Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jehofa N Dari Ise Ikonilekoo Ti A N Se Kari Aye

Jehofa N Dari Ise Ikonilekoo Ti A N Se Kari Aye

“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”AÍSÁ. 48:17.

1. Àwọn ohun ìdènà wo làwọn Kristẹni ń kojú lónìí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

ÀWỌN Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì * tó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní ohun tó ju àádóje [130] ọdún sẹ́yìn kojú ọ̀pọ̀ ìdènà. Bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń wàásù ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn kò nífẹ̀ẹ́ sí. Wọ́n kéré níye, àwọn èèyàn sì kà wọ́n sí púrúǹtù ẹ̀dá. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n kojú “ìbínú ńlá” látọ̀dọ̀ Sátánì Èṣù. (Ìṣí. 12:12) Ohun míì ni pé, wọ́n ń wàásù ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí ó jẹ́ “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.”—2 Tím. 3:1.

2. Kí ni Jèhófà ń ṣe ká lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó lóde òní?

2 Ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wàásù ìhìn rere náà dé gbogbo ilẹ̀ ayé lóde òní, kò sì sí ohun tó lè dí ìfẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kó má ṣẹ. Bí Jèhófà ṣe dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ nídè kúrò ní ìlú Bábílónì, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní nídè kúrò ní “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣí. 18:1-4) Jèhófà ti kọ́ wa ká lè ṣe ara wa láǹfààní, ó mú kí àlàáfíà wà láàárín wa, ó sì jẹ́ ká lè kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ tó ti kọ́ wa. (Ka Aísáyà 48:16-18.) Èyí kò túmọ̀ sí pé Jèhófà ń fi agbára tó ní láti mọ ohun  tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú darí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, torí kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba rẹ̀ ṣáà lè máa tẹ̀ síwájú. Lóòótọ́, àwọn nǹkan míì ti ṣẹlẹ̀ láyé tó mú kí iṣẹ́ ìwàásù wa rọrùn, àmọ́ ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ló ń mú ká lè fara da inúnibíni àti àwọn ipò míì tó le koko tó sì mú kó nira fún wa láti wàásù nínú ayé yìí tó wà lábẹ́ agbára Sátánì.—Aísá. 41:13; 1 Jòh. 5:19.

3. Báwo ni “ìmọ̀ tòótọ́” ṣe ń pọ̀ yanturu?

3 Jèhófà mí sí wòlíì Dáníẹ́lì láti sọ tẹ́lẹ̀ pé “ìmọ̀ tòótọ́” máa pọ̀ yanturu ní àkókò ìkẹyìn. (Ka Dáníẹ́lì 12:4.) Jèhófà ran àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni èyí tí ẹ̀kọ́ èké Krisitẹndọmu ti bò mọ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́. Ní báyìí, Jèhófà ń lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú kí ìmọ̀ tòótọ́ dé ibi gbogbo láyé. Lónìí, à ń rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Dáníẹ́lì sọ. Nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ [8,000,000] èèyàn ló ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ń kéde òtítọ́ yìí kárí ayé. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn nǹkan tó ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kárí ayé láti máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí?

IPA TÍ IṢẸ́ ÌTÚMỌ̀ BÍBÉLÌ KÓ

4. Báwo ni èdè tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí ṣe pọ̀ tó ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún?

4 Bí Bíbélì ṣe wà lárọ̀ọ́wọ́tó ọ̀pọ̀ èèyàn mú kí ìhìn rere náà tún tètè tàn kálẹ̀. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ò fi jẹ́ káwọn èèyàn ka Bíbélì, wọ́n sì ṣe inúnibíni sáwọn tí ó ń kà á, kódà wọ́n pa àwọn kan tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, àwọn ẹgbẹ́ tó ń ṣe Bíbélì jáde túmọ̀ Bíbélì ní odindi tàbí lápá kan sí èdè tí ó tó irinwó [400]. Nígbà tó fi máa di ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ní Bíbélì àmọ́ wọn kò ní ìmọ̀ tí ó péye nípa àwọn ẹ̀kọ́ tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni.

5. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe láti túmọ̀ Bíbélì?

5 Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ wàásù, wọ́n sì sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn Jèhófà ti lo oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì, wọ́n sì pín in kiri fáwọn èèyàn. Láti ọdún 1950, wọ́n ti ń tẹ Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun jáde ní odindi tàbí lápá kan ní èdè tí ó ju ọgọ́fà [120] lọ. Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 2013 tí wọ́n tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì máa rọrùn láti túmọ̀ sí ọ̀pọ̀ èdè. Bíbélì tó rọrùn láti kà tó sì yéni kedere máa mú kí iṣẹ́ ìwàásù wa túbọ̀ rọrùn.

