Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kọ́ Ọmọ Rẹ Kó Lè Sin Jèhófà—Apá Kejì

Kọ́ Ọmọ Rẹ Kó Lè Sin Jèhófà—Apá Kejì

“Jésù sì ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ní ọgbọ́n àti ní ìdàgbàsókè ti ara-ìyára àti ní níní ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.”LÚÙKÙ 2:52.

ORIN: 41, 89

1, 2. (a) Kí làwọn òbí máa ń ṣàníyàn lé lórí bí àwọn ọmọ wọ́n ṣe ń dàgbà? (b) Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lo ìgbà èwe wọn lọ́nà tó dára?

Ọ̀KAN lára ọjọ́ tínú àwọn òbí máa ń dùn jù lọ ni ọjọ́ tí ọmọ wọ́n ṣèrìbọmi. Arábìnrin Berenice táwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣèrìbọmi kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sọ pé: “Tá a bá rántí báwọn ọmọ wa ṣe ṣèrìbọmi ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, inú wa máa ń dùn gan-an. Ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé àwọn ọmọ wa pinnu láti sin Jèhófà. Àmọ́, a mọ̀ pé àwọn ọmọ wa máa kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro bí wọ́n ti ń dàgbà.” Ọ̀rọ̀ tí Arábìnrin Berenice sọ yìí á yé ẹ dáadáa tó o bá ní ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà tàbí tó ti di ọ̀dọ́. *

2 Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ní ìmọ̀ nípa ìdàgbàsókè àwọn ọmọdé gbà pé tọ́mọ kan bá ti ń dàgbà, iṣẹ́ ńlá ló já lé ọmọ náà àtàwọn òbí rẹ̀ léjìká. Ó wá sọ pé: “Ó yẹ káwọn òbí mọ̀ pé tọ́mọ kan bá ti ń bàlágà, kì í tún ṣọmọdé mọ́, kí wọ́n má sì rò pé àwọn ọmọ náà ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ọmọ náà ti lè dá ronú kí wọ́n sì ṣe nǹkan fúnra wọn, nǹkan tàwọn èèyàn bá ṣe sí wọn lè dùn wọn tàbí kó múnú wọn dùn àti pé àwọn  ọmọ náà á fẹ́ máa wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọ́n lọ́pọ̀ ìgbà.” Àsìkò táwọn ọmọ rẹ wà lọ́dọ̀ọ́ gan-an ni wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í pinnu àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, wọ́n sì lè pinnu pé àwọn á ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sí i. Bíi ti Jésù, àwọn ọmọ rẹ lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà bí wọ́n ṣe ń dàgbà. (Ka Lúùkù 2:52.) Kí lẹ̀yin òbí lè ṣe láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà? Ẹ̀yin òbí lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú bí Jésù ṣe lo ìfẹ́, ìrẹ̀lẹ̀ àti òye nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Báwo lẹ ṣe lè lo àwọn ànímọ́ yìí bẹ́ ẹ ti ń kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè sin Jèhófà?

NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ

3. Kí nìdí tí Jésù fi lè pe àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ rẹ̀?

3 Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gan-an. (Ka Jòhánù 15:15.) Láyé àtijọ́, ó lójú ọ̀rọ̀ táwọn ọ̀gá máa ń bá àwọn ẹrú wọn sọ. Àmọ́, Jésù ò mú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bí ẹrú, ńṣe ló mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Ó máa ń wà pẹ̀lú wọn, ó máa ń sọ èrò rẹ̀ fún wọn, ó sì máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn tí wọ́n bá ń sọ tinú wọn. (Máàkù 6:30-32) Bí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe jọ máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ yìí mú kí wọ́n di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ìyẹn sì mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tóótun fún iṣẹ́ ìwàásù tó gbé lé wọn lọ́wọ́.

4. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè mú àwọn ọmọ yín lọ́rẹ̀ẹ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

4 Arákùnrin Michael tó ti lọ́mọ méjì sọ pé: “Bí àwa àtọmọ wa ò tiẹ̀ kì í ṣẹgbẹ́, àwa òbí lè dọ̀rẹ́ wọn.” Àwọn ọ̀rẹ́ máa ń wáyè láti bára wọn sọ̀rọ̀. Torí náà, wò ó bóyá o lè dín àkókò tó o fi ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí àwọn nǹkan míì kù, kó o lè túbọ̀ máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, kó o sì bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ tún máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀. Torí náà, gbìyànjú láti máa ṣe àwọn ohun tí ọmọ rẹ nífẹ̀ẹ́ sí. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ náà lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ sí irú àwọn orín, fíìmù tàbí eré ìdárayá tọ́mọ rẹ yàn láàyò. Ilaria tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé: “Àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí àwọn orin tí mò ń gbọ́. Kódà, èmi àti dádì mi wá dọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ débi pé kò sóhun tí mi ò lè bá wọn sọ.” Tó o bá mú àwọn ọmọ rẹ lọ́rẹ̀ẹ́ kó o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní àjọṣe “tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà,” ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ẹ ti wá dẹgbẹ́. (Sm. 25:14) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń fi hàn pé kò sígbà tí wọn ò lè bá ẹ sọ̀rọ̀ àti pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè máa sọ tinú wọn fún ẹ.

5. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn máa fìtara ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

5 Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ọ̀wọ́n rí ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn máa fìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Torí náà, ó wù ú kí wọ́n máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ká sòótọ́, Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn láṣeyọrí! Ó sì fọkàn wọn balẹ̀ pé òun á ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí.Mát. 28:19, 20.

6, 7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn òbí jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ bí ìjọsìn Jèhófà ti ṣe pàtàkì tó?

6 Ó dájú pé ẹ̀yin òbí ò fẹ́ kí àjọṣe táwọn ọmọ yín ní pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́. Ọlọ́run sì fẹ́ kẹ́ ẹ tọ́ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Ẹ̀yin òbí ni Ọlọ́run gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ yín, torí náà ẹ ṣe iṣẹ́ yín bí iṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, torí pé ẹ mọ̀ pé ẹ̀kọ́ dára ẹ sì fẹ́ kí wọ́n fẹ́ràn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lẹ ṣe ń rán wọn lọ síléèwé. Bákan náà, àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn máa ń rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ń lọ sípàdé, wọ́n sì máa ń rí i dájú pé wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan míì tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run káwọn ọmọ wọn lè jàǹfààní látinú “ìlànà èrò orí Jèhófà.” Torí pé ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtàkì, ó yẹ kẹ́yin òbí ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́, kí  wọ́n sì mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló lè fún àwọn lọ́gbọ́n. (Òwe 24:14) Bíi ti Jésù, ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa jáde òde ẹ̀rí déédéé kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù.

7 Báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, lílọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Erin tó ń gbé lórílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Ńṣe la máa ń kùn tá a sì máa ń ṣàròyé tó bá di pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí ká lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí. Nígbà míì, a tiẹ̀ máa ń mọ̀ọ́mọ̀ da Ìjọsìn Ìdílé wa rú ká má bàa ṣe é. Àmọ́ àwọn òbí wa kì í gbà fún wa. Ìyẹn jẹ́ kí èmi náà rí i pé kò yẹ kí n jẹ́ kí nǹkan máa tètè sú mi. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé mo pa ìpàdé kan jẹ tàbí mi ò lọ sóde ẹ̀rí, mo tètè máa ń wá nǹkan ṣe sí i. Ká ní àwọn òbí wa ti gba gbẹ̀rẹ́ fún wa nígbà yẹn ni, mi ò ní fẹ́ràn ìpàdé àti òde ẹ̀rí tó bẹ́ẹ̀. Ká ní wọ́n ti jẹ́ kó sú àwọn ni, á ti mọ́ mi lára láti máa pa ìpàdé jẹ, mi ò sì ní fẹ́ràn òde ẹ̀rí tó bẹ́ẹ̀.”

FI HÀN PÉ O JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀

8. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? (b) Kí ni bí Jésù ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà ṣe?

8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Ka Jòhánù 5:19.) Ṣé bí Jésù ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ wá mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ má bọ̀wọ̀ fún un mọ́? Rárá o. Kódà, bí Jésù ṣe túbọ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ túbọ̀ ń fọkàn tán an. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà wá nírẹ̀lẹ̀ bíi tiẹ̀.Ìṣe 3:12, 13, 16.

