Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  October 2015

“Òpè Eniyan A Máa Gba Ohun Gbogbo Gbọ́”

“Òpè Eniyan A Máa Gba Ohun Gbogbo Gbọ́”

“Òmùgọ̀ lẹni tí kì í ka ìwé ìròyìn rárá, ẹni tó bá sì gba ohun kan gbọ́ kìkì nítorí pé ó kà á nínú ìwé ìròyìn tún gọ̀ jù ú lọ.” —August von Schlözer, òpìtàn àti òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Jámánì (1735 sí 1809).

TÉÈYÀN ò bá lè gba gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé ìròyìn ní igba [200] ọdún sẹ́yìn gbọ́, mélòómélòó wá ni ọ̀pọ̀ nǹkan tá a lè rí kà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ní àkókò tá à ń gbé yìí. Ìmọ̀ ẹ̀rọ ti mú ká ní àwọn ìsọfúnni tó pọ̀ gan-an. Púpọ̀ nínú àwọn ìsọfúnni yìí jóòótọ́, wọ́n wúlò, wọn ò sì lè pani lára, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló jẹ́ irọ́, wọn ò dára fún ohunkóhun, wọ́n sì léwu. Kì í ṣe gbogbo ohun tá a bá ṣáà ti rí la gbọ́dọ̀ máa fún láfiyèsí. Ó tún wá yẹ káwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lo Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ṣọ́ra gan-an. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n lè gbà pé ìròyìn kan tó ṣàjèjì tàbí tó ń tani jí jóòótọ́ kìkì nítorí pé wọ́n rí i lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí torí pé ọ̀rẹ́ wọn kan ló fi ránṣẹ́ sí wọn lórí kọ̀ǹpútà. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ.”—Òwe 14:15Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.

Báwo la ṣe lè jẹ́ “ọlọ́gbọ́n” ká sì mọ èwo nínú àwọn ìsọfúnni tó lè ṣàdédé fara hàn lórí kọ̀ǹpútà wa ló jẹ́ ẹ̀tàn, èwo ni àgbọ́sọgbánù àmọ́ tó jẹ́ irọ́ gbuu, ká sì mọ èyí tí wọ́n fi ń purọ́ gba tọwọ́ ẹni àtàwọn ìròyìn míì tí ń ṣini lọ́nà? Lákọ̀ọ́kọ́, bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ àjọ kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ló ni ìkànnì tí ìsọfúnni náà ti wá, ṣé ìkànnì téèyàn lè fọkàn tán ni àbí irú ìkànnì kan táwọn èèyàn ń pè ní búlọ́ọ̀gì èyí tẹ́nikẹ́ni kàn lè kọ ohun tó bá wù ú sí àbí a ò tiẹ̀ mọ ibi tí ìsọfúnni náà ti wá? Ṣé ìkànnì náà wà lára àwọn ìkànnì tí àṣírí wọn ti tú pé ẹ̀tàn ni wọ́n máa ń gbé jáde?’ * Lẹ́yìn náà, wá lo ‘ọgbọ́n.’ (Òwe 7:7, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Bí ìròyìn kan bá dà bí ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀, a jẹ́ pé kò lè jóòótọ́ nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, bí ìsọfúnni náà bá ń ba àwọn míì lórúkọ jẹ́, bi ara rẹ pé ta nirú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ máa ṣe láǹfààní àti pé kí nìdí tí wọ́n fi ń tàn án kálẹ̀?

ṢÉ GBỌ́YÌÍ-SỌ̀YÍ NI Ẹ́?

Ó máa ń wu àwọn kan tí wọ́n ń fẹ́ káwọn èèyàn gba tiwọn kó jẹ́ pé ẹnu wọn ni wọ́n á ti kọ́kọ́ gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀. Wọ́n máa ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sáwọn èèyàn láì tiẹ̀ tíì mọ ohun tó lè yọrí sí tàbí bóyá ìròyìn náà jóòótọ́ àbí irọ́. (2 Sám. 13:28-33) Àmọ́ tá  a bá jẹ́ “ọlọ́gbọ́n” àá ronú lórí wàhálà tíyẹn lè dá sílẹ̀, bóyá ó tiẹ̀ lè ba ẹnì kan tàbí àjọ kan lórúkọ jẹ́.