IPA TÍ SÁÀ ÀLÀÁFÍÀ KÓ

6, 7. (a) Báwo ni ogun tó wáyé lóde òní ṣe pọ̀ tó? (b) Báwo ni bí àwọn orílẹ̀-èdè kan ṣe ní àlàáfíà díẹ̀ ṣe mú kí iṣẹ́ ìwàásù rọrùn?

6 Ọ̀rọ̀ yìí lè yà ẹ́ lẹ́nu, torí o lè máa wò ó pé, ‘Àlàáfíà wo gan-an ló wà láyé?’ Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni wọ́n bá ogun lọ pàápàá nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní àti Ìkejì. Lọ́dún 1942 nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, Arákùnrin Nathan Knorr tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn sọ àsọyé kan ní àpéjọ àgbègbè kan, àkòrí àsọyé rẹ̀ ni “Àlàáfíà—Ǹjẹ́ Ó Lè Wà Pẹ́?” Arákùnrin Knorr ṣàlàyé Ìṣípayá orí 17, ẹsẹ Bíbélì yẹn sì fi ẹ̀rí hàn pé ogun tó ń lọ́ lọ́wọ́ nígbà náà kò ní jálẹ̀ sí ogun Amágẹ́dọ́nì, àmọ́ ó máa yọrí sí sáà àlàáfíà.—Ìṣí. 17:3, 11.

7 Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì àlàáfíà máa wà níbi gbogbo. Ìṣirò táwọn kan ṣe fi hàn pé láàárín ọdún 1946 sí 2013, ogun tí ó wáyé jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún àti ọgbọ̀n ó lé kan [331]. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló sì kú. Àmọ́ ní gbogbo ọdún tá à ń wí yìí, àwọn orílẹ̀-èdè kan ṣì ní àlàáfíà díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà sì fi àǹfààní yìí  polongo ìhìn rere. Kí ló ti jẹ́ àbájáde rẹ̀? Lọ́dún 1944, iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà kárí ayé dín díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà [110,000]. Àmọ́ lónìí, a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ! (Ka Aísáyà 60:22.) Ǹjẹ́ a kì í láyọ̀ tá a bá láǹfààní láti wàásù ìhìn rere náà láwọn ìgbà tí kò sí wàhálà tí gbogbo nǹkan wà lálàáfíà?

IPA TÍ ÈTÒ ÌRÌNNÀ TÓ RỌRÙN KÓ

8, 9. Báwo ni ètò ìrìnnà ṣe rọrùn tó lónìí, ipa wo sì ni èyí ti ní lórí iṣẹ́ ìwàásù wa?

8 Bí ètò ìrìnnà ṣe túbọ̀ ń dáa sí i ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ rọrùn. Ní ọdún 1900, ìyẹn ọdún mọ́kànlélógún lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn Watch Tower jáde, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] péré ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ ìjọba ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn ọ̀nà tó dáa tí wọ́n sì lè gbé e gbà ò pọ̀ rárá. Àmọ́ ní báyìí, ọkọ̀ tó wà kárí ayé tí wọ́n forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ ìjọba ti ju bílíọ̀nù kan ààbọ̀ lọ, àìmọye ọ̀nà tó dáa ni wọ́n sì lè gbé e gbà. Èyí ti mú kó rọrùn fún ọ̀pọ̀ nínú wa láti wàásù dé àwọn àdádó tó jìnnà sí ìlú. Kódà tí ọ̀nà ò bá dáa tí kò sì sí ọkọ̀ ládùúgbò tí a wà, tó fi gba pé ká fi ẹsẹ̀ rin ọ̀nà jíjìn, a máa ń sa gbogbo ipá wa ká lè sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19, 20.

9 Oríṣiríṣi ètò ìrìnnà tó wà ti ṣèrànwọ́ gan-an fún iṣẹ́ ìwàásù wa. A máa ń fi ọkọ̀ akẹ́rù, ọkọ̀ òkun àti ọkọ̀ rélùwéè kó àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì lọ sí àwọn àgbègbè tó jìnnà gan-an, tí wọ́n sì máa débẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan. Ọkọ̀ òfuurufú máa ń jẹ́ kí ìrìn àjò yá kíákíá fún àwọn alábòójútó àyíká, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn míì tí wọ́n bá fẹ́ lọ sọ àsọyé ní àwọn àpéjọ àgbègbè tàbí tí wọ́n fẹ́ ṣe àwọn iṣẹ́ míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti àwọn arákùnrin mìíràn tó wà ní orílé-iṣẹ́ máa ń wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kí wọ́n lè fún àwọn ará ní ìtọ́ni àti ìṣírí. Bí ètò ìrìnnà ṣe túbọ̀ ń dáa sí i ti mú kí ìṣọ̀kan túbọ̀ wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run.—Sm. 133:1-3.

