Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  August 2014

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Jésù sọ fún àwọn Sadusí pé àwọn tó jíǹde “kì í gbéyàwó, bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi wọ́n fúnni nínú ìgbéyàwó.” (Lúùkù 20:34-36) Ṣé àjíǹde orí ilẹ̀ ayé ló ń sọ?

Ìbéèrè pàtàkì ni ìbéèrè yìí, pàápàá fún àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn ti kú. Ó lè wu irú àwọn bẹ́ẹ̀ pé kí àwọn ṣì wà pa pọ̀ bíi tọkọtaya nígbà tí ọkọ tàbí aya wọn bá jíǹde nínú ayé tuntun. Ọkùnrin kan tí ìyàwó rẹ̀ ti kú sọ pé: “Èmi àti ìyàwó mi ò ṣàdéhùn pé ká fòpin sí ìgbéyàwó wa. Ohun tó wù wá ni pé ká máa sin Jèhófà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya títí láé. Bó sì ṣe rí lọ́kàn mi dòní nìyẹn, kò yí pa dà.” Ǹjẹ́ ìdí tó ṣe pàtàkì wà tá a fi lè ní ìrètí pé àwọn tó jíǹde máa lè pa dà fẹ́ ara wọn? Kókó ibẹ̀ ni pé, a ò lè sọ.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àlàyé tá a ṣe nínú àwọn ìwé wa ni pé, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa àjíǹde àti ìgbéyàwó tọ́ka sí àjíǹde orí ilẹ̀ ayé àti pé àwọn tó máa jíǹde sínú ayé tuntun kò ní ṣègbéyàwó. * (Mát. 22:29, 30; Máàkù 12:24, 25; Lúùkù 20:34-36) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, a ò lè sọ pàtó bọ́rọ̀ yìí á ṣe rí, àmọ́ ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àjíǹde ti ọ̀run ni Jésù ń tọ́ka sí? Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Jésù sọ yẹ̀ wò.

Jẹ́ ká wo ohun tó mú kí Jésù sọ ọ̀rọ̀ yẹn. (Ka Lúùkù 20:27-33.) Àwọn Sadusí wá béèrè ìbéèrè nípa àjíǹde àti ṣíṣú opó * lọ́wọ́ Jésù, àmọ́ ṣe ni wọ́n kàn fẹ́ dẹkùn mú un torí wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde. Jésù dá wọn lóhùn pé: “Àwọn ọmọ ètò àwọn nǹkan yìí a máa gbéyàwó, a sì máa ń fi wọ́n fúnni nínú ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n àwọn tí a ti kà yẹ fún jíjèrè ètò àwọn nǹkan yẹn àti àjíǹde láti inú òkú kì í gbéyàwó, bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi wọ́n fúnni nínú ìgbéyàwó. Ní ti tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè kú mọ́, nítorí wọ́n dà bí àwọn áńgẹ́lì, ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n nípa jíjẹ́ àwọn ọmọ àjíǹde.”—Lúùkù 20:34-36.

Kí nìdí tá a fi sọ nínú àwọn ìwé wa sẹ́yìn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àjíǹde ti ilẹ̀ ayé ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Ìdí pàtàkì méjì ló jẹ́ ká rò bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́ ni pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àjíǹde ti ilẹ̀ ayé ni àwọn Sadusí yẹn ní lọ́kàn, Jésù sì dá wọn lóhùn ìbéèrè wọn ní tààràtà. Ìdí kejì sì ni pé, nígbà tí Jésù máa kádìí ìdáhùn tó fún wọn, ó tọ́ka sí àwọn baba ńlá ìgbàanì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé, àwọn bí Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.—Lúùkù 20:37, 38.

Àmọ́, ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àjíǹde ti òkè ọ̀run ni Jésù ní lọ́kàn. Kí ló mú ká rò bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò gbólóhùn pàtàkì méjì yìí.

“Àwọn tí a ti kà yẹ fún jíjèrè . . . àjíǹde láti inú òkú.” Ọlọ́run ka àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró “yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.” (2 Tẹs. 1:5, 11) Ó polongo wọn ní olódodo fún ìyè lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi, torí náà, kì í ṣe pé wọ́n kú bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tó jẹ̀bi ikú. (Róòmù 5:1, 18; 8:1) A ka àwọn bẹ́ẹ̀ sí “aláyọ̀ àti mímọ́,” wọ́n sì yẹ fún àjíǹde sí ọ̀run. (Ìṣí. 20:5, 6) Àmọ́, “àwọn aláìṣòdodo” wà lára àwọn tó máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣe 24:15) Ǹjẹ́ a lè sọ pé wọ́n jẹ́ àwọn tí a “kà yẹ” fún àjíǹde?

 “Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè kú mọ́.” Jésù kò sọ pé: “Wọn kò kú mọ́.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú mọ́.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì túmọ̀ gbólóhùn yìí sí, “wọn ò sì lábẹ́ ikú mọ́” àti “ikú ò lágbára lórí wọn mọ́.” Ọlọ́run ń jí àwọn ẹni àmì òróró sí òkè ọ̀run, tí wọ́n bá fi ìṣòtítọ́ parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ń fún wọn ní àìleèkú, ìyẹn ìwàláàyè tí kò lópin, tí kò sì ṣeé pa run. (1 Kọ́r. 15:53, 54) Ikú ò lágbára kankan mọ́ lórí àwọn tí wọ́n ní àjíǹde ti òkè ọ̀run. *

Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, kí la wá lè parí èrò sí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tó ní àjíǹde ti ọ̀run ni Jésù ń tọ́ka sí nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde àti ìgbéyàwó. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mọ àwọn nǹkan kan nípa àwọn tó ní àjíǹde ti ọ̀run látinú ọ̀rọ̀ tó sọ. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé wọn kò ní gbéyàwó, wọn kò lè kú àti pé láwọn ọ̀nà kan wọ́n á dà bí àwọn áńgẹ́lì. Àmọ́, tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ọ̀pọ̀ ìbéèrè ṣì wà tó ń fẹ́ ìdáhùn.

