Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  June 2015

Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà—Apá I

Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà—Apá I

“Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—MÁT. 6:9.

1. Báwo la ṣe lè lo àdúrà tó wà nínú Mátíù 6:9-13 lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló lè ka Àdúrà Olúwa láìwo ìwé. Nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, a sábà máa ń tọ́ka sí àdúrà yìí káwọn èèyàn lè mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ṣe é fọkàn tán, òun ló sì máa mú àyípadà rere bá ilẹ̀ ayé. Nígbà míì sì rèé, a lè tọ́ka sí apá àkọ́kọ́ nínú àdúrà náà ká lè fi hàn pé Ọlọ́run ní orúkọ kan, èyí tó yẹ kó di mímọ́, a ò sì gbọ́dọ̀ tàbùkù sí i.—Mát. 6:9.

2. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ò ní in lọ́kàn pé ká máa sọ ọ̀rọ̀ àdúrà àwòṣe náà léraléra ní gbogbo ìgbà tá a bá ń gbàdúrà?

2 Ǹjẹ́ ohun tí Jésù ń sọ ni pé ká máa sọ ọ̀rọ̀ inú àdúrà yìí léraléra ní gbogbo ìgbà tá a bá ti ń gbàdúrà, bí ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti ń ṣe lónìí? Rárá o. Ṣáájú kí Jésù tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní àdúrà àwòṣe yìí, ó sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” (Mát. 6:7) Ní àkókò mìíràn, Jésù tún gba àdúrà yìí, àmọ́ ó lo àwọn ọ̀rọ̀ míì. (Lúùkù 11:1-4) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká mọ àwọn ohun tá a lè béèrè nínú àdúrà wa, ká sì mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù. Torí náà, àdúrà àwòṣe gan-an ló yẹ ká máa pè é.

3. Àwọn ìbéèrè wo la lè ronú lé lórí bá a ṣe ń jíròrò àdúrà àwòṣe náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́?

 3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àdúrà àwòṣe náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Bá a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni àdúrà àwòṣe yìí ṣe lè ràn mí lọ́wọ́ kí àdúrà tèmi náà lè sunwọ̀n sí i? Ní pàtàkì, ǹjẹ́ mo tiẹ̀ ń gbé ìgbé ayé mi lọ́nà tó bá àdúrà náà mu?’

“BABA WA TÍ Ń BẸ NÍ Ọ̀RUN”

4. Kí ni gbólóhùn náà “Baba wa” rán wa létí, ọ̀nà wo sì ni Jèhófà gbà jẹ́ “Baba” fún àwọn Kristẹni tí wọ́n nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé?

4 Jésù kò sọ pé “Baba mi,” àmọ́ ó sọ pé “Baba wa.” Èyí rán wa létí pé a jẹ́ apá kan “ẹgbẹ́ àwọn ará,” tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. (1 Pét. 2:17) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn jẹ́! Ó tọ́ ní ti gidi bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe pe Jèhófà ní “Baba” wọn torí pé Ọlọ́run ti gbà wọ́n ṣọmọ, wọ́n sì nírètí láti lọ gbé ní ọ̀run. (Róòmù 8:15-17) Bákan náà, àwọn Kristẹni tí wọ́n nírètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé náà lè pe Jèhófà ní “Baba.” Òun ni Olùfúnni-ní-ìyè wọn, ó sì máa ń fìfẹ́ pèsè ohun tí gbogbo àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn rẹ̀ nílò fún wọn. Àwọn tí wọ́n nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò di ọmọ Ọlọ́run ní ti gidi lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bá di ẹ̀dá pípé, tí wọ́n sì ti fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò ìkẹyìn.—Róòmù 8:21; Ìṣí. 20:7, 8.

5, 6. Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye wo ni àwọn òbí lè fún àwọn ọmọ wọn, báwo ló sì ṣe yẹ kí ọmọ kọ̀ọ̀kan lo ẹ̀bùn náà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

