Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  October 2015

“Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”

“Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”

“Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!”—MÁÀKÙ 9:24.

ORIN: 81, 135

1. Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní ìgbàgbọ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

ǸJẸ́ o ti rò ó rí pé, ‘Ṣé irú èèyàn bíi tèmi ni Jèhófà máa fẹ́ gbà là nígbà ìpọ́njú ńlá táá sì mú wọnú ayé tuntun?’ Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè là á já, àmọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun pàtàkì kan tó pọn dandan pé ká ṣe nígbà tó sọ pé: ‘Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run dáadáa.’ (Héb. 11:6) Èyí lè dà bí ohun tí kò ṣòro, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, “ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tẹs. 3:2) Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní ìgbàgbọ́ tó lágbára.

2, 3. (a) Kí ni Pétérù sọ tó jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní ìgbàgbọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò báyìí?

2 Àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ká mọ bí ìgbàgbọ́ ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “ìjójúlówó” rẹ̀ “tí a ti dán wò, . . . èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.” (Ka 1 Pétérù 1:7.) Níwọ̀n bí ìpọ́njú ńlá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán báyìí, ǹjẹ́ kò yẹ ká rí i dájú pé a ní irú ìgbàgbọ́ tó máa mú ká wà lára àwọn tí Ọba wa ológo máa yìn nígbà ìṣípayá rẹ̀ torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́? Ó dájú pé àá fẹ́ jẹ́ “irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.” (Héb. 10:39) Tá a bá fẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, àwa náà lè bẹ̀bẹ̀ bíi ti ọkùnrin tó sọ pé: “Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!” (Máàkù 9:24) Tàbí ká ṣe bíi tàwọn àpọ́sítélì Jésù tí wọ́n sọ pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.”—Lúùkù 17:5.

 3 Torí pé a fẹ́ ní ìgbàgbọ́ sí i, àwọn ìbéèrè kan wà tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò. Báwo la ṣe lè ní ìgbàgbọ́? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́? Kí ló lè mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa pé kó fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i?

WỌ́N NÍ ÌGBÀGBỌ́ TÓ MÚNÚ ỌLỌ́RUN DÙN

4. Àpẹẹrẹ àwọn wo ló máa mú káwa náà fún ìgbàgbọ́ wa lókun?

4 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa,” a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ọ̀pọ̀ àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n ní ìgbàgbọ́. (Róòmù 15:4) Tá a bá kà nípa àwọn èèyàn bí Ábúráhámù, Sárà, Ísákì, Jékọ́bù, Mósè, Ráhábù, Gídíónì, Bárákì àti ọ̀pọ̀ àwọn míì nínú Bíbélì, àpẹẹrẹ wọn máa mú káwa náà ṣàyẹ̀wò bí ìgbàgbọ́ wa ṣe jẹ́ ojúlówó tó. (Héb. 11:32-35) Tá a bá sì tún kà nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lóde òní tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó lè mú ká túbọ̀ sapá láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun. *

5. Báwo ni Èlíjà ṣe fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà? Kí ni àpẹẹrẹ rẹ̀ máa mú káwa náà ṣe?

5 Èlíjà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Bíbélì sọ pé ó ní ìgbàgbọ́. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jèhófà. Nígbà tí Èlíjà sọ fún Áhábù Ọba pé Jèhófà máa mú ọ̀dá wá, Èlíjà fi ìdánilójú sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, . . . kì yóò sí ìrì tàbí òjò . . . bí kò ṣe nípa àṣẹ ọ̀rọ̀ mi!” (1 Ọba 17:1) Ó dá Èlíjà lójú pé Jèhófà máa pèsè gbogbo ohun tí òun àtàwọn míì nílò lásìkò ọ̀dá náà. (1 Ọba 17:4, 5, 13, 14) Ó gbà pé Jèhófà lè jí ọmọ kan tó ti kú dìde. (1 Ọba 17:21) Ó dá a lójú pé Jèhófà máa fi iná jó ọrẹ ẹbọ rẹ̀ lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì. (1 Ọba 18:24, 37) Nígbà tí àsìkò tó lójú Jèhófà láti fòpin sí ọ̀dá náà, kódà kí Èlíjà tó gbọ́ kíkù òjò kankan, ó sọ fún Áhábù pé: “Gòkè lọ, kí o jẹ, kí o sì mu; nítorí ìró ìkùrìrì eji wọwọ ń bẹ.” (1 Ọba 18:41) Ǹjẹ́ àwọn ohun tí Èlíjà ṣe yìí kò ní mú káwa náà yẹ ara wa wò, ká lè mọ̀ bóyá a ní ìgbàgbọ́ tó lágbára bíi tiẹ̀?

