“Dé . . . ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.”ÉFÉ. 4:13.

ORIN: 69, 70

1, 2. Kí ló yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan fi ṣe àfojúsùn rẹ̀? Ṣàpèjúwe.

BÍ ÌYÀWÓ ilé kan bá ń ṣa èso lórí igbá, kì í ṣe èyí tó tóbi jù lọ tàbí èyí tí owó rẹ̀ dín kù jù lọ ló máa mú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa mú èyí tó dáa, tó dùn-ún wò, tó ní òórùn dídùn, tó sì máa ṣara lóore. Á rí i dájú pé irú èso bẹ́ẹ̀ ti gbó dáadáa, ó sì ṣeé jẹ.

2 Bí ìyàwó ilé kan ṣe máa ń fẹ́ èso tó gbó, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé Kristẹni kan tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí ni Jèhófà ń fẹ́ kó jẹ́ ìránṣẹ́ òun. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe ìdàgbàdénú nípa tara là ń sọ o, ìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí ni. Lẹ́yìn tí Kristẹni kan bá ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì ṣèrìbọmi, á máa dàgbà sí i nípa tẹ̀mí. Ohun táá sì fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ ni bó ṣe máa di ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù pé ó yẹ kí wọ́n máa dàgbà nípa tẹ̀mí. Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, títí tí wọ́n á fi di géńdé ọkùnrin, tí wọ́n á fi dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.’Éfé. 4:13.

3. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà lónìí tó ti ṣẹlẹ̀ rí nínú ìjọ Éfésù?

3 Ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ Éfésù sílẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù  kọ lẹ́tà rẹ̀ sí wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà níbẹ̀ ti dàgbà dénú dáadáa nípa tẹ̀mí. Àmọ́, ó yẹ kí àwọn kan nínú wọn mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí náà nìyẹn. Ọjọ́ pẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti ń sin Ọlọ́run, wọ́n sì ti dàgbà dénú dáadáa nípa tẹ̀mí. Àmọ́, ó dájú pé àwọn kan ṣì ní láti mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹni tuntun ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún, torí náà àwọn kan ṣì ní láti mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i. Ìwọ ńkọ́?Kól. 2:6, 7.

BÍ KRISTẸNI KAN ṢE LÈ DÀGBÀ DÉNÚ

4, 5. Ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú gbà yàtọ̀ síra, àmọ́ kí ni gbogbo wọ́n máa ń ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

4 Tó o bá ń yẹ èso tó ti gbó wò lórí igbá, wàá rí i pé gbogbo wọn ò rí bákan náà. Síbẹ̀, wàá rí ohun tó máa mú kó o mọ̀ pé wọ́n ti gbó. Bákan náà, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn Kristẹni tó dàgbà dénú fi yàtọ̀ síra, irú bí ìlú tí wọ́n ti wá, bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà, ìlera wọn, ọjọ́ orí wọn àti ìrírí wọn. Ìwà àti àṣà ìbílẹ̀ wọn sì tún lè yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, àwọn ohun kan wà tá a fi ń mọ gbogbo àwọn tó bá dàgbà dénú. Kí làwọn ohun náà?

5 Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa ká lè máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” Nítorí náà, àpẹẹrẹ Jésù ni ìránṣẹ́ Jèhófà tó dàgbà dénú máa ń tẹ̀ lé. (1 Pét. 2:21) Kí ni Jésù sọ pé ó ṣe pàtàkì jù? Ó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn àti èrò inú wa, ká sì tún nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa bí ara wa. (Mát. 22:37-39) Ohun tí Jésù sọ yìí ni Kristẹni tó dàgbà dénú máa ń ṣe. Ó máa ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ló kà sí pàtàkì jù, ó sì máa ń fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sáwọn èèyàn.

Àwọn Kristẹni tó ti dàgbà máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Kristi nípa kíkọ́wọ́ ti àwọn ọ̀dọ́ tó ń múpò iwájú báyìí (Wo ìpínrọ̀ 6)

6, 7. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ tá a fi ń dá Kristẹni kan tó dàgbà dénú mọ̀? (b) Kí la máa jíròrò?

