Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  April 2015

Eyin Alagba, Nje E Maa N Da Awon Mii Lekoo?

Eyin Alagba, Nje E Maa N Da Awon Mii Lekoo?

“Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.” —ONÍW. 3:1.

1, 2. Kí ni àwọn alábòójútó àyíká ti kíyè sí ní ọ̀pọ̀ ìjọ?

NÍGBÀ tí alábòójútó àyíká kan fẹ́ parí ìpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ kan, inú rẹ̀ dùn gan-an bó ṣe wojú àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára yìí, léyìí tó jẹ́ pé àwọn kan lára wọn tó bí i lọ́mọ. Síbẹ̀, nǹkan kan wà tó fẹ́ kí wọ́n fún láfiyèsí, torí náà ó bi wọ́n pé, “Kí lẹ ti ṣe láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè tẹ́wọ́ gba àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ?” Wọ́n rántí pé nígbà ìbẹ̀wò tí alábòójútó àyíká ṣe kẹ́yìn, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n túbọ̀ máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Alàgbà kan wá sọ pé, “Ká sòótọ́, ohun tá a ṣe kò tó nǹkan.” Àwọn alàgbà tó kù sì gbà pẹ̀lú rẹ̀.

2 Tó o bá jẹ́ alàgbà nínú ìjọ, ohun tó ṣẹlẹ̀ nípàdé àwọn alàgbà yẹn lè ti ṣẹlẹ̀ lójú ìwọ náà rí. Kárí ayé, àwọn alábòójútó àyíká ti kíyè sí i pé ó yẹ kí ọ̀pọ̀ ìjọ ṣe púpọ̀ sí i láti dá àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbàlagbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè bójú tó agbo Ọlọ́run. Lóòótọ́, èyí lè má rọrùn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

3. (a) Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó ṣe pàtàkì ká máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa fún ìjíròrò yìí láfiyèsí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún àwọn alàgbà kan láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́?

 3 Tó o bá jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ, o mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kó o máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. * O mọ̀ pé a nílò àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i kí ìjọ lè máa lágbára nípa tẹ̀mí, kí a sì lè dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀. (Ka Aísáyà 60:22.) O tún mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé kí a “kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” (Ka 2 Tímótì 2:2.) Síbẹ̀, bíi ti àwọn alàgbà tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ó lè má rọrùn fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tó o bá bójú tó ìdílé rẹ, tó o ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tó o ṣe ojúṣe rẹ nínú ìjọ, tó o sì tún bójú tó àwọn ọ̀ràn míì tó jẹ́ kánjúkánjú, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sí àyè láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ ká jíròrò ọwọ́ tó yẹ ká fi mú dídá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́.

ÌDÁLẸ́KỌ̀Ọ́ ṢE PÀTÀKÌ GAN-AN

4. Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ìdí rẹ̀ tí ọ̀pọ̀ fi máa ń fi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ falẹ̀?

4 Kí nìdí tó fi ṣòro fún àwọn alàgbà kan láti wáyè kí wọ́n lè dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́? Àwọn kan lè ronú pé: ‘Ìdálẹ́kọ̀ọ́ ṣe pàtàkì lóòótọ́, àmọ́ àwọn ọ̀ràn míì wà nínú ìjọ tá a gbọ́dọ̀ bójú tó ní kánjúkánjú. Bó bá tiẹ̀ ṣì pẹ́ díẹ̀ kí n tó dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn ò sọ pé kí nǹkan má lọ bó ṣe yẹ nínú ìjọ.’ Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kẹ́ ẹ bójú tó lójú ẹsẹ̀, àmọ́ tẹ́ ẹ bá ń fi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ falẹ̀ ó lè ṣe ìpalára fún ìjọ nípa tẹ̀mí.

5, 6. Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ lára awakọ̀ àti ọwọ́ tó fi mú ṣíṣe àbójútó ọkọ̀ rẹ̀, báwo la sì ṣe lè fi èyí wé bí a ṣe ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ?

