Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—ní New York

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—ní New York

NÍ NǸKAN bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, Cesar àti Rocio ìyàwó rẹ̀ ń gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ ní ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Cesar ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe àwọn ẹ̀rọ tó ń mú kí ilé móoru, ẹ̀rọ tó ń gbé afẹ́fẹ́ wọlé àti ẹ̀rọ amúlétutù, Rocio sì ń ṣiṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ ní ilé ìwòsàn. Ilé ara wọn ni wọ́n ń gbé, wọn ò sì bímọ. Àmọ́, nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó yí ìgbésí ayé wọn pa dà. Kí ni nǹkan náà?

Ní oṣù October ọdún 2009, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ̀wé sí gbogbo ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Wọ́n ní káwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó bá fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn gba fọ́ọ̀mù iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì kí wọ́n lè wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì fúngbà díẹ̀. Wọ́n á lè kópa nínú ìmúgbòòrò ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ìlú Wallkill ní ìpínlẹ̀ New York. Kódà, wọ́n ní káwọn tí ọjọ́ orí wọn ti kọjá ọjọ́ orí àwọn tó lè gba fọ́ọ̀mù iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì gbà á. Cesar àti ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Torí ọjọ́ orí wa, a mọ̀ pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni èyí máa jẹ́ láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì. A ò sì fẹ́ kí àǹfààní yẹn fò wá ru!” Tọkọtaya yìí fi fọ́ọ̀mù tí wọ́n fi béèrè fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ránṣẹ́ lójú ẹsẹ̀.

Díẹ̀ lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní Warwick

Ọdún kan kọjá ó tún lé, síbẹ̀ wọn ò pe tọkọtaya yìí sí Bẹ́tẹ́lì. Àwọn méjèèjì pinnu láti ṣe àwọn àyípadà kan kí ọwọ́ wọn lè tẹ àfojúsùn wọn. Lára ohun tí wọ́n ṣe ni pé, wọ́n dín àwọn ohun ìní tara tí wọ́n ní kù. Cesar sọ pé: “A sọ ibi ìgbọ́kọ̀sí wa di yàrá, ká lè fi ilé wa rẹ́ǹtì fún ẹlòmíì. A kó kúrò nínú ilé wa ńlá tá a nífẹ̀ẹ́ sí gan-an tá a kọ́ ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, a sì kó lọ sí yàrá kékeré tí a ṣe. Àwọn àyípadà tá a ṣe yìí máa mú kó rọrùn fún wa láti lọ sí Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n bá pè wá.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Rocio sọ pé: “Oṣù kan lẹ́yìn tí a kó lọ sínú yàrá wa kékeré yẹn, a gba ìkésíni pé ká wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì fúngbà díẹ̀ ní ìlú Wallkill. Bí a ṣe dín àwọn ohun ìní tara tí a ní kù, ohun tá a fi máa rí ìbùkún Jèhófà gbà la ṣe.”

Jason, Cesar, àti William

JÈHÓFÀ BÙ KÚN WỌN TORÍ PÉ WỌ́N YỌ̀ǸDA ARA WỌN

Bíi ti Cesar àti Rocio, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arákùnrin àti arábìnrin ló ti yááfì àwọn nǹkan kan kí wọ́n lè lọ́wọ́  nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tá à ń ṣe ní ìpínlẹ̀ New York. Àwọn kan nínú wọn ń ṣiṣẹ́ níbi ìmúgbòòrò tá à ń ṣe ní ìlú Wallkill, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì láǹfààní láti kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìkọ́lé ti orílé-iṣẹ́ tí à ń kọ́ sí ìlú Warwick. * Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ti fi ilé àti iṣẹ́ gidi tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀ títí kan àwọn ohun ọ̀sìn wọn kí wọ́n lè ráyè sin Jèhófà dáadáa. Ǹjẹ́ Jèhófà bù kún wọn bí wọ́n ṣe yọ̀ǹda ara wọn? Bẹ́ẹ̀ ni, ó bù kún wọn!

