Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  January 2015

Ìdí Tí A Fi Ń Lọ Síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

Ìdí Tí A Fi Ń Lọ Síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

“Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”1 KỌ́R. 11:24.

1, 2. Kí ni Jésù ṣe ní alẹ́ Nísàn ọjọ́ kẹrìnlá, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

NÍ ALẸ́ Nísàn ọjọ́ kẹrìnlá, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, òṣùpá mọ́lẹ̀ rokoṣo ní ìlú Jerúsálẹ́mù. Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ parí àjọyọ̀ Ìrékọjá ni. Wọ́n ṣèrántí ọjọ́ tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì ní ẹgbẹ̀rún ọdún kan ààbọ̀ sẹ́yìn. Nígbà tí ó ku Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tó jẹ́ adúróṣinṣin nìkan, Jésù dá àkànṣe oúnjẹ kan sílẹ̀. Èyí táá jẹ́ kí wọ́n máa rántí ikú tó máa kú kí ọjọ́ náà tó jálẹ̀. *Mát. 26:1, 2.

2 Jésù gbàdúrà ó sì gbé búrẹ́dì aláìwú náà fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ gbà, ẹ jẹ.” Ó tún mú ife kan tí wáìnì wà nínú rẹ̀, ó gbàdúrà, ó sì sọ pé: “Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín.” (Mát. 26:26, 27) Jésù kò tún gbé oúnjẹ míì fún wọn, àmọ́ ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó fẹ́ sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ lálẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé yẹn.

3. Àwọn ìbéèrè wo ni a máa rí ìdáhùn wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nítorí náà, ńṣe ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe Ìrántí Ikú òun, tí a tún ń pè ní “Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r.  11:20) Àwọn kan lè béèrè pé: Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe Ìrántí Ikú Jésù? Kí ni búrẹ́dì àti wáìní náà ń ṣàpẹẹrẹ? Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ dé Ìrántí Ikú Kristi? Ta ló yẹ kó jẹ, kó sì mu àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ? Ọwọ́ wo làwọn Kristẹni fi mú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìrètí tí Ọlọ́run fún wọn?

ÌDÍ TÁ A FI Ń RÁNTÍ IKÚ JÉSÙ

4. Kí ni ikú Jésù mú kó ṣeé ṣe fún wa?

4 Torí pé a jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù, a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12) Kò sí ẹ̀dá èèyàn aláìpé kankan tó lè san ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ àti tàwọn èèyàn tó kù fún Ọlọ́run. (Sm. 49:6-9) Àmọ́, Jésù fi ara àti ẹ̀jẹ̀ pípé rẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ san ìràpadà kan ṣoṣo tí Ọlọ́run tẹ́wọ́gbà. Bí Jésù ṣe gbé ìtóye ẹbọ ìràpadà náà lọ síwájú Ọlọ́run, ṣe ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ká sì láǹfààní láti gba ẹ̀bùn ìyè ayérayé.—Róòmù 6:23; 1 Kọ́r. 15:21, 22.

5. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run àti Kristi nífẹ̀ẹ́ aráyé? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa lọ síbi Ìrántí Ikú Jésù?

5 Ọlọ́run fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ aráyé bó ṣe pèsè ìràpadà náà. (Jòh. 3:16) Bí Jésù ṣe fi ara rẹ̀ rúbọ jẹ́ ẹ̀rí pé òun náà nífẹ̀ẹ́ wa. Kódà, nígbà tí Jésù jẹ́ “àgbà òṣìṣẹ́” fún Ọlọ́run kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé, ó ‘nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ènìyàn gan-an.’ (Òwe 8:30, 31) Bí a bá fẹ́ fi hàn pé a moore ohun tí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ ṣe fún wa, ó yẹ ká lọ síbi Ìrántí Ikú Jésù, èyí á sì fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa fún wa pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—1 Kọ́r. 11:23-25.