9. Tó o bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tó o sì máa ń tọrọ àforíjì, kí nìyẹn máa mú káwọn ọmọ rẹ náà máa ṣe?

9 Ẹni pípé ni Jésù, àmọ́ àwa kì í ṣe ẹni pípé, a sì lè ṣàṣìṣe. Torí náà, jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Mọ̀ pé kò sẹ́ni tó gbọ́n tán, kó o sì máa tọrọ àforíjì nígbàkigbà tó o bá ṣàṣìṣe. (1 Jòh. 1:8) Bí àpẹẹrẹ, èwo nínú àwọn ọ̀gá méjèèjì yìí lo máa bọ̀wọ̀ fún jù, ṣé èyí tí kì í gbà pé òun lè ṣàṣìṣe ni àbí èyí tó máa ń tọrọ àforíjì tó bá ṣàṣìṣe? Ó dájú pé èyí tó máa ń tọrọ àforíjì tó bá ṣàṣìṣe lo máa bọ̀wọ̀ fún jù. Bákan náà, tọ́mọ rẹ bá rí i pé o máa ń tọrọ àforíjì, á túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ẹ. Òun náà á sì kọ́ láti máa tọrọ àforíjì tó bá ṣàṣìṣe. Arábìnrin Rosemary tó ní àwọn ọmọ mẹ́ta tó ti dàgbà sọ pé: “Ó ti mọ́ èmi àti ọkọ mi lára láti máa tọrọ àforíjì tá a bá ṣàṣìṣe, ìyẹn sì ti mú kó rọrùn fáwọn ọmọ wa láti máa sọ tinú wọn fún wa pàápàá nígbà tí wọ́n bá níṣòro. A mọ̀ pé a ò mọ gbogbo nǹkan tán, torí náà, a kọ́ wọn pé kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tí ohun kan bá ń jẹ wọ́n lọ́kàn, a máa ń ní kí wọ́n lọ ka àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run tó sọ̀rọ̀ nípa nǹkan náà, àá sì jọ gbàdúrà nípa rẹ̀.”

10. Báwo ni Jésù ṣe máa ń fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó bá ń pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?

10 Jésù máa ń sọ ohun tó fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe fún wọn. Àmọ́ torí pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sábà máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe ohun kan. Bí àpẹẹrẹ, Jésù ò kàn sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n kọ́kọ́ máa wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo Rẹ̀, àmọ́ ó sọ pé: “Gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” Lẹ́yìn tó sọ fún wọ́n pé, “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́,” ó jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tóun fi sọ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́.”Mát. 6:31–7:2.

11. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kó o máa sọ ìdí tó o fi fáwọn ọmọ rẹ lófin tàbí ìdí tó o fi ṣe ìpinnu kan?

11 Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, jẹ́ káwọn ọmọ rẹ máa mọ ìdí tó o fi fún wọn lófin kan tàbí ìdí tó o fi ṣèpinnu kan, ìyẹn ló máa mú kó rọrùn fún wọn láti ṣègbọràn tinútinú. Arákùnrin Barry, tóun náà lọ́mọ mẹ́rin sọ pé: “Tá a bá ń jẹ́ káwọn ọmọ wa mọ ìdí tá a fi ṣe ìpinnu kan, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a máa ń gba tiwọn rò, a kì í ṣe apàṣẹwàá  tàbí aṣèyówùú, wọ́n á sì fọkàn tán wa.” Ó ṣe pàtàkì ká rántí pé àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà náà ní “agbára ìmọnúúrò” tiwọn. (Róòmù 12:1) Arákùnrin Barry tún sọ pé: “Ó yẹ ká kọ́ àwọn ọmọ wa náà láti máa ronú jinlẹ̀ kí wọ́n tó ṣèpinnu.” (Sm. 119:34) Tó o bá ń fi pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé ìdí tó o fi ṣèpinnu tó o ṣe fún ọmọ rẹ, òun náà á rí i pé o ò fojú ọmọdé wo òun mọ́, á sì máa lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ̀ tó bá fẹ́ ṣèpinnu.

