“Jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ . . . kọ́ wa ní ohun tí àwa ó ṣe sí ọmọ náà tí a ó bí.”—ONÍD. 13:8, Bíbélì Mímọ́.

ORIN: 88, 120

1. Kí ni Mánóà ṣe nígbà tó gbọ́ pé òun máa di bàbá ọmọ?

Ó YA Mánóà lẹ́nu nígbà tí ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé àwọn máa bímọ. Ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn méjèèjì ti gbà pé àwọn ò lè lọ́mọ láyé. Àmọ́, áńgẹ́lì Jèhófà ti fara han ìyàwó Mánóà, ó sì ti jẹ́ kó mọ̀ pé wọ́n máa bímọ! Ó dájú pé inú Mánóà dùn, àmọ́ ó tún gbà pé iṣẹ́ ńlá ló já lé òun léjìká. Báwo làwọn méjèèjì ṣe máa kọ́ ọmọ wọn kó lè sin Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń hùwà burúkú? Mánóà ‘bẹ Jèhófà’ pé: “Èmi bẹ̀ ọ, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run [áńgẹ́lì], tí ìwọ ràn tún tọ̀ wá wá, kí ó lè kọ́ wa ní ohun tí àwa ó ṣe sí ọmọ náà tí a ó bí.”Oníd. 13:1-8, Bíbélì Mímọ́.

2. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ yín? (Wo àpótí náà, “ Àwọn Wo Ló Ṣe Pàtàkì Jù Pé Kó O Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?”)

2 Tó o bá jẹ́ òbí, ohun tí Mánóà bẹ̀bẹ̀ fún yẹn ò lè ṣàjèjì sí ẹ. Iṣẹ́ ńlá ló já lé ìwọ náà léjìká, ìyẹn bó o ṣe máa kọ́ ọmọ rẹ kó lè mọ Jèhófà kó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. * (Òwe 1:8) Kíyẹn lè ṣeé ṣe, àwọn òbí máa ń ṣètò Ìjọsìn Ìdílé tó ń lọ déédéé tọ́mọ kọ̀ọ̀kan sì máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀. Ká sòótọ́, Ìjọsìn Ìdílé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ nìkan ò tó láti kọ́  ọmọ kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì kó sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (Ka Diutarónómì 6:6-9.) Kí lẹ̀yin òbí tún lè ṣe láti kọ́ ọmọ yín kó lè mọ Jèhófà kó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò bí ẹ̀yin òbí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Bí Jésù ò tiẹ̀ bímọ, ẹ̀yin òbí lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú bó ṣe lo ìfẹ́, ìrẹ̀lẹ̀ àti òye nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ànímọ́ yìí níkọ̀ọ̀kan.

NÍFẸ̀Ẹ́ ỌMỌ RẸ

3. Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe mọ̀ pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn?

3 Jésù máa ń sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. (Ka Jòhánù 15:9.) Bó ṣe máa ń wà pẹ̀lú wọn tún fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́. (Máàkù 6:31, 32; Jòh. 2:2; 21:12, 13) Yàtọ̀ síyẹn, kò kàn máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ṣáá, àmọ́ ó tún mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Torí náà, ó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn. Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

4. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kó dá àwọn ọmọ rẹ lójú pé o nífẹ̀ẹ́ wọn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

4 Máa sọ fáwọn ọmọ rẹ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ọ́ lógún. (Òwe 4:3; Títù 2:4) Samuel tó ń gbé nílẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, Dádì máa ń ka Ìwé Ìtàn Bíbélì fún mi lálaalẹ́. Wọ́n máa ń dáhùn àwọn ìbéèrè mi, wọ́n á gbá mi mọ́ra, wọ́n á sì fẹnu kò mí lẹ́nu ká tó lọ sùn. Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí mo wá mọ̀ pé nígbà tí dádì mi wà ní kékeré, àwọn òbí wọn kì í gbá wọn mọ́ra tàbí fẹnu kò wọ́n lẹ́nu! Síbẹ̀, Dádì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí n lè mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi. Ìdí nìyẹn témi náà fi nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, ara máa ń tù mí ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ pé mo nírú wọn ní Bàbá.” Ẹ̀yin òbí, ẹ jẹ́ kó mọ́ yín lára láti máa sọ fáwọn ọmọ yín pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an,” kí ọkàn wọn lè balẹ̀ bíi ti Samuel tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ rẹ̀ tán. Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn. Ẹ jọ máa sọ̀rọ̀, ẹ jọ máa jẹun, kẹ́ ẹ sì máa bá wọn ṣeré.