5 Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye làwọn òbí ń fún àwọn ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà, tí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n rí Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi Baba wọn ọ̀run onífẹ̀ẹ́. Arákùnrin kan tó ti wá di alábòójútó àyíká báyìí ní orílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Láti ọjọ́ tá a ti bí àwọn ọmọbìnrin wa la ti máa ń gbàdúrà pa pọ̀ ní alaalẹ́ àyàfi ọjọ́ tí mi ò bá sí nílé. Àwọn ọmọ wa sábà máa ń sọ pé àwọn ò rántí àwọn ọ̀rọ̀ pàtó tí à ń sọ nínú àdúrà alaalẹ́ náà. Àmọ́, wọn ò gbàgbé bó ṣe máa ń rí, bí àdúrà tá à ń gbà sí Jèhófà, Baba wa ṣe jẹ́ ohun ọlọ́wọ̀ tó àti bí ara ṣe máa ń tù wọ́n tí ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀. Gbàrà tí wọ́n ti lè gbàdúrà ni mo ti máa ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n gbàdúrà sókè kí n lè gbọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ èrò ọkàn wọn àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn fún Jèhófà. Àǹfààní ńlá lèyí jẹ́ fún mi kí n lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Lẹ́yìn náà, mo lè wá máa fọgbọ́n kọ́ wọn pé kí wọ́n máa fi àwọn ohun pàtàkì látinú àdúrà àwòṣe náà kún àdúrà wọn kí wọ́n lè ti kékeré mọ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà tó nítumọ̀.”

6 Abájọ tí àwọn ọmọ arákùnrin náà fi tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí. Wọ́n ti lọ sílé ọkọ báyìí, wọ́n ń láyọ̀, àwọn àtàwọn ọkọ wọn sì ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ẹ̀yin òbí, ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tẹ́ ẹ lè fún àwọn ọmọ yín ni pé kẹ́ ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ọwọ́ olúkúlùkù wọn ló wá kù sí láti máa ṣìkẹ́ àjọṣe iyebíye tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà yìí. Èyí ní nínú kíkọ́ wọn bí wọ́n á ṣe nífẹ̀ẹ́ orúkọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un.—Sm. 5:11, 12; 91:14.

“KÍ ORÚKỌ RẸ DI SÍSỌ DI MÍMỌ́”

7. Àǹfààní wo làwa èèyàn Ọlọ́run ní, àmọ́ kí ló gba pé ká ṣe?

7 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa pé a ò kàn mọ orúkọ Ọlọ́run nìkan, a tún ń jẹ́ orúkọ náà gẹ́gẹ́ bí “ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀.” (Ìṣe 15:14; Aísá. 43:10) À ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ lọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run pé: “Kí orúkọ [rẹ̀] di sísọ di mímọ́.” Ẹ̀bẹ̀ yìí lè mú kó o sọ fún Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o máa bàa sọ  tàbí ṣe ohunkóhun tó máa tàbùkù sí orúkọ rẹ̀ tó jẹ́ mímọ́. A ò fẹ́ dà bí àwọn kan ní ọ̀rúndún kìíní tí ìwà wọn yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n ń wàásù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa wọn pé: “Orúkọ Ọlọ́run ni a ń sọ̀rọ̀ òdì sí ní tìtorí yín láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”—Róòmù 2:21-24.

8, 9. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn tó fọwọ́ pàtàkì mú sísọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́.

8 A fẹ́ sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ọkọ arábìnrin kan kú lójijì lórílẹ̀-èdè Norway, arábìnrin náà ní láti máa dá tọ́ ọmọkùnrin wọn ọlọ́dún méjì. Ó sọ pé: “Nǹkan nira fún mi gan-an lákòókò yẹn. Mò ń gbàdúrà lójoojúmọ́, kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé wákàtí wákàtí ni mò ń gbàdúrà torí pé mi ò fẹ́ ṣe ohun tó máa fún Sátánì láyè láti ṣáátá Jèhófà, torí náà, mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó fún mi lókun kí n lè ronú lọ́nà tó tọ́, kí n má bàa ṣe ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání tàbí kí n hùwà àìṣòótọ́. Mo fẹ́ sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, mo sì fẹ́ kí ọmọ mi rí bàbá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i nínú Párádísè.”—Òwe 27:11.

9 Arábìnrin yìí fi hàn nínú àdúrà rẹ̀ pé òun fi ti Jèhófà ṣáájú. Ǹjẹ́ Jèhófà dáhùn àdúrà rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ó rí ìrànlọ́wọ́ gbà bó ṣe ń péjọ déédéé pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ó fẹ́ alàgbà kan. Ọmọkùnrin rẹ̀ ti pé ọmọ ogún ọdún báyìí, ó sì ti ṣèrìbọmi. Arábìnrin náà sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé ọkọ mi kà á sí ọmọ rẹ̀ gan-an, ó sì bá mi tọ́ ọ.”