MÁA LO ÒYE KÓ O LÈ MỌ ÀWỌN ỌMỌ RẸ DÁADÁA

12. Báwo ni Jésù ṣe lo òye nígbà tó ń ran Pétérù lọ́wọ́?

12 Òye tí Jésù ní jẹ́ kó mọ ìgbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nílò ìrànlọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ohun tó dáa ni àpọ́sítélì Pétérù ní lọ́kàn nígbà tó rọ Jésù pé kó ṣàánú ara rẹ̀ kí wọ́n má bàa pa á. Jésù mọ̀ pé ohun tí Pétérù ń rò yìí ò tọ́ rárá. Kí Jésù lè ran Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù lọ́wọ́, ó fún wọn ní ìkìlọ̀ tó lágbára, ó jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ téèyàn bá kọ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kódà láwọn ìgbà tí kò rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ àti ìbùkún téèyàn máa rí gbà tó bá fínnú-fíndọ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mát. 16:21-27) Ó dájú pé Pétérù rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tí Jésù sọ.1 Pét. 2:20, 21.

13, 14. (a) Báwo lo ṣe lè mọ̀ bí ìgbàgbọ́ ọmọ rẹ bá ti ń jó rẹ̀yìn? (b) Báwo lo ṣe lè fòye mọ ohun tó ń ṣe ọmọ rẹ, kó o sì ràn án lọ́wọ́?

13 Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o ní òye kó o lè mọ ìgbà tí ọmọ rẹ bá nílò ìrànlọ́wọ́. (Sm. 32:8) Bí àpẹẹrẹ, báwo lo ṣe lè mọ̀ bí ìgbàgbọ́ ọmọ rẹ bá ti ń jó rẹ̀yìn? Ṣó o kíyè sí i pé kò fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́? Ṣó ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ àwọn ará láìdáa? Àbí kì í fẹ́ sọ tinú ẹ̀ mọ́? Èyí wù kó jẹ́, má ṣe yára parí èrò sí pé ọmọ rẹ ti ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù. * Síbẹ̀, má ṣe gbójú fo àwọn ohun tó o kíyè sí nípa ọmọ rẹ tàbí kó o wulẹ̀ ronú pé tó bá yá, kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ (Wo ìpínrọ̀ 14)

14 Kí Jésù lè lóye àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dáadáa, ó máa ń bi wọ́n ní ìbéèrè, ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ kó o lè mọ bí wàá ṣe ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́. Bó ṣe jẹ́ pé téèyàn ò bá rọra fa omi jáde láti inú kànga, ọ̀pọ̀ lára omi ọ̀hún ló máa ṣẹ́ dà nù, bẹ́ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé, tó ò bá fi sùúrù wádìí ohun tó ń ṣe ọmọ rẹ, ó máa  ṣòro fún ẹ láti mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ àti bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀. (Ka Òwe 20:5.) Ilaria tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ó máa ń wù mí kí n máa wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ ará, ó sì tún máa ń wù mí kí n máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ iléèwé mi, mi ò mọ ohun tí ǹ bá ṣe. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú, àwọn òbí mi wá kíyè sí i pé inú mi ò dùn. Wọ́n pè mí jókòó lálẹ́ ọjọ́ kan, wọ́n láwọn kíyè sí i pé inú mi ò dùn lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, wọ́n wá bi mí pé kí ló ń ṣe mí. Mo bú sẹ́kún, mo ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fún wọn mo sì ní kí wọ́n ràn mí lọ́wọ́. Wọ́n gbá mi mọ́ra, wọ́n lóhun tí mo sọ yé àwọn, wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn á ràn mí lọ́wọ́.” Àwọn òbí Ilaria ò jáfara, kíá ni wọ́n ran ọmọ wọn lọ́wọ́ kó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi nínú ìjọ.