5 Ronú nípa àpèjúwe yìí ná: Awakọ̀ kan lè mọ̀ pé tí òun bá fẹ́ kí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ òun àti ẹ́ńjìnnì rẹ̀ máa ṣiṣẹ́ dáadáa, ó ṣe pàtàkì kí òun máa pààrọ̀ ọ́ìlì ọkọ̀ náà látìgbàdégbà. Síbẹ̀, ó lè ronú pé kí òun máa ra epo pẹtiróòlù sọ́kọ̀ náà jẹ́ kánjúkánjú ju kí òun máa pààrọ̀ ọ́ìlì lọ. Ó ṣe tán, tí pẹtiróòlù ò bá sí nínú ọkọ̀ rẹ̀, kò ní pẹ́ tí ọkọ̀ náà fi máa dáṣẹ́ dúró. Awakọ̀ náà lè máa wò ó pé, ‘tí mi ò bá ráyè pààrọ̀ ọ́ìlì náà, ìyẹn ò sọ pé kí ọkọ̀ náà má ṣiṣẹ́, ó kéré tán á ṣì ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀.’ Àmọ́, ewu wo ló wà nínú ohun tí awakọ̀ yìí ń ṣe? Tó bá ń fòní dónìí, fọ̀la dọ́la tó sì kọ̀ láti ṣàyẹ̀wò ọkọ̀ rẹ̀ lásìkò, kò ní pẹ́ tí ọkọ̀ náà á fi bàjẹ́. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó máa ná ọ̀pọ̀ owó, ó sì tún máa gba àkókò láti tún ọkọ̀ náà ṣe kó tó lè máa rìn geerege lẹ́ẹ̀kan sí i. Ẹ̀kọ́ wo ni àpèjúwe yìí kọ́ wa?

6 Àwọn alàgbà ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n gbọ́dọ̀ bójú tó ní kánjúkánjú; torí bí wọn kò bá ṣe é, ó máa pa ìjọ lára gan-an. Bí awakọ̀ inú àpèjúwe yẹn ṣe gbọ́dọ̀ máa fi epo pẹtiróòlù sínú ọkọ̀ rẹ̀, àwọn alàgbà náà gbọ́dọ̀ “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:10) Àmọ́, àwọn iṣẹ́ pàtàkì tó ń fẹ́ àbójútó ní kánjúkánjú máa ń mú kí ọwọ́ àwọn alàgbà kan dí gan-an, ìyẹn ni kì í jẹ́ kí wọ́n ráyè dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Ńṣe nìyẹn sì dà bí ìgbà tí awakọ̀ kan kò pààrọ̀ ọ́ìlì ọkọ̀ rẹ̀. Tí àwọn alàgbà bá ń fòní dónìí fọ̀la dọ́la lórí ọ̀rọ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́, bó pẹ́ bó yá àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n kò ní pọ̀ tó láti bójú tó àwọn iṣẹ́ tó yẹ ká ṣe nínú ìjọ.

7. Ojú wo ló yẹ ká fi wo àwọn alàgbà tó máa ń wáyè láti kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́?

7 A ti wá rí i báyìí pé, kò yẹ kí àwọn alàgbà máa rò pé dídá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́  kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Àwọn alàgbà tó bá ń ronú nípa ohun tó máa ṣe ìjọ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú, tí wọ́n sì ń wáyè láti dá àwọn arákùnrin tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ìríjú, ìbùkún gidi ni wọ́n sì jẹ́ fún gbogbo ìjọ. (Ka 1 Pétérù 4:10.) Báwo lèyí ṣe ń ṣe ìjọ láǹfààní?

