Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  April 2015

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Gba Opo Ibukun Ni “Asiko Ti O Rogbo ati Ni Asiko Ti O Kun Fun Idaamu”

Mo Gba Opo Ibukun Ni “Asiko Ti O Rogbo ati Ni Asiko Ti O Kun Fun Idaamu”

ÀÁRÍN àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn ni wọ́n bí mi sí ní March, ọdún 1930. Abúlé tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Namkumba ni wọ́n bí mi sí, kò jìnnà sí ìlú Lilongwe ní orílẹ̀-èdè tá a mọ̀ sí Màláwì báyìí. Lọ́dún 1942, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run, mo sì ṣèrìbọmi nínú ọ̀kan lára àwọn odò tó rẹwà lórílẹ̀-èdè wa. Látìgbà tí mo ti ṣèrìbọmi, ó ti ju àádọ́rin ọdún lọ tí mo ti ń sapá láti ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó ṣe, ó ní “wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.”—2 Tím. 4:2.

Àbẹ̀wò tí Arákùnrin Nathan H. Knorr àti Milton G. Henschel ṣe sí orílẹ̀-èdè Màláwì ní ọdún 1948 ló mú kí iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí. Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tá a gbọ́ látẹnu àwọn arákùnrin yẹn, tí wọ́n wá láti orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York. Àwa bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ló dúró lórí pápá ẹlẹ́rẹ̀ kan tá a fara balẹ̀ gbọ́ àsọyé alárinrin tí Arákùnrin Knorr sọ. Àsọyé náà dá lórí alákòóso tó máa jẹ títí láé lórí gbogbo ayé, àkòrí rẹ̀ ni, “Permanent Governor of All Nations.”

Mo pàdé arábìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lidasi, èèyàn dáadáa ni, èmi àti ẹ̀ sì láwọn ibi kan tọ́rọ̀ wa ti jọra. Bí àpẹẹrẹ, Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ìdílé rẹ̀, ó sì wu òun náà láti wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Torí náà, lọ́dún 1950, a ṣègbéyàwó, nígbà tó sì fi máa di ọdún 1953, a ti lọ́mọ méjì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ wa ti pọ̀ sí i torí pé a ní láti bójú tó àwọn ọmọ wa, síbẹ̀, a pinnu pé èmi lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, mo rí ìkésíni pé kí n di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo láǹfààní láti di alábòójútó àyíká, mo sì ń bẹ àwọn ìjọ wò. Torí pé ìyàwó mi fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú mi, mo lè pèsè ohun táwọn ìdílé mi nílò nípa tara àti tẹ̀mí, ìyẹn kò sì dí iṣẹ́ ìsìn mi lọ́wọ́. * Àmọ́ ohun tó wù wá gan-an ni pé káwa méjèèjì jọ wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Torí náà, a fara balẹ̀ ṣètò bí èyí á ṣe ṣeé ṣe, àwọn ọmọ wa sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa, èyí jẹ́ kí ìyàwó mi lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní ọdún 1960.

Àwọn àpéjọ fún wa lókun ká lè fara da inúnibíni tó ń bọ̀ níwájú

A gbádùn bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ sin àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní onírúurú ìjọ, àkókò alárinrin ni wọ́n jẹ́ fún wa. Iṣẹ́ wa gbé wá dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn òkè rírẹwà Mulanje tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Màláwì títí lọ dé àwọn agbami tó pa lọ́lọ́ tí wọ́n ń pè ní Lake Malawi, èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣàn láti ìbẹ̀rẹ̀  ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà títí dé ìparí rẹ̀. A ń rí bí iye àwọn akéde àti ìjọ ní àyíká tá a ti ń sìn ṣe ń pọ̀ sí i ṣáá.

Lọ́dún 1962, a ṣe ìpàdé àgbègbè tí àkọlé rẹ̀ dá lórí báwọn òjíṣẹ́ ṣe gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà, ìyẹn “Courageous Ministers.” A pa dà wá rí i pé irú àpéjọ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwa ará lórílẹ̀-èdè Màláwì nílò kó lè múra wa sílẹ̀ de àwọn àkókò tó nira tó ń bọ̀ níwájú. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Arákùnrin Henschel ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Màláwì lẹ́ẹ̀kan sí i, a sì ṣe àkànṣe ìpàdé àgbègbè ní ẹ̀yìn odi ìlú Blantyre. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ló pésẹ̀ síbẹ̀. Àpéjọ yẹn fún wa níṣìírí gan-an, ó sì fún wa lókun ká lè fara da àdánwò tó ń bọ̀.

