Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  May 2015

Won “Ri” Awon Ohun Ti Olorun Seleri

Won “Ri” Awon Ohun Ti Olorun Seleri

‘Wọn kò rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn lókè réré.’—HÉB. 11:13.

1. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí a kò tíì rí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

BÁ A ṣe lè fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí a kò tíì rí jẹ́ ẹ̀bùn kan tí Ọlọ́run fi jíǹkí wa. Ó máa ń jẹ́ ká ṣe àwọn ètò tó mọ́gbọ́n dání, ká sì máa retí àwọn ohun tó dáa lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó sábà máa ń lo Ìwé Mímọ́ láti sọ fún wa nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ kó tó di pé wọ́n ṣẹlẹ̀, èyí sì lè jẹ́ ká fọkàn yàwòrán ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Ká sòótọ́, bá a ṣe lè fọkàn yàwòrán ohun tí a kò rí máa ń jẹ́ ká lè lo ìgbàgbọ́.—2 Kọ́r. 4:18.

2, 3. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fọkàn yàwòrán ohun tó máa ṣẹlẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Nígbà míì, tá a bá fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí a kò tíì rí, ó lè má fìgbà gbogbo rí bá a ṣe rò ó. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọbìnrin kékeré kan bá ń fọkàn yàwòrán pé òun ń gun labalábá bí ẹní gẹṣin, àlá tí kò lè ṣẹ nìyẹn. Àmọ́, nígbà tí Hánà ń ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí tí òun bá mú Sámúẹ́lì ọmọkùnrin òun lọ sìn nínú àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn kì í ṣe àlá lásán torí pé ó ní ìdí pàtàkì tó fi ronú bẹ́ẹ̀. Ohun tó ti pinnu láti ṣe nìyẹn, èyí sì jẹ́ kó lè mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ. (1 Sám. 1:22) Tá a bá ń fọkàn yàwòrán ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa ṣe, ohun tó dájú pé ó máa ṣẹlẹ̀ là ń fọkàn rò yẹn.—2 Pét. 1:19-21.

3 Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn ló fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Àǹfààní wo ni wọ́n rí bí wọ́n ṣe fọkàn yàwòrán àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú? Àǹfààní wo ló sì wà níbẹ̀ tá a bá ń ronú lórí àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe fún àwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n jẹ́ onígbọràn?

ÌGBÀGBỌ́ WỌN TÚBỌ̀ JINLẸ̀ TORÍ PÉ WỌ́N “RÍ” OHUN TÍ WỌ́N Ń RETÍ

4. Kí ni ohun tó jẹ́ kí Ébẹ́lì lè fọkàn yàwòrán bí ọjọ́ iwájú sẹ máa rí?

4 Ǹjẹ́ ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ tó jẹ́ olóòótọ́, ìyẹn Ébẹ́lì “rí” ohunkóhun tí Jèhófà ṣèlérí? A ò lè sọ pé Ébẹ́lì ti mọ̀ ṣáájú bí àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa ejò náà ṣe máa nímùúṣẹ, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ pé: “Èmi yóò . . . fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́n. 3:14, 15) Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí Ébẹ́lì ti ronú jinlẹ̀ lórí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, kó sì rí i pé ó máa gba pé kí wọ́n ‘pa ẹnì kan ni gìgísẹ̀’ kí àwọn ẹ̀dá èèyàn tó lè di ẹ̀dá pípé, bí Ádámù àti Éfà ṣe rí kó tó di pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀. Ohun yòówù kí Ébẹ́lì máa rò nípa ọjọ́ iwájú, ẹ̀rí fi hàn pé ó nígbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run, Jèhófà sì tẹ́wọ́ gba ẹbọ rẹ̀.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 4:3-5; Hébérù 11:4.

