Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Máa Ṣe Àṣàrò Lórí Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Tí Jèhófà Ní sí Wa

Máa Ṣe Àṣàrò Lórí Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Tí Jèhófà Ní sí Wa

“Èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ.”SM. 77:12.

ORIN: 18, 61

1, 2. (a) Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Kí ni gbogbo èèyàn máa ń fẹ́?

KÍ LÓ mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀? Kó o tó dáhùn ìbéèrè yìí, ronú nípa àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta yìí: Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn ará fi rọ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Taylene tìfẹ́tìfẹ́ pé kó kíyè sára, kó má sì máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi torí ohun tí kò lè ṣe. Arábìnrin Taylene sọ pé: “Bó bá jẹ́ pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ mi ni, kò ní máa gbà mí níyànjú lemọ́lemọ́.” Arábìnrin Brigitte, tó dá tọ́ ọmọ méjì lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ kú, sọ pé: “Kéèyàn máa tọ́mọ nínú ayé Sátánì yìí jẹ́ ọ̀kan lára ìṣòro tó le jù lọ téèyàn lè dojú kọ, pàápàá òbí tó ń dá tọ́mọ bíi tèmi. Àmọ́, ó dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi torí pé kò fi mí sílẹ̀ nígbà ìbànújẹ́ àti ìrora ọkàn, kò sì jẹ́ kí ohun tí mi ò lè mú mọ́ra ṣẹlẹ̀ sí mi.” (1 Kọ́r. 10:13) Àrùn tí kò gbóògùn ló ń da Sandra láàmú ní tiẹ̀. Ní àpéjọ kan, ìyàwó arákùnrin kan táwọn ará mọ̀ dáadáa fìfẹ́ hàn sí i. Ọkọ Arábìnrin Sandra wá sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ìyàwó arákùnrin náà rí tẹ́lẹ̀, bó ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ wa jẹ òun lógún yìí mú kí inú wa dùn gan-an ni. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan díẹ̀ ni àwọn ará ṣe fún wa, ìyẹn máa ń jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó.”

 2 Nítorí bí Ọlọ́run ṣe dá àwa èèyàn, a máa ń fìfẹ́ hàn, a sì máa ń fẹ́ káwọn míì nífẹ̀ẹ́ wa. Ó rọrùn láti rẹ̀wẹ̀sì torí àwọn ohun àìròtẹ́lẹ̀ tàbí ìjákulẹ̀, àìsàn, ìṣòro ìṣúnná owó, tàbí tí àwọn èèyàn ò bá fetí sí iṣẹ́ ìwàásù wa. Látàrí èyí, tá a bá ń ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa mọ́, ó máa dáa ká rántí pé a ṣeyebíye lójú rẹ̀ àti pé kò gbàgbé wa, ó ń “di ọwọ́ ọ̀tún [wa] mú” ó sì ń ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin, ó dájú pé kò ní gbàgbé wa láé!Aísá. 41:13; 49:15.

3. Kí ló lè mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ìfẹ́ tó ní sí wa kì í yẹ̀?

3 Àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ò fi àwọn sílẹ̀ nígbà àdánwò. Ó sì yẹ kó dá àwa náà lójú pé Ọlọ́run ò ní fi wá sílẹ̀. (Sm. 118:6, 7) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ṣe fara hàn nínú (1) àwọn ohun tó dá, (2) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí, (3) àdúrà àti (4) ìràpadà. Tá a bá ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe, a óò túbọ̀ mọyì ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí wa.Ka Sáàmù 77:11, 12.