ÀWỌN ÀKÓKÒ TÓ KÚN FÚN ÌDÀÀMÚ DÉ

Wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa, ìjọba sì gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì

Lọ́dún 1964, wọ́n ṣe inúnibíni tó le koko sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ sọ́rọ̀ òṣèlú. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] àti ilé àwọn ará tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan [1,000] ni wọ́n bàjẹ́ nígbà inúnibíni náà. Àmọ́, à ń ba iṣẹ́ arìnrìn-àjò wa nìṣó títí dìgbà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Màláwì fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1967. Wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nílùú Blantyre, wọ́n lé àwọn míṣọ́nnárì pa dà sí orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n sì ju ọ̀pọ̀ àwọn ará títí kan èmi àti ìyàwó mi sẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn tí wọ́n dá wa sílẹ̀, à ń fọgbọ́n bá iṣẹ́ arìnrìn-àjò nìṣó.

Lọ́jọ́ kan lóṣù October, ọdún 1972, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọmọ Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ ní Màláwì ń ṣígun bọ̀ wá sílé wa. Àmọ́, ọmọ ẹgbẹ́ wọn kan sáré wá sọ fún mi pé kí n yáa sá pamọ́ torí ṣe ni wọ́n fẹ́ pa mí. Mo sọ fún ìyàwó àtàwọn ọmọ mi pé kí wọ́n sá pa mọ́ sáàárín àwọn igi ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó wà nítòsí ilé wa. Èmi wá sáré lọ gun orí igi máńgòrò ńlá kan. Láti orí igi náà ni mo ti ń wo bí wọ́n ṣe ń run ilé wa àti gbogbo nǹkan ìní wa.

Torí pé àwọn ará wa ò bá wọn lọ́wọ́ sí òṣèlú, wọ́n dáná sun ilé wọn

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará la sá kúrò lórílẹ̀-èdè Màláwì torí ṣe ni inúnibíni náà ń gbóná sí i. Ìdílé wa dúró sí àgọ́ tí wọ́n ń kó àwọn tí ogun lé wá láti orílẹ̀-èdè míì sí ní apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Mozambique, a sì wà níbẹ̀ títí di oṣù June, ọdún 1974. Ìgbà yẹn ni ètò Ọlọ́run sọ pé kí èmi àti ìyàwó mi lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Dómue, tó wà ní orílẹ̀-èdè Mozambique, ní ìtòsí ẹnubodè orílẹ̀-èdè Màláwì. À ń bá iṣẹ́ náà nìṣó títí di ọdún 1975, nígbà tí orílẹ̀-èdè Mozambique gbòmìnira lábẹ́ orílẹ̀-èdè Potogí. Ó wá di dandan fún àwa àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kù láti pa dà sọ́dọ̀ àwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa ní orílẹ̀-èdè Màláwì.

Lẹ́yìn tá a pa dà sí orílẹ̀-èdè Màláwì, ètò Ọlọ́run ní ká máa ṣe ìbẹ̀wò sáwọn ìjọ tó wà ní ìlú Lilongwe tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Màláwì. Láìka inúnibíni àti bí nǹkan ṣe nira gan-an lákòókò yẹn, ìjọ túbọ̀ ń pọ̀ sí i láwọn àyíká tá a ti sìn.

A RỌ́WỌ́ ÌTÌLẸ́YÌN JÈHÓFÀ

Ó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan pé a dé abúlé kan tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé ìṣèlú lọ́wọ́, àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ̀  òṣèlú náà mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, wọ́n sì fipá mú ká jókòó sáàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Aṣíwájú Ọ̀dọ́ nílẹ̀ Màláwì. A gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, kó sì kọ́ wa mọ̀ ọ́n ṣe lójú ipò tó le koko yìí. Nígbà tí wọ́n parí ìpàdé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í nà wá. Ìyá àgbàlagbà kan sáré wá, ó sì ń pariwo pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi wọ́n sílẹ̀! Ọmọ ẹ̀gbọ́n mi ni ọkùnrin yìí. Ẹ jẹ́ kó máa lọ!” Ẹni tó jẹ́ olórí ìpàdé tí wọ́n ń ṣe náà sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa lọ!” A ò mọ ìdí tí ìyá náà fi ṣe bẹ́ẹ̀ torí kì í ṣe ẹbí wa rárá. Ohun tá a mọ̀ ni pé Jèhófà ló dáhùn àdúrà wa.

