Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  November 2015

 LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

‘Ohunkóhun Ò Gbọ́dọ̀ Dí Yín Lọ́wọ́!’

‘Ohunkóhun Ò Gbọ́dọ̀ Dí Yín Lọ́wọ́!’

NÍGBÀ ìrúwé ọdún 1931, àwọn èrò ń rọ́ tìrítìrí níwájú gbọ̀ngàn ìṣeré Pleyel táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó. Orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélógún [23] ni wọ́n ti wá ṣèpàdé nílùú Paris. Iwájú gbọ̀ngàn náà ni àwọn takisí ń já àwọn èèyàn tó ró dẹ́dẹ́ tó kàn dudu náà sí. Kò sì pẹ́ tí gbọ̀ngàn náà fi kún fáwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000]. Kì í ṣe torin ni wọ́n bá wá, ọ̀rọ̀ Arákùnrin Joseph F. Rutherford, tó ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù wa nígbà náà ni wọ́n wá gbọ́. Wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí èdè Faransé, Jámánì àti èdè Polish. Gbogbo àwọn tó wà nínú gbọ̀ngàn náà ló ń gbọ́ ohùn Arákùnrin Rutherford ketekete, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn.

Mánigbàgbé ni àpéjọ tó wáyé nílùú Paris yìí jẹ́ torí pé ìgbà náà ni àwọn ará fi kún ìtara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè Faransé. Arákùnrin Rutherford ké sí gbogbo àwọn ará tó wà níkàlẹ̀, pàápàá jù lọ àwọn ọ̀dọ́, pé kí wọ́n wọṣẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri lórílẹ̀-èdè Faransé. Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ John Cooke ò tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà tó lọ sí àpéjọ náà, ó sọ pé òun ò jẹ́ gbàgbé ọ̀rọ̀ tó tani jí tí Arákùnrin Rutherford sọ pé: “Ohunkóhun ò gbọ́dọ̀ dí yín lọ́wọ́ láti wọṣẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri!” *

Yàtọ̀ sí Arákùnrin John Cooke, tó wá di míṣọ́nnárì nígbà tó yá, àwọn míì náà wọṣẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri lórílẹ̀-èdè Faransé. (Ìṣe 16:9, 10) Kódà, iye àwọn apínwèé-ìsìn-kiri tó wà lórílẹ̀-èdè Faransé pọ̀ sí i. Wọn ò ju mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] lọ lọ́dún 1930, àmọ́ lọ́dún 1931 wọ́n di mẹ́rìnlélọ́gọ́rùn-ún [104]. Irú ìbísí bẹ́ẹ̀ láàárín ọdún kan ṣoṣo péré kàmàmà! Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tá a lè pè ní aṣáájú-ọ̀nà nígbà yẹn ò gbọ́ èdè Faransé, báwo ni wọ́n á ṣe máa wàásù, báwo ni wọ́n á ṣe máa bójú tó jíjẹ àti mímu, kí wọ́n sì tún gbé níbi tí kò sí ibùgbé tó dára, báwo ni wọ́n á sì ṣe máa gbé nílùú táwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn ò ti tó nǹkan?

BÍ WỌ́N ṢE WÀÁSÙ LÁÌGBỌ́ ÈDÈ FARANSÉ

Kí àwọn apínwèé-ìsìn-kiri tí kì í ṣe ọmọ ilẹ̀ Faransé tó lè wàásù fáwọn èèyàn nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe, àfi kí wọ́n lo káàdì ìjẹ́rìí. Arákùnrin kan tó wá láti ilẹ̀ Jámánì náà fìgboyà wàásù nílùú Paris, ó sọ pé: “A mọ̀ pé alágbára ni Ọlọ́run wa. Bí àyà wa bá tiẹ̀ ń já nígbà tá a wà lóde ẹ̀rí, kì í ṣe torí ìbẹ̀rù èèyàn bí kò ṣe torí pé a ò fẹ́ gbàgbé ọ̀rọ̀ ṣókí tá a kọ́kọ́ máa ń sọ fún onílé, ìyẹn: ‘Voulez-vous lire cette carte, s’il vous plaît? [Jọ̀wọ́ ka ohun tó wà nínú káàdì yìí.]’ A gbà pé iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe pàtàkì gan-an lóòótọ́.”

Kẹ̀kẹ́ àti alùpùpù làwọn apínwèé-ìsìn-kiri máa ń gùn lọ wàásù ìhìn rere lórílẹ̀-èdè Faransé

Wọ́n sábà máa ń lé àwọn apínwèé-ìsìn-kiri kúrò láwọn ilé elérò-púpọ̀ tí wọ́n bá lọ wàásù níbẹ̀. Lọ́jọ́ kan, àwọn arábìnrin méjì kan tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣùgbọ́n tí wọn kò gbọ́ èdè Faransé lọ wàásù nílé kan, ẹni tó ń ṣọ́ ilé náà sì pariwo mọ́ wọn pé, ‘Ta lẹ̀ ń wá?’ Bí ọ̀kan lára àwọn arábìnrin náà ṣe ń wá bó ṣe máa pẹ̀tù sí ọkùnrin náà lọ́kàn, ó kíyè sí irin pẹlẹbẹ kan tó wà lára ilẹ̀kùn kan. Ohun tí wọ́n kọ sára rẹ̀ ni: “Tournez le bouton [Tẹ aago].” Ó rò pé orúkọ onílé náà ni wọ́n kọ  síbẹ̀, ló bá fi tẹ̀rín-tọ̀yàyà fèsì pé: “Ìyáàfin ‘Tournez le bouton’ la wá rí.” Báwọn apínwèé-ìsìn-kiri onítara yìí ṣe ń ṣọ̀yàyà sáwọn èèyàn máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an.