OHUN TÍ BÚRẸ́DÌ ÀTI WÁÌNÌ NÁÀ Ń ṢÀPẸẸRẸ

6. Ojú wo ló yẹ ká fi wo búrẹ́dì àti wáìnì tá à ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi?

6 Nígbà tí Jésù dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, kì í ṣe pé ó yí búrẹ́dì àti wáìnì náà pa dà di ẹran ara rẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́nà ìyanu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ nípa búrẹ́dì náà ni pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi.” Nígbà tó kan wáìnì náà, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Máàkù 14:22-24) Ó ṣe kedere nígbà náà pé ohun ìṣàpẹẹrẹ ló yẹ kí a ka búrẹ́dì àti wáìnì náà sí.

7. Kí ni búrẹ́dì tá à ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi ń ṣàpẹẹrẹ?

7 Ní ọjọ́ ayẹyẹ mánigbàgbé tó wáyé ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù lo búrẹ́dì tó ṣẹ́ kù nígbà tí wọ́n ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá. (Ẹ́kís. 12:8) Nígbà míì, Ìwé Mímọ́ máa ń lo ìwúkàrà láti fi ṣàpẹẹrẹ ìdíbàjẹ́ tàbí ẹ̀ṣẹ̀. (Mát. 16:6, 11, 12; Lúùkù 12:1) Ó gbàfiyèsí bí Jésù ṣe lo búrẹ́dì aláìwú, torí pé ó ṣàpẹẹrẹ ara pípé Jésù. (Héb. 7:26) Torí náà, irú búrẹ́dì yìí la máa ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi.

8. Kí ni wáìnì tá à ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi ń ṣàpẹẹrẹ?

8 Wáìnì tí Jésù lò ní Nísàn ọjọ́ kẹrìnlá, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ Jésù. Lọ́nà kan náà, wáìnì tá à ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi lónìí ń ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ Jésù. Lẹ́yìn òde ìlú Jerúsálẹ́mù, ibì kan wà níbẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Gọ́gọ́tà, ibẹ̀ ni wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ Jésù sílẹ̀ “fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” (Mát. 26:28; 27:33) Torí pé, búrẹ́dì àti wáìnì tá à ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi ń ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ṣeyebíye tí ó fi lélẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀dá onígbọràn, tí a sì mọrírì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa tìfẹ́tìfẹ́ yìí, ó bá a mu wẹ́kú pé ká múra sílẹ̀ fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún.

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÍ A LÈ GBÀ MÚRA SÍLẸ̀

9. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tó wà fún Ìrántí Ikú Kristi? (b) Báwo ni ìràpadà ṣe rí lára rẹ?

9 Tí a bá ń tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tó wà fún Ìrántí Ikú Kristi tó máa ń wà nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́, á jẹ́ ká  lè ṣàṣàrò lórí ohun tí Jésù ṣe ṣáájú ikú rẹ̀. Èyí sì máa jẹ́ ká lè múra ọkàn wa sílẹ̀ de Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. * Arábìnrin kan kọ̀wé pé: “Ó máa ń ṣe wá bíi pé kí Ìrántí Ikú Kristi tètè dé. Ọdọọdún ló máa ń ṣàrà ọ̀tọ̀ lára mi. Mo rántí . . . bí mo ṣe ń wo òkú bàbá mi ọ̀wọ́n níbi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí, èyí sì jẹ́ kí n dúpẹ́ fún àǹfààní ìràpadà tá a ní. . . . Lóòótọ́, mo mọ gbogbo Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa ìràpadà mo sì lè ṣàlàyé rẹ̀. Àmọ́, nígbà tí bàbá mi kú ni mo wá mọ ọṣẹ́ tí ikú ń ṣe fáwọn èèyàn. Ńṣe ni inú mi máa ń dùn tí mo bá ronú nípa ohun tí ìràpadà máa ṣe fún wa.” Torí náà, tá a bá ń múra sílẹ̀ dé Ìrántí Ikú Kristi, ó yẹ ká ronú lórí bí ẹbọ ìràpadà Jésù ṣe máa gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tó ń hàn wá léèmọ̀.

Lo àwọn ohun èlò tí ètò Ọlọ́run ti pèsè kó o lè múra ọkàn rẹ sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi (Wo Ìpínrọ̀ 9)

10. Ipa wo ni ìmúrasílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi lè ní lórí iṣẹ́ ìwàásù wa?

10 Lára ohun tá a lè fi kún ìwéwèé wa tá a bá ń múra sílẹ̀ de Ìrántí Ikú Kristi ni bá a ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. A lè gba aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi. Bá a ṣe ń pe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa àtàwọn míì sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, inú wa yóò máa dùn pé à ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ àtàwọn ìbùkún tó wà nípamọ́ fáwọn tó ń múnú Jèhófà dùn, tí wọ́n sì ń fìyìn fún un.—Sm. 148:12, 13.