MÁA ṢE ÀṢÀRÒ LÓRÍ ÀWỌN OHUN TÍ JÈHÓFÀ DÁ

4. Tá a bá ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tí Jèhófà dá, kí ló máa jẹ́ ká mọ̀?

4 Ṣé òótọ́ ni pé tá a bá ń kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà dá, a máa rí i pé ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí wa? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ìdí sì ni pé ìfẹ́ ló mú kí Ọlọ́run dá àwọn nǹkan. (Róòmù 1:20) Ó dá ayé àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ká lè máa wà láàyè ká sì ní ìlera tó dáa. Àmọ́, kò dá wa lásán, ó tún fẹ́ ká máa gbádùn ara wa. Ó di dandan ká jẹun ká tó lè máa wà láàyè. Torí náà, kí àwa èèyàn lè máa rí oúnjẹ tó gbámúṣe jẹ, Jèhófà rí i dájú pé onírúurú ewéko ń hù jáde. Kódà, ó tún mú kí àwọn oúnjẹ náà ládùn kí wọ́n sì gbádùn mọ́ni. (Oníw. 9:7) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Catherine kúndùn kó máa wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, pàápàá nígbà ìrúwé ilẹ̀ Kánádà tó máa ń mára tuni. Ó sọ pé: “Ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ láti rí bí gbogbo nǹkan ṣe máa ń ṣẹlẹ̀: bí òdòdó ṣe máa ń yọ ọ̀mùnú, bí àwọn ẹyẹ ṣe máa ń darí wálé láti ibi tí wọ́n ṣí lọ àti bí ẹyẹ akùnyùnmù tín-ń-tín ṣe máa ń wá síbi tí mò ń kó oúnjẹ ẹyẹ sí lójú wíńdò ilé ìdáná mi. Bí Jèhófà ò bá nífẹ̀ẹ́ wa, kò ní ṣe àwọn ohun táá máa múnú wa dùn tó bẹ́ẹ̀.” Inú Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ máa ń dùn sáwọn nǹkan tó dá, ó sì fẹ́ kí àwa náà máa gbádùn wọn.Ìṣe 14:16, 17.

5. Báwo ni ọ̀nà tí Jèhófà gbà dá àwa èèyàn ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?

5 Bí Jèhófà ṣe dá wa mú ká lè máa ṣe iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni tó sì nítumọ̀, èyí sì máa ń mú ká túbọ̀ gbádùn ara wa. (Oníw. 2:24) Ó wù ú pé kí àwọn èèyàn kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí wọ́n sì máa jọba lórí ẹja, àwọn ẹyẹ àti àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù. (Jẹ́n. 1:26-28) Jèhófà dá wa pẹ̀lú àwọn ànímọ́ tó lè mú ká fìwà jọ ọ́, ẹ ò rí i bí ìfẹ́ tó ní sí wa ṣe pọ̀ tó!Éfé. 5:1.

MỌRÍRÌ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN TÓ NÍ ÌMÍSÍ

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọrírì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an?

6 Ọlọ́run fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ní ti pé ó fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí. Ó sọ àwọn ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run fún wa, ó sì jẹ́ ká mọ bó ṣe ń bá aráyé lò. Bí àpẹẹrẹ, léraléra ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, Ìwé Mímọ́ sì jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run máa ń ṣe ni gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ṣàìgbọràn. Ìwé Sáàmù 78:38 sọ pé: “Ó jẹ́ aláàánú; òun a sì bo ìṣìnà náà, kì yóò sì  mú ìparun wá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó sì mú kí ìbínú rẹ̀ yí padà, kì í sì í ru gbogbo ìhónú rẹ̀ dìde.” Tó o bá ń ronú lórí ẹsẹ Bíbélì yìí, wàá rí i pé Jèhófà fẹ́ràn ìwọ alára, ó sì bìkítà nípa rẹ. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà kà ẹ́ kún.Ka 1 Pétérù 5:6, 7.

7. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú Bíbélì?

7 Ó yẹ ká fi ọwọ́ pàtàkì mú Bíbélì torí pé òun ni ọ̀nà pàtàkì tí Ọlọ́run ń gbà bá wa sọ̀rọ̀. Kí àwọn òbí àti àwọn ọmọ lè fọkàn tán ara wọn kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa bára wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó nítumọ̀ tó sì fi ìgbatẹnirò hàn. Kí la retí pé kí Jèhófà náà ṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò rí Ọlọ́run rí tàbí ká gbọ́rọ̀ rẹ̀ ní tààràtà, ó ń bá wa “sọ̀rọ̀” nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí, a sì gbọ́dọ̀ máa tẹ́tí sí i. (Aísá. 30:20, 21) Torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ó wù ú kó máa tọ́ wa sọ́nà kó sì máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ ewu. Ó tún fẹ́ ká mọ òun ká sì gbẹ́kẹ̀ lé òun.Ka Sáàmù 19:7-11; Òwe 1:33.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jéhù bá Jèhóṣáfátì wí, Jèhófà rí “àwọn ohun rere” tí ọba náà ṣe (Wo ìpínrọ̀ 8 àti 9)

8, 9. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká mọ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì.

8 Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa àti pé kì í ṣe ibi tá a kù sí ni òun ń ṣọ́. Ibi tá a dá a sí ló máa ń wá. (2 Kíró. 16:9) Bí àpẹẹrẹ, ó wá ibi tí Jèhóṣáfátì Ọba Júúdà dá a sí. Nígbà kan, Jèhóṣáfátì hùwà tí kò bọ́gbọ́n mu. Ó bá Áhábù Ọba Ísírẹ́lì lọ sógun kí wọ́n lè lọ gba ìlú Ramoti-gílíádì pa dà lọ́wọ́ àwọn ará Síríà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn irínwó [400] wòlíì èké fi dá Áhábù Ọba burúkú lójú  pé ó máa ṣẹ́gun, Mikáyà tó jẹ́ wòlìí tòótọ́ fún Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣẹ́gun rẹ̀. Áhábù kú sójú ogun, díẹ̀ ló sì kù kí wọ́n pa Jèhóṣáfátì náà. Nígbà tó pa dà dé Jerúsálẹ́mù, Jéhù bá a wí torí pé ó bá Áhábù da nǹkan pọ̀. Síbẹ̀, Jéhù, ọmọ Hánáánì aríran sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “A rí àwọn ohun rere pẹ̀lú rẹ.”2 Kíró. 18:4, 5, 18-22, 33, 34; 19:1-3.

9 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Jèhóṣáfátì, ó sọ fún àwọn ọmọ aládé, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà pé kí wọ́n lọ jákèjádò gbogbo ìlú Júdà láti kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Jèhófà. Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ náà gbéṣẹ́ débi pé gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù Jèhófà. (2 Kíró. 17:3-10) Òótọ́ ni pé Jèhóṣáfátì hùwà òmùgọ̀, àmọ́ Jèhófà rí gbogbo ohun rere tó ti ṣe. Àkọsílẹ̀ yìí rán wa létí pé bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa kò ní yẹ̀ tá a bá ń fi tọkàntọkàn wá a.

MỌYÌ ÀǸFÀÀNÍ TÓ O NÍ LÁTI GBÀDÚRÀ

10, 11. (a) Kí nìdí tí àdúrà fi jẹ ẹ̀bùn pàtàkì látọ̀dọ̀ Jèhófà? (b) Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń dáhùn àdúrà wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

10 Bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ máa ń wáyè láti tẹ́tí sí wọn tí wọ́n bá fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. Torí pé ohun tó wà lọ́kàn wọn jẹ ẹ́ lógún, ó máa fẹ́ mọ ohun tó ń bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàníyàn lé lórí. Jèhófà, Baba wa ọ̀run, máa tẹ́tí sí wa tá a bá lo àǹfààní iyebíye tá a ní láti bá a sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àdúrà.

11 Ìgbàkigbà la lè gbàdúrà sí Jèhófà. Kò sígbà tá a ké pè é tí kì í gbọ́. Ọ̀rẹ́ wa ni Jèhófà, ó sì ṣe tán láti tẹ́tí sí wa. Arábìnrin Taylene tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “O lè sọ gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn rẹ fún Ọlọ́run.” Tá a bá sọ ohun tó ń dùn wá lọ́kàn fún Ọlọ́run nínú àdúrà, ó lè dá wa lóhùn nípasẹ̀ àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn wa, ẹsẹ Bíbélì kan tí a kà, tàbí ìṣírí tí arákùnrin tàbí arábìnrin wa bá fún wa. Bí ẹnikẹ́ni ò bá tiẹ̀ mọ ohun tó ń ṣe wá, Jèhófà máa ń gbọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wa ó sì máa ń lóye wa. Bó ṣe ń dáhùn àdúrà wa fi hàn pé ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí wa.

12. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àdúrà tó wà nínú Bíbélì? Sọ àpẹẹrẹ kan.

12 Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí kọ́ nínú àwọn àdúrà tó wà nínú Bíbélì. Torí náà, ó máa dáa ká jíròrò irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ nígbà ìjọsìn ìdílé wa. Tá a bá ń ronú lórí bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà àtijọ́ ṣe sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún Ọlọ́run, á jẹ́ kí àdúrà wa sunwọ̀n sí i. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bí Jónà ṣe sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún Ọlọ́run nígbà tó wà nínú ikùn ẹja ńlá. (Jónà 1:17–2:10) Ṣe àgbéyẹ̀wò àdúrà àtọkànwá tí Sólómọ́nì gbà sí Jèhófà nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì. (1 Ọba 8:22-53) Ronú nípa ohun tá a lè rí kọ́ nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù gbà. (Mát. 6:9-13) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, “ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run” nígbà gbogbo. Látàrí èyí, “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.” Ó sì dájú pé èyí á mú ká máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà torí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí wa.Fílí. 4:6, 7.

