Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Fífojú Sọ́nà

Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Fífojú Sọ́nà

“Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un.” HÁB. 2:3.

ORIN: 128, 45

1, 2. Kí ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti máa ń ṣe láti ìgbà pípẹ́ wá?

LÁTI ìgbà pípẹ́ ni àwọn olùjọ́sìn Jèhófà ti máa ń fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí àwọn wòlíì rẹ̀ láti sọ. Bí àpẹẹrẹ, Jeremáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìlú Júdà máa di ahoro, ohun tí àwọn ará Bábílónì sì ṣe gan-an nìyẹn ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Jer. 25:8-11) Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò tí Jèhófà máa ṣe, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.” (Aísá. 30:18) Wòlíì Míkà náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́. Ó wá sọ ohun tó jẹ́ ìpinnu rẹ̀ pé: “Jèhófà ni èmi yóò máa wá.” (Míkà 7:7) Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ń fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú Mèsáyà, tàbí Kristi.Lúùkù 3:15; 1 Pét. 1:10-12. *

2 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní náà ń fojú sọ́nà, torí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ṣì ń ṣẹ. Nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà náà,  Jèhófà máa tó fi òpin sí ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn. Ó máa pa àwọn èèyàn búburú run, ó sì máa dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò nínú ayé Sátánì tó máa tó kásẹ̀ nílẹ̀ yìí. (1 Jòh. 5:19) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa wà lójúfò ká sì mọ̀ dájú pé ayé yìí ò ní pẹ́ dópin.

3. Ìbéèrè wo ló lè wá sọ́kàn wa bó bá pẹ́ tá a ti ń retí pé kí òpin dé?

3 Ó wu àwa ìránṣẹ́ Jèhófà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run “ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mát. 6:10) Àmọ́, tó bá pẹ́ tí àwọn kan ti ń fojú sọ́nà pé kí òpin dé, wọ́n lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ ìdí kankan ṣì wà tó fi yẹ ká máa fojú sọ́nà?’ Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tó fi yẹ ká máa fojú sọ́nà.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA FOJÚ SỌ́NÀ?

4. Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa fojú sọ́nà?

4 Bíbélì sọ ohun tó yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa nípa ìparun tó ń bọ̀ wá sórí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà” kí wọ́n sì “máa wà lójúfò.” (Mát. 24:42; Lúùkù 21:34-36) Jésù sọ pé ká máa ṣọ́nà, ìyẹn sì jẹ́ ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbà gbogbo ni àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run ń gbà wá níyànjú pé ká máa ‘dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà,’ ká máa ‘fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí,’ ká sì máa gbé ìrètí wa karí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Nípa báyìí, ètò Jèhófà ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa ṣọ́nà.Ka 2 Pétérù 3:11-13.

5. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé ká máa sọ́nà ní àkókò tá a wà yìí?

5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni tí wọ́n gbé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa sọ́nà, ó pọn dandan pé kí àwa náà máa ṣọ́nà lóde òní. Kí nìdí? Ìdí ni pé à ń gbé ní àkókò wíwàníhìn-ín Kristi. Láti ọdún 1914 la ti ń rí àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀. Lára àmì alápá púpọ̀ yìí ni ipò ayé tó ń burú sí i àti ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù rẹ̀ kárí ayé, èyí sì ń fi hàn pé à ń gbé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 24:3, 7-14) Jésù ò sọ bí àkókò náà ṣe máa pẹ́ tó kí òpin tó dé, torí náà, ó yẹ ká túbọ̀ máa wà lójúfò, ká sì máa ṣọ́nà.

6. Kí nìdí tá a fi lè retí pé kí ayé máa burú sí i bá a ṣe ń sún mọ́ àkókò òpin?

6 A lè bi ara wa pé: Ṣé ọjọ́ iwájú kan tí ayé á ti burú sí i ju bó ṣe wà yìí lọ ni “ìparí ètò àwọn nǹkan” ń tọ́ka sí? Ohun tí Bíbélì sọ ni pé ìwà búburú máa lékenkà sí i “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tím. 3:1, 13; Mát. 24:21; Ìṣí. 12:12) Torí náà, a lè retí pé kí ayé tó ti burú yìí túbọ̀ máa burú sí i.