Káàdì ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú

Lọ́dún 1981, a tún kó sọ́wọ́ ẹgbẹ́ àwọn Aṣíwájú Ọ̀dọ́ nílẹ̀ Màláwì. Wọ́n gba àwọn kẹ̀kẹ́ wa, ẹrù, àwọn páálí ìwé wa àtàwọn fáìlì àyíká. A sá mọ́ wọn lọ́wọ́, a sì sá lọ sílé alàgbà kan. A tún gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀. Ohun tó ń ká wa lára ni gbogbo ìsọfúnni tó wà nínú àwọn fáìlì tí wọ́n gbà lọ́wọ́ wa. Nígbà táwọn ẹgbẹ́ Aṣíwájú Ọ̀dọ́ nílẹ̀ Màláwì wo àwọn fáìlì náà, wọ́n rí àwọn lẹ́tà tí wọ́n kọ sí mi láti onírúurú ìlú lórílẹ̀-èdè Màláwì. Èyí bà wọ́n lẹ́rù gan-an, torí wọ́n rò pé òṣìṣẹ́ ìjọba ni mí. Torí náà, wọ́n dá gbogbo ẹrú wa pa dà sọ́dọ̀ àwọn alàgbà tó wà ládùúgbò, wọ́n kò yọ ohunkóhun níbẹ̀.

Ó tún ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé, a wọ ọkọ̀ ojú omi ká lè sọdá odò kan. Alága ẹgbẹ́ òṣèlú kan ló ni ọkọ̀ ojú omi náà, torí náà, ó sọ pé òun fẹ́ rí káàdì ẹgbẹ́ òṣèlú gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà. Bó ṣe ku díẹ̀ kó dé ọ̀dọ̀ wa, ó rí olè kan táwọn aláṣẹ ti ń wá. Èyí dá arukutu sílẹ̀, bí wọn ò ṣe lè wo káàdì kankan mọ́ nìyẹn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a tún rọ́wọ́ ìtìlẹ́yìn Jèhófà.

WỌ́N MÚ MI, WỌ́N SÌ JÙ MÍ SẸ́WỌ̀N

Ní oṣù February, ọdún 1984, mò ń lọ sí ìlú Lilongwe kí n lè fi àwọn ìròyìn wa ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní orílẹ̀-èdè Sáńbíà. Ọlọ́pàá kan dá mi dúró, ó sì tú àpò mi. Ó rí àwọn ìtẹ̀jáde kan níbẹ̀, ló bá mú mi lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lù mí. Ó fokùn dé mí, ó sì jù mí sínú yàrá kan pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ká ẹrù olè mọ́ lọ́wọ́.

Lọ́jọ́ kejì, ọ̀gá ọlọ́pàá mú mi lọ sí yàrá míì, ó sì kọ ọ̀rọ̀ kan sínú ìwé kan pé: “Èmi, Trophim R. Nsomba, kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, kí n bàa lè máa lọ lómìnira.” Mo dáhùn pé: “Mo fara mọ́ ọn kẹ́ ẹ dè mí, kódà kẹ́ ẹ tiẹ̀ pa mí pàápàá. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí dọ̀la.” Mo kọ̀ jálẹ̀ láti buwọ́ lu ìwé náà. Èyí bí ọ̀gá ọlọ́pàá náà nínú gan-an, ó sì fìbínú gbá tábìlì kíkankíkan débi pé ọlọ́pàá tó wà ní yàrá kejì sáré wa kó lè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Ọ̀gá ọlọ́pàá náà sọ fún un pé: “Ọkùnrin yìí kọ̀ láti tọwọ́ bọ̀wé pé òun ò ṣe ajẹ́rìí mọ́. Jẹ́ kó tọwọ́ bọ̀wé pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóun, àá sì rán an lọ sílùú Lilongwe, kí wọ́n lè dé e mọ́lẹ̀ síbẹ̀.” Ní gbogbo àsìkò yìí, ìyàwó mi ti ń retí mi, kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin, àwọn arákùnrin kan sọ ibi tí mo wà fún un.

Wọ́n ṣe mí jẹ́jẹ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá tó wà nílùú Lilongwe. Ọ̀gá ọlọ́pàá sọ pé: “Gba ìrẹsì yìí kó o jẹ́ nítorí pé torí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ṣe fokùn dè ẹ́.  Olè làwọn tó kù tó wà níbi.” Lẹ́yìn náà, ó rán mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ń pè ní Kachere, mo sì wà níbẹ̀ fún oṣù márùn-ún.

