NÍ ỌDÚN 1870 àwùjọ kékeré kan ní ìlú Pittsburgh (Allegheny) ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́. Arákùnrin Charles Taze Russell ló múpò iwájú nínú àwùjọ yìí, wọ́n ṣèwádìí nípa ìràpadà Kristi, wọ́n sì rí i pé ìràpadà ṣe pàtàkì gan-an kí ìfẹ́ Jèhófà lè ṣẹ. Inú wọ́n dùn gan-an bí wọ́n ṣe mọ̀ pé ìràpadà ló mú kí ìgbàlà ṣeé ṣe kódà fáwọn tí kò tíì gbọ́ nípa Jésù pàápàá! Èyí mú kí wọ́n máa fi tayọ̀tayọ̀ ṣe Ìrántí Ikú Jésù lọ́dọọdún.—1 Kọ́r. 11:23-26.

Arákùnrin Russell tẹ ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower jáde, ìwé ìròyìn yìí ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìràpadà ni ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù tí Ọlọ́run gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ aráyé. Ìwé ìròyìn Watch Tower pe àkókò Ìrántí Ikú Kristi ní “àkókò tá a mọyì jù lọ,” ó sì rọ àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn náà pé kí wọ́n ṣe ìrántí yìí ní ìlú Pittsburgh tàbí ní àwọn ibòmíì tí àwùjọ kéékèèké ti ń pàdé pọ̀. Ìwé ìròyìn náà sì fi kún un pé, “bó tiẹ̀ jẹ́ ẹni méjì tàbí mẹ́ta tó ní ìgbàgbọ́ ṣíṣeyebíye ló pàdé pọ̀,” kódà ì báà tiẹ̀ jẹ́ ẹnì kan ṣoṣo péré ló wà níbẹ̀ “Kristi yóò wà pẹ̀lú wọn.”

Ọdọọdún ni àwọn tó ń wá ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ìlú Pittsburgh ń pọ̀ sí i. Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìkésíni pé, “àwọn tó wà níbí lọ́yàyà, wọ́n á sì mú kára tù ẹ́.” Tinútinú làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi gba àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí sílé, wọ́n sì tún fún wọn lóúnjẹ. Lọ́dún 1886 nígbà Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n ṣe ìpàdé gbogbo gbòò fún ọjọ́ mélòó kan. Ìwé ìròyìn Watch Tower rọ àwọn èèyàn pé: “Ẹ wá ẹ̀yin tí ẹ ní ìfẹ́ tó kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún Ọ̀gá náà, fún ìjọ rẹ̀ àti fún òtítọ́.”

Àtẹ Ìsọfúnnni tó fi hàn bí wọ́n ṣe ń gbé ohun ìṣàpẹẹrẹ káàkiri nígbà Ìrántí Ikú Kristi ní gbọ̀ngàn London Tabernacle

Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà nílùú Pittsburgh fi gba àlejò àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ìràpadà tí wọ́n wá ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Bí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn tó ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi ń pọ̀ sí i kárí ayé. Arákùnrin Ray Bopp tó wà ní ìjọ Chicago sọ pé lọ́dún 1910 ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n fi gbé búrẹ́dì àti wáìnì ìṣàpẹẹrẹ náà káàkiri láàárín ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi, torí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ló jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà.

Kí làwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tí wọ́n lò? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wáìnì ni Jésù lò nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ìgbà kan wà tí ètò Ọlọ́run dábàá pé ká máa lo omi èso àjàrà tàbí àjàrà gbígbẹ tí wọ́n sè kí wáìnì má bàa di ìdẹwò fáwọn tí wọ́n jẹ́ “aláìlera ní ẹran ara.” Àmọ́, wọ́n gbé wáìnì fáwọn tó gbà pé “wáìnì kíkan ló yẹ kí wọ́n lò.” Nígbà tó yá, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá mọ̀ pé wáìnì tí kò lábùlà ló yẹ kí wọ́n fi ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ Jésù.

