Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  September 2014

Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀ Láìka “Ọ̀pọ̀ Ìpọ́njú” Sí

Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀ Láìka “Ọ̀pọ̀ Ìpọ́njú” Sí

“A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.”—ÌṢE 14:22.

1. Kí nìdí tí kò fi jẹ́ ìyàlẹ́nu fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n bá dojú kọ ìpọ́njú?

ǸJẸ́ kò já ẹ láyà pé o lè dojú kọ “ọ̀pọ̀ ìpọ́njú” kó o tó lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun? Ó ṣeé ṣe kí àyà ẹ máà já. Yálà o ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni o tàbí ó ti pẹ́ tó o ti ń sin Jèhófà, o mọ̀ pé ìnira jẹ́ ara ohun tá à ń dojú kọ nínú ayé Sátánì.—Ìṣí. 12:12.

2. (a) Yàtọ̀ sí ìṣòro tó ń bá gbogbo ẹ̀dá èèyàn aláìpé fínra, ìpọ́njú wo làwọn Kristẹni ń dojú kọ? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Ta ló wà nídìí inúnibíni tó ń dojú kọ wá yìí, báwo la sì ṣe mọ̀?

2 Yàtọ̀ sáwọn ìṣòro tó “wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn,” ìyẹn àwọn ìṣòro tó máa ń dé bá gbogbo èèyàn aláìpé, àwọn Kristẹni tún ń dojú kọ ìpọ́njú kan tó yàtọ̀. (1 Kọ́r. 10:13) Irú ìpọ́njú wo nìyẹn? Èyí ni inúnibíni tó le koko tí wọ́n ń dojú kọ torí pé wọ́n ń ṣègbọràn sáwọn òfin Ọlọ́run tọkàntọkàn. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòh. 15:20) Ta ló wà nídìí inúnibíni yìí? Kò sí ẹlòmíì ju Sátánì lọ, ẹni tí Bíbélì ṣàpèjúwe pé ó jẹ́ “kìnnìún tí ń ké ramúramù,” tó ń ‘wá ọ̀nà láti pa’ àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ. (1 Pét. 5:8) Sátánì á pa gbogbo itú tó bá lè pa kó lè ba ìwà títọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù jẹ́. Jẹ́ ká jíròrò ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.

 ÌPỌ́NJÚ NÍLÙÚ LÍSÍRÀ

3-5. (a) Ìpọ́njú wo ni Pọ́ọ̀lù dojú kọ ní Lísírà? (b) Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìpọ́njú tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú ṣe lè fúnni lókun?

3 Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí wọ́n ṣenúnibíni sí Pọ́ọ̀lù nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. (2 Kọ́r. 11:23-27) Ọ̀kan ṣẹlẹ̀ nílùú Lísírà. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù wo ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní arọ sàn, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kókìkí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pé òrìṣà ni wọ́n. Ńṣe làwọn méjèèjì ní láti bẹ àwọn èrò tó ń fò fáyọ̀ yìí pé kí wọ́n má ṣe jọ́sìn àwọn. Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn táwọn Júù alátakò dé, wọ́n sì ba Pọ́ọ̀lù àti Bánábà jẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Lísírà. Bìrí ni nǹkan yí pa dà! Làwọn èèyàn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta títí tí wọ́n fi rò pé ó ti kú.—Ìṣe 14:8-19.

4 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kúrò ní Débè, “wọ́n padà sí Lísírà àti Íkóníónì àti sí Áńtíókù, wọ́n ń fún ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun, wọ́n ń fún wọn ní ìṣírí láti dúró nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì wí pé: ‘A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.’” (Ìṣe 14:21, 22) Gbólóhùn yẹn lè kọ́kọ́ yani lẹ́nu. Ó ṣe tán, èrò pé èèyàn máa dojú kọ “ọ̀pọ̀ ìpọ́njú” lè mú kí nǹkan súni tàbí kí ó kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni. Báwo ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe “fún ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun” nígbà tí wọ́n sọ fún wọn pé wọ́n máa ní láti kojú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú?

