Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  September 2014

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 37:25 àti èyí tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:33 túmọ̀ sí pé Jèhófà kò ní jẹ́ kí Kristẹni kan ṣàìní oúnjẹ tí ó tó?

Dáfídì sọ pé òun “kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” Ohun tí Dáfídì ti rí ló mú kó sọ ohun tó sọ yìí. Ó mọ̀ dáadáa pé Ọlọ́run máa ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà gbogbo. (Sm. 37:25) Àmọ́, ọ̀rọ̀ Dáfídì yìí ò túmọ̀ sí pé kò sí ohunkóhun tó máa wọ́n ìránṣẹ́ Jèhófà, kò sì túmọ̀ sí pé kò ṣẹlẹ̀ rí kí nǹkan wọ́n ìránṣẹ́ Jèhófà.

Àwọn ìgbà kan wà tí nǹkan nira fún Dáfídì gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó ń sá kiri kí Sọ́ọ̀lù má bàa pa á. Oúnjẹ Dáfídì ti ń tán lọ, ló bá ní kí ẹnì kan fún òun ní búrẹ́dì tí òun àtàwọn tó wà pẹ̀lú òun máa jẹ. (1 Sám. 21:1-6) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé ṣe ni Dáfídì ń “wá oúnjẹ kiri.” Síbẹ̀ nínú ipò tó wà yẹn, ó mọ̀ pé Jèhófà kò pa òun tì. Kókó ibẹ̀ ni pé, kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti sọ pé Dáfídì ń tọrọ oúnjẹ kiri kó tó rí oúnjẹ jẹ.

Nínú Mátíù 6:33, Jésù jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa pèsè ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nílò fún wọn tí wọ́n bá fi ire Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí [títí kan oúnjẹ, ohun mímu àti aṣọ] ni a ó sì fi kún un fún yín.” Àmọ́ Jésù tún sọ pé ebi lè pa àwọn “arákùnrin” òun torí inúnibíni. (Mát. 25:35, 37, 40) Ó sì ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àwọn ìgbà kan wà tí kò rí oúnjẹ jẹ, kò sì rí omi mu.—2 Kọ́r. 11:27.

Jèhófà sọ fún wa pé wọ́n lè ṣe inúnibíni sí wa lónírúurú ọ̀nà. Jèhófà lè fàyè gbà á pé ká ṣe aláìní àwọn nǹkan kan ká lè fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Èṣù fi kan ọmọ aráyé. (Jóòbù 2:3-5) Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni bíi tiwa, irú bí àwọn tí wọ́n fi sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nígbà ìṣàkóso Hitler, wà nínú ewu torí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wọn. Ọ̀kan lára ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí wọ́n dá káwọn Ẹlẹ́rìí bàa lè sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn ni bí wọn ò ṣe fún wọn ní oúnjẹ tí ó tó. Àwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ jẹ́ onígbọràn sí Jèhófà; kò sì ta wọ́n nù. Ó fàyè gbà á kí wọ́n dojú kọ inúnibíni yìí, bó ṣe fàyè gbà á kí gbogbo Kristẹni dojú kọ onírúurú inúnibíni. Síbẹ̀, Jèhófà máa ń ran gbogbo àwọn tó jìyà nítorí orúkọ rẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n lè fara dà á. (1 Kọ́r. 10:13) Ó yẹ ká fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú Fílípì 1:29 sọ́kàn, ó ní: “Ẹ̀yin ni a fún ní àǹfààní náà nítorí Kristi, kì í ṣe láti ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.”

Jèhófà ṣèlérí pé òun ò ní fi àwọn ìránṣẹ́ òun sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Aísáyà 54:17 sọ pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.” Ìlérí yìí àtàwọn míì tó wà nínú Bíbélì jẹ́ kó dájú pé Ọlọ́run á máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀. Àmọ́ o, Kristẹni kan lè dojú kọ àdánwò, kódà ó lè yọrí sí ikú.