Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  May 2015

 LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

O Ri I Pe Ife Lo Mu Ki Nnkan Wa Letoleto Nile Ijeun Naa

O Ri I Pe Ife Lo Mu Ki Nnkan Wa Letoleto Nile Ijeun Naa

KÒ SÍGBÀ táwọn èèyàn Jèhófà pé jọ láti jẹun lórí tábìlì rẹ̀ tí inú wọn kì í dùn. Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá lọ sáwọn àpéjọ wa láti gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí, tó bá sì tún tó àsìkò tá a máa jẹ oúnjẹ tara níbẹ̀, ayọ̀ wa máa ń pọ̀ sí i.

Ní oṣù September, ọdún 1919, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àpéjọ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́jọ ní ìlú Cedar Point, ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ṣètò pé àwọn hòtẹ́ẹ̀lì táwọn ará máa dé sí ló máa pèsè oúnjẹ fún wọn, àmọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló tún dé yàtọ̀ sáwọn tí wọ́n ń retí. Iye àwọn ará tó dé yìí ka àwọn tó ń gbé oúnjẹ fúnni láwọn ilé ìjẹun láyà, ni gbogbo wọn bá daṣẹ́ sílẹ̀. Ọ̀gá tó ń mójú tó ilé ìjẹun náà bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́nà àbáyọ, ó wá béèrè bóyá lára àwọn ọ̀dọ́ tó wá sí àpéjọ náà lè ran òun lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ lára wọn sì fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn. Ọ̀kan lára wọn ni Arábìnrin Sadie Green. Ó sọ pé “Ìgbà àkọ́kọ́ tí màá ṣe iṣẹ́ ká máa gbé oúnjẹ fúnni nílé ìjẹun nìyí, àmọ́ mo gbádùn rẹ̀ gan-an ni.”

1982 lórílẹ̀-èdè Sierra Leone

Ní àwọn àpéjọ tó wáyé láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn ará ṣètò ilé ìjẹun, ó sì mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn yọ̀ǹda ara wọn tayọ̀tayọ̀ láti ṣètò oúnjẹ fáwọn ará yòókù. Bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe báwọn ará bíi tiwọn ṣiṣẹ́ tún jẹ́ kí ọ̀pọ̀ lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí í ní àfojúsùn tẹ̀mí. Arábìnrin Gladys Bolton ṣiṣẹ́ nílé ìjẹun ní àpéjọ kan tó wáyé lọ́dún 1937. Ó sọ pé: “Mo pàdé àwọn tó wá láti àwọn ìlú míì, wọ́n sì sọ bí wọ́n ṣe borí àwọn ìṣòro wọn fún mi. Ìgbà yẹn ló kọ́kọ́ wá sí mi lọ́kàn pé èmi náà lè di aṣáájú-ọ̀nà.”

Ara àwọn tó wá sí àpéjọ àgbègbè kan ni Arábìnrin Beulah Covey, ó sọ pé: “Bí gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ṣe jára mọ́ṣẹ́ kò jẹ́ kí nǹkan kan wọ́lẹ̀ rárá.” Àmọ́ ṣá, àwọn ìṣòro kan máa ń jẹyọ lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ ní 1969, ìgbà tí arákùnrin Angelo Manera dé pápá ìṣeré Dodger Stadium, tí wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọ àgbègbè ní ìlú Los Angeles, ìpínlẹ̀ California ló tó mọ̀ pé òun ni wọ́n yàn láti bójú tó ilé ìjẹun tí wọ́n máa lò níbẹ̀. Ó sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀, ó ní, “Mi ò tíì ronú kàn án rí láyé mi pé mo lè ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀!” Ọ̀kan lára iṣẹ́ ńlá tá a ní láti ṣe ká lè múra sílẹ̀ ni gbígbẹ́ ilẹ̀ tá a máa ri páìpù tó máa gbé gáàsì lọ sí ilé ìdáná, gígùn páìpù náà sì lé ní ẹgbẹ̀rún kan ẹsẹ̀ bàtà!

1951 ní ìlú Frankfurt, ilẹ̀ Jámánì

Lọ́dún 1982, lórílẹ̀-èdè Sierra Leone, àwọn ará tó ní akíkanjú tó yọ̀ǹda ara wọn ní láti kọ́kọ́ ṣánko tó wà lórí ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ kọ́ ilé ìjẹun sí, àwọn ohun èlò tó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó ni wọ́n fi kọ́ ilé náà. Lọ́dún 1951, ní ìlú Frankfurt, lórílẹ̀-èdè Jámánì, àwọn ará kan tó láròjinlẹ̀ lọ yá ẹ̀rọ tó ń lo èédú láti fi pèsè ooru iná tí wọ́n máa fi se oúnjẹ nínú ogójì [40] ìkòkò ìse-oúnjẹ. Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] èèyàn ni wọ́n fún lóúnjẹ láàárín wákàtí kan péré. Kí iṣẹ́ má bàa wọ àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [576] tó ń fọ abọ́ lọ́rùn, ṣe ni àwọn tó wá sí àpéjọ náà mú fọ́ọ̀kì àti ọ̀bẹ tí wọ́n fi jẹun wá láti ilé. Ní ìlú Yangon, lórílẹ̀-èdè Myanmar, kí àwọn tó ń se oúnjẹ lè gba tàwọn ará tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè rò, wọ́n dín àwọn èlò tó máa jẹ́ kí oúnjẹ wọn ta kù.