5. Kí nìdí tó fi jẹ́ ìṣírí fún Énọ́kù bó ṣe fọkàn yàwòrán ọjọ́ iwájú?

5 Énọ́kù ọkùnrin olóòótọ́ náà lo ìgbàgbọ́, kódà nígbà tó ń wàásù fáwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ tó burú jáì sí Ọlọ́run. Ọlọ́run mí sí Énọ́kù láti sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà yóò wá ‘pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun búburú jáì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ sí i.’ (Júúdà 14, 15) Torí pé Énọ́kù lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó lè fọkàn yàwòrán ayé kan tí kò ní sí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run mọ́.—Ka Hébérù 11:5, 6.

6. Kí ló ṣeé ṣe kí Nóà máa rò lọ́kàn lẹ́yìn Ìkún omi náà?

6 Torí pé Nóà nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó la Ìkún omi náà já. (Héb. 11:7) Lẹ́yìn Ìkún omi náà, ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú kó fi ẹran rúbọ sí Jèhófà. (Jẹ́n. 8:20) Bíi ti Ébẹ́lì, òun náà ní ìgbàgbọ́ tó dájú pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ẹ̀dá èèyàn máa bọ́ nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nóà ṣì ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí nínú Jèhófà kódà lẹ́yìn Ìkún omi lákòókò táwọn èèyàn kẹ̀yìn sí Jèhófà, ìyẹn lákòókò tí Nímírọ́dù tako àṣẹ Jèhófà. (Jẹ́n. 10:8-12) Ó ṣeé ṣe kí Nóà máa fọkàn yàwòrán ìgbà tí ẹ̀dá èèyàn máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí wọ́n jogún, tí wọ́n á sì bọ́ lọ́wọ́ àwọn alákòóso aninilára. Àwa náà lè “rí” àkókò alárinrin yìí. Ó sì ti dé tán báyìí!—Róòmù 6:23.

WỌ́N “RÍ” ÀWỌN ÌLÉRÍ NÁÀ BÍI PÉ WỌ́N TI NÍMÙÚṢẸ

7. Irú ọjọ́ iwájú wo ló ṣeé ṣe kí Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù “rí”?

7 Ó ṣeé ṣe kí Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù máa fọkàn yàwòrán ọjọ́ iwájú aláyọ̀ kan. Ìdí ni pé Ọlọ́run ti ṣèlérí pé nípasẹ̀ irú ọmọ wọn, gbogbo orílẹ̀-èdè ayé máa gba ìbùkún. (Jẹ́n. 22:18; 26:4; 28:14) Àwọn àtọmọdọ́mọ àwọn baba ńlá yìí máa di púpọ̀ rẹpẹtẹ, wọ́n sì máa gbé ní Ilẹ̀ Ìlérí tí Ọlọ́run ṣèlérí fún wọn. (Jẹ́n. 15:5-7) Torí pé àwọn ọkùnrin tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run yẹn ní ìgbàgbọ́, wọ́n “rí” àwọn àtọmọdọ́mọ wọn bíi pé wọ́n tí ń gbé ní ilẹ̀ náà. Látìgbà tí Ádámù àti Éfà ti dẹ́ṣẹ̀, tí ìran èèyàn sì ti di aláìpé, ni Jèhófà ti fi dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin lójú pé wọ́n ṣì lè gba àwọn ìbùkún tí Ádámù gbé sọnù.

8. Kí ló jẹ́ kí Ábúráhámù lè lo ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀?

8 Ó lè jẹ́ pé bí Ábúráhámù ṣe lè fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí ló jẹ́ kó lè fi ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀ hàn. Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù àtàwọn míì tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò “rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà” nígbà ayé wọn, ‘wọ́n rí wọn lókè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n.’ (Ka Hébérù 11:8-13.) Ábúráhámù ti rí ẹ̀rí tó pọ̀ rẹpẹtẹ tó jẹ́ kó gbà pé ohun tó ń retí lọ́jọ́ iwájú máa ṣẹlẹ̀, àfi bíi pé ó rí ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú!

9. Àǹfààní wo ni Ábúráhámù rí gbà torí bó ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run?