Kò rọrùn láti mọ̀ bóyá ìròyìn kan jóòótọ́ àbí irọ́. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń fi irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ fi máa ń rò pé ó kù sọ́wọ́ ẹni tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí láti wádìí bóyá òótọ́ ni àbí irọ́. Àmọ́, ìyẹn máa gba ẹni náà lákòókò gan-an, àkókò ò sì ṣeé fi ṣòfò. (Éfé. 5:15, 16) Dípò kó o fi ohun tó ò ń ṣiyè méjì nípa rẹ̀ ránṣẹ́, á dáa kó o tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n náà pé, “Tó o bá ń ṣiyè méjì, má fi ránṣẹ́ rárá!”

Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo ti di gbọ́yìí-sọ̀yí tó máa ń fẹ́ fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sáwọn èèyàn lórí kọ̀ǹpútà ṣáá? Ṣé ìgbà kan wà tí mo ní láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn tí mo fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí lórí kọ̀ǹpútà torí pé irọ́ pátá gbáà ni ìsọfúnni tí mo fún wọn pa dà já sí? Ṣé ẹnì kan ti sọ fún mi rí pé kí n má fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sóun lórí kọ̀ǹpútà mọ́?’ Rántí pé gbogbo àwọn tó ò ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí lórí kọ̀ǹpútà náà lè fúnra wọn wá ìsọfúnni tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kò pọn dandan ká da ìsọfúnni bò wọ́n débi tó fi máa kà wọ́n láyà, irú bí àwọn ìròyìn tí ń pani lẹ́rìn-ín, fídíò tàbí fọ́tò. Kò sì bọ́gbọ́n mu láti fi àsọyé tá a gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ tàbí àwọn àkọsílẹ̀ tá a ṣe nígbà tá à ń gbọ́ àsọyé ránṣẹ́ sáwọn ẹlòmíì. * Bákan náà, tá a bá ń fi àwọn ìwádìí tá a ṣe tàbí àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a kọ jáde láti fi kẹ́kọ̀ọ́, tàbí àwọn ìdáhùn tá a kọ sílẹ̀ láti lò nípàdé ránṣẹ́ sáwọn míì, kò ní jẹ́ kí wọ́n lè máa dá ṣe ìwádìí, wọn ò ní lè máa ṣí Bíbélì fúnra wọn kí wọ́n sì ka ohun tó sọ, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n jàǹfààní.

Ṣó yẹ kí n fi ìròyìn kàyéfì ránṣẹ́ sáwọn míì?

Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá rí ìròyìn kan táwọn kan fi ń ba ètò Ọlọ́run lórúkọ jẹ́ lórí Íńtánẹ̀ẹ̀tì? Kò yẹ ká ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀. Àwọn kan lè rò pé ńṣe ló yẹ káwọn fi han àwọn míì tàbí kí wọ́n fi ránṣẹ́ sí wọn káwọn lè mọ èrò wọn nípa rẹ̀, àmọ́ ńṣe nìyẹn á jẹ́ kí irọ́ náà máa tàn kálẹ̀. Tá a bá ka ohun kan lórí Íńtánẹ̀ẹ̀tì, tí ọkàn wa ò sì balẹ̀ nípa rẹ̀, ńṣe ló yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa lọ́gbọ́n ká sì bá àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Ják. 1:5, 6; Júúdà 22, 23) Wọ́n parọ́ mọ́ Jésù náà, ó sì kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé àwọn ọ̀tá wọn máa ṣe inúnibíni sí wọn àti pé wọ́n á “fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí [wọn].” (Mát. 5:11; 11:19; Jòh. 10:19-21) Ó yẹ ká lo “agbára láti ronú” àti “ìfòyemọ̀” ká lè mọ àwọn “tí ń sọ  àwọn ohun àyídáyidà” àti àwọn tí “ń ṣe békebèke ní gbogbo ipa ọ̀nà wọn.”—Òwe 2:10-16.

