Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Nje O Da E Loju Pe O Ni Ajose To Dan Moran Pelu Jehofa

Nje O Da E Loju Pe O Ni Ajose To Dan Moran Pelu Jehofa

“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” —JÁK. 4:8.

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá kí àjọṣe àwa àti Jèhófà lè lágbára gan-an?

ṢÉ O ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, tí o sì ti ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o ní ohun iyebíye kan, ìyẹn ni pé o ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́, ayé Sátánì ń gbógun ti àjọṣe àwa àti Ọlọ́run, ẹran ara wa aláìpé kò sì jẹ́ ká gbádùn. Gbogbo àwa Kristẹni là ń kojú ìṣòro yìí. Torí náà, àjọṣe àwa àti Jèhófà gbọ́dọ̀ lágbára gan-an.

2. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti ní àjọṣe pẹ̀lú ẹlòmíì? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Báwo la ṣe lè mú kí àjọṣe àwa àti Jèhófà lágbára sí i?

2 Ǹjẹ́ ó dá ẹ lójú pé o ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà? Ṣé wàá fẹ́ kí àjọṣe yẹn dán mọ́rán sí i? Jákọ́bù 4:8 sọ bó o ṣe lè ṣe é, ó sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” Kíyè sí i pé ọ̀nà méjì ni ìgbésẹ̀ yìí pín sí. * Bá a ṣe ń sapá láti sún mọ́ Ọlọ́run, òun náà á máa sún mọ́ wa. Tá a bá wá ń tẹra mọ́ ọn, àjọṣe àwa àti Jèhófà á máa dán mọ́rán síwájú àti síwájú sí i. Èyí máa jẹ́ kó dá wa lójú pé a ní àjọṣe tó dán  mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Àwa náà á lè ní irú ìdánilójú tí Jésù ní nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ó rán mi jẹ́ ẹni gidi, . . . Èmi mọ̀ ọ́n.” (Jòh. 7:28, 29) Àmọ́, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

Báwo lo ṣe lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, kó o sì gbọ́ ohun tó ń bá ẹ sọ? (Wo ìpínrọ̀ 3)

3. Ọ̀nà wo la gbà ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀, báwo ló sì ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀?

3 Tá a bá fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá a sọ̀rọ̀ déédéé. Báwo lo ṣe lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, kó o sì tún gbọ́ ohun tó ń bá ẹ sọ? Rò ó wò ná, báwo nìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ kan tó ń gbé lọ́nà jíjìn ṣe máa ń bá ara yín sọ̀rọ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, ẹ sábà máa ń kọ lẹ́tà síra yín tàbí kí ẹ bá ara yín sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Ọ̀nà tó o lè gbà bá Jèhófà sọ̀rọ̀ ni kó o máa gbàdúrà sí i déédéé. (Ka Sáàmù 142:2.) O sì ń jẹ́ kí Jèhófà bá ẹ sọ̀rọ̀ tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó o sì ń ṣàṣàrò lé e lórí déédéé. (Ka Aísáyà 30:20, 21.) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí bíbá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé àti fífetí sílẹ̀ sí i á ṣe jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ dán mọ́rán sí i, kó sì túbọ̀ jẹ́ ẹni gidi sí wa.

JÈHÓFÀ Ń BÁ Ẹ̀ SỌ̀RỌ̀ NÍPASẸ̀ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

4, 5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti bá ẹ sọ̀rọ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan.

4 Kò sí àní-àní pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì wà fún gbogbo èèyàn. Àmọ́, ǹjẹ́ Bíbélì sọ bí ìwọ alára ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni o. Lọ́nà wo? Bó o ṣe ń ka Bíbélì déédéé tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, tó o bá ń kíyè sí bí ohun tó sọ ṣe rí lára rẹ, tó o sì ń ronú lórí bó o ṣe lè fi ohun tó o kà náà sílò, ò ń jẹ́ kí Jèhófà lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti bá ẹ sọ̀rọ̀ nìyẹn. Èyí á sì jẹ́ kí o ní àjọṣe tó túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.—Héb. 4:12; Ják. 1:23-25.

