Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun Asán

Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun Asán

“Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.”—1 KỌ́R. 15:26.

1, 2. Báwo ni ipò nǹkan ṣe rí fún Ádámù àti Éfà nígbà tí Ọlọ́run dá wọn, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?

NÍGBÀ tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, wọn ò ní ọ̀tá kankan rárá. Ẹ̀dá pípé ni wọ́n, inú párádísè ni wọ́n sì ń gbé. Wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn, bí ọmọ ni wọ́n jẹ́ sí i. (Jẹ́n. 2:7-9; Lúùkù 3:38) Irú ìgbé ayé tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n máa gbé ṣe kedere nínú iṣẹ́ tó gbé fún wọn. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:28.) Wọ́n lè “kún ilẹ̀ ayé, kí [wọ́n] sì ṣèkáwọ́ rẹ̀” láàárín àkókò kan pàtó. Àmọ́ tí Ádámù àti Éfà bá máa ‘jọba lórí olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé,’ wọ́n gbọ́dọ̀ máa wà láàyè títí láé. Kò ní sí pé ikú ṣí Ádámù lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe rẹ̀.

2 Àmọ́, kí nìdí tí nǹkan fi wá yí pa dà? Báwo ló ṣe wá di pé aráyé ní ọ̀pọ̀ ọ̀tá tó ń dínà ayọ̀ wọn, àgàgà ikú tó jẹ́ ọ̀tá tó burú jù lọ? Kí ni Ọlọ́run máa ṣe kó lè sọ àwọn ọ̀tá yìí di asán? A lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè míì tó jẹ mọ́ ọ̀ràn yìí nínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì yẹn.

 ÌKÌLỌ̀ ONÍFẸ̀Ẹ́

3, 4. (a) Àṣẹ wo ni Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà? (b) Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n ṣègbọ́ràn sí àṣẹ yẹn?

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà láǹfààní láti máa wà láàyè títí láé, wọn kì í ṣe ẹ̀dá tí kò lè kú. Kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó, wọ́n gbọ́dọ̀ máa mí, kí wọ́n máa jẹun, kí wọ́n máa mu, kí wọ́n sì máa sùn. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, wọ́n gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Olùfúnni-ní-ìyè wọn tí wọ́n bá fẹ́ máa wà láàyè nìṣó. (Diu. 8:3) Tí wọ́n bá fẹ́ máa gbádùn ìgbésí ayé wọn nìṣó, wọ́n gbọ́dọ̀ gbà kí Ọlọ́run máa tọ́ wọn sọ́nà. Jèhófà mú kí èyí ṣe kedere sí Ádámù kódà kí Éfà tó dé. Lọ́nà wo? Bíbélì sọ pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù Jèhófà Ọlọ́run sì gbé àṣẹ yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin náà pé: ‘Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.’”—Jẹ́n. 2:16, 17.

4 “Igi ìmọ̀ rere àti búburú” dúró fún ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti pinnu ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Èyí ò ṣàjèjì sí Ádámù torí pé ó mọ ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́; Ọlọ́run dá a ní àwòrán ara rẹ̀, ó sì ní ẹ̀rí ọkàn. Igi náà máa jẹ́ kí Ádámù àti Éfà mọ̀ pé wọ́n nílò ìtọ́sọ́nà Jèhófà nígbà gbogbo. Tí wọ́n bá jẹ èso yẹn, ohun tí wọ́n ń fi ìyẹn sọ ni pé, bó ṣe wu àwọn làwọn fẹ́ máa ṣe, èyí sì máa fa ìṣòro ńlá bá àwọn àti àwọn ọmọ tí wọ́n máa bí. Òfin tí Ọlọ́run fún wọn àti ìyà tó sọ pé wọ́n máa jẹ tí wọ́n bá rú òfin náà jẹ́ ká mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe tóbi tó.

OHUN TÓ FA IKÚ FÚN ÌRAN ÈÈYÀN

5. Báwo ló ṣe di pé Ádámù àti Éfà hùwà àìgbọràn?

5 Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Éfà, Ádámù sọ òfin Ọlọ́run fún un. Éfà mọ òfin náà dáadáa, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má fi ìkan pe méjì nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa òfin náà. (Jẹ́n. 3:1-3) Ó sọ ọ́ fẹ́nì kan tó fara hàn án ní àwọ̀ ejò tí ó jẹ́ ẹ̀dá oníṣọ̀ọ́ra. Sátánì Èṣù, ìyẹn ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ló lo ejò náà láti bá Éfà sọ̀rọ̀. Ẹ̀dá ẹ̀mí yìí fẹ́ wà lómìnira, ó sì fẹ́ di apàṣẹwàá. (Fi wé Jákọ́bù 1:14, 15.) Kọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ ohun tó ń wá, ó fẹ̀sùn kan Ọlọ́run. Ó fi dá Éfà lójú pé tó bá lómìnira láti ṣe ohun tó wù ú, kò ní yọrí sí ikú láéláé, ó ní ṣe ló máa dà bí Ọlọ́run. (Jẹ́n. 3:4, 5) Éfà gbà á gbọ́, òun náà fẹ́ wà lómìnira, torí náà, ó jẹ èso náà, ó sì tún rọ Ádámù láti jẹ nínú rẹ̀. (Jẹ́n. 3:6, 17) Èṣù ti pa irọ́ fún wọn. (Ka 1 Tímótì 2:14.) Síbẹ̀, Ádámù “fetí sí ohùn aya rẹ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì Èṣù tó lo ejò náà ṣe bí ọ̀rẹ́, àmọ́ ọ̀tá aláìláàánú yìí mọ ìṣòro ńlá tí ọ̀rọ̀ tó sọ fún Éfà máa kó o sí.

6, 7. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣèdájọ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ náà?

6 Torí àǹfààní tara wọn, Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹni tó dá wọn sáyé, tó sì fún wọn ní gbogbo nǹkan tí wọ́n ní. Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ pátá ni Jèhófà rí. (1 Kíró. 28:9; ka Òwe 15:3.) Àmọ́, ó gba àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láyè láti fi bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ òun tó hàn. Láìsí àní-àní, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí dún Jèhófà tó jẹ́ bàbá wọn gan-an ni. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 6:6.) Abájọ tí Jèhófà fi di Adájọ́, ní ti pé ó mú ọ̀rọ̀ tó sọ ṣẹ pé àbájáde rẹ̀ kò ní dára tí Ádámù àti Éfà bá ṣàìgbọràn.

7 Ọlọ́run ti sọ fún Ádámù tẹ́lẹ̀ pé: “Ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” Ó ṣeé ṣe kí Ádámù rò pé “ọjọ́” oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ni Ọlọ́run ní lọ́kàn. Lẹ́yìn tí wọ́n rú òfin Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe kó máa rò pé Jèhófà máa pa àwọn kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó ṣú.  Àmọ́ ó bá tọkọtaya náà sọ̀rọ̀ ní “ìgbà tí atẹ́gùn máa ń fẹ́ yẹ́ẹ́ ní ọjọ́.” (Jẹ́n. 3:8) Ó pè wọ́n wá jẹ́jọ́, ó sì gbọ́ tẹnu Ádámù àti Éfà kó lè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. (Jẹ́n. 3:9-13) Lẹ́yìn ìyẹn ló wá dájọ́ fáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yẹn. (Jẹ́n. 3:14-19) Tó bá pa wọ́n lójú ẹsẹ̀ níbẹ̀, a jẹ́ pé ohun tó ní lọ́kàn fún Ádámù àti Éfà àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn já sásán nìyẹn. (Aísá. 55:11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dájọ́ ikú fún wọn, tí wọ́n sì di ẹlẹ́ṣẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ọlọ́run ṣì gba Ádámù àti Éfà láyè láti bí àwọn ọmọ tí wọ́n lè jàǹfààní nínú àwọn ohun míì tí Ọlọ́run máa ṣe. Nítorí náà, lójú Ọlọ́run, Ádámù àti Éfà kú lọ́jọ́ tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀. Bó sì ṣe rí nìyẹn lóòótọ́, torí wọ́n kú láàárín ẹgbẹ̀rún ọdún kan tó ṣàpẹẹrẹ “ọjọ́” kan lójú Ọlọ́run.—2 Pét. 3:8.

8, 9. Báwo ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

8 Ǹjẹ́ ohun tí Ádámù àti Éfà ṣe máa ní ipa lórí àwọn ọmọ wọn? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìwé Róòmù 5:12 sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” Ébẹ́lì ọkùnrin olóòótọ́ ló kọ́kọ́ kú. (Jẹ́n. 4:8) Lẹ́yìn náà, àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù yòókù ń darúgbó, wọ́n sì ń kú. Ṣé àwọn náà jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ni? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:19) Torí náà, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù di ọ̀tá tí kò ṣeé tù lójú, agbára ẹ̀dá aláìpé kò sì ká a. Lóòótọ́ a ò lè sọ ní pàtó gbogbo ohun tó jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ ran àwọn ọmọ Ádámù títí tó fi mọ́ àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀, ohun tó ṣáà dájú ni pé wọ́n jogún ẹ̀ṣẹ̀.