Wọ́n fi bébà àti pẹ́ńsù yìí ránṣẹ́ láti yàrá ẹ̀wọ̀n kan dé òmíràn kí wọ́n lè fi kọ iye àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tó wà ní orílẹ̀-èdè Nicaragua

Ìrántí Ikú Kristi ń mú kéèyàn lè ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Jésù ṣe. Ní àwọn ìjọ kan, tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìrántí Ikú  Kristi bá ń lọ lọ́wọ́ ńṣe ni ibẹ̀ máa pa rọ́rọ́, tí wọ́n bá sì parí, gbogbo wọn lè túká láìbá ara wọn sọ̀rọ̀ rárá. Ìwé tí ètò Ọlọ́run tẹ̀ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1934 tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ Jehovah, sọ pé kò yẹ ká máa fi Ìrántí Ikú Kristi “ṣọ̀fọ̀” ikú oró tí Jésù kú, àmọ́ ká máa fi “ayọ̀” ṣe é torí pé Jésù ti ń ṣàkóso bí Ọba látọdún 1914.

Àwọn arákùnrin tó ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní àgbègbè Mordvinia, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lọ́dún 1957

Àyípadà ńláǹlà ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1935, èyí sì ní ipa lórí Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n ṣe láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e. Lọ́dún yẹn wọ́n rí ìlàlóye lórí Ìṣípayá 7:9, wọ́n wá mọ ìtumọ̀ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ. Ṣáájú ọdún 1935, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ka àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” sí àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ àmọ́ tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìtara. Àmọ́ ní báyìí, a mọ àwọn ogunlọ́gọ̀ yìí sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n ní ìrètí láti gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn ìlàlóye tí wọ́n ní yìí, Arákùnrin Russell Poggensee fara balẹ̀ yẹ ara rẹ̀ wò, ó sì sọ pé: “Jèhófà ò tíì sọ fún mi nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ pé mo ní ìrètí ti ọ̀run.” Arákùnrin Poggensee àti àwọn míì táwọn náà jẹ́ olóòótọ́ kò jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ náà mọ́, àmọ́ wọ́n ṣì ń lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi.

Ìwàásù táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń ṣe lákànṣe ní “àkókò tá a mọyì jù lọ” yìí máa ń mú kí gbogbo wọn fi hàn pé wọ́n mọrírì ìràpadà náà. Lọ́dún 1932, ìtẹ̀jáde wa kan tó ń jẹ́ Bulletin rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe máa jẹ búrẹ́dì kí wọ́n sì máa mu wáìnì nígbà Ìrántí Ikú Kristi nìkan, àmọ́ kí wọ́n tún máa kópa nínú wíwàásù òtítọ́ náà fáwọn èèyàn. Lọ́dún 1934, ìbéèrè kan jáde nínú ìtẹ̀jáde Bulletin pé: “Ǹjẹ́ a máa rí àwọn ẹgbẹ̀rún kan [1,000] tó máa gba aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà Ìrántí Ikú Kristi?” Ní ti àwọn ẹni àmì òróró, ìtẹ̀jáde Informant sọ pé: “Tí wọ́n bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni ayọ̀ wọn tó lè kún.” Ohun tó yẹ káwọn tó ní ìrètí ti ilẹ̀ ayé náà máa ṣe nìyẹn. *

Nígbà tí Arákùnrin Harold King wà ní àtìmọ́lé, ó kọ ewì àti orin nípa Ìrántí Ikú Kristi

Gbogbo àwa èèyàn Jèhófà gbà pé alẹ́ mímọ́ ni alẹ́ ọjọ́ tí a máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi. A máa ń ṣe é kódà nígbà tí ipò nǹkan ò bá rọrùn fún wa pàápàá. Lọ́dún 1930, Arábìnrin Pearl English àti Arábìnrin Ora tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò rin ọgọ́rin [80] kìlómítà kí wọ́n lè lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Nígbà tí Arákùnrin Harold King tí ó jẹ́ míṣọ́nnárì wà ní àtìmọ́lé lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, ó kọ ewì àti orin nípa Ìrántí Ikú Kristi, ó wá fi èso àjàrà ṣe wáìnì, ó sì fi ìrẹsì ṣe búrẹ́dì. Kódà, nígbà ogun àti ìfòfindè, àwọn Kristẹni onígboyà ṣì ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi, láti Ìlà Oòrùn Yúróòpù tó fi dé Amẹ́ríkà Àárín títí lọ dé Áfíríkà. Láìka ibi tí a wà tàbí ipò tí a wà sí, a máa ń pàdé pọ̀ ká lè bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ní ìgbà Ìrántí Ikú Kristi tí a kà sí àkókò tá a mọyì jù lọ.

^ ìpínrọ̀ 10 A bẹ̀rẹ̀ sí í pe ìtẹ̀jáde Bulletin Informant nígbà kan, àmọ́ ní báyìí òun là ń pè ní Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.