5, 6. (a) Kí ni Jésù máa ń ṣe fáwọn tó nífẹ̀ẹ́? (b) Ṣàlàyé bí ìbáwí tó yẹ ṣe máa fọkàn àwọn ọmọ rẹ balẹ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.

 5 Jésù sọ pé: “Gbogbo àwọn tí mo ní ìfẹ́ni fún ni mo ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, tí mo sì ń bá wí.” * (Ìṣí. 3:19) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò yéé bára wọn jiyàn nípa “ẹni tí ó tóbi jù” láàárín wọn, Jésù ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn sú òun. Nígbà tó sì rí i pé wọn ò fi ìmọ̀ràn òun sílò, ó fìfẹ́ bá wọn wí lákòókò tó tọ́ àti níbi tó yẹ.Máàkù 9:33-37.

6 Máa bá àwọn ọmọ rẹ wí kí wọ́n lè mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn. Nígbà míì, ohun tó o nílò ò ju pé kó o jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tí ohun kan fi dáa tàbí ìdí tí kò fi dáa. Nígbà míì sì rèé, wọ́n lè ṣàìgbọràn. (Òwe 22:15) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Máa fìfẹ́ bá wọn wí lákòókò tó tọ́ àti níbi tó yẹ, kó sì jẹ́ lóhùn pẹ̀lẹ́. Máa fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà kó o sì máa fún wọn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́. Arábìnrin Elaine tó ń gbé lórílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Àwọn òbí mi máa ń bá mi wí nígbàkigbà tí mo bá ṣẹ̀. Tí wọ́n bá sọ fún mi pé àwọn á fìyà jẹ mí tí mo bá ṣe ohun tí ò dáa, wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Wọn kì í fìbínú bá mi wí, wọn kì í sì bá mi wí láìsọ ohun tí mo ṣe. Torí náà, ọkàn mi máa ń balẹ̀. Mi ò kì í kọjá àyè mi, mo mọ ohun tí wọ́n fẹ́ àtohun tí wọn ò fẹ́.”

JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀

7, 8. (a) Báwo ni àdúrà tí Jésù gbà ṣe fi hàn pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? (b) Báwo ni àdúrà rẹ ṣe lè jẹ́ káwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé ó yẹ káwọn gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run?

7 Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀kan lára àwọn àdúrà tí Jésù gbà kẹ́yìn nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé? Ó gbàdúrà pé: “Ábà, Baba, ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ọ; mú ife yìí kúrò lórí mi. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí èmi fẹ́, bí kò ṣe ohun tí ìwọ fẹ́.” * (Máàkù 14:36) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Ọmọ Ọlọ́run, ó bẹ Bàbá rẹ̀ pé kó ran òun lọ́wọ́, torí náà, ó dájú pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ á mọ̀ pé ó yẹ káwọn náà máa bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́.

8 Kí làwọn ọmọ rẹ máa ń rí kọ́ nínú àdúrà tó o máa ń gbà? Òótọ́ ni pé kì í ṣe torí kó o lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ nìkan lo ṣe ń gbàdúrà sí Jèhófà. Àmọ́, tí wọ́n bá gbọ́ bó o ṣe ń gbàdúrà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, àwọn náà á mọ̀ pé ó yẹ káwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ana tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Nígbà tá a bá níṣòro, àwọn òbí mi máa ń gbàdúrà sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tí ara àwọn òbí mi àgbà ò yá, wọ́n gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún àwọn lókun táwọn á fi lè fara da ìṣòro náà, kó sì fún àwọn lọ́gbọ́n káwọn lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Kódà nígbà tí nǹkan bá nira fún wọn, wọ́n máa ń kó gbogbo àníyàn wọn lé Jèhófà. Torí náà, èmi náà kọ́ láti máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” Tó o bá ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, bó o ṣe ń gbàdúrà fún wọn, tún máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ran ìwọ náà lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè bá ọ̀gá rẹ sọ̀rọ̀ pé kó fún ẹ láyè láti lọ sí àpéjọ, o sì tún lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o nígboyà kó o lè wàásù fún aládùúgbò yín kan tàbí kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àwọn ọmọ rẹ náà á sì kọ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀.

9. (a) Báwo ni Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kí wọ́n sì máa ran àwọn míì lọ́wọ́? (b) Tó o bá ń ran àwọn míì lọ́wọ́, kí làwọn ọmọ rẹ á rí kọ́ lára rẹ?