BÁ A ṢE LÈ MÚ KÍ ÌGBÀGBỌ́ WA MÁA LÁGBÁRA SÍ I?

6. Kí ló yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa ká lè ní ìgbàgbọ́ sí i?

6 A ò lè ní ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ agbára àwa fúnra wa. Ó ṣe tán, ara èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni ìgbàgbọ́. (Gál. 5:22) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù, ká máa bẹ Jèhófà pé kó túbọ̀ máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́. Jésù sì fi dá wa lójú pé Baba yóò “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”—Lúùkù 11:13.

7. Ṣàpèjúwe bá a ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára.

7 Lẹ́yìn tí ìgbàgbọ́ wa bá ti fìdí múlẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá mú kó máa pọ̀ sí i. Bí ìgbà téèyàn ń dáná igi ni ìgbàgbọ́ rí. Tá a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dáná ọ̀hún, ńṣe lá máa jó lala. Àmọ́, tá ò bá koná mọ́ ọn, ńṣe ni iná ọ̀hún á kú táá wá ku ẹ̀ṣẹ́ná nìkan, tó bá sì yá, ẹ̀ṣẹ́ná ọ̀hún á di eérú. Ṣùgbọ́n tó o bá ń figi sí i tó o sì ń koná mọ́ ọn, iná náà ò ní kú. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nípa ìgbàgbọ́ wa náà nìyẹn, tá ò bá fẹ́ kó dòkú, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ìfẹ́ tá a ní fún Bíbélì àti fún Jèhófà á máa pọ̀ sí i, ìyẹn láá sì wá mú kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i.

8. Kí la lè ṣe kí ìgbàgbọ́ wa lè máa lágbára sí i, kó má sì yingin?

8 Kí lo tún lè ṣe kí ìgbàgbọ́ rẹ lè máa lágbára  sí i, kó má sì yingin? Rí i dájú pé ò ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ kódà lẹ́yìn tó o ti ṣèrìbọmi. (Héb. 6:1, 2) Bí àpẹẹrẹ, máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì tó ti nímùúṣẹ, ìyẹn á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára sí i, kó má sì yingin. O tún lè máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara rẹ wò bóyá ìgbàgbọ́ rẹ lágbára bíi tàwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára.—Ka Jákọ́bù 1:25; 2:24, 26.

9, 10. Báwo làwọn nǹkan yìí ṣe ń mú kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i: (a) alábàákẹ́gbẹ́ rere? (b) àwọn ìpàdé ìjọ? (d) iṣẹ́ ìwàásù?

9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni lè máa fún ara wọn ní “ìṣírí . . . nípasẹ̀ ìgbàgbọ́” ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. (Róòmù 1:12) Bá a ṣe ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa, àá máa gbé ìgbàgbọ́ ara wa ró lẹ́nì kìíní kejì, pàápàá jù lọ tó bá jẹ́ pé àwọn tá a ti ‘dán ìjójúlówó’ ìgbàgbọ́ wọn wò là ń bá kẹ́gbẹ́. (Ják. 1:3) Ẹgbẹ́ búburú máa ń ba ìgbàgbọ́ jẹ́, ṣùgbọ́n àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rere máa ń gbé ìgbàgbọ́ ẹni ró. (1 Kọ́r. 15:33) Ìdí kan nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi gbà wá níyànjú pé ká má máa kọ “ìpéjọpọ̀ ara wa” sílẹ̀, àmọ́ ká máa “fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì.” (Ka Hébérù 10:24, 25.) Ìdí mìíràn ni pé àwọn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ láwọn ìpàdé wa máa ń gbé ìgbàgbọ́ wa ró. Èyí sì bá ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ mu pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Torí náà, ó yẹ kó o bi ara rẹ pé, Ǹjẹ́ mo máa ń lọ sí ìpàdé déédéé?