5 Bí àpẹẹrẹ, ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé, “ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé,” kó o sì ṣàṣàrò lé e lórí. Tí ọkàn ẹ bá balẹ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run lo fi sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ, o máa mọ̀ ọ́n lára pé inú Jèhófà dùn sí ẹ. Ṣùgbọ́n tó o bá wá rí i pé ó yẹ kó o jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ ẹ lọ́rùn kó o sì máa lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a jẹ́ pé Jèhófà ti jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kí o ṣe kó o lè túbọ̀ sún mọ́ òun.—Mát. 6:19, 20.

6, 7. (a) Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kó sì nífẹ̀ẹ́ wa? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ àfojúsùn wa tá a bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́?

6 Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ó máa  jẹ́ ká mọ bí àjọṣe àwa àti Jèhófà ṣe lè túbọ̀ dán mọ́rán. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa jẹ́ ká mọyì ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà gbà ń ṣe nǹkan, ká sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ṣe ń jinlẹ̀ sí i ni Ọlọ́run á túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ wa, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ á sì máa lágbára sí i.—Ka 1 Kọ́ríńtì 8:3.

7 Ká bàa lè sún mọ́ Jèhófà, ó yẹ kí ìdí tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ tọ̀nà. Jòhánù 17:3 sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” Ọ̀pọ̀ nǹkan tó gbádùn mọ́ni la lè kọ́ tá a bá ń ka Bíbélì, àmọ́ ohun tó yẹ ká fi ṣe àfojúsùn wa ni bá a ṣe máa mọ Jèhófà.—Ka Ẹ́kísódù 33:13; Sm. 25:4.

8. (a) Kí nìdí tí ohun tí Jèhófà ṣe fún Asaráyà Ọba bó ṣe wà nínú 2 Àwọn Ọba 15:1-5 fi lè kọni lóminú? (b) Báwo ló ṣe jẹ́ pé tá a bá mọ Jèhófà a kò ní máa ṣiyèméjì nípa ìdí tó fi ṣe ohun tó bá ṣe?

8 Tá a bá ti wá mọ Jèhófà dáadáa, kò ní yà wá lẹ́nu púpọ̀ tá a bá ka àwọn ìtàn kan nínú Bíbélì tá ò sì mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe ohun tó ṣe. Bí àpẹẹrẹ, báwo ni ohun tí Jèhófà ṣe fún Asaráyà Ọba Júdà ṣe rí lára rẹ? (2 Ọba 15:1-5) Kíyè sí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé “àwọn ènìyàn ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń rú èéfín ẹbọ lórí àwọn ibi gíga,” Asaráyà ní tiẹ̀ “ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó dúró ṣánṣán ní ojú Jèhófà.” Síbẹ̀, “Jèhófà fi àrùn kọlu ọba, ó sì ń bá a lọ ní jíjẹ́ adẹ́tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.” Kí nìdí? Ẹsẹ Bíbélì yẹn kò sọ fún wa. Ṣé ó wá yẹ kí àkọsílẹ̀ náà máa kọ wá lóminú tàbí kó mú ká máa ronú pé Jèhófà fìyà jẹ Asaráyà láìnídìí? A ò ní rò bẹ́ẹ̀ tá a bá mọ Jèhófà dunjú. Torí tá a bá mọ Jèhófà dáadáa àá fi sọ́kàn pé gbogbo ìgbà tó bá ń báni wí ló máa ń jẹ́ “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Jer. 30:11) Èyí ló máa jẹ́ ká gbà pé bá ò bá tiẹ̀ mọ ìdí tó fi fìyà jẹ Asaráyà, ohun tí Jèhófà ṣe bá ìdájọ́ òdodo mu.