9 Ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run mú kó túbọ̀ tẹra mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Torí ìgbàgbọ́ tó ní, ó kúrò ní ìlú Úrì, kò sì jókòó pa sí èyíkéyìí nínú àwọn ìlú tó wà nílẹ̀ Kénáánì. Àwọn ìlú tó wà nílẹ̀ Kénáánì dà bí ìlú Úrì, wọn ò láyọ̀lé torí pé àwọn alákòóso wọn ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. (Jóṣ. 24:2) Ní gbogbo ọjọ́ gígún tí Ábúráhámù fi gbé láyé ló fi ń “dúró de ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.” (Héb. 11:10) Ábúráhámù “rí” ara rẹ̀ bíi pé ó ti wà ní ibì kan tí yóò máa gbé títí láé, èyí tí Jèhófà ń ṣàkóso rẹ̀. Ébẹ́lì, Énọ́kù, Nóà, Ábúráhámù àtàwọn míì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ bíi tiwọn nígbàgbọ́ pé àwọn òkú máa jíǹde, wọ́n sì ń retí ìgbà tí wọ́n á máa gbé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, tó jẹ́ “ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́.” Bí wọ́n ṣe fọkàn yàwòrán irú àwọn ìbùkún yìí, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.—Ka Hébérù 11:15, 16.

10. Àǹfààní wo ni Sárà rí bó ṣe ń ronú nípa ọjọ́ iwájú?

10 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìyàwó Ábúráhámù, ìyẹn Sárà. Nígbà tó wà lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún tí kò sì lọ́mọ, ó gbà pé ọjọ́ iwájú máa dáa, ìyẹn sì jẹ́ kó lè ṣe ohun tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́. Ńṣe ló dà bí ìgbà tó ń wo àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tí wọ́n ń gbádùn àwọn ìbùkún tí Jèhófà ti ṣèlérí fún wọn. (Héb. 11:11, 12) Kí ló jẹ́ kó ní irú ìrètí yìí? Jèhófà ti sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Èmi yóò sì bù kún un, èmi yóò sì tún fi ọmọkùnrin kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀; èmi yóò sì bù kún un, òun ó sì di àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ọba àwọn ènìyàn yóò sì wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (Jẹ́n. 17:16) Lẹ́yìn tí Sárà bí Ísákì, ó ní ẹ̀rí tó lágbára láti fọkàn yàwòrán pé gbogbo àwọn ìlérí tó kù tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù máa ṣẹ. Ẹ ò rí i pé ẹ̀bùn iyebíye làwa náà ní torí bá a ṣe lè fọkàn yàwòrán àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣèlérí, tó sì dá wa lójú pé ó máa nímùúṣẹ!

TẸJÚ MỌ́ ÈRÈ NÁÀ

11, 12. Báwo ni Mósè ṣe dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

11 Ẹlòmíì tó tún lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà ni Mósè, ó fi hàn pé òun ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà. Nígbà tí Mósè wà lọ́dọ̀ọ́ tó ń gbé láàfin àwọn ará Íjíbítì, ó rọrùn kí agbára àti ọrọ̀ kó sí i lórí. Àmọ́, àwọn tó jẹ́ òbí rẹ̀ gangan ti kọ́ ọ nípa Jèhófà àti bí Jèhófà ṣe pinnu pé òun máa dá àwọn Hébérù nídè kúrò lóko ẹrú tí á sì mú wọn dé Ilẹ̀ Ìlérí. (Jẹ́n. 13:14, 15; Ẹ́kís. 2:5-10) Tí Mósè bá ń fìgbà gbogbo ronú lórí àwọn ìbùkún táwọn èèyàn Ọlọ́run máa rí gbà lọ́jọ́ iwájú, ó dájú pé ìfẹ́ Jèhófà ló máa gbà á lọ́kàn jù lọ, kò ní máa ro bó ṣe máa di olókìkí èèyàn.

