Tẹ́lẹ̀ rí, àwọn ìtẹ̀jáde wa sábà máa ń sọ pé ẹnì kan, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tàbí ohun kan nínú Bíbélì ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan míì. Àmọ́ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí a kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa wọn. Kí nìdí?

Ohun tí Ilé Ìṣọ́ September 15, 1950 sọ ni pé nígbà míì ẹnì kan, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tàbí ohun kan nínú Bíbélì máa ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan míì tó ṣe pàtàkì jù ú lọ.

Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn ìtẹ̀jáde wa sọ pé àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin olóòótọ́ bíi Dèbórà, Élíhù, Jẹ́fútà, Jóòbù, Ráhábù, Rèbékà, àti ọ̀pọ̀ àwọn míì ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹni àmì òróró tàbí àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá.” (Ìṣí. 7:9) Bí àpẹẹrẹ, a lérò pé Jẹ́fútà, Jóòbù àti Rèbékà ń ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹni àmì òróró, nígbà tí Dèbórà àti Ráhábù dúró fún ogunlọ́gọ̀ ńlá. Àmọ́ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a kò ṣe irú àwọn ìfiwéra bẹ́ẹ̀. Kí nìdí?

ÀPẸẸRẸ

Ọ̀dọ́ àgùntàn ìrékọjá tí wọ́n máa ń fi rúbọ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì jẹ́ àpẹẹrẹ.—Núm. 9:2

ÌMÚṢẸ

Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé Kristi ni ọ̀dọ́ àgùntàn “Ìrékọjá wa.” —1 Kọ́r. 5:7

Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kan àwọn kan nínú Bíbélì tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ ohun míì tó ṣe pàtàkì jù wọ́n lọ. Nínú Gálátíà 4:21-31, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìṣàpẹẹrẹ” kan tí obìnrin méjì kópa níbẹ̀. Nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, Hágárì tó jẹ́ ẹrúbìnrin Ábúráhámù dúró fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, tó jẹ́ pé Òfin Mósè ló mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́, Sárà tó jẹ́ “òmìnira obìnrin,” dúró fún ìyàwó Ọlọ́run, ìyẹn apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Hébérù, ó fi Melikisédékì tó jẹ́ Ọba àti Àlùfáà wé Jésù, ó sì sọ àwọn ohun pàtó tí àwọn méjèèjì fi jọra. (Héb. 6:20; 7:1-3) Síwájú sí i, Pọ́ọ̀lù fi Aísáyà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wé Jésù àti àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Héb. 2:13, 14) Nítorí pé Ọlọ́run ló mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ ohun tí ó kọ, a gbà tọkàntọkàn pé àwọn ohun tó sọ ṣàpẹẹrẹ àwọn ohun tó fi wọ́n wé lóòótọ́.

Àmọ́, níbi tí Bíbélì bá ti sọ pé ẹnì kan ṣàpẹẹrẹ ẹlòmíì, kò yẹ ká parí èrò sí pé gbogbo àlàyé tí Bíbélì ṣe tàbí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí onítọ̀hún ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó túbọ̀ ṣe pàtàkì nígbèésí ayé ẹni táà ń fi wé náà. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé Melikisédékì dúró fún Jésù, àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò sọ nǹkan kan fún wa nípa ìgbà kan tí Melikisédékì mú  búrẹ́dì àti wáìnì wá fún Ábúráhámù láti jẹ nígbà tí ó ṣẹ́gun àwọn ọba mẹ́rin kan. Nítorí náà, kò sí ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu láti máa wá àwọn ìtumọ̀ tó fara sin nínú irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀.—Jẹ́n. 14:1, 18.

Ní ọ̀gọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn ikú Kristi, àwọn òǹkọ̀wé kan gbà gbọ́ pé gbogbo nǹkan tí Bíbélì sọ ló ń ṣàpẹẹrẹ ohun mìíràn. Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The International Standard Bible Encyclopædia ń ṣàlàyé lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí Origen, Ambrose, àti Jerome ṣe agbátẹrù rẹ̀, ó sọ pé: “Wọ́n wá àwọn nǹkan tó ṣàpẹẹrẹ ohun mìíràn nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ àti àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́, àní dórí bíńtín, wọ́n sì rí ohun tí wọ́n ń wá. Kódà wọ́n rò pé òtítọ́ tó fara sin pọ̀ nínú àwọn ohun tí ò já mọ́ nǹkan kan àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wọ́pọ̀ . . . , débi pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ti sọ nípa bó ṣe jẹ́ pé ẹja mẹ́tàléláàádọ́jọ [153] ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pa ní alẹ́ tí Olùgbàlà tá a ti jí dìde fara hàn wọ́n!”