Inú ọ̀gá wọ́dà náà dùn gan-an; ó fẹ́ kí n di “pásítọ̀” ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ó yọ pásítọ̀ tó wà níbẹ̀ kúrò, ó sì sọ fún un pé: “Mi ò fẹ́ kó o kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níbí mọ́, torí pé o kó owó ṣọ́ọ̀ṣì jẹ ni wọ́n ṣe jù ẹ́ sẹ́wọ̀n!” Torí náà, mo láǹfààní láti máa kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní Bíbélì níbi ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí wọ́n máa ń ṣe.

Nígbà tó yá, nǹkan burú sí i. Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò kí wọ́n lè mọ iye Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Màláwì. Nígbà tí mi ò fún wọn ní ìdáhùn tí wọ́n fẹ́, wọ́n lù mí títí mo fi dákú. Wọ́n tún pè mí lọ́jọ́ míì, lọ́tẹ̀ yìí wọ́n fẹ́ mọ ibi tí orílé-iṣẹ́ wa wà. Mo sọ fún wọn pé, “Ìbéèrè tó rọrùn lẹ bí mi yìí, màá sì sọ fún yín.” Inú àwọn ọlọ́pàá náà dùn, wọ́n sì tan ẹ̀rọ tí wọ́n fẹ́ fi gba ohùn mi sílẹ̀. Mo sọ fún wọn pé Bíbélì ṣàlàyé ibi tó jẹ́ orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an, wọ́n sì bi mí pé, “Níbo ló wà nínú Bíbélì?”

Mo dá wọn lóhùn pé ó wà nínú Aísáyà 43:12. Wọ́n ṣí Bíbélì, wọ́n sì fara balẹ̀ kà á: “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘èmi sì ni Ọlọ́run.’” Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ka ẹsẹ Bíbélì yẹn. Wọ́n wá bi mí pé: “Báwo ni orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lè wà nínú Bíbélì tí kò sí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà?” Mo sọ fún wọn pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà náà gbà pé ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ibi tí orílé-iṣẹ́ wọn wà.” Torí wọ́n rí i pé mi ò ní sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́ fún wọn, wọ́n gbé mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n míì tó ń jẹ́ Dzaleka Prison, tó wà ní apá àríwá ìlú Lilongwe.

A RÍ ÌBÙKÚN KÓDÀ LÁKÒÓKÒ TÓ KÚN FÚN ÌDÀÀMÚ

Lóṣù July, ọdún 1984, mo dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́kànlélọ́gọ́rin [81] tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Dzaleka. Ní ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí, ọ̀ọ́dúnrún [300] àwọn ẹlẹ́wọ̀n ni wọ́n kó pọ̀ sójú kan, ńṣe ni wọ́n máa ń fún ara wọn mọ́ orí ilẹ̀ tí wọ́n máa ń sùn sí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí pín ara wa sí àwùjọ-àwùjọ, tá a ti máa ń jíròrò ẹsẹ ojúmọ́ lójoojúmọ́, ẹnì kan ló sì máa dábàá ẹsẹ tá a máa jíròrò náà. Èyí fún wa níṣìírí gan-an ni.

Nígbà tó yá, ọ̀gá wọ́dà náà kó àwa Ẹlẹ́rìí sójú kan. Ẹ̀ṣọ́ kan sọ fún wa láṣìírí pé: “Ìjọba kò kórìíra yín. Torí ìdí méjì la fi jù yín sọ́gbà ẹ̀wọ̀n: Ìjọba ò fẹ́ káwọn ẹgbẹ́ Aṣáájú Ọ̀dọ́ pa yín, àti torí pé ẹ máa ń wàásù pé ogun kan ń bọ̀, ìjọba ń fòyà pé ẹrù lè bá àwọn ọmọ ogun wọn, kí wọ́n sì sá lọ nígbà ogun náà.”

Wọ́n ń kó àwọn arákùnrin yìí lọ lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ wọn

Ní oṣù October, ọdún 1984, wọ́n kó gbogbo wa lọ sílé ẹjọ́. Wọ́n sì dá ẹ̀wọ̀n ọdún méjì-méjì fún gbogbo wa. Bíi ti tẹ́lẹ̀, àwa àtàwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ni wọ́n kó pọ̀. Àmọ́ ọ̀gá wọ́dà ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kéde fún gbogbo èèyàn pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í mu sìgá. Torí náà, ẹ̀yin ẹ̀ṣọ́, ẹ má ṣe dà wọ́n láàmú pé kí wọ́n fún yín ní sìgá, ẹ má sì rán wọn pé  kí wọ́n lọ mú ẹyin iná wa kẹ́ ẹ lè fi tan sìgá yín. Èèyàn Ọlọ́run ni wọ́n! Ẹ máa fún gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóúnjẹ lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́, torí kì í ṣe ìwà ọ̀daràn ló gbé wọn débi, bí kò ṣe ìgbàgbọ́ wọn nínú Bíbélì.”