6 Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìfẹ́ wulẹ̀ jẹ́ apá kan lára èso tẹ̀mí tí Kristẹni kan tó dàgbà dénú máa ń fi hàn. (Gál. 5:22, 23) Àwọn apá míì lára èso tẹ̀mí irú bí, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìpamọ́ra tún ṣe pàtàkì. Wọ́n á mú kó máa fẹ̀sọ̀ yanjú àwọn ìṣòro tó bá jẹ yọ kó sì máa fara da àwọn ìjákulẹ̀ tó ń bani nínú jẹ́ láìsọ ìrètí nù. Gbogbo ìgbà tó bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń ṣèwádìí lórí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó lè ràn án lọ́wọ́ láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Á wá hàn nínú àwọn ìpinnu tó bá ṣe lẹ́yìn náà pé ó dàgbà dénú. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ bá sọ fún un ló máa ń ṣe. Kristẹni kan tó dàgbà dénú á tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ torí ó mọ̀ pé ìgbà gbogbo ni ọ̀nà Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀ máa ń dára ju tòun lọ. * Ó máa ń fìtara wàásù ìhìn rere, ó sì máa ń pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ.

7 Láìka bó ti pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn ìyípadà kan ṣì wà tó yẹ kí n ṣe kí n lè máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí, kí n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i?’

“OÚNJẸ LÍLE JẸ́ TI ÀWỌN ÈNÌYÀN TÍ Ó DÀGBÀ DÉNÚ”

8. Kí la lè sọ nípa ìmọ̀ àti òye tí Jésù ní nípa Ìwé Mímọ́?

8 Jésù Kristi lóye ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Kódà, nígbà tí kò  ju ọmọ ọdún méjìlá péré lọ, ó jíròrò ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú àwọn tó ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì. “Gbogbo àwọn tí ń fetí sí i ni wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.” (Lúùkù 2:46, 47) Lẹ́yìn náà, nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, ó pa àwọn alátakò rẹ̀ lẹ́nu mọ́ nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ nígbà tó ń bá wọn sọ̀rọ̀.Mát. 22:41-46.

9. (a) Kí ló yẹ kí ẹnì kan tó fẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú òun máa ṣe tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (b) Kí nìdí tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

9 A rí i nínú àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ pé bí Kristẹni kan bá fẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú òun, kì í ṣe ìmọ̀ oréfèé lásán ló yẹ kó ní nípa Bíbélì. Ó ní láti máa walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó sì gbà pé “oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú.” (Héb. 5:14) Ó dájú pé Kristẹni tó dàgbà dénú máa fẹ́ ní “ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run.” (Éfé. 4:13) Ǹjẹ́ o máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́? Ǹjẹ́ o máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tó o sì ń sapá gidigidi láti ya àkókò sọ́tọ̀ fún Ìjọsìn Ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, máa kíyè sí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ táá jẹ́ kó o túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Lẹ́yìn náà, sapá láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, jẹ́ kó máa darí àwọn ìpinnu tó o bá ń ṣe, kó o sì túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà.

10. Báwo ni ìmọ̀ tí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ ní ṣe ń nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀?

10 Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ mọ̀ pé ìmọ̀ nìkan kò tó. Ní àfikún sí ohun tó mọ̀, ó gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ọ̀nà Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó ní àwọn  àfojúsùn tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu dípò kó máa lépa ìfẹ́ tara rẹ̀. Síwájú sí i, ó ti ní láti “bọ́” àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ àtijọ́ “sílẹ̀.” Bí Kristẹni kan bá ti ń ṣe ìyípadà yìí, ńṣe ló ń gbé ìwà tuntun wọ̀ ní àfarawé Kristi, èyí tí a “dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Ka Éfésù 4:22-24.) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló darí àwọn tó kọ Bíbélì. Torí náà, bí Kristẹni kan bá túbọ̀ ń lóye ìlànà Bíbélì, tó sì túbọ̀ ń wù ú láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà, ẹ̀mí mímọ́ á máa darí rẹ̀, òtítọ́ á sì jinlẹ̀ nínú rẹ̀.