Augustine ará ìlú Hippo ṣàlàyé tó pọ̀ gan-an lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Jésù ṣe fi ìṣù búrẹ́dì báálì márùn-ún àti ẹja méjì bọ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin lọ́nà ìyanu. Augustine parí èrò sí pé ìṣù búrẹ́dì márùn-ún dúró fún ìwé márùn-ún tí Mósè kọ torí wọ́n gbà pé àlìkámà níye lórí ju ọkà báálì lọ, (bí “ọkà báálì” kò ṣe níye lórí yìí jẹ́ kí wọ́n gbà pé “Májẹ̀mú Láéláé” kò fi bẹ́ẹ̀ wúlò). Kí wá ni ẹja méjì túmọ̀ sí? Fún àwọn ìdí kan, ńṣe ló fi wọ́n wé ọba àti àlùfáà. Ọ̀mọ̀wé míì tó mú ìwádìí lórí kókó yìí bí iṣẹ́ sọ pé bí Jákọ́bù ṣe fi abọ́ ẹ̀wà pupa ra ogún ìbí lọ́wọ́ Ísọ̀ ń ṣàpẹẹrẹ bí Jésù ṣe fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó jẹ́ pupa ra ogún ti ọ̀run fún aráyé!

Ẹ ò rí i pé irú àwọn ìtumọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣòro láti gbà gbọ́! A mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Àwa èèyàn kò lè mọ àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì tó ń ṣàpẹẹrẹ àwọn ohun tó ṣì ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ àtàwọn tí kò ṣàpẹẹrẹ ohunkóhun. Ohun tó yé wa kedere ni pé: Ibi tí Ìwé Mímọ́ bá ti fi kọni pé ẹnì kan, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tàbí ohun kan ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan míì tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, a gbà pé bó ṣe rí nìyẹn. Yàtọ̀ sí èyí, níbi tí kò bá ti sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pàtó tó sọ pé ẹnì kan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan míì, a ò ní fẹ́ sọ bẹ́ẹ̀.

Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni a ṣe lè jàǹfààní látinú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtàwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Ìwé Mímọ́? Nínú Róòmù 15:4, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé àwọn arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó lágbára nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Síbẹ̀, àwọn èèyàn Ọlọ́run láti ìran dé ìran, yálà wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí “àgùntàn mìíràn,” bóyá wọ́n ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ti jàǹfààní látinú “gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú,” wọ́n sì ń bá a nìṣó láti jàǹfààní.—Jòh. 10:16; 2 Tím. 3:1.

Dípò ká máa wo ọ̀pọ̀ lára àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì pé kìkì àwọn ẹni àmì òróró tàbí àgùntàn mìíràn ló ṣẹ sí lára àti pé sáà kan ṣoṣo ló nímùúṣẹ, àwa èèyàn Ọlọ́run yálà a jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí àgùntàn mìíràn lé fi àwọn ẹ̀kọ́ inú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà sílò nígbà yòówù ká gbé láyé. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ kí á kàn fi ẹ̀kọ́ tí a rí kọ́ nínú ìwé Jóòbù mọ sórí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní nìkan. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àwọn ẹni àmì òróró àti ogunlọ́gọ̀ ńlá ni wọ́n ti fara da irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù, wọ́n “sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá, pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.”—Ják. 5:11.

Rò ó wò ná: Nínú àwọn ìjọ wa lónìí, ǹjẹ́ kò sí àwọn àgbà obìnrin tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin bíi Dèbórà, àwọn ọ̀dọ́ alàgbà tí wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n bíi ti Élíhù, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó jẹ́ onígboyà tí wọ́n ní ìtara bíi ti Jẹ́fútà àti ọ̀pọ̀ olóòótọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ní sùúrù bíi ti Jóòbù? A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà mú kí “gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú” yìí wà lákọọ́lẹ̀ pé “nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí”!

Fún àwọn ìdí yìí ni àwọn ìtẹ̀jáde wa láwọn ọdún àìpẹ́ yìí ṣe ń tẹnu mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí a lè rí kọ́ nínú àwọn ohun tí Bíbélì sọ dípò ká máa wá ẹnì kan, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tàbí ohun kan nínú Bíbélì tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan míì tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú.