IṢẸ́ ILÉ kíkọ́ kì í ṣe ohun àjèjì sí Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù. Ó dájú pé wọ́n á ti mọ ọ̀pọ̀ bíríkì nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n tiẹ̀ lè máà rántí iye bíríkì tí wọ́n mọ. Àmọ́ nísinsìnyí, gbogbo ìyẹn ti kọjá lọ. Ní báyìí wọ́n á di oníṣẹ́ ọnà tó ta yọ jù lọ, nígbà tí Jèhófà yàn wọ́n láti kọ́ àgọ́ ìjọsìn. (Ẹ́kís. 31:1-11) Síbẹ̀, àwọn tó máa rí ohun tó kàmàmà tí wọ́n ṣe kò tó nǹkan. Ǹjẹ́ wọ́n wá rẹ̀wẹ̀sì torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò rí iṣẹ́ ọwọ́ wọn? Ṣé ó tiẹ̀ ṣe pàtàkì pé kí àwọn èèyàn rí àwọn ohun tí wọ́n ṣe? Ǹjẹ́ ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn èèyàn rí ohun tí ìwọ náà bá ṣe?

ÀWỌN IṢẸ́ ỌNÀ TÓ JOJÚNÍGBÈSÈ, SÍBẸ̀ ÈÈYÀN DÍẸ̀ LÓ RÍ WỌN

Àwọn kan lára ohun ọ̀ṣọ́ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn jẹ́ àgbà iṣẹ́ ọnà. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn kérúbù tí a fi wúrà ṣe tó wà lórí àpótí májẹ̀mú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè wọ́n ní kérúbù “ológo.” (Héb. 9:5) Ronú nípa bí ẹwà àwọn kérúbù tí wọ́n fi òòlù ṣe iṣẹ́ ọnà wúrà sí lára náà ṣe máa ga lọ́lá tó!—Ẹ́kís. 37:7-9.

Tí a bá rí àwọn iṣẹ́ ọnà tí Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù ṣe yìí lónìí, ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí tó rẹwà jù lọ la máa kó wọn sí, níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn á ti láǹfààní láti rí wọn. Àmọ́, nígbà tí wọ́n ṣe àwọn kérúbù wúrà náà, ẹni mélòó gan-an ló rí bí wọ́n ṣe rẹwà tó? Inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìjọsìn ni wọ́n gbé àwọn kérúbù náà sí, àlùfáà àgbà nìkan ló sì máa ń rí wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ní Ọjọ́ Ètùtù. (Héb. 9:6, 7) Ìyẹn fi hàn pé èèyàn díẹ̀ ló rí wọn.

BÁ A ṢE LÈ NÍ ÌTẸ́LỌ́RÙN BÍ ÀWỌN ÈÈYÀN Ò TIẸ̀ KAN SÁÁRÁ SÍ WA

Tó bá jẹ́ pé ìwọ ní Bẹ́sálẹ́lì tàbí Òhólíábù, tó o sì ṣe làálàá láti ṣe àwọn iṣẹ́ ọnà tó ta yọ lọ́lá yẹn, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá gbọ́ pé àwọn èèyàn kéréje ló rí àwọn ohun tó o ṣe? Lónìí, orí àwọn èèyàn máa ń wú, inú wọn sì máa ń dùn tí àwọn èèyàn bá yìn wọ́n tàbí gba tiwọn torí ohun tí wọ́n ṣe. Ìyẹn ni wọ́n fi ń pinnu bí iṣẹ́ táwọn ṣe ṣe gbayì tó tàbí bó ṣe wúlò tó. Àmọ́, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà kì í ronú bẹ́ẹ̀. Bíi ti Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù, a máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà àti rírí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀.

Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn sábà máa ń fi àdúrà ṣe fọ́rífọ́rí fún àwọn èèyàn kí wọ́n lè gbayì lójú wọn. Àmọ́, Jésù sọ ohun tó yàtọ̀ sí ìyẹn, ó ní ká máa gbàdúrà àtọkànwá, a ò sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀  torí pé a fẹ́ kí àwọn èèyàn máa kan sáárá sí wa. Kí wá ni àbájáde irú àdúrà àtọkànwá bẹ́ẹ̀? Ó ní: “Baba rẹ tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.” (Mát. 6:5, 6) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ojú tí Jèhófà fi wo àdúrà wa, kì í ṣe ohun tí àwọn èèyàn ń rò. Ojú bá fi wo àdúrà wa ló máa pinnu bóyá ó máa ní ìtẹ́wọ́gbà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Bákan náà ni ohunkóhun tí a bá ṣe ní àṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Kò dìgbà táwọn èèyàn bá kan sáárá sí wa kí ohun tí a bá ṣe tó ní ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run, kàkà bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà “tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀” dùn sí ohunkóhun tí a bá ṣe.

Nígbà tí wọ́n parí kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn náà, àwọsánmà “bẹ̀rẹ̀ sí bo àgọ́ ìpàdé, ògo Jèhófà sì kún inú àgọ́ ìjọsìn náà.” (Ẹ́kís. 40:34) Èyí fi hàn pé iṣẹ́ náà ní ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Báwo lo ṣe rò pé èyí máa rí lára Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbẹ́ orúkọ wọn sára àwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n ṣe, ó dájú pé wọ́n máa ní ayọ̀ tó ti ọkàn wá torí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ àwọn. (Òwe 10:22) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, inú wọn á ṣì máa dùn bí wọ́n ti ń rí i pé àgọ́ ìjọsìn náà ṣì wúlò fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nígbà tí Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù bá jíǹde nínú ayé tuntun, tí wọ́n wá mọ̀ pé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn náà, ni wọ́n fi lo àgọ́ ìjọsìn náà fún ìjọsìn tòótọ́, inú wọ́n máa dùn gan-an.

Bí ẹnikẹ́ni kò bá ti ẹ̀ rí iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tinútinú, Jèhófà ń rí i!

Lónìí nínú ètò Jèhófà, iṣẹ́ tí àwọn kan ń ṣe là ń rí, a kì í sábàá mọ àwọn tó wà nídìí iṣẹ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, a ní àwọn tó ń ṣe fídíò bèbí, àwọn ayàwòrán, àwọn tó ń kọrin, àwọn tó ń ya fọ́tò, àwọn atúmọ̀ èdè àti àwọn tó ń kọ gbogbo ìwé tí à ń kà. Nípa bẹ́ẹ̀, a kì í mọ ipa tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń kó. Bí àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe nínú àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà [110,000] kárí ayé ṣe rí náà nìyẹn. Àbí ta ló máa ń rí i nígbà tí ìránṣẹ́ tó ń bójú tó àkáǹtì bá ń ṣe àkọsílẹ̀ ìnáwó ìjọ ní ìparí oṣù? Àwọn ará mélòó ló máa ń rí akọ̀wé ìjọ tó bá ń kọ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá sílẹ̀? Ẹni mélòó ló ń rí i nígbà tí ẹnì kan bá ń ṣe àwọn àtúnṣe tó pọn dandan nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Kí Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù tó kú, wọn ò gba ife ẹ̀yẹ tàbí àmì ẹ̀yẹ kankan, a ò sì gbẹ́ orúkọ wọn sára òkúta èyíkéyìí torí iṣẹ́ ọnà tó jojú ní gbèsè àti iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe. Àmọ́, wọ́n rí ohun tó ṣeyebíye ju ìyẹn lọ gbà, ìyẹn ni ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Dájúdájú, Jèhófà rí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe. Ẹ jẹ́ ká fara wé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ní àti iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ṣe tinútinú.