Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  October 2015

Sísún Mọ́ Ọlọ́run Dára fún Mi

Sísún Mọ́ Ọlọ́run Dára fún Mi

NÍGBÀ tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, mi ò ga ju bí mo ṣe wà lọ mọ́. Ọ̀rọ̀ ọgbọ̀n ọdún ó lé mẹ́rin [34] sẹ́yìn nìyẹn, orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire ni mo wà nígbà náà, àmọ́ títí di bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, mi ò ga ju mítà kan, ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta. Nígbà tó hàn kedere sáwọn òbí mi pé mi ò lè ga ju bí mo ṣe wà lọ mọ́, wọ́n gbà mí níyànjú pé kí n máa ṣiṣẹ́ kára, kó má lọ jẹ́ pé ìrísí mi lá máa bà mí lọ́kàn jẹ́ ṣáá. Mo ṣe káńtà kan síwájú ilé wa tí mo fi ń ta èso, mo sì máa ń rí i dájú pé ó wà ní mímọ́ tónítóní. Èyí máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn bá mi rajà.

Àmọ́, iṣẹ́ àṣekára ò tán ìṣòro mi, mo ṣì kúrú gan-an. Ó máa ń ṣòro fún mi láti ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bíi kí n nawọ́ mú ọjà níbi tí wọ́n tò ó sí nínú ṣọ́ọ̀bù. Ńṣe ló dà bíi pé àwọn tó ga nìkan ni wọ́n ṣe gbogbo nǹkan tó wà láyé fún. Èyí máa ń bà mí nínú jẹ́ gan-an, àmọ́ ìyẹn yí pa dà nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14].

Lọ́jọ́ kan, àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá ra èso lọ́wọ́ mi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ tí mo fi mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì ju ìrísí mi lọ ni pé kí n kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ohun àgbàyanu tó fẹ́ ṣe fáráyé. Ìyẹn ṣe mí láǹfààní gan-an. Ìwé Sáàmù 73:28 wá di ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo yàn láàyò. Apá àkọ́kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.”

Àmọ́ ṣàdédé la kó lọ sórílẹ̀-èdè Burkina Faso, nǹkan sì yí pa dà bìrí fún mi. Lórílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire tá à ń gbé tẹ́lẹ̀, mi ò kí ń ṣe àjèjì àwọn aládùúgbò wa mọ́, torí gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń rí mi nídìí káńtà tí mo ti ń ta èso. Àmọ́ níbi tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kó lọ, kò sẹ́ni tó mọ̀ mí, àwọn èèyàn sì máa ń wò mí gan-an. Torí náà, mo lè má jáde nílé rárá fún bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan nígbà míì. Mo wá rántí bí inú mi ṣe máa ń dùn tó nígbà tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Mo kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n rán míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Nani sí mi. Kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta ló gbé wá. Bí mo sì ṣe rí i ni mo ti mọ̀ pé ẹni tó máa ràn mí lọ́wọ́ gan-an nìyẹn.

Iyẹ̀pẹ̀ pọ̀ ládùúgbò wa, irú àwọn iyẹ̀pẹ̀ yìí máa ń yọ̀, tó bá sì dìgbà òjò, ẹrẹ̀ máa ń pọ̀ lọ́nà. Àìmọye ìgbà ni Nani máa ń ṣubú lórí kẹ̀kẹ́ tó bá ń bọ̀ wá kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ kò jẹ́ kó sú òun. Nígbà tó yá, ó sọ fún mi pé òun á máa fi kẹ̀kẹ́ òun gbé mi lọ sípàdé. Mo mọ̀ pé èyí máa mú kí n máa jáde kúrò nílé káwọn èèyàn sì tún máa dojú bò mí. Yàtọ̀ síyẹn, bá a ṣe máa pé méjì lórí kẹ̀kẹ́ náà á tún dẹrù pa kẹ̀kẹ́ náà, á sì  túbọ̀ ṣòro láti wà. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo gbà láti máa bá Nani lọ sípàdé, mo fi apá kejì nínú ẹsẹ Bíbélì tí mo yàn láàyò sọ́kàn pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi.”