7. Kí ni Mátíù 24:37-39 sọ nípa bí nǹkan á ṣe rí nínú ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?

7 Báwo lo ṣe rò pé àwọn nǹkan á burú tó nínú ayé kí “ìpọ́njú ńlá” tó dé? (Ìṣí. 7:14) Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o retí pé kí gbogbo orílẹ̀-èdè máa jagun, kí ẹnikẹ́ni máà rí oúnjẹ jẹ, kí gbogbo èèyàn sì máa ṣàìsàn? Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn tó ń ṣiyè méjì pàápàá máa gbà pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ń ṣẹ. Àmọ́, Jésù sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn “kò” ní “fiyè sí” wíwàníhìn-ín rẹ̀, wọ́n á máa gbé ìgbé ayé wọn nìṣó títí tí òpin á fi dé bá wọn lójijì. (Ka Mátíù 24:37-39.) Ìwé Mímọ́ tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ipò àwọn nǹkan ò ní burú nínú ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn débi tí àwọn èèyàn á fi gbà lọ́ranyàn pé òpin ti sún mọ́lé.Lúùkù 17:20; 2 Pét. 3:3, 4.

8. Kí ni àwọn tó ń fi ìmọ̀ràn Jésù sọ́kàn pé kí wọ́n “máa ṣọ́nà” mọ̀ dájú?

8 Lọ́wọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, kí àwọn èèyàn tó lè lóye àmì alápá púpọ̀ náà, ó gbọ́dọ̀ ṣe kedere débi tí gbogbo àwọn tó ń ṣègbọràn  sí àṣẹ Jésù pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà” á fi rí i. (Mát. 24:27, 42) A sì ti ń rí àmì náà láti ọdún 1914. Láti ìgbà yẹn ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó para pọ̀ di àmì náà ti ń wáyé. Láìsí àní-àní, a ti ń gbé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” náà báyìí, ìyẹn àkókò kúkúrú tó máa ṣáájú ìparun ètò búburú yìí àti ìparun ọ̀hún fúnra rẹ̀.

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fojú sọ́nà fún òpin ètò àwọn nǹkan yìí?

9 Kí wá nìdí tó fi yẹ kí àwa Kristẹni tòótọ́ máa fojú sọ́nà? À ń fojú sọ́nà torí pé a fẹ́ ṣègbọràn sí ìtọ́ni Jésù Kristi. Bákan náà, a lóye àwọn àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀. Kì í ṣe torí pé a kàn fẹ́ máa gba gbogbo ohun tá a bá ti rí gbọ́ la ṣe ń fojú sọ́nà. Kàkà bẹ́ẹ̀, à ń fojú sọ́nà torí pé a rí ẹ̀rí tó ṣe kedere látinú Ìwé Mímọ́, èyí tó ń mú ká máa wà lójúfò, ká sì máa sọ́nà bá a ti ń retí òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí.

BÁWO LÓ ṢE MÁA PẸ́ TÓ?

10, 11. (a) Kí ni Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé ó lè ṣẹlẹ̀? (b) Kí ni Jésù sọ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun ṣe tó bá jọ pé àkókò tí wọ́n fi ń dúró kí òpin dé ti ń pẹ́ ju bí wọ́n ti rò lọ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

10 Ọ̀pọ̀ lára wa ti ń wà lójúfò nípa tẹ̀mí láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Àmọ́, ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò tó ti kọjá mú kó sú wa láti máa fojú sọ́nà. A gbọ́dọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀ de ìgbà tí Jésù máa wá gẹ́gẹ́ bí Amúdàájọ́ṣẹ nígbà òpin ètò àwọn nǹkan yìí. Rántí pé Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́. Ó dà bí ọkùnrin kan tí ó ń rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀, tí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi ọlá àṣẹ fún àwọn ẹrú rẹ̀, tí ó fún olúkúlùkù ní iṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì pàṣẹ fún olùṣọ́nà láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà. Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí ọ̀gá ilé náà ń bọ̀, yálà nígbà tí alẹ́ ti lẹ́ tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru tàbí ìgbà kíkọ àkùkọ tàbí ní kùtùkùtù òwúrọ̀; kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí ó bá dé lójijì, òun kò ní bá yín lójú oorun. Ṣùgbọ́n ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”Máàkù 13:33-37.