BỌ̀WỌ̀ FÚN Ẹ̀TỌ́ ÀWỌN MÍÌ

A lè gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tàbí ká gbọ́ ìròyìn kan nípa wọn. Ó tún yẹ ká ṣọ́ra fún sísọ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ káàkiri. Kódà bí ọ̀rọ̀ náà bá jẹ́ òótọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ká wá máa sọ ọ́ kiri. Àwọn ìgbà míì wà tí kò ní dáa ká máa sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa fáwọn míì, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ò sì ní fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (Mát. 7:12) Bí àpẹẹrẹ, bó bá tiẹ̀ jóòótọ́ lohun tá à ń sọ nípa wọn, irú òfófó bẹ́ẹ̀ ò ní fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, kò sì ní gbé wọn ró. (2 Tẹs. 3:11; 1 Tím. 5:13) Àwọn ọ̀rọ̀ míì wà tó jẹ́ ọ̀rọ̀ àṣírí, ó sì yẹ ká mọ̀ pé ẹni tọ́rọ̀ kàn ló lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ ọ́ fáwọn ẹlòmíì nígbà tó bá wù ú àti lọ́nà tó bá fẹ́. Nǹkan lè bà jẹ́ tá a bá ń sọ̀rọ̀ kí ẹni tọ́rọ̀ kàn tó sọ ọ́.

Lónìí, ó rọrùn gan-an láti máa tan ìròyìn kálẹ̀, yálà ìròyìn náà jóòótọ́ tàbí irọ́, yálà ó wúlò tàbí kò dára fún ohunkóhun, ó sì lè jẹ́ èyí tí kò lè pani lára tàbí kó jẹ́ èyí tó léwu. Ó yẹ kí gbogbo wa mọ̀ pé àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí ọ̀rọ̀ tá a fi ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà, kódà sí ẹnì kan ṣoṣo péré, lè tàn yí ká ayé ní ìsẹ́jú àáyá. Torí náà, ó yẹ ká ronú jinlẹ̀ ká tó máa fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sáwọn èèyàn, ká má sì ṣe máa kù gìrì tan ìròyìn kálẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ “a máa gba ohun gbogbo gbọ́,” kì í sì fura òdì, kò yẹ ká jẹ́ òmùgọ̀ kó wá jẹ́ pé gbogbo ìròyìn tá a bá ṣáà ti rí tàbí tá a gbọ́ la óò máa gbà gbọ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, tá a bá nífẹ̀ẹ́ ètò Jèhófà àtàwọn ará wa, a ò ní máa gba àwọn irọ́ tí wọ́n ń pa mọ́ ètò Jèhófà àtàwọn ará wa gbọ́, ká sì mọ̀ pé ìfẹ́ Sátánì Èṣù tó jẹ́ “baba irọ́” làwọn tó ń tan irọ́ náà kálẹ̀ ń ṣe. (Jòh. 8:44; 1 Kọ́r. 13:7) Tá a bá ń ronú lọ́nà tó yẹ tá a sì ń lo ìfòyemọ̀, àá jẹ́ “ọlọ́gbọ́n,” àá sì lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe nípa àwọn ìsọfúnni rẹpẹtẹ tá à ń gbọ́ lójoojúmọ́. Bí Bíbélì ṣe sọ, “àwọn òpè a máa jogún àìgbọ́n, ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa dé adé ìmọ̀.”—Òwe 14:18, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.

^ ìpínrọ̀ 4 Ó yẹ kó o mọ̀ pé àwọn ìròyìn táyé ti mọ̀ pó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí irọ́ gbuu, tún máa ń wá sójú táyé látìgbàdégbà, wọ́n sì lè ti yí wọn pa dà díẹ̀ kí wọ́n lè dà bí òótọ́.

^ ìpínrọ̀ 8 Wo “Àpótí Ìbéèrè” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ti April 2010.