“A ó sì sọ ọwọ́ Jèhófà di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.” —AÍSÁ. 66:14.

ORIN: 65, 26

1, 2. Kí lèrò àwọn kan nípa Ọlọ́run?

Ọ̀PỌ̀ èèyàn máa ń rò pé kò sí ohun tó kan Ọlọ́run nínú ọ̀rọ̀ àwọn. Àwọn kan sì gbà pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwa èèyàn ò kan Ọlọ́run. Kódà, lẹ́yìn tí ìjì líle kan jà ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Philippines ní oṣù November ọdún 2013, ohun tí olórí ìlú ńlá kan níbẹ̀ sọ ni pé: “Ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run ò rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí.”

2 Àwọn míì máa ń ṣe bíi pé Ọlọ́run ò rí ohun tí wọ́n ń ṣe. (Aísá. 26:10, 11; 3 Jòh. 11) Wọ́n dà bí àwọn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “wọn kò . . . tẹ́wọ́ gba mímọ Ọlọ́run nínú ìmọ̀ pípéye.” Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ “kún fún gbogbo àìṣòdodo, ìwà burúkú, ojúkòkòrò, ìwà búburú.”—Róòmù 1:28, 29.

3. (a) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa nípa Ọlọ́run? (b) Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa “ọwọ́” Jèhófà, kí ló sábà máa ń túmọ̀ sí?

3 Ṣé bíi tàwọn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ wọn tán yìí lọ̀rọ̀ wá rí? Rárá o. A mọ̀ pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tá à ń ṣe. Àmọ́, ṣé àwa náà ń rí i pé ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún àti pé ó ń tì wá lẹ́yìn? Ṣé a sì wà lára àwọn tí Jésù sọ pé ‘yóò rí Ọlọ́run’? (Mát. 5:8) Ká lè mọ ohun tó túmọ̀ sí láti rí Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tí Bíbélì sọ  nípa àwọn tó rí ọwọ́ Ọlọ́run àtàwọn tó kọ̀ láti rí i. Nígbà náà la óò wá mọ bá a ṣe lè fi ojú ìgbàgbọ́ rí ọwọ́ Jèhófà kedere nínú ìgbésí ayé wa. Bá a ṣe ń gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa “ọwọ́” Ọlọ́run, ó sábà máa ń túmọ̀ sí bí Jèhófà ṣe ń lo agbára rẹ̀ láti ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ àti bó ṣe ń lò ó láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.—Ka Diutarónómì 26:8.

WỌ́N KỌ̀ LÁTI RÍ ỌWỌ́ ỌLỌ́RUN

4. Kí nìdí táwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi kọ̀ láti rí ọwọ́ Ọlọ́run?

4 Nígbà àtijọ́, àwọn èèyàn láǹfààní láti rí bí Ọlọ́run ṣe gbèjà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì gbọ́ nípa rẹ̀. Jèhófà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò ní Íjíbítì lọ́nà ìyanu, lẹ́yìn náà wọ́n ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ àwọn ọba. (Jóṣ. 9:3, 9, 10) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ọba tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì ló gbọ́ ìròyìn yìí tí wọ́n sì rí bí Jèhófà ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè, síbẹ̀ “wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pe ara wọn jọpọ̀ láti bá Jóṣúà àti Ísírẹ́lì jagun ní ìfìmọ̀ṣọ̀kan.” (Jóṣ. 9:1, 2) Kódà lẹ́yìn tí àwọn ọba náà bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà, wọ́n láǹfààní láti rí ọwọ́ Ọlọ́run. Jèhófà mú kí ‘oòrùn dúró sójú kan, kí òṣùpá sì dúró jẹ́ẹ́, títí orílẹ̀-èdè náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ (Jóṣ. 10:13) Jèhófà “jẹ́ kí ọkàn-àyà [àwọn ọ̀tá] wọn di alágídí láti polongo ogun lòdì sí Ísírẹ́lì.” (Jóṣ. 11:20) Àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì ò gbà pé Ọlọ́run ló ń jà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí ló sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun wọn.