11 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀ pé ọdún 1914 ni ìgbà wíwàníhìn-ín Kristi bẹ̀rẹ̀, torí náà wọ́n múra sílẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé ìgbàkigbà ni òpin lè dé. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nípa títúbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Jésù sọ pé òun lè dé yálà ní “ìgbà kíkọ àkùkọ tàbí ní kùtùkùtù òwúrọ̀.” Ìgbà yòówù kí Jésù dé, kí ló yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe? Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” Torí náà, bí òpin ò bá tiẹ̀ tètè dé, ìyẹn ò ní ká máa rò pé kò ní dé mọ́ tàbí ká má fojú sọ́nà fún un mọ́.

12. Kí ni Hábákúkù béèrè lọ́wọ́ Jèhófà, báwo sì ni Ọlọ́run ṣe dá a lóhùn?

12 Ronú nípa wòlíì Hábákúkù, tí Ọlọ́run pàṣẹ fún pé kó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù. Kí Hábákúkù tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ tiẹ̀, àwọn wòlíì míì ti kéde fún ọ̀pọ̀ ọdún pé ìlú náà máa pa run. Ọ̀rọ̀ sì ti burú débi pé ‘ẹni burúkú ti yí olódodo ká, ìdájọ́ òdodo sì ti jáde lọ ní wíwọ́.’ Torí náà, kò yani lẹ́nu pé Hábákúkù béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́?” Jèhófà ò dáhùn ìbéèrè yẹn ní tààràtà. Àmọ́, ó fi dá wòlíì olóòótọ́ náà lójú pé ìparun tó sọ tẹ́lẹ̀ náà “kì yóò pẹ́.” Ọlọ́run sọ fún Hábákúkù pé kó “máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà.”Ka Hábákúkù 1:1-4; 2:3.

13. Èrò wo ni Hábákúkù lè ní, kí sì nìdí tíyẹn ò fi ní bọ́gbọ́n mu?

13 Ká sọ pé Hábákúkù rẹ̀wẹ̀sì tó sì wá  ń ronú pé: ‘Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti ń gbọ́ pé Jerúsálẹ́mù máa pa run. Bó bá máa pẹ́ kí ìparun náà tó dé ńkọ́? Mi ò rò pé ó bọ́gbọ́n mu kí n máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ẹni pé ìlú náà máa pa run lójijì. Àwọn míì ni màá jẹ́ kó ṣèyẹn.’ Bó bá jẹ́ pé nǹkan tí Hábákúkù ń rò lọ́kàn nìyẹn, ì bá ti pàdánù ojúure Jèhófà, ó sì ṣeé ṣe kó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí àwọn ará Bábílónì wá pa Jerúsálẹ́mù run.

14. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà ò ní já wa kulẹ̀ tá a bá ń fojú sọ́nà?

14 Nínú ayé tuntun, àá rántí pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú òpin ètò àwọn nǹkan ló ti ṣẹ. Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ibi tí gbogbo nǹkan wá já sí, àá túbọ̀ fọkàn tán Jèhófà, àá sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ó máa mú èyí tó kù lára àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Ka Jóṣúà 23:14.) Ó dájú pé àá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó ‘ti fi àwọn ìgbà àti àsìkò sí abẹ́ àṣẹ òun fúnra rẹ̀,’ tó sì ti kìlọ̀ fún wa láti máa fi sọ́kàn pé “òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.”Ìṣe 1:7; 1 Pet. 4:7.

Ó YẸ KỌ́WỌ́ WÁ DÍ BÁ A ṢE Ń FOJÚ SỌ́NÀ

Ǹjẹ́ ò ń fìtara wàásù ìhìn rere? (Wo ìpínrọ̀ 15)

15, 16. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká jẹ́ kí ọwọ́ wa túbọ̀ dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní àkókò òpin tá à ń gbé yìí?

