Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín

Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín

“Ó yẹ kí o mọ ìrísí agbo ẹran rẹ ní àmọ̀dunjú.”—ÒWE 27:23.

1, 2. (a) Kí ni díẹ̀ lára ojúṣe àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà ní Ísírẹ́lì? (b) Kí nìdí tá a fi lè fi àwọn òbí wé olùṣọ́ àgùntàn?

IṢẸ́ àṣekára làwọn olùṣọ́ àgùntàn ní Ísírẹ́lì àtijọ́ máa ń ṣe. Yàtọ̀ sí oòrùn àti òtútù tí wọ́n ní láti fara dà, wọ́n tún gbọ́dọ̀ dáàbò bo agbo wọn lọ́wọ́ ẹranko àti èèyàn tó lè fẹ́ ṣe wọ́n ní jàǹbá. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń yẹ àwọn àgùntàn wọn wò déédéé, wọ́n á sì tọ́jú àwọn tó ń ṣàìsàn àti àwọn tó fara pa. Wọ́n máa ń fún àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ torí ara wọn kò tíì fi bẹ́ẹ̀ le, wọ́n ò sì lágbára bí àgùntàn tó ti dàgbà.—Jẹ́n. 33:13.

2 Láwọn ọ̀nà kan, àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni dà bí olùṣọ́ àgùntàn, torí wọ́n láwọn ìwà tó máa jẹ́ kí wọ́n lè tọ́jú àgùntàn. Ojúṣe wọn ni láti tọ́ àwọn ọmọ wọn “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Ǹjẹ́ iṣẹ́ yìí rọrùn? Kò rọrùn o! Ìdí ni pé, gbogbo ìgbà ni Sátánì ń fínná mọ́ àwọn ọmọdé pẹ̀lú àwọn èrò ẹ̀tàn tó ń gbé kiri. Yàtọ̀ síyẹn, ẹran ara aláìpé tún wà níbẹ̀ tó ń bá wọn fínra. (2 Tím. 2:22; 1 Jòh. 2:16) Tó o bá ní àwọn ọmọ, báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ohun mẹ́ta tó o lè ṣe tí wàá fi dà bí olùṣọ́ àgùntàn fún àwọn  ọmọ rẹ. O gbọ́dọ̀ mọ̀ wọ́n, kó o máa bọ́ wọn, kó o sì máa tọ́ wọn sọ́nà.

MỌ ÀWỌN ỌMỌ RẸ

3. Báwo làwọn òbí ṣe lè “mọ ìrísí” àwọn ọmọ wọn?

3 Olùsọ́ àgùntàn tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ máa ń wo àwọn àgùntàn rẹ̀ fínnífínní kó lè rí i dájú pé ara wọ́n dá ṣáṣá. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó yẹ kó o máa ṣe ohun kan náà fáwọn ọmọ rẹ. Bíbélì sọ pé: “Mọ ìrísí agbo ẹran rẹ ní àmọ̀dunjú.” (Òwe 27:23) Ó gba pé kó o mọ ìwà àwọn ọmọ rẹ, ohun tí wọ́n ń rò àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ọ̀kan lára ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ tó o lè gbà ṣe é ni pé kí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ jọ máa sọ̀rọ̀ déédéé.

4, 5. (a) Àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ wo làwọn òbí lè tẹ̀ lé tó máa mú kó rọrùn fáwọn ọmọ láti máa sọ tinú wọn? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí lo ti ṣe tó mú kó rọrùn fún àwọn ọmọ rẹ láti máa sọ tinú wọn fún ẹ?

4 Àwọn òbí kan ti kíyè sí i pé kò rọrùn fáwọn láti ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn tó ti di ọ̀dọ́. Àwọn ọmọ náà lè máa lọ́tìkọ̀ láti sọ èrò wọn àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Kí lo lè ṣe tí ọmọ tìẹ náà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀? Má fipá mú ọmọ rẹ jókòó kó o wá máa rọ̀jò ọ̀rọ̀ lé e lórí fún àkókò gígùn, kàkà bẹ́ẹ̀, gbìyànjú láti lo àwọn àǹfààní míì tó bá ṣí sílẹ̀ láti bá a sọ̀rọ̀. (Diu. 6:6, 7) Ó lè gba pé kó o túbọ̀ sapá kẹ́ ẹ lè jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè jọ ṣeré jáde, kí ẹ jọ ṣe eré ìdárayá tàbí kí ẹ jọ ṣe iṣẹ́ ilé pa pọ̀. Táwọn òbí bá ń bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ nírú àwọn ìgbà tí wọ́n jọ wà pa pọ̀ yìí, ó máa ń mú káwọn ọmọ túra ká kí wọ́n sì sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.

5 Tí ọmọ rẹ bá ń lọ́ tìkọ̀ láti sọ̀rọ̀ ńkọ́? Nǹkan míì wà tó o tún lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin rẹ pé “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí lónìí? tàbí “Kí lo ṣe lónìí?” Ìwọ ni kó o sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ àti ohun tí o ṣe lọ́jọ́ náà. Ìyẹn lè jẹ́ kí ara tu ọmọ rẹ kó sì sọ ohun tí òun náà ṣe lọ́jọ́ náà fún ẹ. Tí o bá sì fẹ́ béèrè èrò rẹ̀ nípa ọ̀ràn kan, o lè bi í pé, “Ǹjẹ́ o ti rí i káwọn èèyàn ṣe irú nǹkan báyìí rí?” Má ṣe bí i pé, “Ǹjẹ́ o ti ṣe báyìí rí?” O lè bi í pé kí lèrò ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan nípa ọ̀rọ̀ yìí. Lẹ́yìn náà, o lè ní kó sọ ìmọ̀ràn tó máa fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.

6. Báwo làwọn òbí ṣe lè ráyè fún àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́?

6 Má gbàgbé pé kí àwọn ọmọ rẹ lè sọ tinú wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i pé o ráyè fún àwọn àti pé o ṣeé sún mọ́. Táwọn ọmọ bá kíyè sí i pé gbogbo ìgbà ni ọwọ́ òbí àwọn máa ń dí, tí wọn kì í lè bá òbí wọn sọ̀rọ̀, ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ náà má sọ ìṣòro wọn jáde. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ rí ẹ bí ẹni tó ṣeé sún mọ́? Èyí kì í ṣe ọ̀ràn káwọn òbí kàn máa sọ fáwọn ọmọ wọn pé, “Kò sígbà tó ò lè bá mi sọ̀rọ̀.” Ó yẹ kó hàn sáwọn ọmọ rẹ pé o ò ní kóyán ìṣòro wọn kéré, o ò sì ní gbaná jẹ. Ọ̀pọ̀ òbí ń ṣe dáadáa lórí kókó yìí. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Kayla sọ pé: “Kò sí ohun tó wà lọ́kàn mi tí mi ò lè sọ fún dádì mi, wọn kì í dá ọ̀rọ̀ mọ́ mi lẹ́nu tàbí kí wọ́n yára dá mi lẹ́bi, ńṣe ni wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí mi. Ìmọ̀ràn tó dára jù lọ ni wọ́n sì máa ń fún mi.”

7. (a) Táwọn òbí bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́sọ́nà, ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà sọ ọ́? (b) Báwo làwọn òbí ṣe lè mú àwọn ọmọ wọn bínú láìfura?