FI ÌMỌRÍRÌ HÀN FÚN ÌRÀPADÀ

13. Kí ni ìràpadà tí Jèhófà fìfẹ́ pèsè mú kó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn?

13 Ọlọ́run fún wa ní ẹbọ ìràpadà Jésù tó jẹ́ ẹ̀bùn tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí kí a lè “jèrè ìyè.” (1 Jòh. 4:9) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tó ga jù lọ tí  Ọlọ́run fi hàn sí wa yìí, ó sọ pé: “Kristi kú fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ní àkókò tí a yàn kalẹ̀. Nítorí èkukáká ni ẹnikẹ́ni yóò fi kú fún olódodo; ní tòótọ́, bóyá ni ẹnì kan á gbójúgbóyà láti kú fún ènìyàn rere. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:6-8) Ìfẹ́ tó ga jù lọ tí Ọlọ́run fi hàn sí wa yìí mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ojúure Jèhófà.

14, 15. Kí ni ìràpadà náà túmọ̀ sí fún (a) àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró? (b) àwọn tó ní ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé?

14 Àwọn kan wà tí Jèhófà fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Jòh. 1:12, 13; 3:5-7) Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n, torí náà wọ́n di “ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:15, 16) Pọ́ọ̀lù sọ pé a “gbé” àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “dìde” a “sì mú [wọn] jókòó pa pọ̀ ní àwọn ibi ọ̀run ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (Éfé. 2:6) Wọ́n wà ní ipò àrà ọ̀tọ̀ yìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run torí pé a ti ‘fi èdìdì dì wọ́n pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí, èyí tí ó jẹ́ àmì ìdánilójú ṣáájú ogún wọn,’ ìyẹn ni, ‘ìrètí tí a fi pa mọ́ dè wọ́n ní ọ̀run.’Éfé. 1:13, 14; Kól. 1:5.

15 Ní ti àwọn tí kì í ṣe ẹni àmì òróró, àwọn náà lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà bí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà náà. Ọlọ́run á gbà wọ́n ṣọmọ, wọ́n á sì máa fojú sọ́nà láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. Nípa báyìí, Jèhófà tipasẹ̀ ìràpadà náà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí gbogbo aráyé. (Jòh. 3:16) Tó bá wù wá láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, tá a sì ń sin Jèhófà nìṣó láìyẹsẹ̀, ó dájú pé ìgbésí ayé wa máa ládùn nínú ayé tuntun. Ó bá a mu nígbà náà láti máa wo ìràpadà náà bí ẹ̀rí tó ga jù lọ pé Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa.

MỌYÌ ÌFẸ́ TÍ JÈHÓFÀ NÍ SÍ Ẹ

16. Tá a bá ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fìfẹ́ hàn sí wa, báwo ló ṣe máa ṣe wá láǹfààní?

16 Ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa ò lóǹkà. Onísáàmù náà sọ pé: “Lójú mi, àwọn ìrònú rẹ mà ṣe iyebíye o! Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn pátápátá mà pọ̀ o! Ká ní mo fẹ́ gbìyànjú láti kà wọ́n ni, wọ́n pọ̀ ju àwọn egunrín iyanrìn pàápàá.” (Sm. 139:17, 18) Máa ronú lórí ohun tí onísáàmù sọ yìí kó lè máa wù ẹ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkànwá torí pé ó ń fìfẹ́ bójú tó wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.

17, 18. Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

17 Onírúurú ọ̀nà la lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, a lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa tá a bá ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14; 28:19, 20) A tún lè fi hàn pé òótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tá a bá ń fara da àwọn ìṣòro tó ń dán ìgbàgbọ́ wa wò tá ò sì jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. (Ka Sáàmù 84:11; Jákọ́bù 1:2-5.) Bí àdánwò tó dé bá wa bá ń peléke sí i, ó dá wa lójú pé Ọlọ́run mọ ìṣòro tá à ń dojú kọ, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ torí pé a ṣeyebíye lójú rẹ̀.Sm. 56:8.

18 Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a máa ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tó dá àtàwọn ohun àgbàyanu míì tó ti ṣe. À ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti pé a fi ọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ń jẹ́ ká gbàdúrà sí i ká lè túbọ̀ sún mọ́ ọn. Bá a sì ṣe ń ronú lórí ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè torí ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìfẹ́ tá a ní sí i á máa jinlẹ̀ sí i. (1 Jòh. 2:1, 2) Gbogbo ohun tá a ti jíròrò yìí jẹ́ díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà torí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí wa.