Ẹ WÀ NÍ ÌṢỌ̀KAN

11. Irú àjọṣe wo ni Jésù ní pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn àti àwọn ẹbí rẹ̀?

11 Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ẹ̀dá èèyàn pípé ni, àmọ́ àwọn èèyàn aláìpé ló yí i ká. Aláìpé làwọn òbí tó tọ́ ọ dàgbà, òun àtàwọn ìbátan rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìpé ni wọ́n sì jọ ń gbé. Àwọn èèyàn tó wà nígbà náà máa ń wá ipò ọlá, wọ́n máa ń hùwà ẹ̀tàn, wọ́n sì máa ń lo ọgbọ́n àyínìke, èyí pẹ̀lú sì nípa lórí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ìrọ̀lẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa Jésù, “awuyewuye gbígbónájanjan kan . . . dìde láàárín wọn lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.” (Lúùkù 22:24) Àmọ́, ó dá Jésù lójú pé bí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, wọ́n ṣì máa dàgbà dénú, wọ́n á sì para pọ̀ di ìjọ tó wà ní ìṣọ̀kan. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, Jésù gbàdúrà pé kí ìfẹ́ so àwọn àpọ́sítélì òun pọ̀, ó sì bẹ Baba rẹ̀ ọ̀run pé: “Kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, . . . kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan.”Jòh. 17:21, 22.

12, 13. (a) Kí ni Éfésù 4:15, 16 sọ tó fi hàn pé ó yẹ kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ? (b) Báwo ni arákùnrin kan ṣe yí ojú tó fi ń wo àìpé àwọn ará pa dà tó sì tipa bẹ́ẹ̀ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn?

12 Bí ìránṣẹ́ Jèhófà kan bá dàgbà dénú, ńṣe ni yóò máa pa kún ìṣọ̀kan ìjọ. (Ka Éfésù 4:1-6, 15, 16.) Àfojúsùn gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run ni pé ká wà “ní ìṣọ̀kan” ká sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wa. Bí Bíbélì ṣe sọ, a gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká tó lè wà ní ìṣọ̀kan. Arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó dàgbà dénú máa ń wá bó ṣe máa wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn míì kódà tí àìpé wọn bá mú kó ṣòro fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àìpé arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú ìjọ bá mú kó ṣe ohun tó kù-díẹ̀-káàtó, kí lo máa ṣe? Bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ọ́ nínú ìjọ ńkọ́? Ṣé o máa bẹ̀rẹ̀ sí í yàn án lódì? Àbí ńṣe lo máa yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín yín? Kristẹni tó dàgbà dénú máa ń yanjú ìṣòro ni, kì í dá kún un.

13 Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Uwe. Nígbà kan, ó máa ń jẹ́ kí àìpé àwọn ará mú òun bínú. Ó wá pinnu láti lo Bíbélì àti ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Dáfídì. Kí nìdí tó fi yàn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Dáfídì? Uwe sọ pé: “Àwọn kan lára àwọn olùjọ́sìn Jèhófà hùwà àìdáa sí Dáfídì. Bí àpẹẹrẹ, Sọ́ọ̀lù Ọba fẹ́ pa á, àwọn kan fẹ́ sọ ọ́ lókùúta, ìyàwó rẹ̀ pàápàá sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. (1 Sám. 19:9-11; 30:1-6; 2 Sám. 6:14-22) Ṣùgbọ́n, Dáfídì ò jẹ́ kí ìwà àwọn èèyàn bomi paná ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà. Bákan náà, Dáfídì jẹ́ aláàánú, mo sì mọ̀ pé ó yẹ kémi náà jẹ́ aláàánú. Ohun tí mo kọ́ yìí mú kí n yí ojú tí mo fi ń wo àìpé àwọn ará pa dà. Mi ò gbé àṣìṣe àwọn míì sọ́kàn mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, mò ń sapá láti pa  kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ.” Ṣó máa ń wu ìwọ náà láti pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ?