7 Tó bá tiẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́ ni ẹ̀ ń sọ, irú bíi níní àfẹ́sọ́nà, kí lẹ lè ṣe? Ẹ kíyè sára kó má lọ jẹ́ pé ìkìlọ̀ nìkan ni ọ̀rọ̀ yín máa dá lé. Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín bó ṣe yẹ kí wọ́n bójú tó ọ̀ràn ìfẹ́sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o lọ sí ilé oúnjẹ kan, o wá rí i pé níbi tí wọ́n máa ń kọ oríṣiríṣi oúnjẹ tí wọ́n ní sí, jàǹbá tí oúnjẹ onímájèlé máa ń ṣe fúnni nìkan ni wọ́n kọ síbẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó o kúrò nílé oúnjẹ yẹn, kó o lọ sí ilé oúnjẹ míì tí wàá ti jẹun. Ó lè jẹ́ ohun táwọn ọmọ rẹ máa ṣe náà nìyẹn tó bá jẹ́ pé ìkìlọ̀ tó lágbára lo máa ń fún wọn ṣáá tí wọ́n bá ti wá fọ̀rọ̀ lọ̀ ẹ́. (Ka Kólósè 3:21.)  Ohun tó dáa ni pé kó o ronú lórí ọ̀nà tó o lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́, lẹ́sẹ̀ kan náà, kó o fún wọn ní ìkìlọ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Emily sọ pé: “Àwọn òbí mi kì í sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́sọ́nà bíi pé nǹkan tí kò dára ni. Wọ́n máa ń tẹnu mọ́ ayọ̀ téèyàn máa ń ní tó bá ní àfẹ́sọ́nà tí wọ́n sì jọ ṣègbéyàwó. Èyí máa ń mú kára tù mí láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́sọ́nà, kódà mo ti pinnu pé mi ò nì fẹ́ ẹnikẹ́ni lẹ́yìn wọn.”

8, 9. (a) Àǹfààní wo ló wà níbẹ̀ tó o bá ń tẹ́tí sí àwọn ọmọ rẹ láì dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu? (b) Àṣeyọrí wo lo ti ṣe bó o ṣe ń tẹ́tí sáwọn ọmọ rẹ?

8 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Kayla sọ nípa àwọn òbí rẹ̀, o lè fi hàn pé o ṣeé sún mọ́ tó o bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí àwọn ọmọ rẹ. (Ka Jákọ́bù 1:19.) Òbí anìkàntọ́mọ kan tó ń jẹ́ Katia sọ pé, “Nígbà kan sẹ́yìn, mi ò ṣe sùúrù fún ọmọbìnrin mi rara. Mi ò kì í fún un láyè kó sọ tọkàn rẹ̀ fún mi. Nínú kí n sọ pé ó rẹ̀ mí, tàbí kí n máà tiẹ̀ fẹ́ kó dà mí láàmú. Ní báyìí tí mo ti yí ìwà mi pa dà, ọmọ mi náà ti yí pa dà. Ó máa ń wù ú láti sọ ohun tó bá wà lọ́kàn rẹ̀ fún mi báyìí.”

Máa tẹ́tí sí wọn kó o lè mọ̀ wọ́n (Wo ìpínrọ̀ 3 sí 9)

9 Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí bàbá kan tó ń jẹ́ Ronald tóun náà ní ọmọbìnrin kan. Ronald sọ pé: “Inú kọ́kọ́ bí mi gan-an nígbà tó sọ fún mi pé òun ń fẹ́ ọmọkùnrin kan níléèwé. Àmọ́ nígbà tí mo ronú lórí bí Jèhófà ṣe máa ń mú sùúrù fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti bó ṣe máa ń fòye bá wọn lò, mo wò ó pé ohun tó máa dáa ni pé kí n fún ọmọbìnrin mi láyè láti sọ tọkàn rẹ̀ kó tó di pé màá tọ́ ọ sọ́nà. Inú mi dùn pé mo jẹ́ kó sọ tọkàn rẹ̀! Fún ìgbà àkọ́kọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ yé mi. Nígbà tó sọ tọkàn rẹ̀ tán, ó rọrùn fún mi láti bá a sọ̀rọ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Ó yà mí lẹ́nu pé ó fayọ̀ gba ìmọ̀ràn mi. Ó sì ṣèlérí fún mi tọkàntọkàn pé òun máa yí ìwà òun pa dà.” Tí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ bá ń sọ̀rọ̀ déédéé, á jẹ́ kó o lè mọ ohun tí wọ́n ń rò àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Ìyẹn sì máa jẹ́ kó o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú àwọn ìpinnu tí wọ́n bá ń ṣe nígbèésí ayé wọn. *

MÁA BỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ

10, 11. Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa sú lọ?