IPA TÍ ÈDÈ KÓ

10. Báwo ni wọ́n ṣe ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì kárí ayé?

10 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, èdè Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní Koine lọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ nílé lóko ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Èdè wo la lè sọ pé àwọn èèyàn ń sọ nílé lóko lónìí?  Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé èdè Gẹ̀ẹ́sì ni. Ìwé kan tí wọ́n ń pè ní English as a Global Language sọ pé: “Nǹkan bí ìdá mẹ́rin àwọn tó wà láyé ló ń sọ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n sì lóye rẹ̀ dáadáa.” Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè ilẹ̀ òkèèrè tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ń kọ́ torí pé kárí ayé ni wọ́n ti ń lò ó yálà fún òwò, òṣèlú, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti fún ìmọ̀ ẹ̀rọ.

11. Ipa wo ni èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ní lórí ìjọsìn tòótọ́?

11 Báwọn èèyàn ṣe ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì kárí ayé ti mú kí ìjọsìn tòótọ́ túbọ̀ tẹ̀ síwájú. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni a fi ń tẹ ìwé ìròyìn The Watchtower àti àwọn ìtẹ̀jáde míì tí wọ́n ṣàlàyé Bíbélì. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè àjùmọ̀lò tá à ń lò ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Òun ni a sì fi ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower ní ìlú Patterson, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

12. Èdè mélòó ni a ti tẹ àwọn ìwé wa tó ṣàlàyé Bíbélì sí, báwo ni ìmọ̀ ẹ̀rọ ṣe mú kí èyí ṣeé ṣe?

12 Torí pé a láǹfààní láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fún gbogbo èèyàn kárí ayé, a ti túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí èdè tí ó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700]. Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó ń tẹ̀ síwájú títí kan ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà kan tá a pè ní MEPS (ìyẹn Multilanguage Electronic Publishing System), ti mú kí iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè rọrùn. Ó ti mú kí a lè wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé ibi tó pọ̀, ó sì ti jẹ́ ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan kárí ayé. Àmọ́ ohun tó túbọ̀ mú ká wà níṣọ̀kan gan-an ni èdè pàtàkì kan tí gbogbo wa ń sọ, ìyẹn “èdè mímọ́ gaara” ti ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni.—Ka Sefanáyà 3:9.

IPA TI ÒFIN KÓ

13, 14. Báwo ni àwọn Kristẹni òde òní ṣe jàǹfààní nínú òfin àti àwọn ìpinnu ilé ẹjọ́?

13 Bí a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni jàǹfààní nínú òfin Róòmù, èyí tó fìdí múlẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ọba náà. Bákan náà, àwọn Kristẹni òde òní ń lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà níbi ti orílé-iṣẹ́ wa wà, òfin gba àwọn èèyàn láyè láti ṣe ẹ̀sìn tí wọ́n bá fẹ́, láti sọ ohun tó wù wọ́n àti láti péjọ pọ̀. Èyí ti fún àwọn ará lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lómìnira láti pàdé pọ̀ kí wọ́n sì jíròrò Bíbélì ní fàlàlà, wọ́n sì tún láǹfààní láti wàásù fáwọn èèyàn. Àmọ́, ìgbà míì wà tí wọ́n ní láti lọ sí ilé ẹjọ́ kí wọ́n lè fìdí àwọn ẹ̀tọ́ kan múlẹ̀ lábẹ́ òfin. (Fílí. 1:7) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lẹ́jọ́ kí wọ́n lè fòfin de  iṣẹ́ ìwàásù wọn, wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sílé ẹjọ́ gíga, léraléra ni wọ́n sì gbèjà ẹ̀tọ́ wọn láti máa polongo ìhìn rere Ìjọba náà.