5. Kí ni Áhábù Ọba búburú kọ̀ láti gbà?

5 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lẹ́yìn náà mú kó ṣeé ṣe fún Áhábù Ọba búburú láti rí ọwọ́ Ọlọ́run. Èlíjà sọ fún un pé: “Kì yóò sí ìrì tàbí òjò . . . bí kò ṣe nípa àṣẹ ọ̀rọ̀ mi!” (1 Ọba 17:1) Ó dájú pé Jèhófà ló gbẹnu wòlíì Èlíjà sọ̀rọ̀ yẹn, àmọ́ Áhábù ò gbà bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, Áhábù rí bí iná ṣe já bọ́ láti ọ̀run nígbà tí Èlíjà gbàdúrà pé kí iná jẹ ọrẹ ẹbọ òun run. Lẹ́yìn náà, Èlíjà sọ fún Áhábù pé Jèhófà máa fòpin sí ọ̀dá náà, ó sì tún sọ fún un pé: “Sọ̀ kalẹ̀ lọ kí eji wọwọ má bàa dá ọ dúró!” (1 Ọba 18:22-45) Áhábù rí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, síbẹ̀ ó kọ̀ láti gbà pé agbára ńlá Ọlọ́run ló mú kí èyí ṣeé ṣe. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àtàwọn tá a sọ ṣáájú kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ máa mọ̀ bí Jèhófà bá ṣe ohun tó lè mú ká rí ọwọ́ rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa.

WỌ́N RÍ ỌWỌ́ JÈHÓFÀ

6, 7. Nígbà ayé Jóṣúà, kí làwọn kan mọ̀?

6 Àwọn ọba kan wà táwọn náà láǹfààní láti rí bí Ọlọ́run ṣe gbèjà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n sì gbọ́ nípa rẹ̀, àmọ́ wọn kò ṣe bíi tàwọn ọba búburú yẹn, torí náà wọ́n rí ọwọ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ló bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà nígbà ayé Jóṣúà, àmọ́ àwọn ará Gíbéónì wá àlàáfíà pẹ̀lú wọn. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Wọ́n sọ pé: “Àwa ìránṣẹ́ rẹ ti wá ní tìtorí orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ṣe.” (Jóṣ. 9:3, 9, 10) Ó dáa bí wọ́n ṣe tètè yáa mọ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ ló ń ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn.

7 Ráhábù náà rí ọwọ́ Ọlọ́run nínú àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Lẹ́yìn tó gbọ́ bí Jèhófà ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè, ó sọ fún àwọn amí méjì tó wá láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà yóò fi ilẹ̀ yìí fún yín.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Ráhábù ṣe yẹn léwu, ó fi hàn pé òun nígbàgbọ́ pé Jèhófà lè dá òun àti ìdílé òun sí.—Jóṣ. 2:9-13; 4:23, 24.

8. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣe rí ọwọ́ Ọlọ́run?

8 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan tí wọ́n fojú ara  wọn rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà Èlíjà ò ṣe bíi ti Áhábù ọba búburú. Wọ́n gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ní ọwọ́ Ọlọ́run nínú. Nígbà tí wọ́n rí i tí iná látọ̀dọ̀ Jèhófà jẹ ọrẹ ẹbọ náà run, wọ́n kígbe pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!” (1 Ọba 18:39) Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ gbà pé àwọn rí ọwọ́ Ọlọ́run.

9. Báwo la ṣe lè rí Jèhófà tàbí ọwọ́ rẹ̀ lónìí?

9 Àwọn àpẹẹrẹ tó dáa àtèyí tí kò dáa tá a ti gbé yẹ̀ wò ti jẹ́ ká lóye ohun tó túmọ̀ sí pé ká rí Ọlọ́run tàbí ká rí ọwọ́ rẹ̀. Bí àwa náà bá ṣe túbọ̀ ń mọ Ọlọ́run, àá máa rí ọwọ́ rẹ̀ torí à ń mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ a sì ń fi ‘ojú ọkàn wa’ rí àwọn ohun tó ń ṣe. (Éfé. 1:18, Bíbélì Mímọ́) Láìsí àní-àní, àá fẹ́ dà bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ àti lóde òní tí wọ́n rí i kedere pé Jèhófà ń ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ à ń rí ọwọ́ Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn lónìí?

OHUN TÓ FI HÀN PÉ ỌLỌ́RUN Ń LỌ́WỌ́ SÍ Ọ̀RỌ̀ ÀWA ÈÈYÀN LÓNÌÍ

10. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lónìí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

10 A ní ìdí tó pọ̀ láti gbà pé Jèhófà ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ títí dòní. Látìgbàdégbà là ń rí báwọn èèyàn ṣe ń gbàdúrà pé káwọn lè sún mọ́ Ọlọ́run, tí Ọlọ́run sì ń gbọ́ àdúrà wọn. (Sm. 53:2) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Allan ń wàásù láti ilé dé ilé ní erékùṣù kékeré kan ní orílẹ̀-èdè Philippines, ó bá obìnrin kan pàdé. Nígbà tí obìnrin náà rí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Allan sọ pé: “Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, obìnrin náà gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ wá òun rí. Nígbà tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ nígbà tó ṣègbéyàwó tó sì kó lọ sí erékùṣù yẹn, kò rí wọn mọ́. Àdúrà rẹ̀ yára gbà débi pé kò lè pa á mọ́ra mọ́, ló bá bú sẹ́kún.” Láàárín ọdún kan, ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà.