10 Olùṣọ́ àgùntàn rere mọ̀ pé èyíkéyìí nínú àwọn àgùntàn rẹ̀ ló lè ṣáko lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé koríko tí àgùntàn kan rí lọ́ọ̀ọ́kán ló lọ jẹ, ibi tó ti ń jẹ ìyẹn lá tún rí òmíràn tó jìnnà díẹ̀, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ á rìn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ àwọn yòókù. Lọ́nà kan  náà, ọmọ kan lè máa sú lọ díẹ̀díẹ̀ sọ́nà tó lè ṣàkóbá fún un nípa tẹ̀mí, ohun tó sì lè fa ìdẹwò fún un ni ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ tàbí eré ìnàjú tó ń sọni di ẹlẹ́gbin tó kúnnú ayé. (Òwe 13:20) Báwo lo ṣe lè dènà irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kó má ṣẹlẹ̀?

11 Tó o bá ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ, gbé ìgbésẹ̀ kíá tó o bá kíyè sí àwọn ohun tó lè fẹ́ kó bá ìgbàgbọ́ wọn. Àwọn ọmọ rẹ lè ní àwọn ìwà Kristẹni kan, àmọ́ ó lè gba pé kó o ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa fi ṣèwà hù. (2 Pét. 1:5-8) Ìgbà ìjọsìn ìdílé tẹ́ ẹ̀ ń ṣe déédéé ló dáa jù lọ láti ṣe èyí. Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù October, ọdún 2008 sọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn ìdílé, ó ní: “A gba àwọn olórí ìdílé níyànjú láti máa ṣe ojúṣe tí Jèhófà gbé lé wọn lọ́wọ́, kí wọ́n rí i pé àwọn ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tó nítumọ̀, tó sì ń lọ déédéé.” Ṣé ò ń lo ìjọsìn ìdílé ní kíkún láti fi bójú tó àwọn ọmọ rẹ? Mọ̀ dájú pé àwọn ọmọ rẹ mọrírì bí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe jẹ ọ́ lógún.—Mát. 5:3; Fílí. 1:10.

Bọ́ wọn dáadáa (Wo ìpínrọ̀ 10 sí 12)

12. (a) Àǹfààní wo làwọn ọ̀dọ́ ti rí nínú ìjọsìn ìdílé tó ń lọ déédéé? (Tún wo àpótí tá a pè ní “ Wọ́n Mọrírì Rẹ̀.”) (b) Ọ̀nà wo lo ti gbà jàǹfààní látinú ìjọsìn ìdílé?

12 Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Carissa sọ bí ìdílé rẹ̀ ṣe jàǹfààní látinú Ìjọsìn Ìdílé. Ó ní: “Inú mi dùn pé gbogbo wa lè jókòó pa pọ̀ ká sì sọ̀rọ̀. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe la túbọ̀ ń mọwọ́ ara wa tá a sì ń ní àwọn àkókò alárinrin tá a lè máa rántí. Dádì mi rí i dájú pé à ń ṣe ìjọsìn ìdílé wa déédéé. Ó wú mi lórí pé wọn ò fọ̀rọ̀ ìjọsìn ìdílé wa ṣeré rárá, ìyẹn sì jẹ́ kí èmi náà fọwọ́ pàtàkì mú un. Ó tún jẹ́ kí n túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún wọn gẹ́gẹ́ bíi bàbá mi àti ẹni tó ń múpò iwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Brittney sọ pé: “Ìjọsìn ìdílé jẹ́ kí èmi àtàwọn òbí mi túbọ̀ sún mọ́ra. Ó jẹ́ kí n mọ̀ pé wọ́n fẹ́ gbọ́ ìṣòro mi àti pé ọ̀rọ̀ mi jẹ wọ́n lógún. Gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ó mú kí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wa, ó sì mú ká ṣe ara wa lọ́kan.” Ó ṣe kedere pé ọ̀nà pàtàkì tó o fi lè jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn rere ni pé kó o máa bọ́ àwọn ọmọ rẹ nípa tẹ̀mí nípasẹ̀ ìjọsìn ìdílé. *

MÁA TỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ SỌ́NÀ

13. Kí ló máa mú kó wu ọmọ kan láti sin Jèhófà?

13 Olùṣọ́ àgùntàn rere máa ń lo ọ̀pá láti fi darí àwọn àgùntàn rẹ̀ àti láti fi dáàbò bò wọ́n. Ọ̀kan pàtàkì lára àfojúsùn rẹ̀ ni láti darí àwọn àgùntàn rẹ̀ lọ sí “pápá ìjẹko tí ó dára.” (Ìsík. 34:13, 14) Ǹjẹ́ kì í ṣe irú àfojúsùn tẹ̀mí tí ìwọ náà ní fáwọn ọmọ rẹ nìyí? O fẹ́ tọ́ àwọn ọmọ rẹ sọ́nà kí wọ́n lè máa sin Jèhófà. O fẹ́ káwọn ọmọ rẹ náà lè sọ bíi ti onísáàmù kan tó sọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” (Sm. 40:8) Àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n nírú ìmọrírì bẹ́ẹ̀ máa ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n á sì ṣèrìbọmi. Àmọ́ o, ìgbà tí òtítọ́ bá ti jinlẹ̀ nínú wọn tó sì wù wọ́n látọkànwá láti sin Jèhófà ló yẹ kí wọ́n ṣe irú ìpinnu yẹn.

14, 15. (a) Kí ló yẹ kó jẹ́ àfojúsùn àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni? (b) Kí ló lè mú kí ọ̀dọ́ kan máa ṣiyèméjì nípa ìsìn tòótọ́?

14 Àmọ́ tó bá ẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ rẹ kò tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ fara mọ́ ohun tí wọ́n gbà gbọ́, kí lo lè ṣe? Ńṣe ni kó o sapá láti tẹ ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run mọ́ wọn lọ́kàn, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọrírì gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe. (Ìṣí. 4:11) Tí wọ́n bá wá dàgbà tó láti ṣèpinnu, wọ́n á lè pinnu fúnra wọn láti sin Ọlọ́run.

15 Táwọn ọmọ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì ńkọ́? Báwo lo ṣe lè tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n lè rí i pé kéèyàn sin Jèhófà ni ìgbé ayé tó dára jù lọ àti pé ó máa jẹ́ kí wọ́n ní ayọ̀ tó wà pẹ́ títí? Gbìyànjú láti mọ ohun tó fà á tí wọ́n fi ń ṣiyè méjì. Bí àpẹẹrẹ, ṣé  ọmọkùnrin rẹ kọ̀ jálẹ̀ pé òun ò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ni àbí kò kàn ní ìgboyà débi táá fi lè sọ ohun tó gbà gbọ́ lójú àwọn ojúgbà rẹ̀? Ṣé kò tíì dá ọmọbìnrin rẹ lójú pé ó bọ́gbọ́n mu láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà tàbí ṣe ni ó ń wò ó pé òun dá wà tàbí pé àwọn ọ̀rẹ́ òun pa òun tì?

Tọ́ wọn sọ́nà (Wo ìpínrọ̀ 13 sí 18)

16, 17. Àwọn ọ̀nà wo làwọn òbí lè gbà mú káwọn ọmọ wọn sọ òtítọ́ di tara wọn?

