Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  February 2015

Ebun Pataki Kan To Wa fun Awon Ara Japan

Ebun Pataki Kan To Wa fun Awon Ara Japan

NÍ April 28, 2013, àkànṣe ìpàdé kan wáyé ní ìlú Nagoya lórílẹ̀-èdè Japan, ibẹ̀ ni Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ṣe ìfilọ̀ kan tó ya gbogbo àwọn tó pésẹ̀ sípàdé náà lẹ́nu. Ìfilọ̀ náà ni pé ètò Ọlọ́run ti mú ìwé tuntun kan jáde ní èdè ilẹ̀ Japan, àkọlé rẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì ni The Bible—The Gospel According to Matthew. Àwọn tó lé ní ẹgbàá márùnlélọ́gọ́rùn-ún [210,000] tí wọ́n pésẹ̀ síbi ìpàdé náà àti àwọn tí wọ́n fi Íńtánẹ́ẹ̀tì ta á látaré síbi tí wọ́n wà pàtẹ́wọ́ tó rinlẹ̀ gan-an.

Ìwé olójú ìwé méjìdínláàádóje [128] yìí jẹ́ ẹ̀dà ìwé Ìhìn rere Mátíù nìkan, ó sì ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an ni. Ó jẹ́ àtúntẹ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè ilẹ̀ Japan. Arákùnrin Morris ṣàlàyé pé ètò Ọlọ́run dìídì ṣe ìwé náà “kó lè wúlò fáwọn ara Japan.” Àwọn ohun wo ló wà nínú ìwé yìí? Kí nìdí tí ètò Ọlọ́run fi ṣe é? Báwo ló sì ṣe rí lára àwọn tó ń gba ìwé náà?

ÀWỌN OHUN WO LÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ?

Ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe ìtẹ̀jáde yìí ya àwọn èèyàn lẹ́nu. Torí pé, àwọn ará Japan máa ń kọ àwọn álífábẹ́ẹ̀tì wọn ní ìdábùú tàbí ní òró, àwọn ìwé wọn mélòó kan títí kan àwọn ìtẹ̀jáde wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́ la sì kọ ní ìdábùú. Àmọ́, a kọ àwọn álífábẹ́ẹ̀tì inú ìtẹ̀jáde tuntun yìí ní òró, a to àwọn ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó bá àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé míì lórílẹ̀-èdè Japan mu. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Japan ló gbà pé ọ̀nà ìgbàkọ̀wé yìí rọrùn láti kà. Bákan náà, a sọ àwọn àkòrí tó máa ń wà lọ́wọ́ òkè ní ojú ìwé kọ̀ọ̀kan di ìsọ̀rí ọ̀rọ̀, kó lè rọrùn fún ẹni tó bá ń kà á láti rí àwọn kókó pàtàkì náà.

Ojú ẹsẹ̀ tí àwọn ará lórílẹ̀-èdè Japan gba ìwé yìí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Arábìnrin kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin [80] ọdún sọ pé: “Mo ti ka ìwé Mátíù tán lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ bí wọ́n ṣe to àwọn álífábẹ́ẹ̀tì ìwé náà àtàwọn ìsọ̀rí rẹ̀ jẹ́ kó rọrùn fún mi láti túbọ̀ lóye ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè dáadáa.” Arábìnrin kan sọ pé: “Mo ka ìwé náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní ìdábùú ni mo sábà máa ń kà, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ara Japan ló fẹ́ràn èyí tó wà ní òró.”

ÀWỌN ARÁ JAPAN LA DÌÍDÌ ṢE É FÚN

Báwo ló ṣe jẹ́ pé ìwé kan ṣoṣo nínú Bíbélì lè dìídì wúlò fáwọn ara Japan? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará Japan ò fi bẹ́ẹ̀ mọ púpọ̀ nípa Bíbélì, wọ́n múra tán láti kà á. Ìwé Ìhìn rere Mátíù yìí máa fún àwọn tí kò tíì rí Bíbélì rí láǹfààní láti ní apá kan Ìwé Mímọ́ kí wọ́n sì kà á.

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìwé Mátíù la dìídì tún ṣe fún àwọn ará Japan? Ìdí ni pé táwọn ará Japan bá gbọ́ Bíbélì sétí, ohun tó sábà máa ń wá sí wọn lọ́kàn ni Jésù Kristi. Torí náà, a yan ìwé Mátíù láàyò torí àlàyé tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Japan máa nífẹ̀ẹ́ sí ló wà nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ ìtàn ìran Jésù àti bí wọ́n ṣe bí i, ó sọ nípa ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa àti àwọn ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn.

 Àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè Japan bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìtara pín ìtẹ̀jáde yìí láti ilé dé ilé àti fún àwọn ìpadàbẹ̀wò wọn. Arábìnrin kan sọ pé: “Àǹfààní ti ṣí sílẹ̀ fún mi báyìí láti fún àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Kódà, mo fún ẹnì kan ní ìtẹ̀jáde náà ní ọ̀sán ọjọ́ tá a ṣe àkànṣe ìpàdé náà!”

BÁWO LÓ ṢE RÍ LÁRA ÀWỌN TÓ GBA ÌWÉ NÁÀ?

Báwo làwọn akéde ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀ kí wọ́n tó fáwọn èèyàn ní ìtẹ̀jáde náà? Àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ bí “ẹnubodè tóóró,” “péálì . . . síwájú àwọn ẹlẹ́dẹ̀,” àti “ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la” kò ṣàjèjì sí ọ̀pọ̀ àwọn ará Japan. (Mát. 6:34; 7:6, 13) Ó yà wọ́n lẹ́nu láti gbọ́ pé Jésù ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Báwọn kan ṣe rí àwọn ọ̀rọ̀ yẹn nínú ìwé Ìhìn Rere Mátíù, ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sọ ni pé: “Ó ti máa ń wù mí láti ka Bíbélì bí ò tiẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ.”

Táwọn akéde bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó gba ìtẹ̀jáde náà, àwọn onílé sábà máa ń sọ pé ojú ẹsẹ̀ làwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í kà á báwọn ò tiẹ̀ tíì kà á tán. Ọkùnrin kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta [60] ọdún sọ fún akéde kan pé: “Mo kà á léraléra láìmọye ìgbà, ó sì tù mí nínú. Jọ̀wọ́, kọ́ mi ní ohun púpọ̀ sí i nípa Bíbélì.”

Àwọn akéde tún fún àwọn èèyàn ní ìtẹ̀jáde yìí láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí. Lọ́jọ́ kan, Ẹlẹ́rìí kan fún obìnrin kan tó gba ìtẹ̀jáde náà ní àdírẹ́sì tó fi ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Wákàtí kan lẹ́yìn náà, obìnrin náà fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Ẹlẹ́rìí yìí pé òun ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìtẹ̀jáde náà, òun sì fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìyẹn, ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé.

Ó lé ní mílíọ̀nù kan àti ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [1,600,000] ẹ̀dà ìtẹ̀jáde náà tí wọ́n ti kó lọ sáwọn ìjọ ní orílẹ̀-èdè Japan. Àwọn ará sì ń fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀ síta lóṣooṣù. Ètò Ọlọ́run sọ èrò rẹ̀ nípa ìwé yìí nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú tó wà nínú ìwé náà pé: “A retí pé ìwé yìí máa mú kó o túbọ̀ wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”