Way

Bí àpẹẹrẹ, Way àti Debra ìyàwó rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́ta [60] ọdún, iṣẹ́ atúnnáṣe ni Way ń ṣe. Òun àti ìyàwó rẹ̀ ta ilé wọn àti ọ̀pọ̀ nínú àwọn ohun ìní wọn ní ìpínlẹ̀ Kansas, wọ́n kó lọ sí ìlú Wallkill, wọ́n sì ń tilé wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì. * Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí gba pé kí wọ́n ṣe àwọn ìyípadà kan nígbèésí ayé wọn, wọ́n rí i pé ó tó bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ káwọn yááfì àwọn nǹkan kan. Debra sọ nípa iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì pé: “Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé mo ti wà nínú Párádísè níbi tí wọ́n ti ń kọ́lé, bó ṣe máa ń wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa kan!”

Melvin àti Sharon ìyàwó rẹ̀ ta ilé wọn àtàwọn ohun ìní wọn tó wà ní ìpínlẹ̀ South Carolina kí wọ́n lè lọ ṣiṣẹ́ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Warwick. Lóòótọ́ kò rọrùn fún wọn láti ṣe ohun tí wọ́n ṣe yẹn, àmọ́ wọ́n kà á sí àǹfààní ńlá láti kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé mánigbàgbé yìí. Tọkọtaya yìí sọ pé: “Ayọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ lèèyàn máa ń ní téèyàn bá mọ̀ pé ohun tóun ń ṣe máa ṣe ètò Ọlọ́run láǹfààní.”

Kenneth

Ẹlòmíì tún ni Kenneth, ó ti fẹ̀yìn tì nídìí iṣẹ́ kọ́lékọ́lé, òun àti Maureen ìyàwó rẹ̀ sì ti lé lẹ́ni àádọ́ta [50] ọdún, wọ́n kó kúrò ní ìpínlẹ̀ California kí wọ́n lè lọ ṣiṣẹ́ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Warwick. Kí wọ́n tó kó kúrò, wọ́n ṣètò pé kí arábìnrin kan nínú ìjọ máa bá àwọn tọ́jú ilé wọn. Torí pé bàbá Kenneth ti dàgbà, wọ́n ṣètò pé kí àwọn tó kù nínú ìdílé wọn máa bójú tó bàbá Kenneth. Ǹjẹ́ wọ́n kábàámọ̀ gbogbo ohun tí wọ́n yááfì kí wọ́n lè wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì? Ó tì o! Kenneth sọ pé: “À ń jàǹfààní gan-an ni. Lóòótọ́ kì í ṣe pé a ò ní ìṣòro kankan, àmọ́ ìgbé ayé tó lérè là ń gbé, a sì rọ àwọn míì pé káwọn náà wá ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí.”

WỌ́N BORÍ ÌṢÒRO

Ọ̀pọ̀ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ló ní àwọn ìṣòro tí wọ́n kojú, àmọ́ wọ́n borí wọn. Bí àpẹẹrẹ, William àti Sandra ń gbé ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, wọ́n sì ń gbádùn ìgbésí ayé wọn. Àwọn méjèèjì ti lé lẹ́ni ọgọ́ta [60] ọdún. Wọ́n ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti máa ń rọ àwọn ẹ̀yà ara ẹ̀rọ èyíkéyìí, wọ́n sì láwọn òṣìṣẹ́ mẹ́tàdínlógún tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ wọn. Inú ìjọ táwọn méjèèjì ti wà láti kékeré ni wọ́n ṣì wà, ọ̀pọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn ló sì wà ládùúgbò yẹn. Nígbà tí àǹfààní láti máa ti ilé wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú Wallkill yọjú, wọ́n mọ̀  pé àwọn máa ní láti fi àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn mọ̀lẹ́bí wọn sílẹ̀. William sọ pé: “Ohun tó nira jù fún wa ni fífi ìgbé ayé ìrọ̀rùn tí à ń gbé sílẹ̀.” Àmọ́, lẹ́yìn tí tọkọtaya yìí gbàdúrà nípa ẹ̀ dáadáa, wọ́n pinnu pé àwọn máa lọ, wọn ò sì kábàámọ̀ ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí. William sọ pé: “Ayọ̀ tí à ń ní bí a ṣe ń kọ́lé yìí tí a sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìdílé Bẹ́tẹ́lì ò láfiwé rárá. Èmi àti ìyàwó mi sì ń láyọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ!”

Díẹ̀ rèé lára àwọn tọkọtaya tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ìlú Wallkill

Arákùnrin Ricky ń gbé ní ìpínlẹ̀ Hawaii, iṣẹ́ àwọn tó máa ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé ló ń ṣe. Wọ́n pè é kó máa tilé wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì kó lè ṣèrànwọ́ nídìí iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Warwick. Ìyàwó rẹ̀ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kendra sì fẹ́ kó gba ìkésíni yìí. Àmọ́, ohun tó ń kọ wọ́n lóminú ni ọ̀rọ̀ ọmọkùnrin wọn Jacob, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá. Wọ́n ń rò ó bóyá ó máa bọ́gbọ́n mu fáwọn láti kó lọ sí ìpínlẹ̀ New York àti bó ṣe máa rí lára ọmọkùnrin wọn tó bá dé àgbègbè tó yàtọ̀ pátápátá síbi tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀.

Ricky sọ pé: “Ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa rí ìjọ táwọn ọ̀dọ́ tó ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí pọ̀ sí. A fẹ́ kí Jacob ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ gidi tó máa ràn án lọ́wọ́.” Bí wọ́n ṣe fẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ náà ló rí, kò fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ọmọ kéékèèké nínú ìjọ tí wọ́n wà báyìí, àmọ́ àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì pọ̀ níbẹ̀. Ricky sọ pé: “Lẹ́yìn ìpàdé àkọ́kọ́ tí a ṣe níbẹ̀, mo bi ọmọ mi pé kí ló rò nípa ìjọ tuntun tá a wà yìí torí kò sí ọmọdé kankan tó jẹ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ níbẹ̀. Lọmọ mi bá dáhùn pé, ‘Dádì mi ẹ má ṣèyọnu, àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ló máa di ọ̀rẹ́ mi.’”

Jacob àti àwọn òbí rẹ̀ ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ

Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, àwọn ọ̀dọ́ tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì mú Jacob lọ́rẹ̀ẹ́. Ipa wo ni wọ́n ní lórí rẹ̀? Ricky sọ pé: “Lálẹ́ ọjọ́ kan, bí mo ṣe kọjá níwájú yàrá Jacob mo rí i pé ó ṣì tanná yàrá ẹ̀ sílẹ̀. Mo rò pé géèmù ni màá bá lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ Bíbélì ni mo bá a tó ń kà. Mo wá bi í pé kí ló ń ṣe, Jacob sọ pé, ‘Ọ̀dọ́ tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì lèmi náà, mo sì máa ka Bíbélì tán lọ́dún kan.’” Inú Ricky àti Kendra dùn gan-an, wọ́n láyọ̀ pé Ricky lè kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Warwick àti pé ọmọ wọn ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí ní ibi tí wọ́n wà yìí.—Òwe 22:6.

WỌN Ò ṢÀNÍYÀN NÍPA ỌJỌ́ Ọ̀LA

Luis àti Dale

Ilé tí wọ́n ń kọ́ ní ìlú Wallkill àti Warwick máa parí lọ́jọ́ kan, kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì fúngbà díẹ̀ yìí? Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin yìí ń ṣàníyàn nípa ibi tí wọ́n máa lọ tàbí ohun tí wọ́n á máa ṣe lẹ́yìn tí iṣẹ́ ìkọ́lé yìí bá parí? Rárá o! Jẹ́ ká gbọ́ ohun táwọn kan sọ. Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ John àti Carmen wá láti ìpínlẹ̀ Florida kí wọ́n lè yọ̀ǹda ara wọn fúngbà díẹ̀ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ń ṣe ní ìlú Warwick. Iṣẹ́ àwọn tó máa ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé ni John ń ṣe, òun àti ìyàwó rẹ̀ sì ti lé lẹ́ni àádọ́ta [50] ọdún. Àwọn méjèèjì sọ pé: “A ti fojú ara wa rí  bí Jèhófà ṣe ń pèsè àwọn ohun tá a nílò fún wa títí di àkókò yìí. Ó dá wa lóju pé Jèhófà ò ní mú wa wá síbi, kó sì pa wá tì nígbà tó bá yá.” Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lára ọ̀pọ̀ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé yìí nìyẹn. (Sm. 119:116) Luis àti ìyàwó rẹ̀ Quenia ń sìn ní ìlú Wallkill, Luis máa ń ṣe ẹ̀rọ tó máa ń tú omi jáde fúnra rẹ̀ tó bá rí i pé iná ń jó. Àwọn méjèèjì sọ pé: “A ti rí bí Jèhófà ṣe ń pèsè gbogbo ohun tí a nílò nípa tara. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì mọ ìgbà tí a máa ṣíwọ́ iṣẹ́ níbí, a ò sì tíì mọ ibi tí a máa lọ àti ohun tá a máa ṣe, ó dá wa lójú pé Jèhófà yóò máa bójú tó wa.”—Sm. 34:10; 37:25.

 ‘ÌBÙKÚN TÍTÍ KÌ YÓÒ FI SÍ ÀÌNÍ MỌ́’

John àti Melvin

Ọ̀pọ̀ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé ní ìpínlẹ̀ New York lè rí àwọn ìdí tí kò fi yẹ káwọn yọ̀ǹda ara àwọn. Àmọ́, wọ́n dán Jèhófà wò, torí Jèhófà sọ pé: “Ẹ sì jọ̀wọ́, dán mi wò, . . . bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.”—Mál. 3:10.

Ṣé ìwọ náà máa dán Jèhófà wò kó o sì rí i bí yóò ṣe bù kún ẹ? Fi ọ̀rọ̀ náà sí àdúrà, kó o sì ro ohun tó o lè ṣe kó o lè nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ New York tàbí àwọn ilé tí à ń lò fún ìjọsìn, kó o sì rí i bí Jèhófà yóò ṣe bù kún ẹ lọ́pọ̀lọpọ̀.—Máàkù 10:29, 30.

Gary

Ẹnjiníà ni Dale, ìpínlẹ̀ Alabama ni òun àti Cathy ìyàwó rẹ̀ ń gbé tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó wá sìn ní ìlú Wallkill. Àwọn méjèèjì dábàá pé káwọn míì náà wá ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí, wọ́n ní: “Tó o bá lo ìgboyà tó o sì kúrò nibi tó ti mọ́ ẹ lára, wàá láǹfààní láti rí i bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́.” Tó o bá fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ, kí ni wàá ṣe? Dale sọ pé: “Gbogbo ohun tó o ní láti ṣe kò ju pé kó o jẹ́ kí ohun tara díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn. O ò ní kàbàámọ̀ rẹ̀ láé!” Ẹlòmíì tún ni Gary àti ìyàwó rẹ̀ Maureen, ìpínlẹ̀ North Carolina, ni wọ́n ti wá sìn ní ìlú Warwick. Ó ti tó ọgbọ̀n [30] ọdún báyìí tí Gary ti ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé. Òun àti ìyàwó rẹ̀ sọ pé ọ̀kan lára ohun tó ń múnú àwọn dùn bí àwọn ṣe ń sìn ní Warwick ni báwọn “ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún sin Jèhófà ní Bẹ́tẹ́lì.” Gary sọ pé: “Tó o bá fẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, wàá jẹ́ kí ohun ìní tara díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn, ìyẹn sì ni ọ̀nà tó dáa jù téèyàn lè gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ nínú ayé yìí.” Jason àti ìyàwó rẹ̀ Jennifer wá láti ìpínlẹ̀ Illinois, Jason ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ mànàmáná. Jason àti ìyàwó rẹ̀ sọ bí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbi ìmúgbòòrò Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú Wallkill ṣe rí lára wọn, wọ́n ní: “Ó jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó máa jẹ́ kó o mọ bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú ayé tuntun.” Jennifer sọ pé: “Ayọ̀ ńlá ló jẹ́ pé Jèhófà mọyì gbogbo nǹkan tó ò ń ṣe àti pé àṣepamọ́ ni nǹkan tá à ń ṣe báyìí, a máa jèrè ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà máa rí i dájú pé ó jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”

^ ìpínrọ̀ 6 Wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà 2014, ojú ìwé 12 sí 13.

^ ìpínrọ̀ 7 Àwọn tó ń tilé wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì fúngbà díẹ̀ máa ń lo ọjọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti fi ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Àwọn fúnra wọn ni wọ́n máa ń sanwó ilé wọn àtàwọn ìnáwó míì.