9 Ó bá a mu wẹ́kú bí Bíbélì ṣe sọ pé àìpé tá a jogún àti ikú dà bí nǹkan tó “ràgà bo gbogbo ènìyàn, àti ohun híhun tí a hun pọ̀ sórí gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Aísá. 25:7) Gbogbo wa pátá ni àìpé àti ikú ràgà bò mọ́lẹ̀, ó dà bí okùn tó wé mọ́ gbogbo èèyàn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ńṣe ni “gbogbo ènìyàn . . . ń kú nínú Ádámù.” (1 Kọ́r. 15:22) Pọ́ọ̀lù béèrè ìbéèrè kan tó máa fẹ́rẹ̀ẹ́ wà lọ́kàn gbogbo èèyàn, ó ní: “Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?” Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà? *Róòmù 7:24.

Ẹ̀ṢẸ̀ ÀTI IKÚ TÍ ÁDÁMÙ FÀ MÁA DI ASÁN

10. (a) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa sọ ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù di asán? (b) Kí làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn nípa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀?

10 Jèhófà lágbára láti gba Pọ́ọ̀lù sílẹ̀. Ní kété lẹ́yìn tí Aísáyà sọ̀rọ̀ “ìràgàbò,” ó sọ ní ẹsẹ tó tẹ̀ lé e pé: “Òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” (Aísá. 25:8) Bíi bàbá onífẹ̀ẹ́ kan tó yanjú ìṣoro àwọn ọmọ rẹ̀ tó sì nu omijé ojú wọn kúrò, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe fẹ́ sọ ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù di asán! Jésù ni Jèhófà sì máa lò. Ìwé 1 Kọ́ríńtì 15:22 sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.” Bákan náà, lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù béèrè pé “Ta ni yóò gbà mí?” ó sọ síwájú sí i pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:25) Ó ṣe kedere pé bí Ádámù àti Éfà tiẹ̀ ya ọlọ̀tẹ̀, síbẹ̀ ìfẹ́ tó mú kí Jèhófà dá ìran èèyàn kò dín kù. Bákan náà, Jésù  tó wà pẹ̀lú Jèhófà nígbà tó dá tọkọtaya àkọ́kọ́ ò jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní sí àtọmọdọ́mọ wọn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ dín kù. (Òwe 8:30, 31) Àmọ́, báwo ni aráyé ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?

11. Kí ni Jèhófà ṣe láti ran aráyé lọ́wọ́?

11 Àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti ìdájọ́ òdodo Jèhófà ló fa àìpé ẹ̀dá àti ikú. (Róòmù 5:12, 16) Bíbélì sọ pé: “Nípasẹ̀ àṣemáṣe kan ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ ìdálẹ́bi.” (Róòmù 5:18) Kí ni Jèhófà lè ṣe táá fi mú ìdájọ́ ikú tó dá fún Ádámù kúrò síbẹ̀ tí kò ní sọ ìlànà rẹ̀ di ohun tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀? A rí ìdáhùn nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, ó ní: ‘Ọmọ ènìyàn wá kí ó lè fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.’ (Mát. 20:28) Ẹni tó jẹ́ àkọ́bí nínú àwọn áńgẹ́lì Jèhófà mú kó ṣe kedere pé níwọ̀n bí òun ti wá sáyé ní ẹ̀dá èèyàn pípé, òun máa pèsè ìràpadà. Báwo ni ìràpadà yìí ṣe bá ìdájọ́ òdodo Jèhófà mu?—1 Tím. 2:5, 6.

12. Kí ni ìràpadà tó ṣe rẹ́gí tó bá ìdájọ́ òdodo mu?

12 Torí pé ẹni pípé ni Jésù, ó nírú àǹfààní tí Ádámù ní kó tó di pé Ádámù dẹ́ṣẹ̀. Ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá pípé kún ilẹ̀ ayé. Abájọ tí Jésù fi ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn rúbọ torí pé ó ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Baba rẹ̀ àti fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù. Jésù yááfì ìwàláàyè pípé tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí tí Ádámù pàdánù. Lẹ́yìn náà, Jèhófà jí Ọmọ rẹ̀ pa dà sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí. (1 Pét. 3:18) Torí náà, ó bá ìdájọ́ òdodo mu bí Jèhófà ṣe tẹ́wọ́ gba ẹbọ ọkùnrin pípé náà, ìyẹn Jésù, gẹ́gẹ́ bí iye owó téèyàn san tàbí ìràpadà láti fi ra àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù pa dà, kó sì fún wọn ní ìwàláàyè pípé tí Ádámù fi tàfàlà. Ńṣe ni ká kúkú sọ pé Jésù rọ́pò Ádámù. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A tilẹ̀ ti kọ̀wé rẹ̀ bẹ́ẹ̀ pé: ‘Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ di alààyè ọkàn.’ Ádámù ìkẹyìn di ẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè.”—1 Kọ́r. 15:45.

Ébẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn tó kọ́kọ́ kú máa jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. Kí ni “Ádámù ìkẹyìn” máa ṣe fáwọn tó ti kú?

13 Àkókò náà máa dé tí “Ádámù ìkẹyìn” máa di “ẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè” fún gbogbo ẹ̀dá èèyàn. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù ló máa wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. Kí nìdí? Torí pé wọ́n ti gbé láyé tẹ́lẹ̀, àmọ́ wọ́n ti kú. Torí náà, wọ́n máa jíǹde, kí wọ́n lè pa dà máa gbé lórí ilẹ̀ ayé.—Jòh. 5:28, 29.

14. Kí ni Jèhófà ṣe tó máa fòpin sí àìpé tí Ádámù kó ran àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀?

14 Báwo ni aráyé ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ àìpé tó ti ń hàn wọ́n léèmọ̀ tipẹ́tipẹ́? Ìjọba kan ni Jèhófà gbé kalẹ̀ láti ṣe èyí. “Ádámù ìkẹyìn” àti àwọn kan tí Jèhófà yàn nínú aráyé ló máa wà nínú Ìjọba náà. (Ka Ìṣípayá 5:9, 10.) Àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run ti jẹ́ aláìpé nígbà kan rí, torí náà wọ́n mọ bí àìpé ṣe máa ń rí. Ẹgbẹ̀rún ọdún kan gbáko ni wọ́n á fi ran àwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí àìpé tó kọjá agbára wọn.—Ìṣí. 20:6.

15, 16. (a) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, ‘ọ̀tá ìkẹyìn, ìyẹn ikú,’ tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀? Ìgbà wo sì ni yóò di asán? (b) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:28, kí ni Jésù máa ṣe láìpẹ́?

15 Ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Ìjọba Kristi, àwọn ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ onígbọràn yóò ti bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí àìgbọràn Ádámù sọ di ọ̀tá aráyé. Bíbélì sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi [ìyẹn àwọn tó máa bá a ṣàkóso] nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ni òpin,  nígbà tí ó bá fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́, nígbà tí ó bá ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára di asán. Nítorí òun gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́r. 15:22-26) Nígbẹ̀yìn gbẹ́yìn, ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù kò ní sí mọ́. “Ìràgàbò” tó bo gbogbo aráyé mọ́lẹ̀ kò ní sí mọ́ títí láé.—Aísá. 25:7, 8.

16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.” (1 Kọ́r. 15:28) Nípa bẹ́ẹ̀, ìṣàkóso Ọmọ rẹ̀ á ti ṣàṣeparí iṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, inú rẹ̀ yóò dùn láti dá ọlá àṣẹ àti ìràn èèyàn tó ti di pípé pa dà fún Jèhófà.

17. Báwo ni Sátánì ṣe máa jìyà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín?

17 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Sátánì tó dá gbogbo aburú tó ń bá aráyé fínra yìí sílẹ̀? Ìwé Ìṣípayá 20:7-15 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i. Ọlọ́run máa gba Sátánì láyè láti ṣe ìdẹwò ìkẹyìn fún gbogbo ẹ̀dá èèyàn tó ti di pípé. Èṣù àtàwọn tó bá tẹ̀ lé e máa pa run títí láé nígbà “ikú kejì.” (Ìṣí. 21:8) Torí pé àwọn tó bá kó sọ́wọ́ Sátánì kò ní sí mọ́ títí láé, ikú tiwọn kò ní di asán. Torí náà, “ikú kejì” kì í ṣe ọ̀tá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn, tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀.

18. Báwo ni iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún Ádámù ṣe máa di ṣíṣe?

18 Ẹ̀dá èèyàn tó ti di pípé lè wá dúró níwájú Jèhófà torí wọ́n ti yẹ lẹ́ni tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun láìsí ọ̀tá èyíkéyìí níbikíbi. Iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Ádámù yóò ti di ṣíṣe, àmọ́ Ádámù ò ní sí níbẹ̀. Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa kún orí ilẹ̀ ayé. Wọ́n á máa fayọ̀ bójú tó ilẹ̀ ayé àtàwọn ohun abẹ̀mí míì. Ǹjẹ́ ká máa fìgbà gbogbo mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa bó ṣe ń sọ ọ̀tá wa, ìyẹn ikú di asán!

^ ìpínrọ̀ 9 Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sapá láti mọ ohun tó ń fà á táwa èèyàn fi ń darúgbó tá a sì ń kú, àmọ́ ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures sọ nípa ìsapá wọn pé: “Wọ́n gbàgbé pé Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀ ló dájọ́ ikú fún tọkọtaya àkọ́kọ́, ọ̀nà tó sì gbé e gbà kò lè yé ẹ̀dá láéláé.”—Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 247.