9 Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́rọ̀ àti níṣe pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì máa  ran àwọn míì lọ́wọ́. (Ka Lúùkù 22:27.) Ó kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n máa yááfì àwọn nǹkan nítorí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àti nítorí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Tí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ bá ń mú kí ìwọ náà yááfì àwọn nǹkan, àwọn ọmọ rẹ á kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ. Arábìnrin Debbie tó lọ́mọ méjì sọ pé: “Alàgbà ni ọkọ mi, tó bá ń wáyè láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, mi ò kí ń jowú. Mo mọ̀ pé tó bá tó àsìkò láti gbọ́ tiwa, ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.” (1 Tím. 3:4, 5) Arákùnrin Pranas tó jẹ́ ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Nígbà tó yá, inú àwọn ọmọ wa máa ń dùn láti yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ní àpéjọ, kí wọ́n sì tún ṣe àwọn iṣẹ́ míì nínú ètò Ọlọ́run. Inú wọn máa ń dùn yùngbà, wọ́n lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀, wọ́n sì rí i pé àwọn wúlò nínú ètò Ọlọ́run!” Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni gbogbo ìdílé náà ń ṣe báyìí. Tó o bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tó o sì máa ń yááfì nǹkan nítorí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, àwọn ọmọ rẹ á kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ, àwọn náà á sì máa ran àwọn míì lọ́wọ́.

MÁA LO ÒYE

10. Nígbà táwọn kan wá bá Jésù, báwo ló ṣe lo òye?

10 Jésù máa ń lo òye, ó máa ń wò ré kọjá ohun tó fara hàn sójú táyé, ó sì máa ń fòye mọ ìdí táwọn èèyàn fi ṣe ohun tí wọ́n ṣe. Lọ́jọ́ kan, àwọn kan lára àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ ní Gálílì ń tẹ̀ lé e kiri ṣáá. (Jòh. 6:22-24) Àmọ́ torí pé Jésù lè mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn, ó fòye mọ̀ pé torí oúnjẹ ni wọ́n ṣe ń wá òun kì í ṣe torí kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ òun. (Jòh. 2:25) Jésù rí i pé wọ́n ní èrò tí kò tọ́, ó wá fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà, ó sì ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ ṣàtúnṣe.Ka Jòhánù 6:25-27.

Ṣé ọmọ rẹ fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù, ṣé ó sì máa ń jàǹfààní nínú rẹ̀? (Wo ìpínrọ̀ 11)

11. (a) Báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè mú kó o mọ̀ bóyá ó máa ń wu ọmọ rẹ láti lọ sóde ẹ̀rí? (b) Báwo lo ṣe lè mú kí ọmọ rẹ fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù kó sì máa jàǹfààní nínú rẹ̀?

11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o kì í ṣe arínú-róde, o lè fòye mọ̀ bóyá ọmọ rẹ fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù tàbí kò fẹ́ràn rẹ̀. Àwọn òbí kan máa ń wáyè fún ìsinmi ráńpẹ́ kí wọ́n sì fi nǹkan díẹ̀ panu nígbà tí wọ́n bá wà lóde ẹ̀rí. Síbẹ̀, o lè wò ré kọjá ohun tó hàn sójú táyé kó o sì bi ara rẹ pé, ‘Ṣé iṣẹ́ ìwàásù gan-an ni ọmọ mi fẹ́ràn ni àbí àkókò tá a fi ń wá nǹkan panu?’ Tó o bá róye pé àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe kí ọmọ rẹ lè túbọ̀ fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù kó sì máa jàǹfààní nínú rẹ̀, wá bó o ṣe lè ràn án lọ́wọ́. Ronú oríṣiríṣi ọ̀nà tó  o lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́, kẹ́ ẹ sì jọ máa ṣiṣẹ́ déédéé lóde ẹ̀rí.

12. (a) Báwo ni Jésù ṣe lo òye nígbà tó ń kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ìṣekúṣe? (b) Kí ló fi hàn pé ìkìlọ̀ tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bọ́ sákòókò?

12 Jésù tún lo òye nígbà tó ń sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa àwọn àṣìṣe tó lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ pé ìṣekúṣe ò dáa. Àmọ́ Jésù kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn ohun tó lè yọrí sí ìṣekúṣe, ó sọ fún wọn pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Mátíù 5:27-29) Ìkìlọ̀ yẹn bọ́ sákòókò gan-an fáwọn Kristẹni tó ń gbé láyé nígbà tí ìjọba Róòmù ń ṣàkóso. Nígbà tí òpìtàn kan ń kọ̀wé nípa ohun tó máa ń wáyé nínú gbọ̀ngàn ìṣeré nílùú Róòmù, ó sọ pé: “Oríṣiríṣi ìwòkuwò àtàwọn ọ̀rọ̀kọrọ̀ ló kún ibẹ̀, èyí tí ìṣekúṣe bá pọ̀ jù nínú rẹ̀ ni inú wọn máa ń dùn sí jù, wọ́n á sì máa hó yèè.” Ẹ ò rí i pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì fòye mọ̀ pé ó yẹ kóun kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn nǹkan tó lè mú kó ṣòro fún wọn láti ṣe ohun tó tọ́!