10 Bá a ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ tiwa náà á máa lágbára sí i. Bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwa náà ti kọ́ bá a ṣe lè ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jèhófà, a sì ń fìgboyà wàásù níbi gbogbo.—Ìṣe 4:17-20; 13:46.

11. Kí ló mú kí Kálébù àti Jóṣúà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, báwo la sì ṣe lè dà bíi wọn?

11 Bá a ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbèésí ayé wa àti bó ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà wa, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i. Bó ṣe rí fún Kálébù àti Jóṣúà nìyẹn. Wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà nígbà tí wọ́n lọ ṣe amí Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́, bí Jèhófà ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn náà, ìgbàgbọ́ wọn ń lágbára sí i. Abájọ tí Jóṣúà fi fi ìdánilójú sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín.” Ó tún sọ pé: “Wàyí o, ẹ bẹ̀rù Jèhófà, kí ẹ sì máa sìn ín ní àìlálèébù àti ní òtítọ́ . . . Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.” (Jóṣ. 23:14; 24:14, 15) Tá a bá tọ́ Jèhófà wò, a óò rí i pé ẹni rere ni, àwa náà á sì ní irú ìdánilójú tí Jóṣúà ní.—Sm. 34:8.

BÁ A ṢE LÈ FI HÀN PÉ A NÍ ÌGBÀGBỌ́

12. Kí ni Jákọ́bù sọ pé ó máa fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́?

12 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ tí kì í ṣe òkú? Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù dáhùn ìbéèrè yìí, ó ní: “Èmi yóò . . . fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ mi.” (Ják. 2:18) Àwọn ohun tá à ń ṣe ló ń fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ tí kì í ṣe òkú. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Àwọn tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ń fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́?

13 Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe jẹ́ ọ̀nà títayọ tá a lè gbà fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ká tó lè wàásù, a gbọ́dọ̀ gbà pé àkókò tí Ọlọ́run máa fòpin sí ètò àwọn nǹkan yìí ti sún mọ́lé, àti pé “kì yóò pẹ́.” (Háb. 2:3) Torí náà, bó ṣe ń wù wá tó láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà mọ̀ bóyá a ní ìgbàgbọ́. Ǹjẹ́ à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà, ṣé a sì ń wá bá a ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i? (2 Kọ́r. 13:5) Láìsí àní-àní, ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé à ń lo ìgbàgbọ́ nínú ọkàn wa ni pé ká máa ṣe “ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.”—Ka Róòmù 10:10.

14, 15. (a) Báwo la ṣe lè máa fi hàn lójoojúmọ́ pé a ní ìgbàgbọ́? (b) Sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká rí bí ẹnì kan ṣe ṣe ohun tó fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára.

 14 A tún lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ tá a bá ń fara da àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Bá a tiẹ̀ ń ṣàìsàn, tá a rẹ̀wẹ̀sì, tá a sorí kọ́, tá ò lówó lọ́wọ́, tàbí táwọn ìṣòro míì tó le koko ń bá wa fínra, ó dá wa lójú pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ́ “ní àkókò tí ó tọ́.” (Héb. 4:16) A lè fi hàn pé a ní irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀ tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Kódà, Jésù sọ pé a lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní àwọn nǹkan tara títí kan ‘oúnjẹ òòjọ́ wa ní ojoojúmọ́.’ (Lúùkù 11:3, Bíbélì Mímọ́) Àwọn àpẹẹrẹ tá a rí nínú Bíbélì mú kó dá wa lójú pé Jèhófà lè pèsè àwọn ohun tá a nílò fún wa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tí ọ̀dá dá nílẹ̀ Ísírẹ́lì, Jèhófà fún Èlíjà ní oúnjẹ àti omi. “Àwọn ẹyẹ ìwò sì ń mú búrẹ́dì àti ẹran wá fún un ní òwúrọ̀ àti búrẹ́dì àti ẹran ní ìrọ̀lẹ́, ó sì ń mu omi láti inú àfonífojì olójú ọ̀gbàrá.” (1 Ọba 17:3-6) A nígbàgbọ́ pé Jèhófà lè mú kó ṣeé ṣe fún àwa náà láti rí àwọn ohun tá a nílò.

À ń fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ tá a bá ń fara da àwọn ìṣòro ìgbésí ayé (Wo ìpínrọ̀ 14)

15 Ó dá wa lójú pé tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ìyẹn á jẹ́ ká lè pèsè jíjẹ mímu fún ìdílé wa. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìdílé Arábìnrin Rebecca tó ń gbé ní ilẹ̀ Éṣíà nìyẹn. Wọ́n fi ohun tó wà nínú Mátíù 6:33 àti Òwe 10:4 sílò, ìyẹn ló mú kí wọ́n fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ kára láti pèsè fún ìdílé wọn. Rebecca sọ pé ọkọ òun sọ fún òun pé bí iṣẹ́ òun ṣe rí àti bó ṣe ń gba òun lákòókò lè pa ìjọsìn àwọn lára, torí náà, ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọmọ mẹ́rin ni wọ́n ń bọ́. Rebecca wá sọ ohun tí wọ́n ṣe, ó ní: “A bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpápánu, a sì ń tà á. Ní gbogbo ọdún tá a fi fi iṣẹ́ yìí gbọ́ bùkátà ìdílé wa, Jèhófà ò fi wá sílẹ̀. Kò sígbà kankan tá ò rí oúnjẹ jẹ.” Ṣéwọ náà ń ṣe ohun tó fi hàn pé òótọ́ lo gbà pé inú Bíbélì nìkan la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dára jù lọ lónìí?

16. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, kí ló máa yọrí sí?

16 Ó yẹ kó dá wa lojú pé tá a bá ń tẹ̀  lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Hábákúkù, ó sọ pé: “Olódodo yóò wà láàyè nítorí ìgbàgbọ́.” (Gál. 3:11; Háb. 2:4) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìgbàgbọ́ nínú Ẹni tó dájú pé ó lè ràn wá lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé Ọlọ́run ni “ẹni tí ó lè ṣe ju ọ̀pọ̀ yanturu ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò, ní ìbámu pẹ̀lú agbára rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa.” (Éfé. 3:20) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè ṣèfẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ torí pé wọ́n mọ ibi tí agbára wọ́n mọ, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á bù kún ìsapá wọn. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé Ọlọ́run wa kò ní fi wá sílẹ̀?

JÈHÓFÀ FÚN WỌN NÍ ÌGBÀGBỌ́ TÍ WỌ́N BÉÈRÈ FÚN

17. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fún àwọn àpọ́sítélì ní ìgbàgbọ́ tí wọ́n béèrè fún? (b) Kí nìdí tá a fi lè retí pé kí Jèhófà fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i tá a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?

17 Lẹ́yìn àwọn ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, ó lè ṣe àwa náà bíi tàwọn àpọ́sítélì tí wọ́n bẹ Jésù pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” (Lúùkù 17:5) Àmọ́ ṣé a lè retí pé kí Jèhófà fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i tá a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ náà ní ìgbàgbọ́ sí i. Lọ́nà wo? Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, a tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí wọn, wọ́n wá ní òye tó jinlẹ̀ sí i nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe. Èyí fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. Kí wá nìyẹn yọrí sí? Wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tó gbòòrò jù lọ nígbà yẹn. (Kól. 1:23) Bákan náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i “tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀.”—1 Jòh. 5:14.

18. Báwo ni Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn tó nígbàgbọ́?

18 Ó ṣe kedere pé inú Jèhófà máa ń dùn sáwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. Jèhófà máa fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i tá a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i, ìyẹn á sì mú kó ‘kà wá yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.’—2 Tẹs. 1:3, 5.

^ ìpínrọ̀ 4 Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn tó fi irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ hàn, lọ ka ìtàn ìgbésí ayé Lillian Gobitas Klose (Jí! July 22, 1993, ojú ìwé 12 sí 17), Feliks Borys (Jí! February 22, 1994, ojú ìwé 20 sí 23) àti Brunella Inconditi, bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe sọ ọ́ (Ilé-Ìṣọ́nà July 1, 1994, ojú ìwé 29 sí 31).