“Ète àṣẹ pàtàkì yìí ni ìfẹ́ láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́ àti láti inú ẹ̀rí-ọkàn rere.” 1 TÍM. 1:5.

ORIN: 57, 48

1, 2. Ta ló fún wa ní ẹ̀rí ọkàn, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ pé a ní ẹ̀rí ọkàn?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN fún wa ní òmìnira láti yan ohun tá a bá fẹ́. Ó fún ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ àtàwọn ọmọ wọn ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ìyẹn ẹ̀rí ọkàn tó dà bí ọlọ́pàá inú tó máa jẹ́ kí wọ́n fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Tá a bá lo ẹ̀rí ọkàn wa bó ṣe yẹ, á jẹ́ ká máa ṣe ohun tó tọ́ ká sì máa sá fún ìwà àìtọ́. Ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run fún wa yìí jẹ́ ẹ̀rí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ kí gbogbo wa máa ṣe ohun tó tọ́.

2 Àwa èèyàn ṣì ní ẹ̀rí ọkàn. (Ka Róòmù 2:14, 15.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, àwọn kan ṣì ń ṣe ohun tó dára, wọ́n sì kórìíra ohun tó burú. Ẹ̀rí ọkàn ni kì í jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn hùwà tó burú. Ẹ wo bí nǹkan ì bá ṣe burú tó nínú ayé ká ní kò sẹ́ni tó ní ẹ̀rí ọkàn! À bá máa gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ìwà ibi tó burú jáì ju èyí tá à ń gbọ́ báyìí lọ. Àfi ká máa dúpẹ́ pé Ọlọ́run fún àwa èèyàn ní ẹ̀rí ọkàn.

3. Báwo ni ẹ̀rí ọkàn ṣe ń mú ká ṣe ohun tó tọ́ nínú ìjọ Kristẹni?

3 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yàtọ̀ sí gbogbo èèyàn torí pé wọ́n  máa ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn lẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wọn máa gún wọn ní kẹ́ṣẹ́ kí wọ́n lè máa fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Tá a bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ tó yẹ, á mú ká máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ìjọ. Àmọ́, ṣíṣe ohun tó wà nínú Bíbélì nìkan kọ́ ni ohun tó túmọ̀ sí láti kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa lò ó. Bíbélì fi hàn pé ká tó lè ní ẹ̀rí ọkàn rere, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ète àṣẹ pàtàkì yìí ni ìfẹ́ láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́ àti láti inú ẹ̀rí-ọkàn rere àti láti inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.” (1 Tím. 1:5) Bá a ṣe ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ tá a sì ń ṣe ohun tó sọ fún wa, ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà á máa pọ̀ sí i, ìgbàgbọ́ wa á sì máa lágbára sí i. Kódà, ọ̀nà tá à ń gbà lo ẹ̀rí ọkàn wa tún ń fi irú àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà hàn, ó ń jẹ́ ká mọ̀ bóyá ọkàn wa ń fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́, ó sì ń jẹ́ ká mọ bó ṣe wù wá tó láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Ẹ̀rí ọkàn wa yìí ló ń sọ irú ẹni tá a jẹ́ ní ti gidi.

4. Báwo la ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa?

4 Ṣùgbọ́n, báwo la ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa? Àwọn ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ ni pé ká máa ka Bíbélì déédéé, ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a bá kà, ká sì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká lè máa fi àwọn ohun tá a kọ́ sílò. Kì í wulẹ̀ ṣe kéèyàn ní ìmọ̀ orí lásán nípa Jèhófà tàbí kó mọ àwọn ìlànà rẹ̀ là ń sọ o! Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ ká túbọ̀ máa lóye irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an, ká lóye àwọn ànímọ́ rẹ̀, ká sì mọ àwọn ohun tó fẹ́ àtèyí tí kò fẹ́. Lọ́nà yìí, ẹ̀rí ọkàn wa á jẹ́ ká tètè máa mọ ohun tó tọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run àti ohun tí kò tọ́ lójú rẹ̀. Èyí á wá mú ká máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó.

5. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

5 Àmọ́, a lè bi ara wa pé: Báwo ni ẹ̀rí ọkàn tá a kọ́ dáadáa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu? Báwo la ṣe lè bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn ẹni tá a jọ jẹ́ ará? Báwo ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe lè jẹ́ ká túbọ̀ ní ìtara fún iṣẹ́ rere? Pẹ̀lú àwọn ìbéèrè yìí lọ́kàn, ẹ jẹ́ ká jíròrò mẹ́ta lára ọ̀nà tí ẹ̀rí ọkàn wa lè gbà ṣe wá láǹfààní: (1) ìlera, (2) eré ìtura àti (3) iṣẹ́ ìwàásù.