16 Ohun yòówù kó fa iyèméjì, o lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè fa gbogbo iyèméjì tó lè wà lọ́kàn rẹ̀ tu dà nù. Lọ́nà wo? Àbá kan táwọn òbí ti rí i pé ó wúlò tó sì gbéṣẹ́ ni pé kí wọ́n gbìyànjú láti mọ ohun tó wà lọ́kàn ọmọ wọn, wọ́n lè béèrè pé: “Ṣó o rò pé ó dáa kéèyàn jẹ́ Kristẹni? Àwọn àǹfààní wo lo rò pé ó wà níbẹ̀? Àwọn nǹkan wo lo gbọ́dọ̀ yááfì láti jẹ́ Kristẹni? Kí lèrò rẹ nípa àwọn àǹfààní tá à ń gbádùn nísinsìnyí àti èyí tí Ọlọ́run ṣèlérí pé a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú? Ǹjẹ́ o gbà pé àwọn àǹfààní náà ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan tó o máa yááfì lọ?” Àmọ́ ṣá o, ńṣe ni kó o béèrè irú àwọn ìbéèrè yìí lọ́nà pẹ̀lẹ́, jẹ́ kó lárinrin, kó dà bí ìgbà tẹ́ ẹ̀ ń fi ọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀, má ṣe jẹ́ kó dà bíi pé ṣe lò ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò. Nínú ìjíròrò yín, o lè sọ̀rọ̀ lórí Máàkù 10:29, 30. Àwọn ọ̀dọ́ kan lè fẹ́ kọ èrò wọn sílẹ̀ sórí ìwé, wọ́n lè pín in sí ọ̀nà méjì, kí apá àkọ́kọ́ jẹ́ ohun tí wọ́n máa yááfì, kí apá kejì sì jẹ́ àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀. Tí wọ́n bá rí ohun tí wọ́n kọ sórí ìwé, ó lè jẹ́ kí wọ́n rí ohun tó jẹ́ ìṣòro, á sì jẹ́ kí wọ́n wá ojútùú sí àwọn ìṣòro náà. Tó bá ṣe pàtàkì pé ká lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni àti ìwé Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́runláti fi kọ́ àwọn tó fẹ́ mọ̀ nípa Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́, ǹjẹ́ kò yẹ ká máa fi kọ́ àwọn ọmọ tiwa náà? Ṣé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀?

17 Bópẹ́ bóyá, àwọn ọmọ rẹ ní láti pinnu fúnra wọn ẹni tí wọ́n máa sìn. Má kàn rò pé wẹ́rẹ́ ni wọ́n máa fara mọ́ ẹ̀sìn rẹ. Wọ́n gbọ́dọ̀ sọ òtítọ́ di tara wọn. (Òwe 3:1, 2) Tó o bá rí i pé ó ṣòro fún ọmọ rẹ kan láti ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn ohun tó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ mọ̀. Ràn án lọ́wọ́ kó lè ronú lórí àwọn ìbéèrè bíi: “Báwo ni mo ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run wà? Kí ló mú kó dá mi lójú pé Jèhófà Ọlọ́run kò fọ̀rọ̀ mi ṣeré rárá? Kí nìdí tí mo fi gbà pé àǹfààní mi làwọn ìlànà Jèhófà wà fún?” Tó o bá ń fi sùúrù tọ́ àwọn ọmọ rẹ sọ́nà kí wọ́n lè gbà pé kò sí ohun tó dára tó kéèyàn fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Jèhófà, wàá fi hàn pé o dà bí olùṣọ́ àgùntàn rere fún àwọn ọmọ rẹ. *Róòmù 12:2.

18. Báwo làwọn òbí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn Gíga Jù Lọ?

18 Gbogbo Kristẹni tòótọ́ ló fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Olùṣọ́ Àgùntàn Gíga Jù Lọ. (Éfé. 5:1; 1 Pét. 2:25) Ní pàtàkì, àwọn òbí gbọ́dọ̀ mọ ìrísí agbo wọn, ìyẹn àwọn ọmọ tí Jèhófà fún wọn, kí wọ́n sì sa gbogbo ipá wọn láti tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n lè gba ìbùkún tí Jèhófà fẹ́ fún wọn. Nítorí náà, gbogbo ohun tó bá gbà ni kí ẹ ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ yín, kí ẹ sì máa bá a nìṣó láti tọ́ wọn lọ́nà òtítọ́!

^ ìpínrọ̀ 9 Tó o bá fẹ́ àbá síwájú sí i, wo Ilé Ìṣọ́, August 1, 2008, ojú ìwé 10 sí 12.

^ ìpínrọ̀ 12 Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ́ náà “Ìjọsìn Ìdílé Ṣe Pàtàkì fún Ìgbàlà Ìdílé Wa!” nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 2009, ojú ìwé 29 sí 31.

^ ìpínrọ̀ 17 Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo Ilé Ìṣọ́ February 1, 2012, ojú ìwé 18 sí 21.