5 A máa rí ìdáhùn tá a bá fara balẹ̀ wo ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ. Ẹ kíyè sí i pé kò kàn sọ pé: “A gbọ́dọ̀ fara da ọ̀pọ̀ ìpọ́njú.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.” Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù fún ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun bó ṣe sọ̀rọ̀ nípa ohun rere tó máa yọrí sí téèyàn bá jẹ́ olóòótọ́. Èrè tó máa tìdí rẹ̀ wá kì í ṣe ọ̀rọ̀ àlá lásán. Kódà, Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”Mát. 10:22.

6. Èrè wo làwọn tó bá fara dà á máa gbà?

6 Tá a bá fara dà á, a máa gba èrè. Ní ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, Jèhófà máa fi àìleèkú san èrè fún wọn lókè ọ̀run, wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù. Ní ti àwọn “àgùntàn mìíràn,” wọ́n máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé níbi tí “òdodo yóò . . . máa gbé.” (Jòh. 10:16; 2 Pét. 3:13) Àmọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, a máa dojú kọ ọ̀pọ̀ ìpọ́njú kó tó dìgbà yẹn. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò irú ìpọ́njú méjì tá a lè dojú kọ.

SÁTÁNÌ Ń GBÉJÀ KÒ WÁ NÍ TÀÀRÀTÀ

7. Irú ìpọ́njú wo ni Sátánì ń gbé kò wá ní tààràtà?

7 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn yóò fà yín lé àwọn kóòtù àdúgbò lọ́wọ́, wọn yóò sì lù yín nínú àwọn sínágọ́gù, a ó sì fi yín sórí àpótí ìdúrórojọ́ níwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba.” (Máàkù 13:9) Bá a ṣe rí i nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ìpọ́njú àwọn Kristẹni míì lè yọrí sí pé kí wọ́n fìyà jẹ wọ́n. Nígbà míì ó lè jẹ́ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tàbí àwọn olóṣèlú ló máa ṣokùnfà irú inúnibíni bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 5:27, 28) Ẹ jẹ́ ká tún pa dà sí àpẹẹrẹ ti Pọ́ọ̀lù. Ǹjẹ́ ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà á torí pé wọ́n lè ṣenúnibíni sí i? Rárá o.—Ka Ìṣe 20:22, 23.

8, 9. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun ti pinnu láti fara dà á, báwo sì làwọn kan lóde òní ṣe dúró lórí irú ìpinnu kan náà?

8 Pọ́ọ̀lù kò jẹ́ kí ẹ̀rù ba òun nígbà tí Sátánì gbéjà kò ó ní tààràtà, ó sọ pé: “Èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan kan tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, bí mo bá sáà ti lè parí ipa ọ̀nà mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:24) Ó ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àyà rẹ̀ ò já torí pé inúnibíni ń bọ̀ wá dé bá a. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pinnu láti fara dà á, láìka ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sí. Ohun tó jẹ ẹ́ lógún jù lọ ni pé kó “jẹ́rìí kúnnákúnná” láìka ìpọ́njú èyíkéyìí sí.

9 Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa náà ti ṣe irú ìpinnu  yìí. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè kan, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún ọdún táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ti wà lẹ́wọ̀n torí pé wọn ò dá sí ogun tàbí ọ̀ràn ìṣèlú. Wọn ò tiẹ̀ gbé ọ̀ràn wọn délé ẹjọ́ rárá, torí orílẹ̀-èdè náà ò ṣe òfin kankan lórí ọ̀ràn àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun. Wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni, tó fi mọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn, lọ wò wọ́n lẹ́wọ̀n. Wọ́n na àwọn míì lára àwọn tó wà lẹ́wọ̀n, wọ́n sì fi oríṣiríṣi ìyà jẹ wọ́n.

10. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ẹ̀rù bà wá tí ìpọ́njú bá dé lójijì?

10 Láwọn ibòmíì, àwọn ará wa máa ń fara da àwọn ìpọ́njú tó bẹ̀rẹ̀ lójijì. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, má ṣe jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́. Wo àpẹẹrẹ Jósẹ́fù. Wọ́n tà á sóko ẹrú ní Íjíbítì, àmọ́ Jèhófà “dá a nídè kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.” (Ìṣe 7:9, 10) Jèhófà lè dá ìwọ náà nídè kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ. Má ṣe gbàgbé pé “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.” (2 Pét. 2:9) Ṣé wàá máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nìṣó, bó o ṣe mọ̀ pé ó lè dá ẹ nídè nínú ètò nǹkan búburú yìí kó sì jẹ́ kó o ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú Ìjọba rẹ̀? Kò sídìí tí kò fi yẹ kó o gbẹ́kẹ̀ lé e, kó o sì jẹ́ onígboyà nígbà tí inúnibíni bá dé.—1 Pét. 5:8, 9.