JẸ́ AFÒYEBÁNILÒ

6. Ìgbà wo làwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa ìpinnu tó yẹ kí wọ́n ṣe?

6 Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe lọ́wọ́ sí ohun tó lè pa wá lára, ká sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, irú bíi nígbà tá a bá ń jẹ tá a sì ń mu. (Òwe 23:20; 2 Kọ́r. 7:1) Tá a bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò, a máa dáàbò bo ìlera wa dé ìwọ̀n àyè kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ṣì lè ní ìṣòro àìlera torí ara tó ti ń dara àgbà. Ní àwọn ilẹ̀ kan, oògùn òyìnbó àti onírúurú ìtọ́jú àfirọ́pò ló wà. Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa sì máa ń rí lẹ́tà gbà látọ̀dọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n fẹ́ mọ irú ìtọ́jú tó yẹ káwọn gbà. Ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń béèrè pé, “Ṣó yẹ kí ìránṣẹ́ Jèhófà gba irú ìtọ́jú yìí?”

7. Báwo la ṣe lè ṣèpinnu lórí irú ìtọ́jú tó yẹ ká gbà?

7 Tó bá di ọ̀rọ̀ ìlera, ẹ̀ka ọ́fíìsì tàbí àwọn alàgbà ìjọ kò lè ṣèpinnu fún Ẹlẹ́rìí kan, kódà tó bá béèrè pé kí ló yẹ kóun ṣe. (Gál. 6:5) Àmọ́, wọ́n lè tọ́ka rẹ̀ sí ohun tí Jèhófà sọ, èyí tó máa ràn án lọ́wọ́ láti pinnu ohun tó máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Kristẹni kan gbọ́dọ̀ máa rántí àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún wa pé ká “máa ta kété sí . . . ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:29) Èyí fi hàn pé a gbọ́dọ̀ yẹra fún ìtọ́jú tó máa gba pé kí wọ́n fa ògidì ẹ̀jẹ̀ tàbí èyíkéyìí lára èròjà mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀ sí wa lára. Bí Kristẹni  kan bá mọ èyí dájú, ó máa nípa lórí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó jẹ mọ́ gbígba àwọn ìpín kéékèèké tó wá látara èròjà mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀. * Àmọ́, àwọn ìlànà Bíbélì míì wo ló lè jẹ́ ká mọ ohun tá a máa ṣe tá a bá ń ronú lórí irú ìtọ́jú tó yẹ ká gbà?

8. Báwo ni Fílípì 4:5 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́ nípa ìlera?

8 Ìwé Òwe 14:15 sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Àwọn àìsàn kan lè wà tí kò gbóògùn. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká ṣọ́ra fún irú ìtọ́jú kan táwọn èèyàn gbà pé ó jẹ́ kì-í-bà-á-tì, àmọ́ tí kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ló rí. Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílí. 4:5) Tá a bá jẹ́ afòyebánilò, a ò ní máa lo gbogbo àkókò wa lórí ọ̀rọ̀ ìlera débi tá ò fi ní rí àkókò fún ìjọsìn Jèhófà mọ́. Tá ò bá rí nǹkan míì gbọ́ mọ́ ju ọ̀rọ̀ ìlera lọ, ńṣe la máa di onímọtara-ẹni-nìkan. (Fílí. 2:4) Kò yẹ ká máa ronú pé a lè rí ojútùú sí gbogbo àìlera wa, torí náà a gbọ́dọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa ká sì máa rántí pé ìjọsìn Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù.Ka Fílípì 1:10.

Ṣé o máa ń fipá mú káwọn míì gba èrò rẹ? (Wo ìpínrọ̀ 9)

9. Kí ni Róòmù 14:13, 19 sọ nípa ọ̀rọ̀ ìlera? Kí ló lè ba ìṣọ̀kan wa jẹ́?

9 Kristẹni tó ń fòye báni lò kì í fipá mú káwọn míì gba èrò rẹ̀. Níbì kan nílẹ̀ Yúróòpù, tọkọtaya kan ń fìtara polówó àkànṣe oúnjẹ kan àti oògùn tó ní èròjà oúnjẹ nínú. Wọ́n sọ fún àwọn ará kan pé kí wọ́n lo irú oògùn kan tó ní èròjà oúnjẹ nínú, àwọn kan gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn kan kọ̀. Nígbà tó yá, oògùn náà ò ṣe iṣẹ́ tí wọ́n sọ pó máa ṣe, inú ọ̀pọ̀ àwọn ará ò sì dùn sí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Tọkọtaya náà lè pinnu yálà àwọn máa jẹ irú oúnjẹ kan tàbí káwọn lo oògùn tó ní èròjà oúnjẹ nínú, àmọ́ ṣó bọ́gbọ́n mu pé kí wọ́n ṣe ohun tó máa ba ìṣọ̀kan ìjọ jẹ́ torí ọ̀rọ̀ ìlera? Ní àkókò kan, àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù ní èrò tó yàtọ̀ síra nípa jíjẹ àwọn oúnjẹ kan àti ṣíṣe àwọn ayẹyẹ kan. Ìmọ̀ràn wo ní Pọ́ọ̀lù fún wọn? Ó sọ fún wọn pé: “Ẹnì kan ka ọjọ́ kan sí èyí tí ó ga ju òmíràn lọ; ẹlòmíràn ka ọjọ́ kan sí bí gbogbo àwọn yòókù; kí olúkúlùkù gbà gbọ́ ní kíkún nínú èrò inú òun fúnra rẹ̀.” Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n má ṣe ohun tó máa mú kí àwọn míì kọsẹ̀.Ka Róòmù 14:5, 13, 15, 19, 20.

10. Kí nìdí tó fi yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ìpinnu táwọn míì bá ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

10 Tá ò bá lóye ìdí tí ẹ̀rí ọkàn ará kan fi fàyè gbà á láti ṣe ìpinnu lórí ọ̀rọ̀ kan tó kàn án gbọ̀ngbọ̀n, kò yẹ ká yára dá irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́jọ́ tàbí ká rọ̀ ọ́ títí tó fi máa yí èrò rẹ̀ pa dà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn  rẹ̀ ṣì jẹ́ “aláìlera,” ó sì ní láti túbọ̀ kọ́ ọ, tàbí kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kì í fàyè gbà. (1 Kọ́r. 8:11, 12) Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó lè pọn dandan pé ká ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí ọkàn wa dáadáa, bóyá a ṣì ní láti túbọ̀ kọ́ ọ kó lè máa ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Olúkúlùkù wa gbọ́dọ̀ múra tán láti pinnu irú ìtọ́jú tá a fẹ́, ká sì fara mọ́ ohun tó bá tìdí ẹ̀ yọ.

GBÁDÙN ERÉ ÌTURA TÓ Ń GBÉNI RÓ

11, 12. Tá a bá ń yan eré ìtura, ìmọ̀ràn Bíbélì wo ló yẹ ká fi sọ́kàn?

11 Jèhófà dá àwa èèyàn lọ́nà tá a fi lè gbádùn eré ìtura kó sì ṣe wá láǹfààní. Sólómọ́nì sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” àti “ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” wà. (Oníw. 3:4) Àmọ́ kì í ṣe gbogbo eré ọwọ́dilẹ̀ ló ṣàǹfààní, gbogbo rẹ̀ kọ́ ló ń fára nísinmi tó sì ń mára tuni. Bákan náà, kò yẹ ká máa pẹ́ jù nídìí eré ìtura tàbí ká máa ṣe é ní àṣejù. Báwo ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbádùn eré ìtura kó sì ṣe wá láǹfààní?

12 Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ohun kan tó pè ní “iṣẹ́ ti ara.” Lára wọn ni “àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí.” Pọ́ọ̀lù wá sọ pé “àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Gál. 5:19-21) Látàrí èyí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé ẹ̀rí ọkàn mi kì í fàyè gba àwọn eré ìdárayá táwọn èèyàn ti ń hùwà jàgídíjàgan, tí wọ́n ń bára wọn díje, tí wọ́n ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè lárugẹ, tàbí tí wọ́n ń hùwà ipá? Ṣé ẹ̀rí ọkàn mi sì máa ń kìlọ̀ fún mi nígbà tí mo bá fẹ́ wo àwọn fíìmù tó ní àwòrán oníhòòhò, ìṣekúṣe, ìmutípara tàbí ìbẹ́mìílò nínú?’

13. Báwo ni ìmọ̀ràn inú 1 Tímótì 4:8 àti Òwe 13:20 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tó bá kan eré ìtura?

13 Bíbélì tún fún wa ní àwọn ìlànà tá a lè fi kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa, tó bá kan eré ìtura. Ọ̀kan lára ìlànà náà ni pé “eniyan a máa rí anfani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá.” (1 Tím. 4:8, Ìròhìn Ayọ̀) Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé téèyàn bá ń ṣeré ìdárayá níwọ̀nba, ó máa ń ṣara lóore, ó máa ń mára tuni, ó sì máa ń fini lọ́kàn balẹ̀. Àmọ́, ṣé ẹnikẹ́ni la lè bá ṣeré ìdárayá? Ìwé Òwe 13:20 sọ fún wa pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” Ǹjẹ́ èyí ò fi hàn pó yẹ ká ṣọ́ra tá a bá fẹ́ yan eré ìtura, ká sì jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́ máa tọ́ wa sọ́nà?

14. Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe ṣe ohun tó wà nínú Róòmù 14:2-4?

14 Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Christian àti Daniela ní àwọn ọmọbìnrin méjì tí kò tíì pé ogún ọdún. Bàbá wọn tó ń jẹ́ Christian sọ pé: “Nígbà Ìjọsìn Ìdílé wa, a jíròrò nípa eré ìtura. Gbogbo wa gbà pé àwọn eré ìtura kan dáa àwọn kan ò sì dáa. Yàtọ̀ síyẹn, a tún jíròrò nípa àwọn tó yẹ ká máa bá kẹ́gbẹ́. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin wa sọ pé níléèwé àwọn, lákòókò ìsinmi ráńpẹ́, àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan máa ń hùwà tí kò bójú mu. Ó sì máa ń wu òun náà láti ṣe bíi tiwọn. A bá a fèrò wérò pé olúkúlùkù ló ní ẹ̀rí ọkàn, ó sì yẹ kó máa darí wa tá a bá fẹ́ pinnu ohun tá a máa ṣe àti ẹni tá a jọ máa ṣe é.”Ka Róòmù 14:2-4.

Ẹ̀rí ọkàn rẹ tó o fi Bíbélì kọ́ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ìwà tí kò bójú mu (Wo ìpínrọ̀ 14)

15. Ká tó lọ ṣeré ìtura, báwo ni ohun tó wà nínú Mátíù 6:33 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

15 Ó tún yẹ ká ronú lórí ìgbà tó yẹ ká máa ṣeré ìtura. Ǹjẹ́ o máa ń fi àwọn ìgbòkègbodò bí ìpàdé, òde ẹ̀rí, àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ? Àbí  àkókò tó yẹ kó o lò fún ìjọsìn Ọlọ́run lo fi ń ṣeré ìtura? Àwọn nǹkan wo lo fi sípò àkọ́kọ́? Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mát. 6:33) Ǹjẹ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ máa ń sún ẹ láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ bí Jésù ṣe sọ?

Ẹ̀RÍ ỌKÀN WA Ń SÚN WA LÁTI WÀÁSÙ

16. Báwo ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe ń sún wa láti wàásù?

16 Ẹ̀rí ọkàn tó dáa máa ń kìlọ̀ fún wa nípa ìwà tí kò dáa, ó sì tún máa ń sún wa ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú àwọn iṣẹ́ rere tó yẹ ká máa ṣe ni ìwàásù ilé-dé-ilé, ká sì tún máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà. Ẹ̀rí ọkàn Pọ́ọ̀lù sún un láti ṣe bẹ́ẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi. Ní ti gidi, mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!” (1 Kọ́r. 9:16) Bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, ẹ̀rí ọkàn wa á máa sọ fún wa pé ohun tó tọ́ là ń ṣe. Bá a sì ṣe ń wàásù ìhìn rere, à ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn àwọn tá à ń wàásù fún. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ fífi òtítọ́ hàn kedere, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà olúkúlùkù ẹ̀rí-ọkàn ẹ̀dá ènìyàn níwájú Ọlọ́run.”2 Kọ́r. 4:2.

17. Kí ni ẹ̀rí ọkàn arábìnrin ọ̀dọ́ kan sún un ṣe?

17 Nígbà tí Jacqueline wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun alààyè níléèwé. Wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ àlàyé fún wọn nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Jacqueline wá sọ pé: “Ẹ̀rí ọkàn mi ò jẹ́ kí n lè fi gbogbo ara dá sí ìjíròrò kíláàsì bí mo ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Mi ò lè ti ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n lẹ́yìn, torí náà mo lọ bá olùkọ́ mi, mo sì ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ fún un. Ó yà mí lẹ́nu pé ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí mi, kódà ó gbà mí láyè láti bá àwọn ọmọ kíláàsì mi sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá.” Inú Jacqueline wá dùn pé òun fetí sí ẹ̀rí ọkàn òun tóun ti fi Bíbélì kọ́. Ṣé ẹ̀rí ọkàn tìẹ náà máa ń sún ẹ láti ṣe ohun tó tọ́?

18. Kí nìdí tó fi yẹ kó máa wù wá láti ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa tó sì ṣeé gbára lé?

18 Àfojúsùn wa ni pé ká máa gbé ìgbésí ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀. Ẹ̀rí ọkàn wa sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, tá a sì ń sapá láti fi í sílò, ńṣe là ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀bùn iyebíye yìí á máa dárí wa síbi tó tọ́ nínú ìgbésí ayé wa.

^ ìpínrọ̀ 7 Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004, ojú ìwé 29 sí 31.