Ìbéèrè àkọ́kọ́, kí nìdí tí Jésù fi ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ti ọ̀run nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè àwọn Sadusí, tó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àjíǹde ti ilẹ̀ ayé làwọn Sadusí ní lọ́kàn? Jésù kì í sábà dáhùn ìbéèrè àwọn alátakò rẹ̀ bí wọ́n ṣe lérò pé ó máa dáhùn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn Júù sọ pé kó fún àwọn ní àmì kan, ó sọ pé: “Ẹ wó tẹ́ńpìlì yìí lulẹ̀, ní ọjọ́ mẹ́ta, ṣe ni èmi yóò sì gbé e dìde.” Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti mọ̀ pé tẹ́ńpìlì tí wọ́n ti ń jọ́sìn ni wọ́n rò pé òun ń sọ, “ṣùgbọ́n ó ń sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì ara rẹ̀.” (Jòh. 2:18-21) Jésù lè wò ó pé kò sídìí láti dá àwọn Sadusí alágàbàgebè wọ̀nyẹn lóhùn, torí pé wọn ò nígbàgbọ́ nínú àjíǹde, wọn ò sì gbà pé àwọn áńgẹ́lì wà. (Òwe 23:9; Mát. 7:6; Ìṣe 23:8) Àmọ́, ó lè jẹ́ pé ńṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ fìyẹn ṣí àwọn nǹkan kan payá nípa àjíǹde ti ọ̀run nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, torí pé lọ́jọ́ kan wọ́n máa láǹfààní láti ní irú àjíǹde yìí.

Ìbéèrè kejì, kí nìdí tí Jésù fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àwọn tó máa ní àjíǹde ti orí ilẹ̀ ayé, ìyẹn Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù? (Ka Mátíù 22:31, 32.) Kíyè sí i pé kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa àwọn baba ńlá yìí, ó kọ́kọ́ sọ pé “ní ti àjíǹde àwọn òkú.” Gbólóhùn tí Jésù lò yìí lè mú kí ohun tó máa sọ tẹ̀ lé e yàtọ̀ sí ohun tó ń sọ bọ̀. Lẹ́yìn náà, Jésù wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé tí Mósè kọ, èyí táwọn Sadusí sọ pé àwọn nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Jésù lo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Mósè níbi igbó tó ń jó kó lè fi ṣe àfikún ẹ̀rí tó fi hàn pé àjíǹde ti orí ilẹ̀ ayé jẹ́ ohun tó dájú tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe.—Ẹ́kís. 3:1-6.

Ìbéèrè kẹta, tó bá jẹ́ pé àjíǹde ti ọ̀run ni Jésù ń sọ, ṣé ohun tá a wá ń sọ ni pé àwọn tó bá jíǹde sórí ilẹ̀ ayé máa lè gbéyàwó? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò dáhùn ìbéèrè yìí ní tààràtà. Tó bá jẹ́ pé àjíǹde ti ọ̀run ni Jésù ń sọ, a jẹ́ pé kò sọ ohunkóhun nípa pé àwọn tó bá jíǹde sórí ilẹ̀ ayé máa lè gbéyàwó nínú ayé tuntun.

Ní báyìí ná, a mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ní tààràtà pé ikú fòpin sí ìdè ìgbéyàwó. Torí náà, kò yẹ kí ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú rò pé òun ṣe ohun tí kò dáa tó bá pinnu láti fẹ́ ẹlòmíì. Ìpinnu ara ẹni ni, ẹnikẹ́ni ò sì gbọ́dọ̀ dá irú àwọn bẹ́ẹ̀ lẹ́bi tí wọ́n bá pinnu láti ní alábàákẹ́gbẹ́ míì.—Róòmù 7:2, 3; 1 Kọ́r. 7:39.

Ó bọ́gbọ́n mu pé a lè ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú ayé tuntun. Dípò ká kàn máa méfò nípa ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn, ńṣe ni ka ní sùúrù dìgbà yẹn. Àmọ́, ohun kan dá wa lójú: Àwọn onígbọràn máa láyọ̀, torí pé Jèhófà máa fún wọn ní gbogbo nǹkan tí wọ́n nílò àtèyí tí ọkàn wọ́n ń fẹ́ lọ́nà tó máa tẹ́ wọn lọ́rùn.—Sm. 145:16.

^ ìpínrọ̀ 4 Wo Ilé Ìṣọ́, June 1, 1987, ojú ìwé 30 sí 31.

^ ìpínrọ̀ 5 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n máa ń ṣú opó, ìyẹn ni kí ọkùnrin kan fẹ́ ìyàwó ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ̀ tó kú láìní ọmọkùnrin. Ọmọ tí ìyàwó náà bá bí á máa jẹ́ orúkọ ẹni tó kú náà kí ìdílé rẹ̀ má bàa pa run.—Jẹ́n. 38:8; Diu. 25:5, 6.

^ ìpínrọ̀ 9 Àwọn tó bá jíǹde sí ilẹ̀ ayé máa ní ìrètí láti gba ìyè àìnípẹ̀kun, kì í ṣe àìleèkú. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín àìleèkú àti ìyè àìnípẹ̀kun, lọ wo Ilé Ìṣọ́, April 1, 1984, ojú ìwé 30 sí 31.