9. Báwo la ṣe wá mọ ìdí tí Jèhófà ṣe fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọ lu Asaráyà?

9 Nínú ọ̀ràn ti Asaráyà, a rí ìsọfúnni síwájú sí i níbòmíì nínú Bíbélì. Asaráyà Ọba náà ni Ùsáyà Ọba. (2 Ọba 15:7, 32) Níbòmíì tá a ti rí ìtàn yìí nínú Bíbélì, ìyẹn nínú 2 Kíróníkà 26:3-5, 16-21, a rí i pé Ùsáyà ṣe ohun tó dára lójú Jèhófà fún àwọn àkókò kan, àmọ́ nígbà tó yá “ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera àní títí dé àyè tí ń fa ìparun.” Ìkùgbù mú kó gbìyànjú láti ṣe iṣẹ́ àlùfáà tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí. Àwọn àlùfáà mọ́kànlélọ́gọ́rin [81] ló lọ bá a tí wọ́n sì gbìyànjú láti tún èrò rẹ̀ ṣe. Kí ni Ùsáyà ṣe? Ohun tó ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbéraga ti wọ̀ ọ́ lẹ́wù. Ńṣe ló “kún fún ìhónú” sí àwọn àlùfáà náà. Abájọ tí Jèhófà ṣe fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú!

10. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi gbogbo ìgbà retí pé kí Jèhófà ṣàlàyé ìdí tí òun fi ṣe nǹkan kan fún wa, báwo la sì ṣe lè túbọ̀ ní ìgbàgbọ́ pé ọ̀nà òdodo ni Jèhófà gbà ń ṣe nǹkan?

10 Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé ohun pàtàkì tó yẹ ká fi sọ́kàn. Kí lo máa ṣe ká sọ pé kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìtàn kan ò sí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bó ṣe rí nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú Bíbélì? Ṣé o kò ní máa rò pé ohun tí Ọlọ́run ṣe kò bá ìdájọ́ òdodo mu? Àbí wàá gbà pé ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì ti tó láti fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tí ó tọ́, àti pé, Òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́? (Diu. 32:4) Bá a ṣe ń mọ Jèhófà sí i tó sì jẹ́ ẹni gidi sí wa, a máa túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ a sì máa mọrírì ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan gan-an débi pé a kò ní nílò àlàyé fún gbogbo ohun tó bá ṣe. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tó o bá ń sapá láti  kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run fi ń bá ẹ sọ̀rọ̀ tó o sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, wàá túbọ̀ máa mọyì Jèhófà sí i. (Sm. 77:12, 13) Èyí sì máa mú kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ dán mọ́rán, kó sì jẹ́ ẹni gidi sí ẹ.

MÁA BÁ JÈHÓFÀ SỌ̀RỌ̀ NÍNÚ ÀDÚRÀ

11-13. Báwo lo ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

11 Àdúrà máa ń jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà. Tá a bá ń gbàdúrà, a máa ń yin Ọlọ́run, a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, a sì máa ń wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀. (Sm. 32:8) Àmọ́ kó o tó lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé ó ń gbọ́ àdúrà rẹ.

12 Àwọn míì gbà gbọ́ pé oògùn amáratuni lásán ni àdúrà. Wọ́n máa ń sọ pé tó o bá rò pé Ọlọ́run dáhùn àdúrà rẹ, ìdí tó o fi rò bẹ́ẹ̀ ni pé o sọ èrò rẹ jáde, ìyẹn jẹ́ kó o mọ ìṣòro tó o ní, ìwọ fúnra ẹ sì wá ojútùú sí ìṣòro náà. Yàtọ̀ sí pé àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́ lọ́nà yìí, báwo lo ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà tó o fi òótọ́ inú gbà?

13 Rò ó wò ná: Kí Jésù tó wá sáyé, ó ti máa ń kíyè sí bí Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà àwọn èèyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àdúrà ló fi ń bá Baba rẹ̀ ọ̀run sọ̀rọ̀. Ká sọ pé Jèhófà kì í gbọ́ àdúrà ni, ǹjẹ́ Jésù máa gbàdúrà sí i rárá, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé ó tún lo gbogbo òru ọjọ́ kan láti gbàdúrà sí i? (Lúùkù 6:12; 22:40-46) Ǹjẹ́ ó máa kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà ká sọ pé oògùn amáratuni lásán ni àdúrà jẹ́? Ó ṣe kedere pé Jésù mọ̀ pé Jèhófà là ń bá sọ̀rọ̀ tá a bá ń gbàdúrà. Nígbà kan Jésù sọ pé: “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi. Lóòótọ́, èmi mọ̀ pé ìwọ ń gbọ́ tèmi nígbà gbogbo.” Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà ni “Olùgbọ́ àdúrà.”—Jòh. 11:41, 42; Sm. 65:2.

14, 15. (a) Àǹfààní wo la máa rí tí àdúrà wa bá ṣe pàtó? (b) Báwo ni àdúrà tí arábìnrin kan gbà ṣe mú kí àjọṣe òun àti Jèhófà túbọ̀ dán mọ́rán?

14 Tí àdúrà rẹ bá ṣe pàtó, ìdáhùn Jèhófà sí àdúrà rẹ á ṣe kedere sí ẹ, kódà bí kò tiẹ̀ hàn sójú táyé. Bí o bá sì ṣe ń rí i tí Jèhófà ń dáhùn àdúrà rẹ ni á túbọ̀ máa jẹ́ ẹni gidi sí ẹ. Bákan náà, bí o ṣe  túbọ̀ ń sọ ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn fún Jèhófà, á máa sún mọ́ ẹ sí i.

15 Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Kathy. * Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń jáde òde ẹ̀rí déédéé, kì í gbádùn ẹ̀. Ó sọ pé: “Kì í wù mí láti lọ sóde ẹ̀rí, kódà mi ò nífẹ̀ẹ́ sí i rárá. Nígbà tí mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, alàgbà kan sọ pé ó yẹ kí n bẹ̀rẹ̀ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, kódà ó fún mi ní ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Mo pinnu láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà lójoojúmọ́ pé kí Jèhófà jẹ́ kí òde ẹ̀rí máa wù mí.” Ǹjẹ́ Jèhófà dáhùn àdúrà arábìnrin yìí? Ó sọ pé: “Ọdún kẹta rèé tí mo ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nítorí pé mo ti wá ń lo àkókò púpọ̀ sí i lóde ẹ̀rí, tí mo sì ń kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn arábìnrin míì, ọ̀nà tí mo gbà ń wàásù ti wá sunwọ̀n sí i. Ní báyìí, kì í ṣe pé ó ń mí nìkan, mo tún nífẹ̀ẹ́ láti máa lọ sóde ẹ̀rí. Yàtọ̀ síyẹn, mo ti wá sún mọ́ Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Kò sí àní-àní pé, àdúrà tí Kathy gbà ràn án lọ́wọ́ láti mú kí àjọṣe òun àti Jèhófà dán mọ́rán sí i.

Ẹ JẸ́ KÁ ṢE IPA TIWA

16, 17. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tí àjọṣe àwa àti Jèhófà ò fi ní jó rẹ̀yìn tí á sì máa dán mọ́rán sí i? (b) Ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e?

16 Gbogbo ọjọ́ ayé wa ló yẹ ká máa sapá láti mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i. Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run sún mọ́ wa, a gbọ́dọ̀ máa sapá láti sún mọ́ ọn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá Ọlọ́run wa sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo nípa gbígbàdúrà sí i, ká sì máa tẹ́tí sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àjọṣe àwa àti Jèhófà á máa lágbára sí i, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè kojú àwọn ìṣòro wa.

Gbogbo ọjọ́ ayé wa ló yẹ ká máa sapá láti mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i (Wo ìpínrọ̀ 16 àti 17)

17 Ṣùgbọ́n tá a bá ń gbàdúrà kíkankíkan nípa àwọn ìṣòro kan síbẹ̀ tí a kò rí ojútùú sí i, èyí lè fẹ́ ṣàkóbá fún àjọṣe àwa àti Jèhófà. Ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, ó lè ṣòro fún wa láti fọkàn tán Jèhófà. A lè rò pé Jèhófà kò gbọ́ àdúrà wa tàbí pé kò ní àjọṣe kankan pẹ̀lú wa. Báwo la ṣe lè bójú tó irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé a ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 2 Tá a bá sọ pé ẹni méjì ní àjọṣe, ohun tá à ń sọ ni ọwọ́ táwọn méjèèjì fi mú ara wọn àti bí wọ́n ṣe ń hùwà síra wọn. Àwọn méjèèjì lọ̀rọ̀ náà kàn.

^ ìpínrọ̀ 15 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.