SÁTÁNÌ Ń GBÉJÀ KÒ WÁ LỌ́NÀ ỌGBỌ́N Ẹ̀WẸ́

11. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àtakò tí Sátánì ń gbé kò wà ní tààràtà àtèyí tó ń ṣe lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́?

11 Sátánì tún máa ń gbéjà kò wá lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́. Báwo ni èyí ṣe yàtọ̀ sí àtakò tí Sátánì ń ṣe sí wa ní tààràtà tó máa ń yọrí sí inúnibíni? Àtakò tààràtà dà bí ìgbà tí ìjì líle bá jà ní ìlú kan tó sì ba àwọn ilé ibẹ̀ jẹ́ lójú ẹsẹ̀. Àtakò ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ní tiẹ̀ dà bí ìgbà tí ikán rọra ń jẹ igi òrùlé ilé kan díẹ̀díẹ̀ títí òrùlé náà á fi wó lulẹ̀. Èèyàn tiẹ̀ lè má fura títí nǹkan á fi bà jẹ́ tán.

12. (a) Kí ni ọ̀kan lára ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì máa ń lò, kí sì nìdí tó fi ń rí i lò dáadáa? (b) Ọ̀nà wo ni ìrẹ̀wẹ̀sì gbà bá Pọ́ọ̀lù?

12 Sátánì lè lo àtakò tààràtà tó máa ń yọrí sí inúnibíni tàbí kó lo àtakò ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ láti máa fi jin ìgbàgbọ́ rẹ lẹ́sẹ̀ díẹ̀díẹ̀, ohun tó fẹ́ ṣe ni pé kó ba àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ọ̀kan lára ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì ń rí lò jù lọ ni ìrẹ̀wẹ̀sì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí sí i pé àwọn nǹkan kan ti mú kí òun rẹ̀wẹ̀sì láwọn ìgbà kan. (Ka Róòmù 7:21-24.) Kí wá nìdí tí Pọ́ọ̀lù, ẹni tá a mọ̀ sí akọni nípa tẹ̀mí, tó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, fi pe ara rẹ̀ ní “abòṣì ènìyàn”? Pọ́ọ̀lù sọ pé àìpé òun ló mú kóun ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Ó wù ú gan-an pé kó máa ṣe ohun tí ó tọ́, àmọ́ ó kíyè sí i pé nǹkan míì wà tó ń ta ko ohun rere tóun fẹ́ ṣe. Tí irú ohun tá a sọ yìí bá ń ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ǹjẹ́ kò tù ẹ́ nínú láti mọ̀ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá dojú kọ irú ìṣòro yìí?

13, 14. (a) Kí ló fà á táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan fi rẹ̀wẹ̀sì? (b) Ta ló fẹ́ bi ìgbàgbọ́ wa wó, kí sì nìdí?

13 Nígbà míì, ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin ni wọ́n máa ń sọ pé ìrẹ̀wẹ̀sì mú àwọn tàbí kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn tàbí kó tiẹ̀ máa ṣe wọ́n bíi pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, aṣáájú-ọ̀nà kan tó ní ìtara tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Deborah sọ pé: “Mo sábà máa ń rántí àṣìṣe kan tí mo ti ṣe sẹ́yìn lọ́pọ̀ ìgbà, ó sì máa ń kó ìbànújẹ́ bá mi nígbàkigbà tí mo bá rántí. Tí mo bá ń ronú lórí gbogbo àṣìṣe tí mo ti ṣe, ńṣe ló máa ń jẹ́ kí n wò ó pé kò sẹ́nì kankan tó lè fẹ́ràn mi mọ́ láyé yìí, Jèhófà gan-an ò lè fojúure wò mí.”

