Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  April 2015

Se Igi Ti Won Ge Lule Tun Le Hu Pa Da?

Se Igi Ti Won Ge Lule Tun Le Hu Pa Da?

IGI ólífì tára rẹ̀ rí ṣágiṣàgi, tó sì lọ́ mọ́ra bìrìpà lè má dùn ún wò tá a bá fi wé igi kédárì ti Lẹ́bánónì. Àmọ́ igi ólífì rọ́kú, kò sí ojú ọjọ́ tí kò bá a lára mu, àtìgbà òjò àtìgbà ẹ̀rùn. A gbọ́ pé àwọn míì ti lo ẹgbẹ̀rún ọdún kan. Gbòǹgbò igi ólífì máa ń ta gan-an, ó sì máa ń rinlẹ̀, ìyẹn máa ń jẹ́ kó tún lè sọjí bí wọ́n tiẹ̀ gé ìtì rẹ̀ lulẹ̀. Tí gbòǹgbò ẹ̀ ò bá ṣáà ti kú, ó máa hù pa dà.

Jóòbù baba ńlá ìgbàanì gbà gbọ́ dájú pé bí òun bá tiẹ̀ kú, òun ṣì máa pa dà wà láàyè. (Jóòbù 14:13-15) Ó fi ọ̀rọ̀ igi ṣàpèjúwe bó ṣe dá òun lójú tó pé Ọlọ́run máa jí òun dìde, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé igi ólífì ló ní lọ́kàn. Jóòbù sọ pé: “Ìrètí wà fún igi pàápàá. Bí a bá gé e lulẹ̀, àní yóò tún hù.” Nígbà tí òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ lẹ́yìn tí ọ̀dá ti mú kí gbogbo nǹkan gbẹ táútáú, kùkùté igi ólífì tó ti gbẹ lè sọjí pa dà, á bẹ̀rẹ̀ sí í yọ “ẹ̀tun bí ọ̀gbìn tuntun.”—Jóòbù 14:7-9.

Bí àgbẹ̀ ṣe máa ń retí ìgbà tí gbòǹgbò igi ólífì tí wọ́n gé lulẹ̀ máa sọjí pa dà, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe ń retí ìgbà tó máa jí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì tó ti kú dìde kí wọ́n lè wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. (Mát. 22:31, 32; Jòh. 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ náà máa jẹ́ nígbà tá a bá tún rí àwọn tó ti kú, tí wọ́n sì ń gbádùn ayé wọn lẹ́ẹ̀kan sí i!