Ǹjẹ́ o gbà pé Jèhófà ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ lónìí? (See Wo ìpínrọ̀ 11 sí 13)

11, 12. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́? (b) Sọ ìrírí ẹnì kan tí Ọlọ́run ràn lọ́wọ́.

11 Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti rí i dájú pé òun ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó ti di bárakú bíi mímu sìgá, ìjoògùnyó tàbí wíwo àwọn ohun tó ń mọ́kan ẹni fà sí ìṣekúṣe. Àwọn kan sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ti gbìyànjú láti jáwọ́, àmọ́ pàbó ló já sí. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, ó fún wọn ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n borí àwọn àṣà tó ti di bárakú náà.—2 Kọ́r. 4:7; Sm. 37:23, 24.

12 Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fara da ìṣòro tí wọ́n dojú kọ. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan ò rọrùn fún Amy nígbà tí wọ́n ní kó lọ bá wọn kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan àti ilé àwọn míṣọ́nnárì ní erékùṣù kékeré kan nítòsí Òkun Pàsífíìkì. Ó sọ pé: “Òtẹ́ẹ̀lì kékeré kan la dé sí, ojoojúmọ́ la sì ń gba inú ọ̀gbàrá tó kún ojú pópó lọ síbi tá a ti ń ṣiṣẹ́.” Ó tún ní láti kọ́ àṣà ìbílẹ̀ náà, léraléra ni wọ́n sì máa ń mú iná àti omi lọ. Ó tún wá sọ pé: “Ohun tó dùn mi jù ni pé mo fìbínú sọ̀rọ̀ sí ọ̀kan lára àwọn arábìnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Nígbà tí mo délé, ńṣe ló ń ṣe mi bíi pé mo ti kùnà. Wọ́n ti múná lọ, torí náà mo gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn wá mo sì ní kó ràn mí lọ́wọ́.” Nígbà tí wọ́n múná dé Amy mú Ilé Ìṣọ́ kan tó sọ̀rọ̀ nípa ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, àpilẹ̀kọ yẹn ṣàlàyé gbogbo ohun tí Amy ń kojú, irú bí àṣà ìbílẹ̀ tuntun, bí àárò ilé ṣe ń sọ ọ́ àti bí yóò ṣe máa báwọn èèyàn gbé. Amy wá sọ pé: “Ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà ń bá mi sọ̀rọ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ìyẹn ló sì mú kí n máa  bá iṣẹ́ mi lọ.”—Sm. 44:25, 26; Aísá. 41:10, 13.

13. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ń ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn nínú ‘gbígbèjà ìhìn rere àti fífìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin’?

13 Bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ‘gbèjà ìhìn rere tá a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin’ tún fi hàn pé Jèhófà ló ń fi agbára ńlá rẹ̀ ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn. (Fílí. 1:7) Àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè kan ti gbìyànjú láti dá iṣẹ́ ìwàásù àwa èèyàn Ọlọ́run dúró pátápátá. Láti ọdún 2000 títí di báyìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jàre ẹjọ́ tó tó igba àti méjìdínláàádọ́rin [268] láwọn ilé ẹjọ́ gíga, mẹ́rìnlélógún [24] lára rẹ̀ sì jẹ́ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Gbogbo àṣeyọrí yìí mú kó ṣe kedere pé kò sẹ́ni tó lè dá iṣẹ́ Ọlọ́run dúró.—Aísá. 54:17; ka Aísáyà 59:1.

14. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa àti bá a ṣe wà ní ìṣọ̀kan ṣe ń mú ká rí ọwọ́ Ọlọ́run?

14 Ọlọ́run ló ń jẹ́ kí ìhìn rere tá à ń wàásù kárí ayé kẹ́sẹ járí. (Mát. 24:14; Ìṣe 1:8) Ní àfikún síyẹn, ìṣọ̀kan tó wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará wa láti ibi gbogbo kárí ayé, èyí tí kò sí níbòmíràn, máa ń ya àwọn èèyàn lẹ́nu, ìdí nìyẹn tí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé: “Ọlọ́run wà láàárín [wa] ní ti tòótọ́.” (1 Kọ́r. 14:25) Lápapọ̀, a ní ẹ̀rí tó pọ̀ tá a fi lè gbà pé Ọlọ́run ń ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn. (Ka Aísáyà 66:14.) Àmọ́, ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ ò ń rí ọwọ́ Jèhófà kedere nínú ìgbésí ayé rẹ?

ǸJẸ́ Ò Ń RÍ ỌWỌ́ JÈHÓFÀ NÍNÚ ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ?