14 Bíi ti Deborah, kí ló lè fà á tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi ń mú àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ń fìtara sìn ín? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè fà á. Ojú táwọn kan fi ń wo ara wọn àti ipò tí wọ́n bá ara wọn nígbèésí ayé lè burú jáì.  (Òwe 15:15) Àìlera tó ń bá àwọn míì fínra ló fa èrò òdì tó ń kó ìbànújẹ́ bá wọn. Ohun yòówù kó fà á, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ẹni tó fẹ́ ká máa ro èrò òdì yẹn. Ká sòọ́tọ́, ta ló fẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú wa débi tá a fi máa sọ̀rètí nù? Ta ló fẹ́ kí àjálù ńlá tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí òun máa já ìwọ náà láyà? (Ìṣí. 20:10) Ta ni ì bá tún jẹ́ bí kò ṣe Sátánì. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, yálà Sátánì gbéjà kò wá ní tààràtà tàbí kó lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ohun tó ń fẹ́ ni pé kí ó kó ìdààmú bá wa, ká rẹ̀wẹ̀sì, ká sì ṣíwọ́ sísin Jèhófà. Mọ̀ dájú pé àwọn èèyàn Jèhófà ń ja ogun tẹ̀mí, kí wọ́n lè pa ìwà títọ́ wọn sí Jèhófà mọ́!

15. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ò ní jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì borí wa?

15 Pinnu pé o kò ní juwọ́ sílẹ̀ nínú ogun tẹ̀mí yìí. Tẹjú mọ́ èrè náà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Àwa kò juwọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro, dájúdájú, ẹni tí àwa jẹ́ ní inú ni a ń sọ dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́. Nítorí bí ìpọ́njú náà tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, tí ó sì fúyẹ́, fún àwa, ó ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ògo tí ó jẹ́ ti ìwọ̀n títayọ síwájú àti síwájú sí i, tí ó sì jẹ́ àìnípẹ̀kun.”—2 Kọ́r. 4:16, 17.

MÚRA SÍLẸ̀ NÍSINSÌNYÍ DE ÌPỌ́NJÚ

Àwọn Kristẹni lọ́mọdé lágbà tí kọ́ bí wọ́n ṣe lè gbèjà ìgbàgbọ́ wọn (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká múra sílẹ̀ de ìpọ́njú nísinsìnyí?

16 A ti rí i pé, “àwọn ètekéte” wà lóríṣiríṣi lọ́wọ́ Sátánì. (Éfé. 6:11) Nítorí náà, ó yẹ kí olúkúlùkù wa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Pétérù 5:9, ó ní: “Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.” Ká lè ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti múra ọkàn àti èrò wa sílẹ̀, ká lè kọ́ ara wa nísinsìnyí láti máa ṣe ohun tí ó tọ́. Ẹ jẹ́ ká ṣe àpèjúwe rẹ̀ báyìí: Àwọn sójà sábà máa ń ṣe ìdánrawò aláṣelàágùn ṣáájú kí ogun tiẹ̀ tó dé rárá. Bọ́rọ̀ àwọn ọmọ ogun tẹ̀mí ti Jèhófà náà ṣe rí nìyẹn. A ò mọ bí ogun náà ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú. Nítorí náà, ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu pé ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe  ìdánrawò nígbà tí àlàáfíà díẹ̀ ṣì wà báyìí? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.”—2 Kọ́r. 13:5.

17-19. (a) Àwọn ọ̀nà wo la lè máa gbà wádìí ara wa wò? (b) Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè múra sílẹ̀ kí wọ́n lè gbèjà ohun tí wọ́n gbà gbọ́ níléèwé?

17 Ọ̀nà kan tá a lè gbà tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ yìí ni pé ká wádìí ara wa wò dáadáa. Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé mo máa ń gbàdúrà nígbà gbogbo? Tí mo bá dojú kọ ìdẹwò láti ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe, kàkà kí n ṣègbọràn sí èèyàn ṣé mo ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run tó jẹ́ alákòóso? Ṣé mo máa ń lọ sípàdé ìjọ déédéé? Ṣé mo lè sọ ohun tí mo gbà gbọ́ láìbẹ̀rù? Ǹjẹ́ mo máa ń gbójú fo àṣìṣe àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, bí wọ́n ṣe máa ń gbójú fo àṣìṣe tèmi náà? Ǹjẹ́ mò ń tẹrí ba fún àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ àtàwọn tó ń bójú tó gbogbo ìjọ tó wà kárí ayé?’