15 Ètò Jèhófà á máa bá a nìṣó láti rán wa létí pé ká fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run. Kì í wulẹ̀ ṣe torí kí ọwọ́ wa lè dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run la ṣe ń rí irú ìránnilétí bẹ́ẹ̀ gbà. A tún ń rí i gbà ká lè máa fi sọ́kàn pé a ti ń rí àwọn àmì wíwàníhìn-ín Kristi. Kí wá ni ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ pé ká máa ṣe ní àkókò tá à ń gbé yìí? Ńṣe ló yẹ ká máa wá Ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́ ká sì máa fìtara wàásù ìhìn rere.Mát. 6:33; Máàkù 13:10.

16 Arábìnrin kan sọ pé: “Tá a bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, a . . . lè gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ àjálù tó ń bọ̀ wá sórí ayé yìí.” Arábìnrin yìí mọ ohun tó túmọ̀ sí láti bọ́ lọ́wọ́ àjálù torí pé òun àti ọkọ rẹ̀ wà lára àwọn tó yè bọ́ nínú jàǹbá orí omi tó tíì burú jù nínú ọkọ̀ ojú omi Wilhelm Gustloff lọ́dún 1945. Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn jẹ́ kó rí i pé bí ewu bá dé pàápàá, èèyàn lè má mọ ohun tó yẹ kó kà sí pàtàkì ní ti gidi. Ó rántí bí obìnrin kan ṣe ń ké pé: “Àpò mi o! Àpò mi o! Gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ mi o! Wọ́n wà nísàlẹ̀ ọkọ̀ níbi tí mo kó wọn sí. Gbogbo ẹ ti bómi lọ yéè!” Ṣùgbọ́n ṣe ni àwọn míì tó ti kúrò nínú ọkọ̀ náà fi ẹ̀mí ara wọn wewu, tí wọ́n sì sa gbogbo ipá wọn láti ran àwọn tó ti já sínú omi yìnyín lọ́wọ́. Àwa náà fẹ́ sa gbogbo ipá wa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́  bíi tàwọn èrò ọkọ̀ tó jẹ́ aláìmọ-tara-ẹni nìkan yẹn. Ká má ṣe gbàgbé pé iṣẹ́ ìwàásù wa jẹ́ kánjúkánjú, ká sì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kó tó pẹ́ jù, kí wọ́n lè la àjálù tó ń bọ̀ wá sórí ayé yìí já.

Ǹjẹ́ ò ń ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání kó má bàa di pé ìpínyà ọkàn ò ní jẹ́ kó o fojú sọ́nà mọ́? (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Kí ló mú ká gbà pé òpin lè dé nígbàkigbà?

17 Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé mú kó ṣe kedere pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń ṣẹ báyìí àti pé òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí ti sún mọ́lé. Torí náà, a kò gbọ́dọ̀ lérò pé àkókò púpọ̀ ṣì máa kọjá kó tó di pé “ìwo mẹ́wàá” àti “ẹranko ẹhànnà” inú Ìṣípayá 17:16 máa pa Bábílónì Ńlá, ìyẹn ilẹ́ ọba ìsìn èké àgbáyé run. Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé Ọlọ́run máa “fi í sínú ọkàn-àyà wọn” láti gbé ìgbésẹ̀ yìí, èyí sì lè ṣẹlẹ̀ lọ́nà yíyára kánkán àti nígbàkigbà. (Ìṣí. 17:17) Kò ní pẹ́ mọ́ tí òpin gbogbo ètò àwọn nǹkan yìí á fi dé. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká fetí sí Jésù tó kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.” (Lúùkù 21:34, 35; Ìṣí. 16:15) Ẹ jẹ́ ká wà lójúfò, kó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa “gbé ìgbésẹ̀ ní tìtorí [àwọn] tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.”Aísá. 64:4.

18. Ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Bá a ṣe ń retí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ẹ jẹ́ ká máa ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Júúdà, ọmọ ẹ̀yìn náà láti kọ sílẹ̀. Ó ní: “Ẹ̀yin, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, nípa gbígbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ, àti gbígbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́, ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ ti ń dúró de àánú Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.” (Júúdà 20, 21) Àmọ́, báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń retí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí láìpẹ́ àti pé à ń fojú sọ́nà fún un? Ohun tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn nìyẹn.

^ ìpínrọ̀ 1 Tó o bá fẹ́ ka díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì nípa Mèsáyà àti bí wọ́n ṣe ṣẹ, wo ojú ìwé 200 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?