“Kí Ọlọ́run àlàáfíà . . . fi ohun rere gbogbo mú yín gbára dì láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.”HÉB. 13:20, 21.

ORIN: 136, 14

1. Kí ló fi hàn pé Jésù ka iṣẹ́ ìwàásù sí iṣẹ́ pàtàkì? Ṣàlàyé.

ÌGBÀ gbogbo ni Jésù máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bíbélì fi hàn pé ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù máa ń sọ jù lọ. Kódà, ó ju ọgọ́rùn-ún ìgbà lọ tó fi sọ̀rọ̀ nípa ìjọba náà nígbà tó ń wàásù. Ó dájú pé ọwọ́ pàtàkì ni Jésù fi mú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.Ka Mátíù 12:34.

2. Àwọn mélòó ló ṣeé ṣe kó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù pàṣẹ tó wà nínú Mátíù 28:19, 20, báwo la sì ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

2 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ló fara han àwọn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lọ lára àwọn tó wá pa dà di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (1 Kọ́r. 15:6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà yẹn náà ló pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.” Iṣẹ́ tí kò rọrùn lèyí jẹ́ nígbà yẹn! * Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n á máa ṣe iṣẹ́ ribiribi náà nìṣó títí di “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Bọ́rọ̀ sì ṣe  rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà wà lára àwọn tó ń wàásù ìhìn rere tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ.Mát. 28:19, 20.

3. Àwọn ohun mẹ́ta wo ni Jèhófà ti fún wa ká lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?

3 Lẹ́yìn tí Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa wàásù, ó ṣèlérí fún wọn pé: “Mo wà pẹ̀lú yín.” (Mát. 28:20) Èyí wá fi hàn pé Jésù ni yóò máa darí iṣẹ́ ìwàásù tá a máa ṣe kárí ayé náà. Ọlọ́run sì ti fún wa ní àwọn “ohun rere gbogbo” tá a máa fi ṣe iṣẹ́ náà. (Héb. 13:20, 21) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò mẹ́ta lára àwọn ohun rere náà: (1) àwọn ohun èlò tá a fi ń ṣe iṣẹ́ náà, (2) onírúurú ọ̀nà tá à ń gbà wàásù àti (3) ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá à ń rí gbà. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ohun èlò tá a ti ń lò láti ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn.

ỌBA NÁÀ RAN ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ RẸ̀ LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ WÀÁSÙ

4. Kí nìdí tá a fi ń lo onírúurú ohun èlò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?

4 Jésù fi “ọ̀rọ̀ ìjọba náà” wé irúgbìn tá a gbìn sórí onírúurú ilẹ̀. (Mát. 13:18, 19) Kí àgbẹ̀ kan tó gbin nǹkan sínú oko rẹ̀, ó máa kọ́kọ́ lo àwọn nǹkan bí àdá tàbí ọkọ́ láti ṣáko tàbí kọ ebè. Bákan náà, láti àwọn ọdún yìí wá, Ọba Ìjọba Ọlọ́run ti fún wa ní àwọn ohun èlò táá mú kó rọrùn fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tá à ń wàásù fún láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àkókò díẹ̀ la fi lo àwọn kan lára àwọn ohun èlò yìí, àwọn míì sì wà lára wọn tá a ṣì ń lò títí di báyìí. Àmọ́, gbogbo ohun èlò yìí ti mú ká di ajíhìnrere tó túbọ̀ já fáfá lọ́nà kan tàbí òmíràn.

5. Kí ni káàdì ìjẹ́rìí, báwo ni wọ́n sì ṣe lò ó?

5 Ohun èlò kan tó ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ni káàdì ìjẹ́rìí. Ọdún 1933 làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í lo káàdì náà. Bí ìwé pélébé báyìí ni káàdì náà rí, wọ́n sì kọ ọ̀rọ̀ ìwàásù ṣókí sínú rẹ̀. Látìgbàdégbà, wọ́n máa ń ṣe káàdì míì tọ́rọ̀ inú rẹ̀ yàtọ̀. Ó rọrùn láti fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìwàásù níwájú onílé. Arákùnrin C. W. Erlenmeyer ò ju ọmọ ọdún mẹ́wàá lọ nígbà tó kọ́kọ́ lo káàdì náà lóde ẹ̀rí. Ó sọ pé: “Ohun tá a sábà máa ń sọ ni pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ka ohun tó wà nínú káàdì yìí.’ Lẹ́yìn tí onílé bá ti ka ohun tó wà nínú káàdì náà tán, àá fi ìwé lọ̀ ọ́, lẹ́yìn náà àá máa bá tiwa lọ.”

6. Báwo ni káàdì ìjẹ́rìí ṣe wúlò tó?

6 Káàdì ìjẹ́rìí náà mú kó rọrùn fáwọn akéde láti wàásù. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń wu àwọn akéde kan pé kí wọ́n máa wàásù, àmọ́ ojú máa ń tì wọ́n, wọn ò sì mọ ohun tí wọ́n á sọ. Báwọn míì bá sì dẹ́nu lé ọ̀rọ̀, wọn kì í dákẹ́ bọ̀rọ̀. Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n á sọ fún onílé láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ wọn kì í wọ àwọn onílé lọ́kàn. Ṣùgbọ́n, káàdì ìjẹ́rìí tó ní àṣàyàn ọ̀rọ̀ ṣókí nínú yìí ran gbogbo akéde lọ́wọ́ láti wàásù lọ́nà tó ṣe kedere tí kò sì lọ́jú pọ̀.

7. Kí lojú àwọn kan rí bí wọ́n ṣe ń lo káàdì ìjẹ́rìí?

7 Àmọ́, gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń rọrùn láti lo káàdì ìjẹ́rìí. Arábìnrin Grace A. Estep, tó ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run sọ pé: “Nígbà míì, àwọn onílé máa ń bi wá pé, ‘Kí ló wà níbẹ̀? Ṣẹ́ ò lè sọ ọ́ fún mi ni?’ ” Yàtọ̀ síyẹn, àwọn onílé kan wà tí wọn ò mọ̀wé kà. A sì ráwọn míì tí wọ́n rò pé ńṣe la ní káwọn máa mú káàdì náà lọ, wọ́n á gbà á lọ́wọ́ wa, wọ́n á sì pa ilẹ̀kùn wọn dé. Bó bá sì jẹ́ onílé tínú ń bí ni, ó lè fa káàdì náà ya sí wẹ́wẹ́. Síbẹ̀ náà, káàdì ìjẹ́rìí táwọn ará wa yìí ń lò mú kí wọ́n máa wàásù fáwọn èèyàn ní gbangba, ó sì tún ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé akéde Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n.

8. Ṣàlàyé báwọn ará ṣe lo ẹ̀rọ giramafóònù láti wàásù. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

8 Ohun èlò míì táwọn ará lò láti ọdún 1930 títí di nǹkan bí ọdún 1944 ni ẹ̀rọ giramafóònù tó ṣeé gbé kiri, èyí táwọn ará kan ń pè ní Áárónì torí pé ẹ̀rọ náà ló máa ń gbẹnu sọ fún wọn lóde ẹ̀rí. (Ka  Ẹ́kísódù 4:14-16.) Tí onílé bá gbà pé kí akéde lo ẹ̀rọ náà, akéde náà á gbé àwo sí i, onílé á sì gbọ́ àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú-mẹ́rin àtààbọ̀ tí wọ́n gbà sórí ẹ̀rọ náà. Tí onílé bá ti gbọ́ àsọyé náà tán, akéde á wá fi ìwé lọ̀ ọ́. Nígbà míì, bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ á kóra jọ kí wọ́n lè gbọ́ àsọyé Bíbélì látinú ẹ̀rọ giramafóònù náà. Lọ́dún 1934 àjọ Watch Tower Society bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ̀rọ giramafóònù tó ṣeé gbé kiri. Ńṣe ni wọ́n dìídì ṣe é káwọn ará lè máa lò ó lóde ẹ̀rí. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n gba àsọyé méjìléláàádọ́rùn-ún [92] tó dá lórí onírúurú ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì sórí rẹ́kọ́ọ̀dù, káwọn ará lè máa lò ó lóde ẹ̀rí.

9. Báwo ni ẹ̀rọ giramafóònù ṣe wúlò tó lóde ẹ̀rí?

9 Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Hillary Goslin gbọ́ ọ̀kan lára àwọn àsọyé Bíbélì náà, ó ní kí akéde náà yá òun ní ẹ̀rọ giramafóònù náà fún ọ̀sẹ̀ kan, káwọn aládùúgbò òun náà lè gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tí akéde náà pa dà lọ, àwọn olùfìfẹ́hàn mélòó kan ti ń dúró dè é. Nígbà tó ṣe, àwọn kan lára wọn ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Kódà, àwọn ọmọbìnrin Hillary méjèèjì lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nígbà tó yá, wọ́n sì rán wọn lọ sìn ní orílẹ̀-èdè mìíràn. Bíi ti káàdì ìjẹ́rìí, ẹ̀rọ giramafóònù náà ran ọ̀pọ̀ akéde lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, Ọba náà lo Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run láti kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa wàásù.

WỌ́N WÀÁSÙ ÌHÌN RERE LÓNÍRÚURÚ Ọ̀NÀ

10, 11. Báwo làwọn èèyàn Jèhófà ṣe lo ìwé ìròyìn àti rédíò láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, báwo nìyẹn sì ṣe mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ ìwàásù wa?

10 Ọba náà tún ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere náà fún ọ̀pọ̀ èèyàn lónírúurú ọ̀nà. Ìyẹn sì ṣe pàtàkì torí pé “díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́” tó ń wàásù ìhìn rere náà nígbà yẹn. (Ka Mátíù 9:37.) Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, a lo àwọn ìwé ìròyìn káwọn èèyàn tó pọ̀ sí i lè gbọ́ ìwàásù wa, tó fi mọ́ àwọn tó wà níbi táwọn Ẹlẹ́rìí ò tí tó nǹkan. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, Arákùnrin Charles Taze Russell máa ń fi wáyà tẹ àsọyé Bíbélì ránṣẹ́ sí àwọn aṣojú iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn. Àwọn aṣojú iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn náà á wá fi wáyà tẹ àsọyé náà ránṣẹ́ sáwọn iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn míì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Kánádà àti ilẹ̀ Yúróòpù. Nígbà tó fi máa di ọdún 1913, mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000,000] làwọn tó ń rí àsọyé Arákùnrin Russell kà nínú àwọn ìwé ìròyìn tó tó ẹgbẹ̀rún méjì [2,000]!

11 Lẹ́yìn ikú Arákùnrin Russell, a bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀nà míì tá a rí pé ó wúlò gan-an láti wàásù ìhìn rere. Ní April 16, ọdún 1922, Arákùnrin Joseph F. Rutherford sọ ọ̀kan lára àwọn àsọyé rẹ̀ àkọ́kọ́ lórí rédíò, àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ sì tó ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000]. Àmọ́ nígbà tó di February 24, ọdún 1924, ètò Ọlọ́run dá ilé iṣẹ́ rédíò rẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn WBBR sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó láti wàásù. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ December 1, ọdún 1924 lédè Gẹ̀ẹ́sì tiẹ̀ sọ pé ‘bí wọ́n ṣe ń lo rédíò láti wàásù nígbà yẹn kò ná wọn lówó jù, òun sì tún ni ọ̀nà tó wúlò jù lọ tí wọ́n tíì lò láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn.’ Bó ṣe rí nígbà tá à ń lo ìwé ìròyìn, ìwàásù tá a ṣe lórí rédíò wa náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀, pàápàá láwọn ibi tí àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ò ti tó nǹkan.

Ọ̀pọ̀ akéde Ìjọba Ọlọ́run ń wàásù láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí, wọ́n sì máa ń ní káwọn èèyàn lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org (Wo ìpínrọ̀ 12, 13)

12. (a) Èwo lo fẹ́ràn jù nínú àwọn ọ̀nà tá à ń gbà wàásù láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí? (b) Kí lo lè ṣe tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti wàásù láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí?

12 Ní báyìí, ètò Ọlọ́run túbọ̀ ń kọ́ wa pé ká máa wàásù láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí, irú bí àwọn ibùdókọ̀ yálà ti mọ́tò tàbí rélùwéè, àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí, àwọn gbàgede ìlú àti ní ọjà. Bí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́ láti wàásù láwọn ibi tá a mẹ́nu kàn yìí, o ò ṣe gbàdúrà nípa rẹ̀, kó o sì ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin  Angelo Manera, Jr., tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò sọ. Ó ní: “Bí ètò Ọlọ́run bá gbé ọ̀nà tuntun míì tá a lè gbà máa wàásù jáde, ńṣe la máa ń rí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà míì tá a lè gbà sin Jèhófà, ọ̀nà míì tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin àti ọ̀nà míì tá a lè gbà pa ìwà títọ́ wa mọ́, a sì máa ń fẹ́ kí Jèhófà rí i pé a ṣe tán láti sìn ín lọ́nà èyíkéyìí tó bá fẹ́.” Tá a bá ń lo ọ̀nà tuntun tí ètò Ọlọ́run ní ká máa gbà wàásù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wa, ó máa jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká sì túbọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ á sì túbọ̀ dán mọ́rán.Ka 2 Kọ́ríńtì 12:9, 10.

13. Àwọn àṣeyọrí wo la ti ṣe bá a ti ń lo ìkànnì jw.org lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa? Àwọn ìrírí wo lo ti ní bó o ṣe ń lò ó?

13 Ọ̀pọ̀ akéde máa ń darí àwọn èèyàn lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org, kí wọ́n lè lọ ka àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì níbẹ̀ kí wọ́n sì tún wà wọ́n jáde ní èdè tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] lọ. Àwọn tó ń lọ sórí ìkànnì wa lójoojúmọ́ ju mílíọ̀nù kan ààbọ̀ àti ọ̀kẹ́ márùn-ún [1,600,000] lọ. Bí rédíò ṣe mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ ìwàásù wa ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn bẹ́ẹ̀ náà ni ìkànnì jw.org ń mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbọ́ ìhìn rere lónìí, kódà láwọn ibi tó jìnnà réré pàápàá.

ÀWỌN AKÉDE ÌJỌBA ỌLỌ́RUN GBA ÌDÁLẸ́KỌ̀Ọ́

14. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run nílò, kí ló sì ti jẹ́ kí wọ́n di olùkọ́ tó já fáfá?

14 A ti jíròrò díẹ̀ lára àwọn ohun èlò táwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run fi wàásù ìhìn rere àti onírúurú ọ̀nà tí wọ́n gbà wàásù. Àmọ́, ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a ti rí gbà ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, tó bá ṣẹlẹ̀ pé onílé kan ò fara mọ́ àsọyé tó gbọ́ látorí ẹ̀rọ giramafóònù tàbí tí ohun tí onílé kà nínú káàdì ìjẹ́rìí wù ú tó sì fẹ́ mọ̀ sí i, kí la máa ṣe? Ó pọn dandan káwọn akéde mọ bí wọ́n ṣe lè fọgbọ́n dá àwọn tí kò bá fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn lóhùn àti bí wọ́n ṣe lè kọ́ àwọn tó mọyì òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí Arákùnrin Nathan H. Knorr rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn akéde gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ táá mú kí wọ́n lè máa lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n ní tí wọ́n bá ń wàásù. Kí ni ètò Ọlọ́run wá ṣe? Ètò Ọlọ́run dá Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ nínú àwọn ìjọ fún ìgbà àkọ́kọ́ lọ́dún 1943. Ilé ẹ̀kọ́ yìí ti ràn wá lọ́wọ́ láti di olùkọ́ tó já fáfá.

15. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn kan ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run? (b) Kí ló mú kó o gbà pé òótọ́ ni ìlérí tí Jèhófà ṣe nínú Sáàmù 32:8?

15 Ọ̀pọ̀ àwọn akéde ni kò tètè mọ́ lára láti máa sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ. Arákùnrin Julio S. Ramu sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ tó ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1944. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lórí Dóẹ́gì, ọkùnrin kan tó jẹ́ pé  inú ẹsẹ Bíbélì márùn-ún péré lorúkọ rẹ̀ ti fara hàn! Orí ẹsẹ Bíbélì márùn-ún yìí ló sì ní láti gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà. Torí náà ó sọ pé: “Ńṣe ni ẹsẹ̀ mi àti ọwọ́ mi ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, eyín mi sì ń lù mọ́ra wọn keke. Ìṣẹ́jú mẹ́ta péré ni mo fi ṣiṣẹ́ náà. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí màá sọ̀rọ̀ lórí pèpéle, àmọ́ mi ò jẹ́ kó sú mi.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fáwọn ọmọdé kan láti sọ̀rọ̀ níwájú ìjọ, àwọn náà máa ń ṣiṣẹ́ nílé ẹ̀kọ́ náà. Arákùnrin Angelo Manera tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọmọkùnrin kékeré kan ṣiṣẹ́ fúngbà àkọ́kọ́ nílé ẹ̀kọ́ náà. Ó ní: “Àyà rẹ̀ ń já débi pé nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Kò sì dákẹ́ ẹkún sísun títí tó fi parí iẹ́ náà.” Ṣé ìwọ náà kì í fẹ́ dáhùn nípàdé àbí o kì í fẹ́ ṣiṣẹ́ lórí pèpéle torí pé ò ń tijú tàbí torí pé o rò pé o ò lè ṣe é? Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wàá rí i pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó ṣe ran àwọn tó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run nígbà yẹn lọ́wọ́.Ka Sáàmù 32:8.