13, 14. Báwo lo ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ kí wọ́n má bàa lọ́wọ́ sí àwọn eré ìnàjú tí kò dára?

13 Tó o bá ń lo òye, wàá lè dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ ohun tó lè mú kí wọ́n ṣe nǹkan tí Jèhófà ò fẹ́. Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, ó ti wá rọrùn báyìí fáwọn ọmọdé láti rí àwọn àwòrán oníhòòhò àtàwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe, kódà nígbà tí wọ́n ṣì kéré gan-an. Òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń sọ fáwọn ọmọ wọn pé kò dáa kéèyàn máa wo àwọn nǹkan tó ń mọ́kàn fà sí ìṣekúṣe. Àmọ́, tó o bá ń lo òye, wàá lè mọ̀ bóyá ó ti ń wu ọmọ rẹ láti máa wo àwòrán oníhòòhò. Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ọmọ mi mọ ewu tó wà nínú kéèyàn máa wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe? Ǹjẹ́ ohun kan wà tó lè mú kó fẹ́ láti máa wò ó? Ṣé kì í ṣe pé mo ti le koko jù débi pé á ṣòro fáwọn ọmọ mi láti wá bá mi fún ìrànlọ́wọ́ nígbàkigbà tó bá ń ṣe wọ́n bíi kí wọ́n wo ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe?’ Kódà nígbà táwọn ọmọ rẹ bá ṣì kéré, o lè sọ fún wọn pé: “Jọ̀ọ́ wá sọ fún mi nígbàkigbà tó o bá já sí ìkànnì kan tó ní àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe tó sì ń ṣe ẹ́ bíi kó o wò ó. Má ṣe jẹ́ kójú tì ẹ́. Màá ràn ẹ́ lọ́wọ́.”

14 Ó ṣe pàtàkì kí ìwọ òbí náà kíyè sára nípa irú eré ìnàjú tó o máa yàn. Pranas tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Àpẹẹrẹ táwa òbí bá fi lélẹ̀ nípa irú orin, fíìmù tàbí ìwé tá a yàn láàyò làwọn ọmọ náà á máa tẹ̀ lé. O lè ti sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wọn nípa ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe àtohun tí wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe, àmọ́ ohun tí wọ́n bá rí tó ò ń ṣe làwọn náà á máa ṣe.” Táwọn ọmọ rẹ bá rí i pé eré ìnàjú tó dára nìwọ náà yàn láàyò, ohun táwọn náà á ṣe nìyẹn.Róòmù 2:21-24.

JÈHÓFÀ Á GBỌ́ ÀDÚRÀ RẸ

15, 16. (a) Kí ló lè mú kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

15 Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Mánóà bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kóun lè tọ́ ọmọ òun? “Ọlọ́run tòótọ́ fetí sí ohùn Mánóà.” (Oníd. 13:9) Ẹ̀yin òbí, Jèhófà á gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tiyín náà. Á dáhùn àdúrà yín, á sì ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè kọ́ àwọn ọmọ yín. Ó dájú pé ẹ máa ṣàṣeyọrí tẹ́ ẹ bá nífẹ̀ẹ́ wọn, tẹ́ ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tẹ́ ẹ sì ń lo òye.

16 Bí Jèhófà ṣe ń ran ẹ̀yin òbí lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè kọ́ àwọn ọmọ yín kéékèèké, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bẹ́ ẹ ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù kẹ́ ẹ sì fi ìfẹ́, ìrẹ̀lẹ̀ àti òye kọ́ àwọn ọmọ yín tó ti dàgbà kí wọ́n lè sin Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìjíròrò wa máa dá lórí bí àwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn tí kò tíì ju ọmọ ọdún méjìlá lọ.

^ ìpínrọ̀ 5 Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìbáwí, ohun tó máa ń túmọ̀ sí ni pé ká fìfẹ́ tọ́ni sọ́nà, ká fìfẹ́ dáni lẹ́kọ̀ọ́, ká sì fìyà jẹni nígbà míì, àmọ́ kó má ṣe jẹ́ pẹ̀lú ìbínú.

^ ìpínrọ̀ 7 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé: “Nígbà ayé Jésù, àwọn ọmọ máa ń pe bàbá wọn ní Ábà. Wọ́n máa ń lo èdè yìí láti fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ bàbá wọn, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un.”The International Standard Bible Encyclopedia.