15. Ṣàlàyé ohun tó lè mú ká máà rí ọwọ́ Jèhófà kedere nínú ìgbésí ayé wa nígbà míì.

15 Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí kì í jẹ́ ká rí ọwọ́ Ọlọ́run kedere nínú ìgbésí ayé wa? Àwọn ìṣòro tá à ń kojú lè tán wa lókun. Tí ìṣòro bá ń bá wa fínra, a lè gbàgbé ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ti ṣe fún wa. Nígbà tí Jésíbẹ́lì Ayaba fẹ́ pa wòlíì Èlíjà, fún ìgbà díẹ̀ Èlíjà gbàgbé bí Ọlọ́run ṣe ran òun lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé Èlíjà ní kí Ọlọ́run “gba ọkàn [òun] kúrò.” (1 Ọba 19:1-4) Níbo ni Èlíjà ti lè rí ìṣírí tó nílò  gbà? Àfi kó yíjú sí Jèhófà.—1 Ọba 19:14-18.

16. Kí la lè ṣe ká lè rí Ọlọ́run bíi ti Jóòbù?

16 Ìṣòro gba Jóòbù lọ́kàn débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í wo ipò tó bára ẹ̀ lọ́nà tó yàtọ̀ sí bí Ọlọ́run ṣe ń wò ó. (Jóòbù 42:3-6) Bíi ti Jóòbù, ó lè gba pé kí àwa náà sapá gidigidi ká tó lè rí àwọn ohun tí Ọlọ́run ń ṣe fún wa. Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Tá a bá ń ka Ìwé Mímọ́, ó ṣe pàtàkì ká ronú lórí ọ̀nà tó gbà kàn wá. Bá a bá sì ṣe ń rí ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà tì wá lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ la ó máa rí ìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé e. Àwa náà á wá lè sọ bíi ti Jóòbù pé: “Àgbọ́sọ ni mo gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ojú mi ti rí ọ.”

Ṣé Jèhófà ń lò ẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí òun? (Wo ìpínrọ̀ 17, 18)

17, 18. (a) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fòye mọ̀ pé Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́? (b) Sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí.

17 Báwo la ṣe lè rí ọwọ́ Jèhófà? Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé: O lè gbà pé Ọlọ́run ló jẹ́ kó o kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ǹjẹ́ o ti lọ sípàdé rí, tó o gbọ́ àsọyé kan, tó o wá sọ pé: “Ohun tí mo nílò gan-an nìyí”? Tàbí kó o rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà tó o gbà. Bóyá o pinnu láti mú kí iṣẹ́ ìsìn rẹ gbòòrò sí i, o wá rí bí Jèhófà ṣe mú kí ètò tó o ṣe yọrí sí rere. Àbí ńṣe lo fi iṣẹ́ tó ò ń ṣe sílẹ̀ kó o lè ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, tó o sì wá rí i pé òótọ́ ni ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò . . . kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà”? (Héb. 13:5) Tá a bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, àá lè fòye mọ onírúurú ọ̀nà tó ń gbà ràn wá lọ́wọ́.

18 Sarah tó wá láti orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó ní: “Mo gbàdúrà nípa obìnrin kan tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí mo rò pé kó mọrírì ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà bóyá kí n dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Bí mo ṣe sọ pé ‘Àmín’ báyìí ni fóònù mi dún. Obìnrin náà ló ń pè mí, ó wá bi mí bóyá òun lè bá mi lọ sí ìpàdé. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi!” Tí ìwọ náà bá wà lójúfò, wàá rí ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́. Arábìnrin Rhonna tó ń gbé ní ilẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Ó gba ìfòyemọ̀ kéèyàn tó lè mọ̀ pé Jèhófà ń tọ́ òun sọ́nà. Tó o bá sì ti wá mọ̀ bẹ́ẹ̀, ìwọ náà á gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ wa jẹ Jèhófà lógún.”

19. Kí la tún nílò tá a bá fẹ́ wà lára àwọn tó ń rí Ọlọ́run?

19 Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, níwọ̀n bí wọn yóò ti rí Ọlọ́run.” (Mát. 5:8) Báwo la ṣe lè ‘mọ́ gaara ní ọkàn-àyà’? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá ò bá gba èrò tó ń sọni di aláìmọ́ láyè, tá a sì jáwọ́ nínú ìwà àìtọ́ èyíkéyìí. (Ka 2 Kọ́ríńtì 4:2.) Tá a bá mú kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i, tá à ń hùwà títọ́, àwa náà á wà lára àwọn tó ń rí Ọlọ́run. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bí ìgbàgbọ́ ṣe máa mú ká túbọ̀ rí i kedere pé Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́.