11. Báwo làwọn ará kan ní Kọ́ríńtì ṣe jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa láìyẹ?

11 Bó o ṣe ń múra sílẹ̀ de Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ṣàyẹ̀wò ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ Kristẹni tó wà nílùú Kọ́ríńtì. (Ka 1 Kọ́ríńtì 11:27-34.) Pọ́ọ̀lù sọ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ nínú búrẹ́dì náà, tó sì mu wáìnì náà láìyẹ ti “jẹ̀bi nípa ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa,” ìyẹn Jésù Kristi. Torí náà, ẹnì kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ “tẹ́wọ́ gba ara rẹ̀ lẹ́yìn ìyẹ̀wò fínnífínní” kó tó di pé ó jẹ búrẹ́dì tó sì mu wáìnì náà. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni onítọ̀hún “ń jẹ, ó sì ń mu ìdájọ́ lòdì sí ara rẹ̀.” Nítorí ìwà ìbàjẹ́ àwọn ará Kọ́ríńtì, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ti di “aláìlera àti aláìsàn, tí àwọn púpọ̀ díẹ̀ sì ń sùn nínú ikú [nípa tẹ̀mí].” Ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú wọn ti jẹ àjẹyó tí wọ́n sì ti mu àmujù ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi tàbí nígbà tó ń lọ lọ́wọ́ tó fi jẹ́ pé wọn ò lè ronú dáadáa mọ́, wọn ò sì wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Ọlọ́run bínú sí wọn torí pé wọ́n jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà láìyẹ.

12. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù fi Ìrántí Ikú Kristi wé, ìkìlọ̀ wo ló sì fún àwọn tó ń jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa? (b) Kí ló yẹ kí ẹni tó ń jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ṣe tó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì?

 12 Pọ́ọ̀lù fi Ìrántí Ikú Kristi wé oúnjẹ kan téèyàn pe àwọn míì pé kí wọ́n wá jẹ níbẹ̀, ó wá kìlọ̀ fáwọn tó ń jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ náà pé: “Ẹ kò lè máa mu ife Jèhófà àti ife àwọn ẹ̀mí èṣù; ẹ kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jèhófà’ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.” (1 Kọ́r. 10:16-21) Tí ẹni kan tó máa ń jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, ó gbọ́dọ̀ wá ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí kó lè tún àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣe. (Ka Jákọ́bù 5:14-16.) Tí ẹni àmì òróró yìí bá “mú àwọn èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà” jáde, tí ó sì jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò bọ̀wọ̀ fún ẹbọ ìràpadà Jésù.—Lúùkù 3:8.

13. Kí nìdí tó fi máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ń fi ọ̀rọ̀ ìrètí tí Ọlọ́run fún wa sádùúrà?

13 Bí kálukú wa ti ń múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi, ó máa dáa ká fọ̀rọ̀ ìrètí tí Ọlọ́run fún wa sádùúrà. Ó dájú pé kò sí ìránṣẹ́ Jèhófà kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù tó máa jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ láì kì í ṣe pé ó dá a lójú pé òun wà lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé kò bọ̀wọ̀ fún ẹbọ ìràpadà Jésù nìyẹn. Torí náà, báwo lẹ́nì kan ṣe lè mọ̀ bóyá òun lè jẹ búrẹ́dì kó sì mu wáìnì nígbà Ìrántí Ikú Kristi tàbí òun ò lè ṣe bẹ́ẹ̀?

TA LÓ YẸ KÓ JẸ BÚRẸ́DÌ, KÓ SÌ MU WÁÌNÍ NÍGBÀ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI?