ÀWỌN TÓ Ń ṢÈFẸ́ ỌLỌ́RUN NI KÓ O YÀN LỌ́RẸ̀Ẹ́

14. Àwọn wo ni Jésù yàn lọ́rẹ̀ẹ́?

14 Jésù Kristi nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn dénú. Ara máa ń tu tèwe tàgbà, tọkùnrin tobìnrin àtàwọn ọmọdé pàápàá tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ńṣe ní Jésù fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.” (Jòh. 15:14) Jésù yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láàárín àwọn adúróṣinṣin tí wọ́n ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, tí wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà. Ṣé àwọn tó ń sin Jèhófà láìyẹsẹ̀ ni ìwọ náà ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀?

15. Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè jàǹfààní látinú kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú?

15 Ọ̀pọ̀ èso máa ń tètè pọ́n bí oòrùn bá ta sí wọn lára. Bákan náà, ìwà ọ̀yàyà ẹgbẹ́ àwọn ará wa máa ń mú ká dàgbà dénú. O lè jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń gbìyànjú láti pinnu ohun tó o fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe. Wo bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé kó o máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tí wọ́n sì ń pa kún ìṣọ̀kan ìjọ! Láti ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti ń sìn, wọ́n lè ti dojú kọ àwọn ìṣòro kan tàbí kí wọ́n ti borí àwọn ìpèníjà kan tí wọ́n bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè yan ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ irú àwọn arákùnrin àti arábìnrin bẹ́ẹ̀ tó o sì ń bá wọn kẹ́gbẹ́, wàá lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, wàá sì dàgbà dénú.Ka Hébérù 5:14.

16. Báwo ni àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe ran ọ̀dọ́bìnrin kan lọ́wọ́?

16 Bí àpẹẹrẹ, Helga rántí pé ní ọdún tóun lò kẹ́yìn níléèwé, òun àtàwọn ọmọ kíláàsì òun jọ ń sọ̀rọ̀, olúkúlùkù sì ń sọ ohun tó fi ṣe àfojúsùn rẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn sọ pé àwọn máa lọ sí yunifásítì, káwọn lè rí iṣẹ́ tó máa mowó gọbọi wọlé fáwọn. Helga sọ ọ̀rọ̀ yìí létí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ. Ó wá sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nínu wọ́n jù mí lọ, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Wọ́n gbà mí níyànjú pé kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. Lẹ́yìn náà, mo lo ọdún márùn-ún lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, inú mi dùn pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni mo fi ìgbà ọ̀dọ́ mi ṣe. Mi ò sì kábàámọ̀ pé mo ṣe bẹ́ẹ̀.”

17, 18. Tá a bá dàgbà dénú nípa tẹ̀mí, báwo nìyẹn ṣe lè mú ká fi ìgbésí ayé wa sin Ọlọ́run?

17 Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa, àá dàgbà di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀. Àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, á sì máa wù wá pé ká sìn ín débi tá a bá lè ṣe é dé. Ó dìgbà tí Kristẹni kan bá dàgbà dénú nípa tẹ̀mí kó tó lè sin Jèhófà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.”Mát. 5:16.

18 A ti rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí pé bí Kristẹni kan bá dàgbà dénú, á ní ipa rere lórí ìjọ. Bí Kristẹni kan bá ṣe dàgbà dénú tó tún máa ń nípa lórí bá a ṣe máa lo ẹ̀rí ọkàn rẹ̀. Báwo ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání? Báwọn ará bá sì ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu, báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún irú ìpinnu bẹ́ẹ̀? A óò jíròrò àwọn kókó yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 6 Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ní kí àwọn arákùnrin tó ti dàgbà tí wọ́n sì nírìírí fi díẹ̀ lára àwọn ojúṣe wọn nínú ìjọ sílẹ̀ kí wọ́n sì máa kọ́wọ́ ti àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ tí wọ́n gbé ojúṣe náà lé lọ́wọ́.