Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Igbó Biriya ní Gálílì (nísàlẹ̀)

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé igbó kìjikìji pọ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ bí Bíbélì ṣe sọ?

BÍBÉLÌ sọ pé igbó kìjikìji pọ̀ ní àwọn ibì kan ní Ilẹ̀ Ìlérí àti pé “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ” igi wà níbẹ̀. (1 Ọba 10:27; Jóṣ. 17:15, 18) Síbẹ̀, bí àwọn tó ń ṣiyè méjì bá rí i pé kò sí igbó kìjikìji mọ́ ní ibi tó pọ̀ lára ilẹ̀ náà, ó lè ṣe wọ́n ní kàyéfì pé bóyá ni ìgbà kan tiẹ̀ wà rí tí igbó kìjikìji pọ̀ ní Ilẹ̀ Ísírẹ́lì.

Ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè

Ìwé kan tó sọ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ìyẹn Life in Biblical Israel sọ pé “àwọn igbó tó wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ pọ̀ gan-an ju ti òde òní lọ.” Àwọn igi ńlá tó wọ́pọ̀ jù níbẹ̀ ni, igi ahóyaya Aleppo (Pinus halepensis), igi óákù tó máa ń tutù kádún (Quercus calliprinos) àti igi olóje kan tó ń jẹ́ terebinth (Pistacia palaestina). Ní àgbègbè Ṣẹ́fẹ́là, igi síkámórè (Ficus sycomorus) tún pọ̀ rẹpẹtẹ níbi àwọn ẹsẹ̀ òkè tó wà láàárín Etíkun Mẹditaréníà àti àwọn òkè tó yí ìlú náà ká.

Ìwé kan tó sọ nípa àwọn ewéko tó wà nínú Bíbélì, ìyẹn Plants of the Bible sọ pé àwọn àgbègbè kan wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì báyìí tí kò ní igi kankan mọ́. Kí ló fà á? Ìwé náà ṣàlàyé pé gbogbo ilẹ̀ náà ò ṣàdédé ṣófo. Ó ní: “Lemọ́lemọ́ ni àwọn èèyàn ń gé àwọn igi àti ewéko tó wà níbẹ̀ kí wọ́n lè fi ilẹ̀ náà dáko, kí wọ́n sì máa kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn jẹ̀ níbẹ̀. Bákan náà, wọ́n tún ń fi àwọn igi náà kọ́lé wọ́n sì tún ń là wọ́n dáná.”