OHUNKÓHUN Ò DÍ WỌN LỌ́WỌ́ LÁTI WÀÁSÙ

Bí ipò nǹkan ṣe rí nílẹ̀ Faransé láwọn ọdún 1930 sí ọdún 1939, mú kí àtijẹ àtimu nira fún ọ̀pọ̀ èèyàn, wọn ò sì rílé tó dáa gbé. Kódà, ìyẹn ò yọ àwọn apínwèé-ìsìn-kiri tó wá láti orílẹ̀-èdè míì sílẹ̀. Arábìnrin Mona Brzoska tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì tiẹ̀ sọ ohun tójú òun àti ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà rí. Ó ní: “Àwọn ilé àtijọ́ ló wà níbẹ̀, torí náà ohun tó sábà máa ń jẹ́ olórí ìṣòro wa ni pé kò sí bá a ṣe lè mú kí ilé wa móoru nígbà òtútù. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń di dandan fún wa pé ká sùn sínú yàrá tó tutù bíi yìnyín, tá a bá sì fẹ́ fomi bọ́jú láàárọ̀ àfi ká kọ́kọ́ fọ́ búlọ́ọ̀kù tó dì sójú jọ́ọ̀gì tí omi náà wà.” Ṣé ipò tí kò bára dé yìí mú káwọn aṣáájú-ọ̀nà náà rẹ̀wẹ̀sì? Rárá o! Ọ̀kan nínú wọn tiẹ̀ sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn, ó ní: “A ò ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n ohun tá a nílò kò wọ́n wa.”Mát. 6:33.

Àwọn aṣáájú-ọ̀nà ń pe àwọn èèyàn wá sí Àpéjọ Àgbáyé tó wáyé nílùú Paris lórílẹ̀-èdè Faransé ní May ọdún 1931

Kò tún rọrùn fáwọn apínwèé-ìsìn-kiri onígboyà yìí láti máa gbé nílùú táwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn ò ti tó nǹkan. Ní ọdún 1930 sí ọdún 1934, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà nílẹ̀ Faransé ò ju ọgọ́rùn-ún méje [700] lọ, ibi tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè náà sì jìnnà síra. Bí ọ̀rọ̀ tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí ló mú káwọn apínwèé-ìsìn-kiri yìí máa láyọ̀? Mona sọ ohun tí òun àti ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà yẹn máa ń ṣe. Ó ní: “Bí gbogbo wa ò tiẹ̀ sí lójú kan, ohun tó ràn wá lọ́wọ́ ni pé a jọ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Society. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé a kì í ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn, tó bá di ìrọ̀lẹ́ àyè máa ń ṣí sílẹ̀ fún wa láti kọ lẹ́tà sáwọn ìdílé wa, àti pàápàá jù lọ àwọn aṣáájú-ọ̀nà míì, ká lè sọ ìrírí tá a ní fún wọn ká sì fún ara wa níṣìírí.”1 Tẹs. 5:11.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan wà tó lè mú ìfàsẹ́yìn bá iṣẹ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó fara wọn jìn fún iṣẹ́ ìwàásù yìí, wọ́n ní èrò tó dáa. Ìyẹn sì hàn nínú lẹ́tà tí wọ́n máa ń kọ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ó sì lè jẹ́ lẹ́yìn tí àwọn míì lára wọn ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Faransé ni wọ́n máa kọ lẹ́tà ránṣẹ́. Arábìnrin Annie Cregeen tó jẹ́ ẹni àmì òróró, tóun àti ọkọ rẹ̀ wàásù jákèjádò orílẹ̀-èdè Faransé lọ́dún 1931 sí ọdún 1935, rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó wá sọ nínú lẹ́tà tó kọ pé: “Ayé wa dùn bí oyin, a sì ní ọ̀pọ̀ ìrírí tó ń fún wa láyọ̀. Gbogbo àwa aṣáájú-ọ̀nà ṣera wa lóṣùṣù ọwọ̀. Ṣe lọ̀rọ̀ náà rí bí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé, ‘Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà.’ Jèhófà ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà bí sí i nílẹ̀ Faransé, èyí sì máa ń múnú àwa tá a láǹfààní láti wàásù níbẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn dùn.”1 Kọ́r. 3:6.

Àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí jẹ́ àpẹẹrẹ ìfaradà àti ìtara fún àwọn míì tó ń fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé tó wà nílẹ̀ Faransé báyìí ti tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá [14,000], àwọn àwùjọ tàbí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè ni ọ̀pọ̀ lára wọn sì wà. * Bíi tàwọn aṣáájú-ọ̀nà tó kọ́kọ́ wàásù nílẹ̀ Faransé, wọn ò jẹ́ kí ohunkóhun dí wọn lọ́wọ́.—Látinú àpamọ́ wa lórílẹ̀-èdè Faransé.

^ ìpínrọ̀ 4 Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa báwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Poland tó wà nílẹ̀ Faransé ṣe wàásù níbẹ̀, ka àpilẹ̀kọ náà, “Jèhófà Mú Yín Wá sí Ilẹ̀ Faransé Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́,” nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2015, ojú ìwé 31 sí 32.

^ ìpínrọ̀ 13 Lọ́dún 2014, àwọn àwùjọ tàbí ìjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè, tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ilẹ̀ Faransé ń bójú tó, ti lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900], wọ́n sì ń lo àádọ́rin [70] èdè láti ran àwọn tó ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́ kiri lọ́wọ́.