Àwọn ọ̀nà míì tún wà tá a ti jọlá orúkọ rere táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní. Wọn kì í gba àwọn ẹlẹ́wọ̀n láyè láti rìn kiri tílẹ̀ bá ti ṣú tàbí tí òjò bá ń rọ̀. Àmọ́ wọ́n gbà wá láyè láti jáde nígbàkigbà tó bá wù wá. Wọ́n mọ̀ pé a ò ní sá lọ. Nígbà kan, ó rẹ ẹ̀ṣọ́ tó dúró tì wá nínú oko tá a ti ń ṣiṣẹ́, a sì gbé e pa dà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kí wọ́n lè tọ́jú rẹ̀. Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà mọ̀ pé èèyàn tó ṣeé fọkàn tán ni wá. Torí pé a jẹ́ kí ìwà wa dára, inú wa dùn pé àwọn tó kó wa sẹ́wọ̀n fi ẹnu wọn fògo fún orúkọ Jèhófà.—1 Pét. 2:12. *

ÀSÌKÓ TÓ RỌGBỌ PA DÀ DÉ

Lóṣù May 11, ọdún 1985, wọ́n dá mi sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Dzaleka. Ayọ̀ mi kún nígbà tí mo tún pa dà wà pẹ̀lú àwọn ìdílé mi! A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó jẹ́ ká lè di ìṣòtítọ́ wa mú láwọn àkókò tó kún fún ìdààmú yẹn. Lákòókò tó le koko yẹn, ó ṣe wá bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Àwa kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀, ẹ̀yin ará, nípa ìpọ́njú tí ó bá wa . . . A kò ní ìdánilójú rárá nípa ìwàláàyè wa pàápàá. Ní ti tòótọ́, a nímọ̀lára nínú ara wa pé a ti gba ìdájọ́ ikú. Èyí jẹ́ kí a má bàa ní ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú ara wa, bí kò ṣe nínú Ọlọ́run ẹni tí ń gbé òkú dìde. Láti inú irúfẹ́ ohun ńlá kan bẹ́ẹ̀ bí ikú ni òun ti gbà wá sílẹ̀.”—2 Kọ́r. 1:8-10.

Arákùnrin Nsomba àti Lidasi, ìyàwó rẹ̀ níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba kan lọ́dún 2004

Ká sòótọ́, láwọn ìgbà míì, ó dà bíi pé ikú lọ̀rọ̀ wa máa já sí. Àmọ́ a máa ń bẹ Jèhófà nígbà gbogbo pé kó fún wa nígboyà àti ọgbọ́n ká lè máa lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ táá jẹ́ ká lè máa mú ògo bá orúkọ ńlá rẹ̀.

A ti rọ́wọ́ ìbùkún Jèhófà lára wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láwọn àkókò tó rọgbọ àtàwọn àkókò tó kún fún ìdààmú. Ní báyìí, ayọ̀ wa kún gan-an lọ́dún 2000, nígbà tí wọ́n parí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ìlú Lilongwe, tí wọ́n sì ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan [1,000] jákèjádò orílẹ̀-èdè Màláwì. Àwọn ìbùkún tá a rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà yìí mú kí ìjọsìn wa sí Jèhófà túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa. Èyí dà bí àlá lójú èmi àti ìyàwó mi! *

^ ìpínrọ̀ 7 Ní báyìí, ètò Ọlọ́run kì í késí àwọn arákùnrin tí wọ́n ṣì lọ́mọ tí kò tíì tójúúbọ́ pé kí wọ́n wá ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká.

^ ìpínrọ̀ 30 Tó o bá fẹ́ ka púpọ̀ sí i nípa inúnibíni tó wáyé lórílẹ̀-èdè Màláwì, lọ ka ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn 1999 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 171 sí 223.

^ ìpínrọ̀ 34 Nígbà tí à ń múra láti tẹ àpilẹ̀kọ yìí jáde, Arákùnrin Nsomba sùn nínú oorun ikú lẹ́ni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83].