“ORÍ ÌDÚRÓ NI WỌ́N TI Ń JẸUN”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú oòrùn tó mú ganrín-ganrín ni Arábìnrin Annie Poggensee àtàwọn tó tò sórí ìlà wà nílé ìjẹun ní àpéjọ àgbègbè kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1950, ó jàǹfààní látinú ohun kan tó ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tó gbádùn mọ́ni táwọn arábìnrin méjì kan tó wọkọ̀ ojú omi wá láti ilẹ̀ Yúróòpù ń sọ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.” Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sọ bí Jèhófà ṣe ran òun lọ́wọ́ kí òun lè wá sí àpéjọ náà. Annie tún sọ pé “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tínú rẹ̀ dùn tó tiwọn níbẹ̀. Gbogbo bá a ṣe tò sórí ìlà nínú oòrùn, kò tiẹ̀ jẹ́ nǹkan kan lójú wọn.”

1963 ní ìlú Seoul, ilẹ̀ Korea

Lọ́pọ̀ ìgbà, láwọn àpéjọ ńlá wa, wọ́n máa ń ta tẹ́ǹtì ńlá láti fi bo ilé oúnjẹ tí wọ́n to ọ̀pọ̀lọpọ̀ tábìlì ìjẹun tó ga sí, èèyàn sì lè jẹun lórí wọn tó bá wà lórí ìdúró, èyí sì máa ń mú káwọn tó bá ń jẹun ṣe kíá, káwọn míì náà lè ráyè jẹun. Àbí, báwo ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará ṣe máa ríbi jẹun láàárín àkókò ìjẹun ọ̀sán tí wọn ò bá dá ọgbọ́n yìí? Ọkùnrin kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí sọ pé: “Ẹ̀sìn yìí ṣàjèjì o. Orí ìdúró ni wọ́n ti ń jẹun.”

Ètò táwọn ará ṣe àti bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ dáadáa máa ń ya àwọn ológun àtàwọn aláṣẹ ìjọba lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá wá wo ohun tó ń lọ láwọn àpéjọ. Lẹ́yìn tí ọ̀gá kan lára àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà wá wo ilé ìjẹun tá a lò ní pápá ìṣeré Yankee Stadium ní ìlú New York City, ó ní kí ọ̀gágun Faulkner tó wà ní Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ogun Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá fi ojú ara rẹ̀ rí ohun tóun rí níbẹ̀. Torí náà, lọ́dún 1955 òun àti ìyàwó rẹ̀ wá sí àpéjọ tá a pe ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní “Ijọba Alayọ Iṣẹgun” tá a ṣe ní àgbègbè Twickenham, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ó sọ pé ìfẹ́ tó wà láàárín wọn ló mú kí gbogbo nǹkan wà létòletò ní ilé ìjẹun náà.

Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ará tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú ti ń se oúnjẹ tó ṣara lóore lówó pọ́ọ́kú fáwọn tó ń wá sí àpéjọ àgbègbè wa. Àmọ́, iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n máa ń ṣe gba pé kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn yọ̀ǹda ara wọn láti fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣíṣẹ́, èyí kì í jẹ́ kí wọ́n jàǹfààní nínú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó ń lọ lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ lè gbọ́ ìkankan rárá níbẹ̀. Láàárín ọdún 1976 sí 1979, a mú kí ìṣètò oúnjẹ láwọn àpéjọ àgbègbè túbọ̀ rọrùn. Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1995, ilé làwọn tó ń wá sí àpéjọ wa ti ń gbé oúnjẹ wọn wá. Èyí mú kí àwọn ará tí wọ́n máa ń se oúnjẹ tẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì máa ń bù ú fáwọn èèyàn láǹfààní láti gbádùn àpéjọ náà kí wọ́n sì fara rora pẹ̀lú àwọn ará. *

Ó dájú pé Jèhófà mọyì àwọn tó ṣiṣẹ́ kára kí àwọn ará bíi tiwọn lè gbádùn àwọn àpéjọ tó wáyé nígbà yẹn. Àwọn àkókò yẹn lárinrin lóòótọ́, ó sì máa ń mú kó wu àwọn kan pé káwọn tún láǹfààní láti ṣiṣẹ́ nílé ìjẹun. Àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé: Ìfẹ́ tó wà láàárín wa lohun tó ń mú káwọn àpéjọ wa lárinrin.—Jòh. 13:34, 35.

^ ìpínrọ̀ 12 Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àǹfààní ṣì wà fáwọn ará láti ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka míì ní àpéjọ àgbègbè.