10. Kí la nílò kí orúkọ Ọlọ́run tó lè di mímọ́ pátápátá?

10 Kí la nílò kí orúkọ Ọlọ́run tó lè di mímọ́ pátápátá, tí kò sì ní sí ẹ̀gàn kankan lórí orúkọ rẹ̀ mọ́? Kí èyí tó lè ṣẹlẹ̀, ó pọn dandan pé kí Jèhófà mú gbogbo àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ kẹ̀yìn sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ kúrò. (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:22, 23.) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, aráyé yóò di ẹ̀dá pípé. À ń fojú sọ́nà fún àkókò kan tí gbogbo èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì yóò máa ṣe ohun tó fi hàn pé orúkọ Jèhófà jẹ́ mímọ́! Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ yóò “jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”—1 Kọ́r. 15:28.

“KÍ ÌJỌBA RẸ DÉ”

11, 12. Ìlàlóye wo ni Jèhófà fún àwọn Kristẹni olóòótọ́ bí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún ti ń parí lọ?

11 Kó tó di pé Jésù pa dà sókè ọ̀run, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba náà padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?” Ìdáhùn tí Jésù fún wọn fi hàn pé kò tíì tó àkókò fún wọn láti mọ ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ náà, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù. (Ka Ìṣe 1:6-8.) Síbẹ̀, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa retí ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa dé. Torí náà, láti ọjọ́ àwọn àpọ́sítélì ni àwọn Kristẹni ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé.

12 Nígbà tí àkókò náà tó tí Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí Jésù jẹ́ Ọba rẹ̀, máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso láti ọ̀run, Jèhófà jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ lóye àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan máa wáyé. Lọ́dún 1876, Arákùnrin Charles Taze Russell gbé àpilẹ̀kọ kan jáde nínú ìwé ìròyìn Bible Examiner. Àkòrí àpilẹ̀kọ náà ni, “Àwọn Àkókò Kèfèrí: Ìgbà Wo Ni Wọ́n Dópin?,” èyí sì ń tọ́ka sí ọdún 1914 pé ó jẹ́ ọdún mánigbàgbé. Àpilẹ̀kọ náà jẹ́ ká mọ bí “ìgbà méje” tí Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ ṣe kan “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” tí Jésù sọ. *Dán. 4:16; Lúùkù 21:24.

13. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1914, kí sì ni àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé láti ìgbà yẹn fi ẹ̀rí ẹ̀ múlẹ̀?

 13 Lọ́dún 1914, àwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn jagun, ogun yẹn sì tàn kárí ayé. Ìgbà tó fi máa kásẹ̀ nílẹ̀ lọ́dún 1918, oúnjẹ ti di góòlù, àrùn gágá sì tún fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò débi pé iye tí àìsàn náà pa ju iye àwọn tí ogun pa lọ. Torí náà, “àmì” tí Jésù sọ pé ó máa jẹ́ ẹ̀rí wíwàníhìn-ín òun tí a kò lè fojú rí gẹ́gẹ́ bí Ọba tuntun, èyí tí yóò ṣàkóso lórí ayé ti bẹ̀rẹ̀ sí í nímùúṣẹ. (Mát. 24:3-8; Lúùkù 21:10, 11) Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé ọdún 1914 ni ìgbà tí Ọlọ́run “fún” Jésù Kristi Olúwa “ní adé.” Torí náà, ó “jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìṣí. 6:2) Kó lè fọ ọ̀run mọ́, ó bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jagun, ó sì lé wọn dà nù sí orí ilẹ̀ ayé. Látìgbà yẹn, àwọn ẹ̀dá èèyàn ti gbà pẹ̀lú ohun tí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí sọ, pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣí. 12:7-12.

14. (a) Kí nìdí tó tún fi ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà kí Ìjọba Ọlọ́run dé? (b) Kí la láǹfààní láti ṣe?

14 Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 12:7-12 ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé ìgbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ bọ́ sí ìgbà kan náà tí àjálù lọ́kan-ò-jọ̀kan bẹ̀rẹ̀ sí í han aráyé léèmọ̀. Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í jọba láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀. Títí dìgbà tó fi máa parí ìṣẹ́gun rẹ̀, táá sì mú òpin dé bá ìwà ibi lórí ilẹ̀ ayé, a óò máa bá a nìṣó láti máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Lẹ́sẹ̀  kan náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tí irú àdúrà bẹ́ẹ̀ sọ, lọ́nà wo? Ká máa kópa nínú apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú “àmì” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mát. 24:14.