OHUN TÓ BỌ́GBỌ́N MU

8. (a) Ànímọ́ wo ló máa mú kí àwọn alàgbà dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Ojúṣe tó jẹ́ kánjúkánjú wo ni àwọn alàgbà tó ń sìn níbi tí àìní pọ̀ sí ní? (Wo àpótí náà “ Iṣẹ́ Tó Pọn Dandan.”)

8 Ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí àwọn alàgbà tó nírìírí gan-an gbà pé bí ara ṣe ń dara àgbà ni iṣẹ́ tí àwọn lè ṣe nínú ìjọ á máa dín kù díẹ̀díẹ̀. (Míkà 6:8) Ó tún yẹ kí wọ́n gbà pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” lè wáyé lójijì, èyí sì lè mú kí wọ́n má lè ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ti ń bójú tó nínú ìjọ tẹ́lẹ̀. (Oníw. 9:11, 12; Ják. 4:13, 14) Àwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn Jèhófà dénú, tí wọ́n sì ń ro ohun tó máa ṣe ìjọ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú, máa ń ṣètò déédéé láti ṣàjọpín ìrírí wọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin tó kéré sí wọn.—Ka Sáàmù 71:17, 18.

9. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tó mú kó ṣe pàtàkì pé ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nísinsìnyí?

9 Kí nìdí tá a tún fi lè sọ pé àwọn alàgbà tó ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ìbùkún fún agbo? Wọ́n ń jẹ́ kí ìjọ túbọ̀ jẹ́ alágbára kí wọ́n lè borí ìdẹwò. Lọ́nà wo? Tí àwọn alàgbà bá ń sapá láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, a máa rí àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i tí wọ́n á lè ran ìjọ lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan nísinsìnyí, àti pàápàá jù lọ lákòókò tí nǹkan bá le koko nígbà ìpọ́njú ńlá. (Ìsík. 38:10-12; Míkà 5:5, 6) Nítorí náà, ẹ̀yin alàgbà wa ọ̀wọ́n, à ń rọ̀ yín pé láti àkókò yìí lọ ẹ máa dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ déédéé bẹ́ ẹ ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín.

10. Kí ni alàgbà kan lè ṣe kó bàa lè ráyè dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́?

10 A mọ̀ pé àkókò tẹ́ ẹ̀ ń lò láti bójú tó àwọn iṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ pọ̀, ó tiẹ̀ lè dà bíi pé ó ń tán yín lókun. Nítorí náà, ó lè pọn dandan pé kí ẹ dín àkókò tí ẹ̀ ń lò fún àwọn nǹkan yẹn kù, kí ẹ lè ráyè dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. (Oníw. 3:1) Tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń pọn omi sílẹ̀ de òùngbẹ.

Ẹ KỌ́KỌ́ JẸ́ KÍ ARA TÙ WỌ́N

11. (a) Kí ló gbàfiyèsí nípa àwọn àbá tí àwọn alàgbà láti oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè mú wa nípa ọ̀nà tá a lè gbà dáni lẹ́kọ̀ọ́? (b) Báwo ni Òwe 15:22 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ṣàfààní tá a bá gbé ohun tí àwọn alàgbà míì dábàá yẹ̀ wò?

11 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà kan nípa ọ̀nà tí wọ́n gbé e gbà tí wọ́n fi dá ọ̀pọ̀ arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ débi tí òtítọ́ fi jinlẹ̀ nínú wọn. * Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí àwọn arákùnrin yìí ń gbé àti ipò wọn yàtọ̀ síra, ó gbàfiyèsí pé ìdáhùn wọn jọra gan-an ni. Kí lèyí kọ́ wa? Ó jẹ́ ká rí i pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a gbé ka Bíbélì máa ń ṣàǹfààní fún àwọn èèyàn “níbi gbogbo nínú gbogbo ìjọ,” bó sì ṣe rí náà nìyẹn nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà láyé. (1 Kọ́r. 4:17) Nítorí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àwọn ohun tí àwọn alàgbà náà dábàá. (Òwe 15:22) Kí àlàyé tá à ń ṣe lè rọrùn, nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì a máa pe àwọn tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ ní “olùkọ́” a sì máa pe àwọn tá à ń dá lẹ́kọ̀ọ́ ní “akẹ́kọ̀ọ́.”

12. Kí ló yẹ kí olùkọ́ ṣe, kí sì nìdí?

12 Olùkọ́ gbọ́dọ̀ mú kí ara tu akẹ́kọ̀ọ́ kí ohun tó ń kọ́ ọ bàa lè wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Bó ṣe jẹ́ pé àgbẹ̀ máa ń kọ́kọ́ túlẹ̀ kó tó gbin irúgbìn sí oko rẹ̀, bákan náà ló ṣe yẹ kí olùkọ́ múra ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ tàbí kó  fún un níṣìírí kó tó kọ́ ọ lóhun tuntun. Ọ̀nà wo wá ni olùkọ́ lè gbà múra ọkàn àwọn míì sílẹ̀ kó tó dá wọn lẹ́kọ̀ọ́? Ọ̀nà tó lè gbà ṣe é ni pé kó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wòlíì ìgbàanì kan. Kí ni wòlíì náà ṣe?

13-15. (a) Iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run gbé fún wòlíì Sámúẹ́lì? (b) Ọ̀nà wo ni Sámúẹ́lì gbà ṣe iṣẹ́ náà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (d) Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn alàgbà lóde òní fún àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí nípa Sámúẹ́lì láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀?

13 Ó ṣẹlẹ̀ pé lọ́jọ́ kan ní nǹkan tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn, Jèhófà sọ fún wòlíì tó ti dàgbà náà, Sámúẹ́lì pé: “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì sí ọ, kí o sì fòróró yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.” (1 Sám. 9:15, 16) Èyí jẹ́ kí Sámúẹ́lì mọ̀ pé iṣẹ́ òun láti máa darí orílẹ̀-èdè náà ti wá sópin àti pé Jèhófà ti gbé iṣẹ́ lé òun lọ́wọ́ láti yan ẹni tó máa rọ́pò òun. Ó ṣeé ṣe kí Sámúẹ́lì máa rò ó pé, ‘Báwo ni màá ṣe mú kí ọkùnrin yìí mọ iṣẹ́ tó gbà?’ Ohun kan wá sí i lọ́kàn, ó sì mọ bí òun ṣe máa ṣe é.

14 Lọ́jọ́ kejì nígbà tí Sámúẹ́lì rí Sọ́ọ̀lù, Jèhófà sọ fún wòlíì náà pé: “Ọkùnrin náà rèé.” Sámúẹ́lì wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Ó ní kí Sọ́ọ̀lù wá jẹun ní gbọ̀ngàn ìjẹun. Ó sì fún Sọ́ọ̀lù àti ẹmẹ̀wà rẹ̀ ní ààyè ìjókòó tó lọ́lá jù lọ àti ekìrí ẹran tó dára jù lọ, Sámúẹ́lì sì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Jẹ ẹ́, nítorí wọ́n ti fi pa mọ́ dè ọ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀.” Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì àti Sọ́ọ̀lù jọ rìn lọ sílé wòlíì náà, wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ. Lẹ́yìn tí Sámúẹ́lì àti Sọ́ọ̀lù ti jẹun dáadáa tí wọ́n sì ti jọ rìnrìn gbẹ̀fẹ́ lọ sílé rẹ̀, ó mọ̀ pé ara ti tu Sọ́ọ̀lù ó sì fẹ́ lo àkókò náà lọ́nà rere. Torí náà, ó ní kí Sọ́ọ̀lù jẹ́ káwọn lọ sórí ilé. Bí atẹ́gùn ọwọ́ alẹ́ ṣe ń fẹ́ yẹ́ẹ́ sí wọn lára, Sámúẹ́lì “ń bá a lọ ní bíbá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ní orí ilé” títí wọ́n fi lọ sùn. Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, Sámúẹ́lì fòróró yan Sọ́ọ̀lù, ó fẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì tún fún un ní ìtọ́ni síwájú sí i. Lẹ́yìn tó ti múra Sọ́ọ̀lù sílẹ̀ fún àwọn ohun tó máa wáyé láìpẹ́, ó ní kó máa lọ.—1 Sám. 9:17-27; 10:1.

15 Àmọ́, ìyàtọ̀ wà nínú kí wọ́n fòróró yan ọkùnrin kan láti di olórí orílẹ̀-èdè kan àti fífún arákùnrin kan ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ kó lè di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Síbẹ̀, àwọn alàgbà lóde òní lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú ohun tí Sámúẹ́lì ṣe. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí méjì nínú rẹ̀.

OLÙKỌ́ TÓ ṢE TÁN LÁTI KỌ́NI TÓ SÌ TÚN JẸ́ Ọ̀RẸ́ TÒÓTỌ́

16. (a) Báwo ló ṣe rí lára Sámúẹ́lì nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sọ pé àwọn fẹ́ ọba? (b) Ọwọ́ wo ni Sámúẹ́lì fi mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un pé kó fòróró yan Sọ́ọ̀lù?

16 Múra tán láti kọ́ àwọn ẹlòmíì, má ṣe lọ́ tìkọ̀. Nígbà tí Sámúẹ́lì kọ́kọ́ gbọ́ pé àwọn èèyàn Ísírẹ́lì fẹ́ kí ẹnì kan máa jọba lé wọn lórí, ó ṣe é bíi pé àwọn èèyàn òun já òun kulẹ̀, wọn ò sì fẹ́ kí òun máa darí wọn mọ́. (1 Sám. 8:4-8) Kódà, ó lọ́ tìkọ̀ láti ṣe ohun táwọn èèyàn náà fẹ́ débi pé ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ fún un pé kó ṣe ohun táwọn èèyàn náà ń sọ. (1 Sám. 8:7, 9, 22) Síbẹ̀, Sámúẹ́lì ò di ọkùnrin tó máa gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ sínú tàbí kó kórìíra rẹ̀. Nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé kó fòróró yan Sọ́ọ̀lù, wòlíì náà ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé ó kàn gbà bẹ́ẹ̀ torí pé ó di dandan, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ló mú kó múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀.

17. Báwo làwọn alàgbà lónìí ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì, àǹfààní wo nìyẹn sì máa ń ṣe fún wọn?

17 Lónìí, àwọn alàgbà tó jẹ́ onírìírí máa ń fi ìfẹ́ dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ bíi ti Sámúẹ́lì. (1 Pét. 5:2) Irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ kì í fà sẹ́yìn láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ torí ìbẹ̀rù pé àwọn tí wọ́n bá dá lẹ́kọ̀ọ́ máa gba àwọn iṣẹ́ kan tí wọ́n ń bójú tó nínú ìjọ mọ́ wọn lọ́wọ́. Àwọn olùkọ́ tó lọ́kàn tó dáa máa ń gbà pé àwọn tó múra tán  láti kẹ́kọ̀ọ́ kì í ṣe abánidíje, àmọ́ wọ́n jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀,” wọ́n sì jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye fún ìjọ. (2 Kọ́r. 1:24; Héb. 13:16) Ẹ wo bí inú àwọn olùkọ́ tí kò mọ tara wọn nìkan yìí ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá ń kíyè sí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń lo ẹ̀bùn tí wọ́n ní lọ́nà tó máa ṣe ìjọ láǹfààní!—Ìṣe 20:35.

18, 19. Báwo ni alàgbà kan ṣe lè múra ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, kí sì nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì?

