Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) July 2015

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti August 31 sí September 27, 2015 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Rọ́ṣíà

Kà nípa àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó àti àwọn tó ti ṣègbéyàwó tí wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kí wọ́n lè sìn ní ibi tí a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Wọ́n ti kọ́ láti túbọ̀ gbára lé Jèhófà!

Bá A Ṣe Lè Fi Kún Ẹwà Párádísè Tẹ̀mí

Kí ni ìyàtọ̀ tó wà nínú Párádísè tẹ̀mí àti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí? ‘Párádísè’ wo ni Pọ́ọ̀lù rí ní ‘ọ̀run kẹta’?

Jọ́sìn Jèhófà ní “Àwọn Ọjọ́ Oníyọnu”

Báwo lo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára, kó o sì jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀? Ṣe àgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó dàgbà, tí wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run tayọ̀tayọ̀ láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì.

“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!

Kí ni a máa kéde lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ̀rẹ̀? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró nígbà yẹn?

Ǹjẹ́ Ó Ṣe Pàtàkì Pé Kí Àwọn Èèyàn Rí Ohun Tó O Bá Ṣe?

Àpẹẹrẹ Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù á mú ká gbà pé bí ẹnikẹ́ni ò bá tiẹ̀ rí ohun tí a ṣe, Jèhófà ń rí i.

Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run

Báwo ni àwọn Kristẹni ṣe lè kọ́ ara wọn láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀?

Ibi Ìjọsìn Wa Rèé

Báwo la ṣe le máa ṣe ohun tó fi ọ̀wọ̀ hàn fún Gbọ̀ngàn Ìjọba wa? Báwo la ṣe ń rí owó tí a fi ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti owó tá a fi ń tún un ṣe?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Bíbélì sọ pé igbó kìjikìji pọ̀ ní àwọn ibì kan ní Ilẹ̀ Ìlérí. Kò sí ọ̀pọ̀ lára igi tó wà níbẹ̀ mọ́, ṣó wá lè jẹ́ pé ìgbà kan wà rí tí igbó kìjikìji pọ̀ níbẹ̀?