Tá a bá ń lọ sípàdé, èmi àti Nani máa ń ṣubú sínú ẹrẹ̀ nígbà míì. Àmọ́ gbogbo ìsapá yẹn tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ̀rín músẹ́ táwọn ará fi máa ń pàdé mi ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yàtọ̀ pátápátá sí báwọn èèyàn ládùúgbò ṣe máa ń ranjú mọ́ mi. Oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà ni mo ṣèrìbọmi.

“Láti máa polongo gbogbo iṣẹ́ rẹ” ni apá tó ṣẹ́ kù nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo yàn láàyò. Mo mọ̀ pé ó máa ṣòro fún mi gan-an láti máa wàásù. Mo ṣì rántí ìgbà àkọ́kọ́ tí mo wàásù láti ilé dé ilé. Tọmọdétàgbà ló ń ranjú mọ́ mi, wọ́n ń tẹ̀ lé mi, wọ́n sì ń sín bí mo ṣe ń rìn jẹ. Ó dùn mí gan-an lọ́jọ́ náà, àmọ́ mo ṣáà ń rán ara mi létí pé ó yẹ káwọn náà dé Párádísè bó ṣe ń wu èmi náà pé kí n débẹ̀, torí náà, mò ń wàásù lọ ní tèmi.

Kó lè túbọ̀ rọrùn fún mi láti máa wàásù, mo ra kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta kan tí wọ́n máa ń fọwọ́ yí. Ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí ló máa ń bá mi ti kẹ̀kẹ́ náà tá a bá débi tó ga, lẹ́yìn tó bá tì í jákè, tí kẹ̀kẹ́ náà sì ń da fíríì lọ, á wá bẹ́ sórí kẹ̀kẹ́ náà. Iṣẹ́ ìwàásù tó ti máa ń jẹ́ ìṣòro fún mi tẹ́lẹ̀ wá di ohun tó ń fún mi láyọ̀ gan-an, débi pé lọ́dún 1998, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Mo kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mẹ́rin lára wọn sì ti ṣèrìbọmi. Ní àfikún sí ìyẹn, àbúrò mi obìnrin kẹ́kọ̀ọ́, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Bí mo ṣe ń gbọ́ pé àwọn míì tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò máa ń múnú mi dùn gan-an, ó sì máa ń fún mi níṣìírí. Lọ́jọ́ kan tí ibà ń ṣe mí, mo rí lẹ́tà kan gbà láti orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire. Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnu ọ̀nà pẹ̀lú ọmọ yunifásítì kan ní Burkina Faso, mo sì ti fa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lé arákùnrin kan lọ́wọ́. Nígbà tó yá, ọmọ yunifásítì náà kó lọ sí orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire. Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo gbọ́ pé ó ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi!

Báwo ni mo ṣe ń gbọ́ bùkátà ara mi? Àjọ kan tó ń ran àwọn aláàbọ̀ ara lọ́wọ́ gbà láti kọ́ mi níṣẹ́ aṣọ rírán. Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wa níbẹ̀ rí bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́, ó wá sọ pé: “Ó yẹ ká kọ́ ẹ bí wọ́n ṣe ń ṣe ọṣẹ.” Wọ́n sì kọ́ mi lóòótọ́. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ọṣẹ nílé nìyẹn. Àwọn èèyàn fẹ́ràn ọṣẹ tí mò ń ṣe, wọ́n sì máa ń polówó rẹ̀ fáwọn èèyàn. Kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta tí mò ń lò ni mo fi máa ń gbé ọṣẹ náà lọ fáwọn oníbàárà mi.

Ó ṣeni láàánú pé nígbà tó fi máa di ọdún 2004, eegun ẹ̀yìn mi tó wọ́ ti wá ń dùn mí kọjá àlà débi pé kò sóhun tí mo lè ṣe ju pé kí n fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀. Síbẹ̀, mo ṣì ń wàásù déédéé.

Àwọn èèyàn máa ń pè mí ní ẹlẹ́rìn-ín ẹ̀yẹ torí pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́. Ó sì yẹ kí n máa yọ̀ lóòótọ́ torí pé sísún mọ́ Ọlọ́run dára fún mi.—Gẹ́gẹ́ bí Sarah Maiga ṣe sọ ọ́.