18 Kíyè sí i pé méjì nínú ìbéèrè yìí dá lórí bá a ṣe lè sọ ohun tá a gbà gbọ́ láìbẹ̀rù àti bí a ò ṣe ní gbà kí àwọn èèyàn mú ká ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ wa ló sábà máa ń dojú kọ ìṣòro yìí níléèwé. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ojú tì wọ́n tàbí kí wọ́n bẹ̀rù láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù. A ti gbé àwọn àbá tó lè ṣèrànwọ́ jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn wa. Bí àpẹẹrẹ, Jí! July 2009 dábàá pé tí ọmọléèwé kan bá béèrè pé: “Kí nìdí tó ò fi gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́?” o kàn lè dá a lóhùn pé: “Kí nìdí tí mo fi gbọ́dọ̀ gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó sọ pé ara ẹranko la ti wá gbọ́? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tó yẹ kí wọ́n jẹ́ ògbógi gan-an ò fẹnu kò lórí ẹ̀, ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni kí n wá gbà gbọ́!” Ẹ̀yin òbí, ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń ṣe ìdánrawò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín kí wọ́n bàa lè mọ bí wọ́n ṣe máa fèsì táwọn ọmọléèwé wọn bá bi wọ́n ní irú ìbéèrè yìí.

19 Ká sòótọ́, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti sọ ohun tá a gbà gbọ́ tàbí láti ṣe ohun tí Jèhófà sọ pé ká ṣe. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tá a ti ṣiṣẹ́ lọ látàárọ̀, ó lè jẹ́ pé ńṣe la máa rọ́jú lọ sípàdé torí pé ó ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu. Nígbà míì, kì í rọrùn láti jí láàárọ̀ ká sì lọ sóde ẹ̀rí, àmọ́ a máa ń fi oorun du ara wa torí ká lè lọ. Má gbàgbé pé tó bá ti mọ́ ẹ lára láti máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, tí ìṣòro tó ga bá dé lọ́jọ́ iwájú, á rọrùn fún ẹ láti borí wọn.

20, 21. (a) Báwo ni ríronú lórí ìràpadà ṣe lè jẹ́ ká borí ìrẹ̀wẹ̀sì? (b) Tó bá dọ̀rọ̀ ìpọ́njú, kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

20 Kí la máa ṣe tí Sátánì bá gbéjà kò wá lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́? Bí àpẹẹrẹ, báwo la ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì? Ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tá a lè ṣe ni pé ká fara balẹ̀ ronú lórí ìràpadà. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe nìyẹn. Nígbà míì ó máa ń ṣe é bíi pé ó jẹ́ abòṣì èèyàn, ìyẹn ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, lẹ́sẹ̀ kan náà, ó mọ̀ pé kì í ṣe àwọn ẹni pípé ni Jésù kú fún, bí kò ṣe, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Pọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí. Kódà, ó kọ̀wé pé: “Mo ń gbé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi, tí ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gál. 2:20) Pọ́ọ̀lù mọrírì ìràpadà. Ó mọ̀ pé ìràpadà náà dìídì ṣiṣẹ́ fún òun.

21 Tí ìwọ náà bá ń wo ìràpadà bí ẹ̀bùn tí Jèhófà dìídì fún ẹ, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Àmọ́, èyí ò sọ pé ìrẹ̀wẹ̀sì máa pòórá lójú ẹsẹ̀ o. Dé ìwọ̀n àyè kan, ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú wa máa dojú kọ àtakò tí Sátánì ń gbé kò wá lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ títí ayé tuntun fi máa dé. Àmọ́ má gbàgbé pé: Àwọn tí kò bá juwọ́ sílẹ̀ ló máa gba èrè náà. Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, a ti sún mọ́ ọjọ́ ológo náà tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí àlàáfíà jọba, táá sì mú kí gbogbo olóòótọ́ èèyàn pa dà di ẹ̀dá pípé. Torí náà, pinnu pé wàá wọ Ìjọba Ọlọ́run, ì báà tiẹ̀ jẹ́ nínú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú.