Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

‘Ẹ Máa Ka Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀ Sí Ẹni Ọ̀wọ́n’

‘Ẹ Máa Ka Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀ Sí Ẹni Ọ̀wọ́n’

LÁTI ọdún 1992 ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ń yan àwọn alàgbà tó ní ìrírí tí òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú wọn láti máa ṣèrànwọ́ fún àwọn ìgbìmọ̀ tí wọ́n ń lò láti bójú tó iṣẹ́. * Ara “àwọn àgùntàn mìíràn” ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti yan àwọn tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ yìí, iṣẹ́ ribiribi ni wọ́n sì ń ṣe. (Jòh. 10:16) Wọ́n máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ tí wọ́n yàn wọ́n sí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, wọ́n máa ń fún ìgbìmọ̀ náà ní àwọn ìsọfúnni àti àbá tí wọ́n rí pé ó máa wúlò. Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń ṣe ìpinnu, àmọ́ àwọn olùrànlọ́wọ́ yìí ló máa ń ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu náà, wọ́n á sì ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí bá yàn fún wọn. Àwọn olùrànlọ́wọ́ yìí àtàwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Olùdarí jọ máa ń lọ sí àpéjọ àkànṣe àti ti àgbáyé. Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún máa ń rán wọn lọ bẹ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wò gẹ́gẹ́ bí aṣojú orílé-iṣẹ́.

Ọ̀kan nínú àwọn olùrànlọ́wọ́ náà tó ti ń sìn láti ìgbà tí ètò yìí ti bẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Tí mo bá ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi, á ṣeé ṣe fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí láti túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ojúṣe rẹ̀.” Arákùnrin míì lára àwọn olùrànlọ́wọ́ tó ti sìn fún ohun tó lé ní ogún ọdún sọ pé: “Àǹfààní tí mi ò lè ronú kàn ni mo kà á sí.”

Iṣẹ́ bàǹtàbanta ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi síkàáwọ́ àwọn arákùnrin olóòótọ́ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára yìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí sì mọrírì iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ń ṣe. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa “máa ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.”—Fílí. 2:29.

^ ìpínrọ̀ 2 Tó o bá fẹ́ kà nípa iṣẹ́ ìgbìmọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò, wo Àpótí náà “Bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Ohun Tó Jẹ Mọ́ Ìjọba Ọlọ́run” ní Orí 12 nínú ìwé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!