Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) June 2015

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti July 27 sí August 30, 2015 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Kristi—Agbára Ọlọ́run

Kì í ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ nìkan ni àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù ṣe láàǹfàní, àmọ́ wọ́n tún fi ohun tí Jésù máa ṣe fún aráyé láìpẹ́ hàn.

Ó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn

Báwo ni bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jésù ṣe hàn nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe?

A Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́

Bíbélì sọ ohun mẹ́ta tó lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí èròkerò.

“Tí Kingsley Bá Lè Ṣe É, Èmi Náà Lè Ṣe É!”

Kingsley, tó wá láti orílẹ̀-èdè Siri Láńkà, borí ìṣòro tó ní kó lè ṣe iṣẹ́ tí kò ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.

Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà—Apá I

Kí nìdí tí Jésù fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà “Baba Wa” kàkà kó sọ pé “Baba Mi”?

Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà—Apá Kejì

Nígbà tí a bá bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní, kì í ṣe oúnjẹ nípa tara wa nìkan ni à ń béèrè fún.

“Ẹ Nílò Ìfaradà”

Àwọn ohun mẹ́rin tí Jèhófà fún wa ká lè fara da àdánwò tàbí ipò tó le koko.

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣé o tí ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè rántí àwọn ohun tí o kà.