12 Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí ó dàgbà, fi kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò, ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, nítorí pé ó ka ẹ̀gàn Kristi sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju àwọn ìṣúra Íjíbítì; nítorí tí ó tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.”—Héb. 11:24-26.

13. Àǹfààní wo ni Mósè rí bó ṣe ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe?

13 Bí Mósè ṣe ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìlérí tí Jèhófà ti ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ńṣe ni ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ó ṣeé ṣe kóun náà ṣe bíi tàwọn èèyàn kan tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, kó máa fọkàn yàwòrán àkókò tí Jèhófà máa dá aráyé nídè lọ́wọ́ ikú. (Jóòbù 14:14, 15; Héb. 11:17-19) A lè wá rí ìdí tí Mósè fi wá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run torí bó ṣe fojú àánú hàn sáwọn Hébérù àti sí gbogbo aráyé. Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ló sún Mósè ṣe gbogbo nǹkan tó ṣe jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Diu. 6:4, 5) Kódà nígbà tí Fáráò ń halẹ̀ mọ́ Mósè pé òun máa pa á, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí Mósè ní sí Ọlọ́run àti bó ṣe máa ń fọkàn yàwòrán ọjọ́ iwájú aláyọ̀ kan mú kó nígboyà bí Fáráò tiẹ̀ ń halẹ̀ ikú mọ́ ọn.—Ẹ́kís. 10:28, 29.

MÁA FỌKÀN YÀWÒRÁN ÀWỌN ÌBÙKÚN ÌJỌBA ỌLỌ́RUN

14. Irú èrò wo la lè pè ní àlá ọ̀sán gangan?

14 Ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń rò lónìí nípa ọjọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ lè máa ronú pé lọ́jọ́ iwájú àwọn máa ní ibú owó àti pé ààbò tó péye máa wà fáwọn, nígbà tó sì jẹ́ pé ìgbésí ayé èèyàn nísinsìnyí kún fún “ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́.” (Sm. 90:10) Wọ́n ń ronú pé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn á máa gbé láìséwu lábẹ́ ìjọba èèyàn, nígbà tó sì jẹ́ pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè tán ìṣòro aráyé. (Dán. 2:44) Ọ̀pọ̀ ló rò pé Ọlọ́run kò ní pa ètò nǹkan ìsinsìnyí run, àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. (Sef. 1:18; 1 Jòh. 2:15-17) Ńṣe làwọn tí wọ́n bá ń fọkàn wọn sí àwọn ohun tá a sọ yìí dàbí ẹní tó ń lálàá ọ̀sán gangan, torí pé èrò wọn tako ìfẹ́ Jèhófà.

Ǹjẹ́ o lè máa wo ara rẹ bíi pé o ti wà nínú ayé tuntun? (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. (a) Báwo làwọn Kristẹni ṣe ń jàǹfààní bí wọ́n ṣe ń fọkàn yàwòrán ìrètí wọn? (b) Sọ ohun tó ò ń retí nígbà tí Ọlọ́run bá mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

15 Ní ti àwa Kristẹni, ó máa ń fún wa níṣìírí bá a ṣe ń fọkàn yàwòrán ìrètí wa, yálà à ń retí láti gbé lókè ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ ò ń fọkàn yàwòrán ara ẹ bíi pé ò ń gbádùn àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣèlérí? Ó dájú pé bó o ṣe ń fọkàn yàwòrán àwọn ohun tó o máa ṣe tí Ọlọ́run bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ máa jẹ́ kó o láyọ̀ gan-an. Ó ṣeé ṣe kó o máa “rí” ara rẹ pé o ti ń gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Ronú lórí bó o ṣe ń pawọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn míì láti sọ gbogbo ayé yìí di Párádísè. Bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà náà ni gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ jọ wà láyé ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Koko lara rẹ á máa le, ojú ẹ á sì máa dán gbinrin. Àwọn tó máa ṣe kòkárí bí ayé á ṣe di Párádísè kò mú nǹkan nira rárá torí pé ire rẹ jẹ wọ́n lógún. O sì ń fi tayọ̀tayọ̀ lo ìmọ̀ tó o ní àti ohun tó o mọ̀ ọ́n ṣe, torí pé gbogbo nǹkan tó ò ń ṣe ń ṣàǹfààní fáwọn míì, ó sì ń bọlá fún Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ò ń ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jíǹde lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà. (Jòh. 17:3; Ìṣe 24:15) Èyí kì í ṣe àlá lásán o. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ọjọ́ iwájú lò ń fọkàn yàwòrán rẹ̀ yẹn.—Aísá. 11:9; 25:8; 33:24; 35:5-7; 65:22.

ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA SỌ̀RỌ̀ NÍPA ÌRÈTÍ WA

16, 17. Àǹfààní wo ló máa ṣe fún wa tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìrètí wa?

16 Bá a ṣe ń sọ fún àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni nípa ohun tó máa wù wá ká ṣe nígbà tí Jèhófà bá mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ńṣe ni àwọn ohun tá à ń fọkàn yàwòrán nípa ọjọ́ iwájú á túbọ̀ máa ṣe kedere lọ́kàn wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́nikẹ́ni nínú wa tó lè sọ ní pàtó bí nǹkan ṣe máa rí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ayé tuntun, tá a bá ń sọ ohun tá a rò pé ó máa ṣẹlẹ̀, èyí máa jẹ́ ìṣírí fún olúkúlùkù wa, ó sì máa jẹ́ ká fi hàn pé a nígbàgbọ́ pé àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí máa ṣẹ. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará nílùú Róòmù, wọ́n mọyì “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” tí wọ́n rí gbà, àwa náà sì máa ń mọyì irú ìṣírí bẹ́ẹ̀ láwọn àkókò tó kún fún ìdààmú yìí.—Róòmù 1:11, 12.

17 Tá a bá ń fọkàn yàwòrán ọjọ́ iwájú, kò ní jẹ́ kí àwọn ìṣòro tá a ní nísinsìnyí bò wá mọ́lẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó wà lọ́kàn àpọ́sítélì Pétérù nìyẹn nígbà tó fi sọ fún Jésù pé: “Wò ó! Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kí ni yóò wà fún wa ní ti gidi?” Kí Jésù lè kọ́ Pétérù àtàwọn míì tó wà níbẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa ronú nípa ọjọ́ iwájú, Jésù dáhùn pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ní àtúndá, nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yóò jókòó pẹ̀lú sórí ìtẹ́ méjìlá, ẹ óò máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá. Àti pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi yóò rí gbà ní ìlọ́po-ìlọ́po sí i, yóò sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Mát. 19:27-29) Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù lè wá máa fọkàn ro ojúṣe wọn nínú ìjọba tó máa ṣàkóso lé ayé lórí, tó sì máa mú ìbùkún jìgbìnnì bá àwọn ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ onígbọràn.

18. Báwo ni ríronú lórí ìgbà tí Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ ṣe lè ṣe wá láǹfààní lónìí?

18 Ọjọ́ pẹ́ tí ríronú lórí ìgbà tí Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ ti máa ń ṣe àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé láǹfààní. Ébẹ́lì mọ púpọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe, ìdí nìyẹn tó fi lè fọkàn yàwòrán àwọn ohun rere tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó jẹ́ kó lo ìgbàgbọ́, kó sì ní ìrètí tó dájú. Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé ó “rí” ohun kan tó jẹ́ kó mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa “irú-ọmọ” náà máa ṣẹ. (Jẹ́n. 3:15) Mósè “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà,” èyí jẹ́ kó ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́, ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà sì ń pọ̀ sí i. (Héb. 11:26) Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ táwa náà ní sí Ọlọ́run máa pọ̀ sí i tá a bá ń lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa tó jẹ́ ká lè fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí, bíi pé wọ́n ti ṣẹ. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò bá a ṣe lè lo ẹ̀bùn yìí lọ́nà tó dára jù lọ.