kan lára àwọn àlùfáà á jáwọ́ nínú ìsìn èké tí wọ́n ń ṣe, wọ́n á sì sẹ́ pé àwọn ò ṣe ìsìn èké rí.7/15, ojú ìwé 15 sí 16.

Kí nìdí tí Bárákì fi ní àfi dandan kí Dèbórà tẹ̀ lé òun lọ sójú ogun?

Bárákì nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Kàkà kó bẹ Jèhófà pé kó fún òun ní àwọn ohun ìjà ogun púpọ̀ sí i, ńṣe ló ní kí Dèbórà tó jẹ́ aṣojú Ọlọ́run bá àwọn lọ kó lè máa fún òun àtàwọn ọmọ ogun òun níṣìírí. (Oníd. 4:6-8; 5:7)8/1, ojú ìwé 13.

Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Kristẹni lè máa ṣàṣàrò lé lórí?

Díẹ̀ lára wọn ni àwọn ohun tí Jèhófà dá, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àǹfààní tá a ní láti máa gbàdúrà àti ẹ̀bùn ìràpadà tí Jèhófà fún wa.8/15, ojú ìwé 10 sí 13.

Tá a bá ń yẹra fún ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́ tá a bá fẹ́ yan ẹni tá a máa fẹ́?

Kì í ṣe pé a kórìíra àwọn aláìgbàgbọ́. Àmọ́, ó lòdì sí ìlànà Ọlọ́run kí Kristẹni kan máa fẹ́ ẹnì kan tí kò tíì ṣe ìyàsímímọ́ tí kì í sì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:33)8/15, ojú ìwé 25.

Àṣìṣe wo ni Pétérù ṣe, àmọ́ kí ló fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun?

Ìgbàgbọ́ tí àpọ́sítélì Pétérù ní ló mú kó rìn lórí omi lọ pàdé Jésù. (Mát. 14:24-32) Àmọ́ nígbà tí Pétérù wo ìjì òkun, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà á. Ó wá yíjú pa dà sọ́dọ̀ Jésù, kí Jésù lè ràn án lọ́wọ́.9/15, ojú ìwé 16 sí 17.

Ìwé Ìṣe 28:4 sọ pé àwọn aráàlú Málítà rò pé apààyàn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Kí nìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀?

Wọ́n rò pé abo òrìṣà Dike tí wọ́n gbà pé ó máa ń jẹ́ kí ẹ̀san ké lórí àwọn aṣebi ló ń fìyà jẹ Pọ́ọ̀lù nígbà tí ejò olóró kan gé e jẹ.10/1, ojú ìwé 9.

Kí la rí kọ́ látinú bí Màtá ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tí kò pọn dandan gbà á lọ́kàn?

Nígbà kan, Màtá ń sè ó ń sọ̀ kí ara lè tu Jésù. Jésù sọ pé arábìnrin rẹ̀ ní tiẹ̀ yan ìpín rere bó ṣe tẹ́tí gbọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Jésù. Ó yẹ ká ṣọ́ra kí àwọn ohun tí kò pọn dandan má bàa dí ìjọsìn Jèhófà lọ́wọ́.10/15, ojú ìwé 18 sí 20.