14 Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ilé ẹjọ́ ti gbèjà òmìnira tá a ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wá àti ẹ̀tọ́ tá a ní láti wàásù ní gbangba. Láwọn ilẹ̀ míì, wọ́n ti fi ẹ̀tọ́ wa dù wá nílé ẹjọ́, àmọ́ a pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, a sì gbé ẹjọ́ náà lọ sáwọn ilé ẹjọ́ àgbáyé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó fi máa di oṣù June ọdún 2014, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ti dá wa láre nínú ẹjọ́ mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [57]. Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù ló sì gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí ilé ẹjọ́ yìí wí. Bá a tiẹ̀ “jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,” àwọn ilé ẹjọ́ lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè ti dájọ́ pé a lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìsìn tòótọ́.—Mát. 24:9.

IPA TÍ ÀWỌN Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDE NÍ LORÍ IṢẸ́ ÌKỌ́NI TÁ À Ń ṢE

À ń fún àwọn èèyàn kárí ayé láwọn ìwé ìròyìn tó ṣàlàyé Bíbélì

15. Ìtẹ̀síwájú wo ló ti bá iṣẹ́ ìwé títẹ̀, ipa wo sì ni èyí ní lórí iṣẹ́ wa?

15 Àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ti ìgbàlódé ti ní ipa rere lórí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí à ń ṣe kárí ayé. Fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí Johannes Gutenberg ṣe ní nǹkan bí ọdún 1450 làwọn èèyàn ń lò. Àmọ́ láti igba [200] ọdún sẹ́yìn, àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ti gbọ̀nà àrà yọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí ó tóbi, tí wọ́n yára tí wọ́n sì díjú ti wà. Bébà àti àwọn ẹ̀rọ tó ń di ìwé pọ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́n mọ́. Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo ti ìgbàlódé ti rọ́pò ti àtijọ́ tí wọ́n máa ń fi ọwọ́ to àwọn lẹ́tà rẹ̀ kí wọ́n tó tẹ̀ ẹ́. Ẹ̀rọ ìgbàlódé yìí sì ti mú àyípadà bá iye ìwé téèyàn lè tẹ̀ jáde lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn àwòrán tó sì ń tẹ̀ jáde fani mọ́ra gan-an. Ipa wo ni èyí ní lórí iṣẹ́ wa? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan: Ní oṣù July ọdún 1879, a tẹ ẹ̀dà àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì nìkan, kò ní àwòrán kankan, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] sì ni iye tí a tẹ̀ jáde. Àmọ́ lónìí, ìyẹn nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlógóje [136] lẹ́yìn ìyẹn, ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí ó lé ní àádọ́ta mílíọ̀nù [50,000,000] ni à ń tẹ̀ jáde tí à sì ń pín kiri. Àwòrán aláwọ̀ mèremère kún inú rẹ̀, èdè tí ó ju igba [200] lọ ni a sì ń tẹ̀ jáde.

16. Àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé wo ló ti mú kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti wàásù kárí ayé? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

16 Ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé tá a ti ń lò láti ohun tó ju igba [200] ọdún lọ báyìí ti jẹ́ ká lè máa wàásù ìhìn rere náà káàkiri. A ti mẹ́nu kan ọkọ̀ rélùwéè, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ọkọ̀ òfuurufú, àmọ́ àwọn nǹkan míì tún wà irú bíi kẹ̀kẹ́, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń tẹ ìwé àwọn afọ́jú, wáyà ìbánisọ̀rọ̀, fóònù, kámẹ́rà, ẹ̀rọ tó ń gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀, rédíò, tẹlifíṣọ̀n, sinimá tó ń gbé ohùn jáde, kọ̀ǹpútà àti Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn nǹkan yìí ti ní ipa tó pọ̀ lórí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí à ń ṣe. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn Jèhófà yóò máa “fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu,” ní ti gidi à ń fi àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tẹ Bíbélì àti àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì ní ọ̀pọ̀ èdè.—Ka Aísáyà 60:16.

17. (a) Kí ni ẹ̀rí fi hàn? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi fún wa láǹfààní láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú rẹ̀?

17 Láìsí àní-àní, a ní ẹ̀rí tó lágbára pé Jèhófà ń bù kún wa. Òótọ́ ni pé Jèhófà ò gbára lé wá kí ìfẹ́ rẹ̀ tó lè ṣẹ. Síbẹ̀, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ fún wa láǹfààní láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú rẹ̀, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò wa. (1 Kọ́r. 3:9; Máàkù 12:28-31) Ǹjẹ́ kí a lo àǹfààní tá a ní yìí láti fi ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì bí Jèhófà ṣe ń darí wa lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe kárí ayé àti bó ṣe ń bù kún iṣẹ́ náà!

^ ìpínrọ̀ 1 Ọdún 1931 làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Aísá. 43:10.