14. Báwo ni májẹ̀mú tuntun ṣe kan àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì nígbà Ìrántí Ikú Kristi?

14 Ó dá àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tó sì ń mu wáìnì nígbà Ìrántí Ikú Kristi lójú hán-ún hán-ún pé àwọn wà nínú májẹ̀mú tuntun. Jésù sọ nípa wáìnì náà pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi.” (1 Kọ́r. 11:25) Ọlọ́run mí sí wòlíì Jeremáyà láti sọ pé Òun máa dá májẹ̀mú tuntun kan tó máa yàtọ̀ sí májẹ̀mú Òfin tí òun dá pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ka Jeremáyà 31:31-34.) Ọlọ́run sì ti dá májẹ̀mú náà pẹ̀lú àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Gál. 6:15, 16) Ẹbọ ìràpadà Kristi ló fìdí májẹ̀mú tuntun yìí múlẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rúbọ. (Lúùkù 22:20) Jésù ni Alárinà májẹ̀mú tuntun náà. Àwọn adúróṣinṣin ẹni àmì òróró táwọn náà sì wà nínú májẹ̀mú náà gba ogún wọn ní ọ̀run.—Héb. 8:6; 9:15.

15. Àwọn wo ló wà nínú májẹ̀mú Ìjọba náà, àǹfààní wo ni wọ́n sì máa jẹ tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́?

15 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ń jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ náà lọ́nà tó yẹ ló mọ̀ pé àwọn wà nínú májẹ̀mú Ìjọba. (Ka Lúùkù 12:32.) Àwọn tó di ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù, tí wọ́n dúró tì í gbágbáágbá, tí wọ́n sì ṣàjọpín nínú àwọn ìjìyà rẹ̀ máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba ọ̀run. (Fílí. 3:10) Torí pé àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró wà nínú májẹ̀mú Ìjọba, wọ́n máa jọba pẹ̀lú Kristi lókè ọ̀run títí láé. (Ìṣí. 22:5) Nítorí ìdí èyí, wọ́n ń jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà lọ́nà tó yẹ.

16. Ní ṣókí ṣàlàyé ìtumọ̀ Róòmù 8:15-17.

16 Àwọn tí ẹ̀mí mímọ́ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wọn pé wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nìkan ló gbọ́dọ̀ jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ náà. (Ka Róòmù 8:15-17.) Èdè Árámáíkì ni gbólóhùn tí Pọ́ọ̀lù lò nígbà tó sọ pé “Ábà,” èyí tó túmọ̀ sí “Bàbá!” Ọmọ kan lè lo ọ̀rọ̀ Árámáíkì yìí tó bá ń bá bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀, torí pé ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ọmọ àti bàbá nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an, ó sì fọ̀wọ̀ fún bàbá náà. Àwọn tí Ọlọ́run sọ di ọmọ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ làwọn ti wọ́n gba “ẹ̀mí ìsọdọmọ.” Ẹ̀mí rẹ̀ jẹ́rìí  pẹ̀lú ẹ̀mí wọn, ní ti pé ó mú un dá wọn lójú pé ọmọ Jèhófà tó fẹ̀mí mímọ́ yàn ni wọ́n. Èyí kì í ṣe torí pé wọn kò fẹ́ gbé lórí ilẹ̀ ayé mọ́. Ó dá wọn lójú pé wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba ọ̀run tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ títí tí wọ́n fi kú. Lóde òní, kìkì àṣẹ́kù ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ọmọlẹ́yìn Jésù tí wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ ló “ní ìfòróróyàn láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́ náà,” ìyẹn Jèhófà. (1 Jòh. 2:20; Ìṣí. 14:1) Ipasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ ni wọ́n fi lè ké jáde pé, “Ábà, Baba!” Ẹ ò rí i pé àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run!

FỌWỌ́ PÀTÀKÌ MÚ ÌRÈTÍ TÍ ỌLỌRUN FÚN Ẹ

17. Ìrètí wo ni àwọn ẹni àmì òróró ní, ọwọ́ wo ni wọ́n sì fi mú un?

17 Tó o bá jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró, wàá máa fi ọ̀rọ̀ ìrètí ti ọ̀run tí Ọlọ́run fún ẹ ṣe kókó pàtàkì nínú àdúrà rẹ. Tó o bá ń ka Bíbélì, tó o sì kà á débi tó ti sọ pé wọ́n ‘fẹ́ àwọn kan sọ́nà’ fún Ọkọ ìyàwó tó wà ní ọ̀run, ìyẹn Jésù Kristi, wàá mọ̀ pé ẹsẹ Bíbélì yẹn kàn ẹ́, wàá sì máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí o máa di ara “ìyàwó” Kristi. (2 Kọ́r. 11:2; Jòh. 3:27-29; Ìṣí. 21:2, 9-14) Tí Ọlọ́run bá sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ tí òun fi ẹ̀mí yàn, wàá sọ nínú ara rẹ pé, “Èmi ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń bá sọ̀rọ̀.” Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá sì fún àwọn ọmọ tí Jèhófà fẹ̀mí yàn ní ìtọ́ni, ẹ̀mí mímọ́ máa mú kó o ṣègbọràn, kó o sì sọ lọ́kàn rẹ pé, “Ọ̀rọ̀ yìí kàn mí.” Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ ń jẹ́rìí pa pọ̀ pé o ní ìrètí ti ọ̀run.

18. Ìrètí wo làwọn “àgùntàn mìíràn” ní, báwo sì ni èyí ṣe rí lára rẹ?

18 Ní ìdàkejì, tó o bá wà lára “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àgùntàn mìíràn,” Ọlọ́run ti fún ẹ ní ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣí. 7:9; Jòh. 10:16) Ó dájú pé ó wù ẹ́ kó o gbé nínú Párádísè títí láé, o sì ń láyọ̀ bó o ṣe ń ṣàṣàrò lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Ò ń retí ìgbà tí àlàáfíà máa jọba lórí ilẹ̀ ayé, tí wàá rí àwọn ẹ̀bi rẹ àtàwọn olódodo èèyàn níbikíbi tó o bá yíjú sí. Ǹjẹ́ ò ń fayọ̀ retí ìgbà tí kò ní sí àìtó oúnjẹ mọ́, tí àwọn èèyàn ò ní tòṣì mọ́, tí ìyà ò ní jẹ àwọn èèyàn mọ́, tí àìsàn àti ikú tó ń han aráyé léèmọ̀ kò ní sí mọ́? (Sm. 37:10, 11, 29; 67:6; 72:7, 16; Aísá. 33:24) Ǹjẹ́ ara rẹ kò ti wà lọ́nà láti rí àwọn tí yóò jíǹde tí wọ́n sì nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé? (Jòh. 5:28, 29) Ó dájú pé ò ń dúpẹ́ pé Jèhófà fi ìrètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé jíǹkí rẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò ní jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà, wàá lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi kó lè fi hàn pé o mọyì ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi.

ṢÉ O MÁA WÁ?

19, 20. (a) Báwo ni ìrètí tí Ọlọ́run yàn fún ẹ ṣe lè tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́? (b) Kí nìdí tí wàá fi lọ síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?

19 Yálà orí ilẹ̀ ayé ni ìrètí rẹ tàbí òkè ọ̀run, o ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run, Jésù Kristi àti ìràpadà náà kí ìrètí yìí tó lè tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́. Tó o bá lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi, wàá láǹfààní láti ronú lórí ìrètí tí Ọlọ́run fún ẹ àti bí ikú Jésù ti ṣe pàtàkì tó. Torí náà, pinnu pé o máa wà lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó máa wà níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní ọjọ́ Friday, April 3, 2015, láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà kárí ayé àti láwọn ibòmíì.

20 O lè túbọ̀ mọyì ẹbọ ìràpadà Jésù tó o bá lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Tó o bá tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí àsọyé náà, èyí á mú kó wù ẹ́ láti sọ ohun tó o ti kọ́ nípa ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún aráyé àti ohun tó pinnu láti ṣe fáwọn èèyàn, èyí á sì fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. (Mát. 22:34-40) Rí i dájú pé o lọ síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.

^ ìpínrọ̀ 1 Ìrọ̀lẹ́ sí ìrọ̀lẹ́ ni àwọn Hébérù máa ń ka ọjọ́ wọn.

^ ìpínrọ̀ 9 Wo Àfikún Àlàyé B12 tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 2013 lédè Gẹ̀ẹ́sì.