18 Má ṣe jẹ́ olùkọ́ nìkan, di ọ̀rẹ́ wọn. Ní ọjọ́ tí Sámúẹ́lì pàdé Sọ́ọ̀lù, wòlíì náà lè mú ṣágo òróró, kó sì yára tú u sórí Sọ́ọ̀lù, lẹ́yìn náà kó ní kí ọba tuntun náà máa lọ. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, Sọ́ọ̀lù á di ọba lóòótọ́, àmọ́ kò ní mọ iṣẹ́ tó gbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Sámúẹ́lì fara balẹ̀ múra ọkàn Sọ́ọ̀lù sílẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ aládùn, tí wọ́n rìnrìn gbẹ̀fẹ́, tí wọ́n sọ̀rọ̀ dáadáa, tí wọ́n sì sùn di ọjọ́ kejì ni wòlíì náà tó gbà pé àkókò ti tó láti fi òróró yan Sọ́ọ̀lù.

Tí a bá fẹ́ kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ kí á kọ́kọ́ mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́

(Wo ìpínrọ̀ 18 àti 19)

19 Bákan náà lónìí, kí olùkọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ó yẹ kó mú kí ara tu akẹ́kọ̀ọ́ náà kó sì mú un lọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn ìgbésẹ̀ tí alàgbà kan máa gbé kó tó lè di ọ̀rẹ́ ẹni tó fẹ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ máa ń yàtọ̀ láti ibì kan sí ibòmíì, ó máa sinmi lórí ipò kálukú àti àṣà wọn. Síbẹ̀, ibi yòówù kó o máa gbé, tó o bá ń wáyè láti wà pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí alàgbà máa ń mú kí ọwọ́ rẹ dí, ohun tó ò ń sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà ni pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ mí lógún gan-an ni.” (Ka Róòmù 12:10.) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ibi yòówù kó o máa gbé, àwọn tó múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ á mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn, wọ́n á sì mọyì rẹ̀ gan-an.

20, 21. (a) Irú olùkọ́ wo ni o lè sọ pé ó kẹ́sẹ járí? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

20 Ó yẹ kí ẹ̀yin alàgbà rántí pé: Yàtọ̀ sí pé olùkọ́ tó kẹ́sẹ járí máa ń fẹ́ dá ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́, ó tún máa nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń dá lẹ́kọ̀ọ́. (Fi wé Jòhánù 5:20.) Kò ní pẹ́ rárá tí akẹ́kọ̀ọ́ náà á fi rí i pé olùkọ́ náà nífẹ̀ẹ́ òun, èyí sì máa jẹ́ kí ohun tó ń kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Nítorí náà, ẹ̀yin alàgbà, bí ẹ ṣe ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, ẹ má ṣe jẹ́ olùkọ́ nìkan, ẹ di ọ̀rẹ́ wọn.—Òwe 17:17; Jòh. 15:15.

21 Lẹ́yìn tí alàgbà kan bá ti múra ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, ohun tó kàn ni pé kó kọ́ ọ láwọn nǹkan tó yẹ kó mọ̀. Ọ̀nà wo ni alàgbà náà lè gbé e gbà? Èyí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

^ ìpínrọ̀ 3 Àwọn alàgbà ni a dìídì kọ àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e fún, àmọ́ gbogbo wa nínú ìjọ ló yẹ ká fún ohun tá a fẹ́ jíròrò láfiyèsí. Kí nìdí? Ó máa jẹ́ kí gbogbo àwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi mọ̀ pé ó yẹ káwọn gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọn bàa lè ṣèrànwọ́ láti bójú tó iṣẹ́ nínú ìjọ. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí sì máa wá ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní.

^ ìpínrọ̀ 11 Àwọn alàgbà tá a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò wá láti Amẹ́ríkà, Bangladesh, Belgium, Brazil, Faransé, French Guiana, Japan, Kòríà, Mẹ́síkò, Nàìjíríà, Nàmíbíà, Ọsirélíà, Réunion, Rọ́ṣíà àti South Africa.