16. Àwọn wo ló ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì (a) ṣáájú ọdún 2011 àti (b) láti ọdún 2011?

16 Kì í ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run nìkan làwọn èèyàn Jèhófà ti ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́. Àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn míì ti jàǹfààní tó pọ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ náà ń sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí ètò Ọlọ́run fi dá ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀, ó ní wọ́n dá a sílẹ̀ “kí ohun táwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa kọ́ níbẹ̀ lè mú kí wọ́n ní ìtara tó pọ̀ sí i fún iṣẹ́ ajíhìnrere.” Ọdún 1943 ni wọ́n dá Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sílẹ̀, àwọn tó sì ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ látìgbà yẹn ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ààbọ̀ [8,500]. Àwọn míṣọ́nnárì tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ sì ti sìn láwọn ilẹ̀ tó tó àádọ́sàn-án [170]. Àmọ́ látọdún 2011, kìkì àwọn tó wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ló ń lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Irú bí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí àwọn míṣọ́nnárì tó ń sìn ní pápá àmọ́ tí wọn kò tíì lọ sílé ẹ̀kọ́ náà rí.

17. Báwo ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ṣe gbéṣẹ́ tó?

17 Báwo ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ṣe gbéṣẹ́ tó? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Japan. Ní oṣù August ọdún 1949, àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Japan ò ju mẹ́wàá lọ. Àmọ́ nígbà tó fi máa di ìparí ọdún yẹn, àwọn míṣọ́nnárì mẹ́tàlá tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ń wàásù lọ ní pẹrẹu níbẹ̀. Ní báyìí, nǹkan bí ẹgbàá méjì-dín-láàádọ́fà [216,000] akéde ló wà lórílẹ̀-èdè Japan, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára wọn tó ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà!

18. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ míì wo ló ti ran àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè túbọ̀ lágbára?

18 Àwọn ilé ẹ̀kọ́ míì bí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà, Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run, Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Àyíká Àtàwọn Ìyàwó Wọn àti Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Àtàwọn Ìyàwó Wọn, ti ṣe gudugudu méje láti mú kí ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn Jèhófà túbọ̀ lágbára kí wọ́n sì túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Láìsí àní-àní, Ọba náà ń bá a nìṣó láti máa kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́.

19. Kí ni Arákùnrin Charles Taze Russell sọ nípa iṣẹ́ ìwàásù, báwo lọ̀rọ̀ sì ṣe rí bẹ́ẹ̀?

19 Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tí Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Jésù Kristi, Ọba wa, sì ń bá a nìṣó láti máa kọ́ wa. Kí Arákùnrin Charles Taze Russell tó kú lọ́dún 1916, ó sọ pé iṣẹ́ ìwàásù náà máa dé apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Ó sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kan pé: “Iṣẹ́ náà ń yára gbèrú sí i, yóò sì máa bá a nìṣó láti gbèrú, torí pé a ṣì máa wàásù ‘ìhìn rere ìjọba náà’ jákèjádò ayé.” (Ìwé Faith on the March, látọwọ́ A. H. Macmillan, ojú ìwé 69) Bó ṣe sọ gan-an lọ̀rọ̀ rí! Ó sì yẹ ká kún fún ọpẹ́ pé Ọlọ́run àlàáfíà ń bá a nìṣó láti fún wa ní ohun tá a nílò láti ṣe iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ jù lọ yìí! Òótọ́ ni pé ó ń fún wa ní “ohun rere gbogbo” tá a nílò láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀!

^ ìpínrọ̀ 2 Ẹ̀rí fi hàn pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó wà níbẹ̀ di Kristẹni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará ní Kọ́ríńtì ó pè wọ́n ní “ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: ‘Púpọ̀ jù lọ nínú wọn ṣì wà títí di ìsinsìnyí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú.’ Torí náà, ó jọ pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni míì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní mọ ọ̀pọ̀ lára àwọn tí Jésù pàṣẹ náà fún ní tààràtà.