“KÍ ÌFẸ́ RẸ ṢẸ . . . LÓRÍ ILẸ̀ AYÉ”

15, 16. Báwo la ṣe lè máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá àdúrà wa mu pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé?

15 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún sẹ́yìn, àwọn èèyàn ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ lórí ilẹ̀ ayé. Abájọ tí Jèhófà fi wo àwọn ohun rere tó ṣe fún àwọn ẹ̀dá èèyàn tó wá sọ pé: “Ó dára gan-an ni.” (Jẹ́n. 1:31) Nígbà tó yá, Sátánì di ọlọ̀tẹ̀, látìgbà yẹn sì rèé, ìwọ̀nba èèyàn kéréje ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ lóde òní, àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń gbé lásìkò tí iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ. Gbogbo wọn ń gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì tún ń sapá láti gbé ìgbé ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà náà. Wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó mú inú Ọlọ́run dùn, wọ́n sì ń kópa kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù.

Ǹjẹ́ ò ń ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó bá àdúrà náà mu pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé? (Wo ìpínrọ̀ 16)

16 Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1948, tó sì ti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Áfíríkà sọ pé: “Tí mo bá fẹ́ gbàdúrà nípa kókó yìí nínú àdúrà àwòṣe, mo sábà máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí á lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ẹni bí àgùntàn, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà kó tó pẹ́ jù. Bákan náà, tí mo bá fẹ́ wàásù fún ẹnì kan, mo máa ń béèrè fún ọgbọ́n kí n lè dénú ọkàn ẹni náà. Mo sì tún máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà máa bù kún ìsapá wa ká lè máa bójú tó àwọn ẹni bí àgùntàn tá a ti rí.” Abájọ tí arábìnrin ẹni ọgọ́rin [80] ọdún yìí fi ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn àwọn ará míì, ó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láìsí àní-àní, ìwọ náà lè ronú kan àpẹẹrẹ rere àwọn míì tí wọ́n fi gbogbo okun wọn ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bí ọjọ́ ogbó ò tiẹ̀ jẹ́ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀.—Ka Fílípì 2:17.

17. Kí lèrò rẹ̀ nípa ohun tí Jèhófà máa tó ṣe láti fi dáhùn àdúrà wa pé kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé?

17 Títí dìgbà tí Ọlọ́run yóò fi pa àwọn ọ̀tá Ìjọba náà run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, a óò máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, a óò rí bí ìfẹ́ Ọlọ́run yóò ṣe nímùúṣẹ lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́ nígbà tí bílíọ̀nù àwọn òkú bá jí dìde. Jésù sọ pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [mi], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòh. 5:28, 29) Ẹ ò rí i pé àsìkò aláyọ̀ ló máa jẹ́ fún wa nígbà tá a bá ń kí àwọn èèyàn wa tó ti kú káàbọ̀! Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [wa].” (Ìṣí. 21:4) Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó bá jíǹde nígbà yẹn máa jẹ́ “àwọn aláìṣòdodo,” ìyẹn àwọn tó gbé láyé tí wọ́n sì kú láìmọ òtítọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. Àǹfààní ló máa jẹ́ fún wa láti jẹ́ kí àwọn tó bá jíǹde mọ ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tóótun láti jogún “ìyè àìnípẹ̀kun.”—Ìṣe 24:15; Jòh. 17:3.

18. Kí ni ohun táwa ẹ̀dá èèyàn nílò jù lọ?

18 Ìjọba Ọlọ́run tó máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ nìkan ló máa mú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan dé bá gbogbo ayé. Torí náà, ìdáhùn sí ìbéèrè mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú àdúrà àwòṣe náà ló máa jẹ́ kí ọwọ́ aráyé tẹ ohun tí wọ́n nílò jù lọ. Àwọn ohun míì ṣì wà tó ṣe pàtàkì tí Jésù mẹ́nu kàn nínú apá mẹ́rin tó kù nínú àdúrà àwòṣe náà. A máa jíròrò wọn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 12 Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i lórí bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ní ìmúṣẹ ní ọdún 1914, ìyẹn ìgbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba Mèsáyà kalẹ̀, wo ìwé Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ojú ìwé 215 sí 218.