15. Báwo ni Jésù ṣe máa ń lo òye nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn?

15 Bí Jésù ṣe máa ń lo òye láti mọ ibi táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti nílò ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ló tún máa ń rí ibi tí wọ́n dáa sí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nàtáníẹ́lì gbọ́ pé ìlú Násárétì ni Jésù ti wá, ó sọ pé: “Ohun rere kankan ha lè jáde wá láti Násárétì bí?” (Jòh. 1:46) Látàrí ohun tí Nàtáníẹ́lì sọ yìí, irú èèyàn wo lo máa rò pó jẹ́? Ṣé alárìíwísí ni? Ṣé ẹni tó máa ń ṣe ẹ̀tanú ni? Àbí wàá rò pé kò nígbàgbọ́? Jésù lo òye ó sì wá ibi tí Nàtáníẹ́lì dáa sí. Kódà ó pè é ní “ọmọ Ísírẹ́lì kan dájúdájú, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kankan kò sí.” (Jòh. 1:47) Jésù lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, ó sì lo agbára tó ní yìí láti máa wá ibi táwọn èèyàn dáa sí.

16. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè ní àwọn ànímọ́ rere?

16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o kì í ṣe arínúróde, Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa lo òye. Ṣé wàá máa lo òye tó o ní láti máa wá ibi tọ́mọ rẹ dáa sí? Kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n sọ òun lórúkọ burúkú. Torí náà, má ṣe máa pe ọmọ rẹ ní “ọlọ̀tẹ̀” tàbí “ọmọkọ́mọ.” Tọ́mọ rẹ ò bá tiẹ̀ tíì máa ṣe tó bó o ṣe fẹ́, jẹ́ kó mọ̀ pé o rí gbogbo ìsapá ẹ̀ àti pé o mọ̀ pé ó wù ú láti máa ṣe ohun tó tọ́. Tó bá ṣe ohun tó dáa tàbí tó o rí i pé ó ti ń gbìyànjú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, gbóríyìn fún un. Nígbà tó bá yẹ, máa fún un lómìnira láti ṣe púpọ̀ sí i kó lè túbọ̀ ní àwọn ànímọ́ rere. Ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà nìyẹn. Ní nǹkan bí ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn tó pàdé Nàtáníẹ́lì (tí wọ́n tún ń pè ní Bátólómíù), Jésù sọ ọ́ di ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, Nàtáníẹ́lì sì wá di Kristẹni tó nítara. (Lúùkù 6:13, 14; Ìṣe 1:13, 14) Bó o ṣe ń gbóríyìn fọ́mọ rẹ tó o sì ń fún un níṣìírí, ọkàn rẹ̀ á balẹ̀ pé òun kì í ṣe ẹni tí kò lè dá nǹkan kan ṣe àmọ́ òun lè lo ẹ̀bùn tóun ní láti sin Jèhófà.

WÀÁ LÁYỌ̀ GAN-AN TÓ O BÁ KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ

17, 18. Kí ló máa yọrí sí tó ò bá jẹ́ kó sú ẹ láti kọ́ ọmọ rẹ kó lè sin Jèhófà?

17 Bó o ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ rẹ, ọ̀rọ̀ rẹ lè wá dà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó ṣàníyàn púpọ̀ nípa àwọn tó dà bí ọmọ fún un, ìyẹn àwọn tó ti ràn lọ́wọ́ láti wá sin Jèhófà. Ó ní “ìpọ́njú àti làásìgbò ọkàn-àyà” kí àwọn ará Kọ́ríńtì tó dà bí ọmọ fún un yìí lè mọ bí “ìfẹ́” tó ní fún wọn ṣe lágbára tó. (2 Kọ́r. 2:4; 1 Kọ́r. 4:15) Arákùnrin Victor tó ti tọ́ àwọn ọmọ mẹ́ta dàgbà sọ pé: “Kò rọrùn láti tọ́ wọn nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà. Àmọ́ ayọ̀ tá a wá rí lẹ́yìn náà pọ̀ ju gbogbo wàhálà tá a ṣe nígbà tá à ń tọ́ wọn lọ. A dúpẹ́ pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ wa.”

18 Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ kí wọ́n lè sin Jèhófà. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Wàá láyọ̀ gan-an nígbà tí wọ́n bá ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, tí wọ́n sì ń “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”3 Jòh. 4.

^ ìpínrọ̀ 1 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìjíròrò wa máa dá lórí bí àwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn tó wà láàárín ọdún mẹ́tàlá [13] sí mọ́kàndínlógún [19].

^ ìpínrọ̀ 13 Ẹ̀yin òbí lè ka àlàyé tó wà nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní, ojú ìwé 317 àti Apá Kejì, ojú ìwé 136 sí 141.